Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni

Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni

“Jèhófà, . . . òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ.”​—SM. 119:​159, 160.

ORIN: 29, 53

1, 2. (a) Iṣẹ́ wo ni Jésù fi sípò àkọ́kọ́, kí sì nìdí? (b) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù wa túbọ̀ méso jáde?

IṢẸ́ káfíńtà ni Jésù kọ́ láti kékeré, nígbà tó yá, ó di òjíṣẹ́ tó ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Máàkù 6:3; Róòmù 15:8) Jésù mọ iṣẹ́ méjèèjì yìí dunjú. Nígbà tí Jésù ń ṣiṣẹ́ káfíńtà, ó kọ́ bó ṣe lè lo onírúurú irinṣẹ́ àti bó ṣe lè fi igi ṣe ohun táwọn èèyàn nílò. Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù, ó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa, ó sì lò ó láti kọ́ àwọn èèyàn débi pé àwọn tí kò mọ̀wé pàápàá lóye òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mát. 7:28; Lúùkù 24:​32, 45) Nígbà tó pé ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún, ó pa iṣẹ́ káfíńtà náà tì torí ó mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù. Òun fúnra ẹ̀ sọ pé ọ̀kan lára ìdí tí Jèhófà fi rán òun wá sáyé ni láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 20:28; Lúùkù 3:23; 4:43) Iṣẹ́ ìwàásù yìí ni Jésù fi sípò àkọ́kọ́ láyé rẹ̀, ó sì gba àwọn míì níyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀.​—Mát. 9:​35-38.

2 Lónìí, a lè má kọ́ṣẹ́ káfíńtà, àmọ́ ó dájú pé gbogbo wa la jẹ́ òjíṣẹ́ tó ń wàásù ìhìn rere. Iṣẹ́ yìí ṣe pàtàkì gan-an torí pé iṣẹ́ Jèhófà ni, kódà Bíbélì pè wá ní “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 3:9; 2 Kọ́r. 6:4) A sì mọ̀ pé “òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run].” (Sm. 119:​159, 160) Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń sapá láti “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́” nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí. (Ka 2 Tímótì 2:15.) Bíbélì ni ìwé tó gbawájú nínú àwọn nǹkan tá à ń lò láti kọ́ni nípa Jèhófà, Jésù àti Ìjọba náà. Torí náà, ó yẹ ká sapá ká lè túbọ̀ di ọ̀jáfáfá nínú bá a ṣe ń lo Bíbélì. Ìdí nìyẹn tí ètò Ọlọ́run fi pèsè àwọn irinṣẹ́ míì tó yẹ ká kọ́ bá a ṣe máa lò kí iṣẹ́ ìwàásù wa lè túbọ̀ méso jáde. Àwọn irinṣẹ́ yìí là ń pè ní Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́.

3. Níwọ̀nba àkókò tó kù tá a ní láti jẹ́rìí fáwọn èèyàn, kí ló yẹ kó jẹ wá lọ́kàn? Báwo ni Ìṣe 13:48 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?

3 O lè máa ronú pé, kí nìdí tá a fi pè é ní Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́, tá ò sì pè é ní Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Wàásù. Ìyàtọ̀ wà nínú kéèyàn “kọ́ni” àti kéèyàn “wàásù.” Kéèyàn wàásù túmọ̀ sí pé kó kéde ọ̀rọ̀ kan fáwọn èèyàn. Àmọ́, kéèyàn kọ́ni gba pé kó ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà kó lè wọ ẹnì kan lọ́kàn dáadáa débi pé ẹni náà á ṣiṣẹ́ lórí ohun tó gbọ́. Níwọ̀nba àkókò tó kù tá a ní láti jẹ́rìí fáwọn èèyàn, ohun tó yẹ kó jẹ wá lọ́kàn ni bá a ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Èyí gba pé ká sapá láti wá àwọn tó ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun,” ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di onígbàgbọ́.​—Ka Ìṣe 13:​44-48.

4. Báwo la ṣe lè rí àwọn tó ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun”?

4 Báwo la ṣe lè rí àwọn tó ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun”? Bíi ti àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà rí wọn ni pé ká lọ wàásù. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ, ó ní: “Ìlú ńlá tàbí abúlé èyíkéyìí tí ẹ bá wọ̀, ẹ wá ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn.” (Mát. 10:11) A mọ̀ pé àwọn alábòsí, àwọn agbéraga àtàwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè má gbọ́ tiwa. Torí náà, àwọn olóòótọ́, tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tó sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ là ń wá kiri. A lè fi èyí wé ohun tí Jésù máa ń ṣe nígbà tó ń ṣiṣẹ́ káfíńtà. Ó dájú pé tó bá fẹ́ ṣe ilẹ̀kùn, àga tàbí àwọn nǹkan míì, igi tó dáa, tó sì jẹ́ ojúlówó ló máa wá lọ. Tó bá ti rí igi tó dáa, á kó àwọn irinṣẹ́ rẹ̀, á wá lo ọgbọ́n iṣẹ́ tó ní láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ ṣe. Ohun tó yẹ káwa náà ṣe nìyẹn, ká wá àwọn tó ní ọkàn rere ká lè kọ́ wọn ní òtítọ́.​—Mát. 28:​19, 20.

5. Kí ló yẹ ká mọ̀ nípa àwọn irinṣẹ́ tó wà nínú Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́? Ṣàpèjúwe. (Wo àwọn àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

5 A mọ̀ pé irinṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tó wà nínú àpótí káfíńtà ló ní iṣẹ́ tó ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó wà nínú àpótí irinṣẹ́ tí Jésù lò. * Ó dájú pé á ní irinṣẹ́ tó fi ń sàmì, èyí tó fi ń rẹ́ igi, èyí tó fi ń lu ihò, èyí tó fi ń fá igi, púlọ́ọ̀mù, òòlù àtàwọn irinṣẹ́ míì. Lọ́nà kan náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn irinṣẹ́ tó wà nínú Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ ló ní iṣẹ́ pàtó tí wọ́n ń ṣe. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo inú àpótí irinṣẹ́ wa, ká sì wo àwọn irinṣẹ́ tó wà níbẹ̀ àti bá a ṣe lè lò wọ́n.

ÀWỌN OHUN TÓ Ń JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN MỌ̀ WÁ

6, 7. (a) Ọ̀nà wo lo ti gbà lo àwọn káàdì ìkànnì wa? (b) Iṣẹ́ méjì wo ni ìwé ìkésíni sí ìpàdé wa máa ń ṣe?

6 Káàdì Ìkànnì. Káàdì yìí kéré lóòótọ́, àmọ́ ó gbéṣẹ́ gan-an torí pé ó ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wá, ó sì ń darí wọn lọ sórí ìkànnì wa. Àwọn èèyàn lè mọ púpọ̀ sí i nípa wa tí wọ́n bá lọ sórí ìkànnì jw.org, wọ́n sì lè béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lójoojúmọ́, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèyàn ló ń béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ìkànnì jw.org. Kódà ní báyìí, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400,000) ló ti béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí! Á dáa tíwọ náà bá ń kó káàdì díẹ̀ lọ́wọ́, kó o lè lò ó nígbàkigbà tí àǹfààní láti wàásù bá yọ.

7 Ìwé Ìkésíni. Iṣẹ́ méjì ni ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn sí ìpàdé wa máa ń ṣe. Ìwé ìkésíni náà sọ pé: “A fẹ́ kí o wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ó wá sọ pé o lè kẹ́kọ̀ọ́ “ní ìpàdé tó wà fún gbogbo èèyàn” “tàbí kí ìwọ àti Ẹlẹ́rìí kan jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Yàtọ̀ sí pé ìwé yìí ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wá, ó tún ń rọ àwọn tí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn” pé kí wọ́n wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wa. (Mát. 5:3) Ohun kan ni pé, a máa ń gba àwọn èèyàn tọwọ́tẹsẹ̀ tí wọ́n bá wá sípàdé wa yálà wọ́n gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Tí wọ́n bá sì wá, ó dájú pé wọ́n á rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ látinú Bíbélì.

8. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn èèyàn wá sípàdé wa bó tiẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ̀kan péré? Sọ àpẹẹrẹ kan.

8 Kò yẹ ká jẹ́ kó sú wa láti máa pe àwọn èèyàn wá sípàdé wa bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan péré ni wọ́n lè wá. Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé wọ́n máa rí ìyàtọ̀ gedegbe tó wà láàárín àwọn ìpàdé wa tó ń tuni lára nípa tẹ̀mí àti ìkórajọ àwọn ẹlẹ́sìn tí kò ṣàǹfààní kankan. (Aísá. 65:13) Ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Ray àti Linda lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn. Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ń gbé, wọ́n sì pinnu pé á dáa káwọn bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì torí pé ó wù wọ́n láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí gbogbo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó wà lágbègbè wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Ṣọ́ọ̀ṣì pọ̀ gan-an lágbègbè wọn, torí náà wọ́n pinnu pé ohun méjì làwọn máa wò káwọn tó pinnu ṣọ́ọ̀ṣì táwọn máa dara pọ̀ mọ́. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn gbọ́dọ̀ rí nǹkan kan kọ́ nínú ìwàásù wọn. Ìkejì, ìrísí àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì náà gbọ́dọ̀ jọ ti ọmọlúàbí, kí wọ́n sì dà bí èèyàn Ọlọ́run lóòótọ́. Lẹ́yìn ọdún mélòó kan, wọ́n ti lọ sí gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì tó wà lágbègbè wọn, àmọ́ wọ́n rí i pé àgbá òfìfo lásán ni gbogbo wọn. Wọn ò rí nǹkan kan kọ́ nínú ìwàásù wọn, ìmúra àwọn ọmọ ìjọ wọn ò sì jọ ti ọmọlúàbí. Lẹ́yìn tí wọ́n jáde nínú ṣọ́ọ̀ṣì tó kẹ́yìn, Linda gba ibiṣẹ́ rẹ̀ lọ, Ray sì pa dà sílé. Bí Ray ṣe ń wakọ̀ pa dà sílé ló rí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, ó wá ronú pé, ‘Ẹ jẹ́ kí n tiẹ̀ wo nǹkan táwọn eléyìí ń ṣe níbí.’ Àmọ́ ohun tó rí níbẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó rí láwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó kù. Gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ló múra dáadáa, ojú wọn fani mọ́ra, ara wọn sì yọ̀ mọ́ọ̀yàn. Iwájú pátápátá ni Ray jókòó sí, ó sì gbádùn ohun tó kọ́ nípàdé náà! Ṣe lọ̀rọ̀ ẹ̀ dà bíi ti ẹni tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ó wá sí ìpàdé Kristẹni nígbà àkọ́kọ́, tó sì sọ pé: “Ọlọ́run wà láàárín yín ní ti tòótọ́.” (1 Kọ́r. 14:​23-25) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, kì í pa ìpàdé ọjọ́ Sunday jẹ, kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí gbogbo ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀. Nígbà tó yá, ìyàwó rẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjèèjì ti lé lẹ́ni àádọ́rin (70) ọdún, wọ́n gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ṣèrìbọmi.

ÀWỌN OHUN TÁ A LÈ FI BẸ̀RẸ̀ ÌJÍRÒRÒ

9, 10. (a) Kí ló mú kí àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà rọrùn láti lò? (b) Ṣàlàyé bá a ṣe lè lo ìwé àṣàrò kúkúrú náà Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

9 Ìwé Àṣàrò Kúkúrú. A ní àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú mẹ́jọ tó rọrùn láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Látìgbà tá a sì ti mú wọn jáde lọ́dún 2013, ẹ̀dà tí ó tó bílíọ̀nù márùn-ún la ti tẹ̀ jáde! Ohun tó mú káwọn ìwé yìí rọrùn láti lò ni pé téèyàn bá ti mọ bó ṣe lè lo ọ̀kan, àtilo àwọn tó kù kò ní ṣòro rárá torí pé bákan náà la ṣe ṣe gbogbo ẹ̀. Báwo lo ṣe lè fi àwọn ìwé yìí bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò?

10 Báwo lo ṣe lè lo ìwé àṣàrò kúkúrú tí àkòrí ẹ̀ sọ pé Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? O lè kọ́kọ́ fi ìbéèrè tó wà níwájú ìwé náà han ẹni náà, kó o wá bi í pé: “Ǹjẹ́ ẹ ti fìgbà kan ronú nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́?” Lẹ́yìn náà, ní kó mú èyí tó rò pé ó jẹ́ òótọ́ nínú àwọn ìdáhùn mẹ́ta tó wà nísàlẹ̀. Dípò tí wàá fi sọ bóyá ó gbà á tàbí kò gbà á, ṣí i sí apá “Ohun Tí Bíbélì Sọ” tó wà láàárín ìwé náà, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò Dáníẹ́lì 2:44 àti Aísáyà 9:6 tí wọ́n tọ́ka sí níbẹ̀. Tó bá ṣeé ṣe, máa bá ìjíròrò náà lọ. Tó o bá ti fẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ, o lè bi í ní ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé náà, lábẹ́ “Rò Ó Wò Ná,” ìyẹn “Báwo ni ìgbésí ayé ṣe máa rí nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso?” Kó o sì sọ fún un pé ìbéèrè yẹn lẹ máa jíròrò nígbà míì tẹ́ ẹ bá ríra. Nígbà tó o bá pa dà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, o lè tọ́ka sí ẹ̀kọ́ 7 nínú ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Ìwé yìí sì wà lára àwọn ìwé tá a lè fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

ÀWỌN OHUN TÓ Ń JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN NÍGBÀGBỌ́ NÍNÚ BÍBÉLÌ

11. Iṣẹ́ wo làwọn ìwé ìròyìn wa ń ṣe, àmọ́ kí ló yẹ ká mọ̀ nípa wọn?

11 Ìwé Ìròyìn. Kárí ayé, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ni ìwé ìròyìn tí wọ́n tú sí èdè tó pọ̀ jù lọ, àwọn sì ni wọ́n tíì tẹ̀ jáde jù lọ lágbàáyé! Torí pé jákèjádò ayé làwọn èèyàn ti ń ka àwọn ìwé ìròyìn yìí, a máa ń yan àwọn àkòrí tá a mọ̀ pé á fa àwọn èèyàn níbi gbogbo lọ́kàn mọ́ra. Ó yẹ ká lo àwọn ìwé ìròyìn yìí láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé. Àmọ́ ká tó lè lo àwọn ìwé ìròyìn yìí lọ́nà tó gbéṣẹ́, ó yẹ ká mọ àwọn tá a dìídì ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà fún.

12. (a) Àwọn wo la dìídì ṣe ìwé ìròyìn Jí! fún, kí sì nìdí tá a fi ṣe é? (b) Ìrírí wo lo ní nígbà tó o lo ìwé ìròyìn yìí lẹ́nu àìpẹ́ yìí?

12 A dìídì ṣe ìwé ìròyìn Jí! fáwọn tí kò mọ̀ nípa Bíbélì tàbí àwọn tó jẹ́ pé òye díẹ̀ ni wọ́n ní nípa Bíbélì. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè má mọ ohunkóhun nípa ohun táwa Kristẹni gbà gbọ́, wọ́n lè má fọkàn tán ẹ̀sìn kankan tàbí kí wọ́n máa ronú pé Bíbélì ò ṣeni láǹfààní. Ìdí pàtàkì tá a fi ń tẹ ìwé ìròyìn Jí! ni pé káwọn èèyàn lè gbà pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run wà. (Róòmù 1:20; Héb. 11:6) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ni Bíbélì lóòótọ́. (1 Tẹs. 2:13) Àkòrí àwọn Jí! mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti ọdún 2018 ni: “Ohun Tó Ń Fúnni Láyọ̀,” “Ohun Méjìlá Tó Ń Mú Kí Ìdílé Láyọ̀,” àti “Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀.”

13. (a) Àwọn wo la dìídì ṣe Ilé Ìṣọ́ tá à ń fi sóde fún? (b) Ìrírí wo lo ní nígbà tó o lo ìwé ìròyìn yìí lẹ́nu àìpẹ́ yìí?

13 Ìdí pàtàkì tá a fi ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tá à ń fi sóde ni láti ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì fáwọn tó gbà pé Ọlọ́run wà, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń ka Bíbélì, wọn ò lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni dáadáa. (Róòmù 10:2; 1 Tím. 2:​3, 4) Àkòrí àwọn Ilé Ìṣọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fún ọdún 2018 ni: “Ṣé Bíbélì Ṣì Wúlò Lóde Òní?,” “Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú?,” àti “Ṣé Ọlọ́run Bìkítà Nípa Rẹ?

ÀWỌN OHUN TÓ Ń MÚ KÁWỌN ÈÈYÀN KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ

14. (a) Iṣẹ́ wo làwọn fídíò mẹ́rin tó wà nínú Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ ń ṣe? (b) Ìrírí wo lo ní nígbà tó o lo àwọn fídíò yìí?

14 Fídíò. Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn irinṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ làwọn káfíńtà máa ń lò. Àmọ́ lónìí, onírúurú ẹ̀rọ ìgbàlódé làwọn káfíńtà fi ń ṣiṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń lo ayùn tó ń báná ṣiṣẹ́, ẹ̀rọ tó ń lu ihò sára igi, èyí tí wọ́n fi ń fá igi àtàwọn míì. Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tiwa náà rí lónìí. Yàtọ̀ sáwọn ìwé tá à ń lò, a tún ti ní onírúurú fídíò tá a lè lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Mẹ́rin lára àwọn fídíò yìí wà nínú Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́, àwọn sì ni: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?, Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?, Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?, àti Ta Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? A lè lo àwọn fídíò tí kò tó ìṣẹ́jú méjì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá pàdé ẹnì kan, tẹ́ni náà bá sì ráyè, a lè fi àwọn fídíò tó gùn díẹ̀ hàn án. A tún lè lo àwọn tó gùn díẹ̀ nígbà ìpadàbẹ̀wò. Ká sòótọ́, àwọn fídíò yìí gbéṣẹ́ gan-an, ó lè mú káwọn èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n sì wá sáwọn ìpàdé wa.

15. Sọ àwọn ìrírí tó fi hàn pé iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn fídíò wa ń ṣe, pàápàá táwọn èèyàn bá wò ó lédè wọn.

15 Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn fídíò wa ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan pàdé obìnrin kan tó wá láti àgbègbè Micronesia. Arábìnrin náà wá fi fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? hàn án lédè Yapese tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ obìnrin náà. Nígbà tí fídíò náà bẹ̀rẹ̀, obìnrin náà sọ pé: “Ẹ̀n-ẹ́n! Èdè mi rèé kẹ̀! Bí ẹni yìí ṣe ń sọ̀rọ̀ gan-an fi hàn pé àdúgbò mi ló ti wá. Èdè mi gangan ló ń sọ!” Lẹ́yìn ìyẹn, obìnrin náà sọ pé gbogbo ìwé tó wà lédè òun lórí ìkànnì jw.org lòun máa kà, òun á sì wo gbogbo fídíò tó wà níbẹ̀. (Fi wé Ìṣe 2:​8, 11.) Tún wo ìrírí míì. Arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi ìlujá fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? ránṣẹ́ sí ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó ń gbé lórílẹ̀-èdè míì. Lẹ́yìn tó wo fídíò náà, ó fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí arábìnrin náà pa dà, ó sọ pé: “Apá ibi tí wọ́n ti sọ pé ẹni burúkú kan ló ń darí ayé wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Kódà mo ti béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí.” Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa lẹni náà ń gbé!

ÀWỌN OHUN TÁ A FI Ń KỌ́NI NÍ ÒTÍTỌ́

16. Ṣàlàyé ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé pẹlẹbẹ yìí wà fún: (a) Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé. (b) Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! (d) Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

16 Ìwé Pẹlẹbẹ. Tẹ́nì kan ò bá fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà tàbí tí kò sí ìtẹ̀jáde kankan ní èdè rẹ̀, báwo la ṣe lè kọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́? A lè fi ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé kọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀. * Ìwé míì tá a lè fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! O lè fi àwọn ẹ̀kọ́ mẹ́rìnlá tó wà lẹ́yìn ìwé náà han ẹnì kan, kó o wá bi í pé èwo ló máa wù ú kẹ́ ẹ jọ jíròrò. O lè wá fi èyí tó bá yàn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ǹjẹ́ o ti lo àbá yẹn rí nígbà tó o lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò? Ìwé pẹlẹbẹ kẹta tó wà nínú Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ ni Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní? Ìwé yìí máa ń jẹ́ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì túbọ̀ mọ̀ nípa ètò Ọlọ́run. Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè lo ìwé yìí nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wo Ìwé Ìpàdé​—Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni ti March 2017.

17. (a) Iṣẹ́ wo ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ń ṣe? (b) Kí ló yẹ kí gbogbo àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi ṣe, kí sì nìdí?

17 Ìwé Ńlá. Lẹ́yìn tó o bá ti fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìgbàkigbà lo lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ìwé yìí máa jẹ́ kẹ́ni náà túbọ̀ lóye àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì. Tẹ́ ẹ bá ti parí ìwé náà, tó o sì rí i pé ẹni náà ń tẹ̀ síwájú, ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìwé yìí máa jẹ́ kẹ́ni náà mọ bó ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé rẹ̀. Àmọ́, ẹ fi sọ́kàn pé tẹ́ni náà bá ṣèrìbọmi láìparí ìwé méjèèjì, ẹ gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ẹ̀ ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ títí tó fi máa parí àwọn ìwé náà. Èyí á jẹ́ kó lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú òtítọ́.​—Ka Kólósè 2:​6, 7.

18. (a) Bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́, kí ni 1 Tímótì 4:16 rọ̀ wá pé ká ṣe, kí nìyẹn sì máa yọrí sí? (b) Bá a ṣe ń lo Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́, kí ló yẹ kó máa jẹ wá lọ́kàn?

18 Jèhófà ti fún àwa Ẹlẹ́rìí rẹ̀ láǹfààní láti máa kéde “òtítọ́ ìhìn rere” táá jẹ́ káwọn èèyàn rí ìyè àìnípẹ̀kun. (Kól. 1:5; ka 1 Tímótì 4:16.) Ká lè ṣe iṣẹ́ yìí yọrí, ètò Ọlọ́run ti fún wa ní ohun tá a nílò gẹ́lẹ́, ìyẹn Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́. (Wo “ Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́.”) Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ kọ́ bá a ṣe lè máa lo àwọn irinṣẹ́ yìí lọ́nà tó já fáfá. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu ìwé tó máa lò tó bá pàdé ẹnì kan. Àmọ́ kì í ṣe bá a ṣe máa fún àwọn èèyàn láwọn ìtẹ̀jáde wa ló jẹ wá lógún, kò sì yẹ ká fún àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa láwọn ìtẹ̀jáde wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa sọ àwọn tó ní “ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” di ọmọlẹ́yìn, ìyẹn àwọn olóòótọ́, tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tó sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.​—Ìṣe 13:48; Mát. 28:​19, 20.

^ ìpínrọ̀ 5 Wo àpilẹ̀kọ náà, “Káfíńtà” àti àpótí náà “Irinṣẹ́ Tó Wà Nínú Àpótí Káfíńtà” nínú Ilé Ìṣọ́ August 1, 2010.

^ ìpínrọ̀ 16 Tí ẹni náà ò bá lè kàwé rárá, o lè fún un ní ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run torí pé àwòrán ló pọ̀ jù níbẹ̀, kó o wá sọ pé kó máa fojú bá a lọ.