Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Sọ Òtítọ́

Máa Sọ Òtítọ́

“Ẹ bá ara yín sọ òtítọ́ lẹ́nì kìíní-kejì.”​—SEK. 8:16.

ORIN: 56, 124

1, 2. Kí lohun tó tíì burú jù tó ṣọṣẹ́ fọ́mọ aráyé, ta ló sì wà nídìí rẹ̀?

ÀWỌN nǹkan kan wà táwọn èèyàn ṣe tó ti mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn. Lára wọn ni tẹlifóònù, gílóòbù, mọ́tò àti fìríìjì. Àmọ́ àwọn nǹkan míì wà táwọn èèyàn ṣe tó ti mú kí nǹkan túbọ̀ burú sí i, lára wọn ni ẹ̀tù ìbọn, sìgá, àdó olóró àti bọ́ǹbù runlérùnnà. Ṣùgbọ́n, ohun kan ti wà ṣáájú àwọn ohun tá a mẹ́nu bà yìí tó ti ṣọṣẹ́ burúkú fọ́mọ aráyé. Kí ni nǹkan ọ̀hún? Irọ́ pípa ni! Kéèyàn parọ́ túmọ̀ sí pé kéèyàn sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ kó lè tan àwọn míì jẹ. Ta ló kọ́kọ́ pa irọ́? “Èṣù” ni, kódà Jésù Kristi pè é ní “baba irọ́.” (Ka Jòhánù 8:44.) Ìgbà wo ló parọ́ àkọ́kọ́?

2 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni Èṣù pa irọ́ àkọ́kọ́ nínú ọgbà Édẹ́nì. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, Ádámù àti Éfà ń gbádùn nínú Párádísè tí Ẹlẹ́dàá fi wọ́n sí. Bí Èṣù ṣe wọlé dé wẹ́rẹ́ nìyẹn. Ó kúkú mọ̀ pé Ọlọ́run ti pàṣẹ fún tọkọtaya yẹn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ lára “igi ìmọ̀ rere àti búburú,” pé tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n máa kú. Síbẹ̀, Sátánì lo ejò láti bá Éfà sọ̀rọ̀, ó ní: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú [irọ́ àkọ́kọ́ rèé]. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.”​—Jẹ́n. 2:​15-17; 3:​1-5.

3. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé irọ́ burúkú ni Sátánì pa, kí ni irọ́ náà sì fà fọ́mọ aráyé?

3 Irọ́ burúkú ni Sátánì pa yìí torí ó mọ̀ dáadáa pé tí Éfà bá jẹ èso náà, ó máa kú. Ó bani nínú jẹ́ pé Éfà àti Ádámù rú òfin Ọlọ́run, àìgbọràn yìí ló sì ṣekú pa wọ́n. (Jẹ́n. 3:6; 5:5) Àmọ́ àwọn nìkan kọ́ ló jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yìí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yẹn ló mú kí ‘ikú tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.’ Kì í ṣèyẹn nìkan, òun ló mú kí “ikú ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba . . . , àní lórí àwọn tí kò dẹ́ṣẹ̀ ní ìfarajọ ìrélànàkọjá Ádámù.” (Róòmù 5:​12, 14) Ìdí nìyẹn tá ò fi gbádùn ìlera tó pé, tá ò sì wà láàyè títí láé bí Ọlọ́run ṣe ní lọ́kàn látìbẹ̀rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, agbára káká lèèyàn fi ń lo àádọ́rin (70) ọdún, “àkànṣe agbára ńlá” sì ni téèyàn bá lè lo ọgọ́rin (80) ọdún. Síbẹ̀, ìgbésí ayé ọ̀hún kún fún “ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́.” (Sm. 90:10) Ẹ ò rí i pé àdánù gbáà lèyí, irọ́ tí Sátánì pa lọ́jọ́ kìíní àná ló sì fà á!

4. (a) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn? (b) Bí Sáàmù 15:​1, 2 ṣe sọ, ta ló lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà?

4 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa Sátánì, ó sọ pé: ‘Kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, nítorí pé òtítọ́ kò sí nínú rẹ̀.’ Títí di báyìí, òtítọ́ ò sí nínú Sátánì torí pé ó ṣì ń parọ́ kó lè “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣí. 12:9) Ó dájú pé a ò ní fẹ́ kí Èṣù fi irọ́ tú wa jẹ. Kíyẹn má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa, a máa jíròrò àwọn ìbéèrè mẹ́ta yìí: Báwo ni Sátánì ṣe ń tan àwọn èèyàn jẹ? Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń parọ́? Báwo la ṣe lè máa “sọ òtítọ́” nígbà gbogbo ká má bàa pàdánù ojú rere Jèhófà bíi ti Ádámù àti Éfà?​—Ka Sáàmù 15:​1, 2.

BÍ SÁTÁNÌ ṢE Ń ṢI ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́NÀ

5. Báwo ni Sátánì ṣe ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà lónìí?

5 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé tá a bá wà lójúfò, Sátánì ò ní lè fi “ọgbọ́n àyínìke borí wa, nítorí àwa kò ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn rẹ̀.” (2 Kọ́r. 2:11) A mọ̀ pé gbogbo ayé ló wà lábẹ́ agbára Sátánì, lára ayé tí Sátánì sì ń ṣàkóso ni ẹ̀sìn èké, àwọn jẹgúdújẹrá olóṣèlú, àtàwọn oníṣòwò oníjẹkújẹ. (1 Jòh. 5:19) Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ lè mú káwọn tó wà nípò àṣẹ máa “purọ́.” (1 Tím. 4:​1, 2) Bí àpẹẹrẹ, àwọn oníṣòwò kan máa ń parọ́ tí wọ́n bá ń polówó ọjà wọn kí wọ́n ṣáà lè gba tọwọ́ àwọn èèyàn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọjà ọ̀hún lè jẹ́ gbàrọgùdù tàbí kó tiẹ̀ ṣàkóbá fáwọn èèyàn.

6, 7. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé irọ́ tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń pa ló burú jù? (b) Àwọn irọ́ wo lo ti gbọ́ lẹ́nu àwọn ẹlẹ́sìn?

6 Irọ́ táwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń pa ló burú jù torí ẹni tó bá gbà wọ́n gbọ́ lè pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹnì kan bá gba àwọn ẹ̀kọ́ èké gbọ́ tó sì ń ṣe àwọn ohun tí Ọlọ́run kórìíra, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun. (Hós. 4:9) Jésù mọ̀ pé onírọ́ burúkú làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé rẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi sọ ọ́ kò wọ́n lójú pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! nítorí pé ẹ̀yin a máa la òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ kọjá láti sọ ẹnì kan di aláwọ̀ṣe, nígbà tí ó bá sì di ọ̀kan, ẹ̀yin a sọ ọ́ di olùdojúkọ ewu Gẹ̀hẹ́nà [ìyẹn ìparun ayérayé] ní ìlọ́po méjì ju ara yín lọ.” (Mát. 23:15) Dẹndẹ ọ̀rọ̀ ni Jésù fi bá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn wí. Kódà Jésù sọ fún wọn pé, ‘àti ọ̀dọ̀ Èṣù baba wọn tó jẹ́ apànìyàn’ ni wọ́n ti wá.​—Jòh. 8:44.

7 Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn pọ̀ lọ jàra nínú ayé lónìí. Wọ́n lè máa pè wọ́n ní pásítọ̀, àlùfáà, rábì, wòlíì tàbí àwọn orúkọ oyè míì. Bíi tàwọn aṣáájú ẹ̀sìn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, wọ́n ń “tẹ òtítọ́” tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “rì,” wọ́n sì ń “fi irọ́ ṣe pàṣípààrọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.” (Róòmù 1:​18, 25) Lára àwọn ẹ̀kọ́ èké tí wọ́n ń gbé lárugẹ ni ẹ̀kọ́ àtúnwáyé, “ìgbàlà lẹ́ẹ̀kan, ìgbàlà gbogbo ìgbà,” àti pé ọkàn èèyàn kì í kú. Wọ́n tún ń kọ́ni pé Ọlọ́run ò ní bínú tí ọkùnrin àti ọkùnrin bá fẹ́ ara wọn tàbí tí obìnrin àti obìnrin bá fẹ́ ara wọn.

8. Irọ́ wo làwọn olóṣèlú máa tó pa láìpẹ́, kí ló sì yẹ ká ṣe?

8 Àwọn olóṣèlú náà máa ń fi irọ́ tan àwọn èèyàn jẹ. Irọ́ kàbìtì kan tí wọ́n ṣì máa pa fáwọn èèyàn lọ́jọ́ iwájú ni pé ọwọ́ àwọn ti tẹ “àlàáfíà àti ààbò!” Ṣùgbọ́n, “ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn.” Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká gba àwọn olóṣèlú yìí gbọ́ tí wọ́n bá ń sọ pé ká fọkàn balẹ̀, kò séwu mọ́! Ká sòótọ́, a “mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí olè ní òru.”​—1 Tẹs. 5:​1-4.

ÌDÍ TÁWỌN ÈÈYÀN FI Ń PARỌ́

9, 10. (a) Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń parọ́, kí ló sì ti yọrí sí? (b) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa Jèhófà?

9 Tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ohun tuntun kan jáde, kì í pẹ́ táwọn èèyàn níbi gbogbo á fi bẹ̀rẹ̀ sí í rà á, ká tó ṣẹ́jú pẹ́, á ti gbalẹ̀ gbòde. Bí irọ́ náà ṣe jẹ́ nìyẹn. Irọ́ ti gbalẹ̀ gbòde lónìí, àtọmọdé àtàgbà, àtolówó àti mẹ̀kúnnù ló ń parọ́. Àpilẹ̀kọ kan tó sọ̀rọ̀ nípa ìdí táwọn èèyàn fi ń parọ́, ìyẹn “Why We Lie” látọwọ́ Y. Bhattacharjee, sọ pé: “Irọ́ pípa ti di bárakú fáwọn èèyàn.” Àwọn èèyàn sábà máa ń parọ́ kí wọ́n lè dáàbò bo ara wọn tàbí kí wọ́n lè gbé ara wọn ga lójú àwọn míì. Ó sì lè jẹ́ torí kí wọ́n má bàa jìyà ìwàkíwà tí wọ́n hù tàbí kí wọ́n lè jẹ èrè tabua nídìí iṣẹ́ wọn. Àpilẹ̀kọ náà tún sọ pé: “Irọ́ rọ àwọn kan lọ́rùn débi pé kò sírú irọ́ tí wọn ò lè pa, kò sì sẹ́ni tí wọn ò lè parọ́ fún, yálà ẹni náà jẹ́ àjèjì, ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, ọ̀rẹ́ wọn tàbí èèyàn wọn.”

10 Kí ni irọ́ táwọn èèyàn ń pa yìí máa ń yọrí sí? Lákọ̀ọ́kọ́, kì í jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán ara wọn mọ́, ó sì máa ń ba àjọṣe àárín àwọn èèyàn jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo bó ṣe máa rí lára ọkọ kan tó ń finú kan bá ìyàwó rẹ̀ lò àmọ́ tó wá mọ̀ pé ìyàwó rẹ̀ lójú míì síta, ó sì tún ń parọ́ kó lè bo ìwàkiwà náà. Nígbà míì sì rèé, ọkọ kan lè máa sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀ tí wọ́n bá wà nílé. Àmọ́ tí wọ́n bá dé ìta, á máa díbọ́n bí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ìdílé rẹ̀ káwọn èèyàn lè rò pé èèyàn dáadáa ni. Ká fi sọ́kàn pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè tan àwọn èèyàn jẹ, àmọ́ kò sóhun tó bò lójú Jèhófà torí pé “ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu” ní ojú rẹ̀.​—Héb. 4:13.

11. Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Ananíà àti Sáfírà ṣe? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

11 Bí àpẹẹrẹ, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, Bíbélì sọ bí ‘Sátánì ṣe ki tọkọtaya kan láyà’ débi tí wọ́n fi parọ́ fún Ọlọ́run. Ananíà àti Sáfírà gbìmọ̀ pọ̀ láti tan àwọn àpọ́sítélì jẹ. Wọ́n ta ohun ìní wọn, wọ́n sì kó apá kan lára owó náà wá fáwọn àpọ́sítélì. Ananíà àti Sáfírà fẹ́ káwọn ará ìjọ máa fojú pàtàkì wò wọ́n, wọ́n wá parọ́ pé gbogbo owó tí wọ́n ta ohun ìní wọn làwọn kó wá pátápátá. Síbẹ̀, Jèhófà rí ohun tí wọ́n ṣe, ó sì fìyà tó tọ́ jẹ wọ́n.​—Ìṣe 5:​1-10.

12. Kí ni Jèhófà máa ṣe fáwọn òpùrọ́ tí kò bá ronú pìwà dà, kí sì nìdí?

12 Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó bá ń parọ́? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì àti gbogbo àwọn òpùrọ́ tí kò bá ronú pìwà dà ni Jèhófà máa fi sọ̀kò sínú “adágún iná.” (Ìṣí. 20:10; 21:8; Sm. 5:6) Kí nìdí? Ìdí ni pé ojú kan náà ni Jèhófà fi ń wo ẹni tó ń parọ́ àtẹni tó ń hu àwọn ìwà burúkú míì tó kórìíra tẹ̀gbin-tẹ̀gbin.​—Ìṣí. 22:15.

13. Kí la mọ̀ nípa Jèhófà, kí ló yẹ kí ohun tá a mọ̀ yìí mú ká máa ṣe?

13 A mọ̀ pé Jèhófà “kì í ṣe ènìyàn tí yóò fi purọ́.” Kódà, Bíbélì fi dá wa lójú pé, “kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.” (Núm. 23:19; Héb. 6:18) Yàtọ̀ síyẹn, “Jèhófà kórìíra . . . ahọ́n èké.” (Òwe 6:​16, 17) Ká fi sọ́kàn pé ká tó lè rí ojú rere rẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo. Torí náà, a kì í “purọ́ fún ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì.”​—Kól. 3:9.

A MÁA Ń “SỌ ÒTÍTỌ́”

14. (a) Kí ló mú ká yàtọ̀ sí àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn èké? (b) Ṣàlàyé ìlànà tó wà nínú Lúùkù 6:45.

14 Ọ̀nà wo làwa Kristẹni tòótọ́ máa ń gbà fi hàn pé a yàtọ̀ sáwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn èké? Ọ̀nà kan ni pé a máa ń “sọ òtítọ́.” (Ka Sekaráyà 8:​16, 17.) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “A ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run, . . . nípa ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Kọ́r. 6:​4, 7) Jésù náà sọ nípa àwa èèyàn pé: ‘Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.’ (Lúùkù 6:45) Torí náà, òótọ́ ọ̀rọ̀ lẹni rere máa ń sọ nígbà gbogbo. Kì í parọ́ fún ẹnikẹ́ni, ẹni náà ì báà jẹ́ àjèjì, ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, ọ̀rẹ́ rẹ̀ tàbí èèyàn rẹ̀ pàápàá. Ẹ jẹ́ ká wo onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.

Ìṣòro wo ni ọ̀dọ́bìnrin yìí ní? (Wo ìpínrọ̀ 15 àti 16)

15. (a) Kí nìdí tí kò fi dáa kéèyàn máa ṣojú ayé? (b) Kí ló lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ tí wọn ò fi ní hùwàkiwà táwọn ẹgbẹ́ wọn ń hù? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

15 Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, o lè fẹ́ káwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ẹgbẹ́ gba tìẹ. Kò yẹ kó o ṣe bíi tàwọn ọ̀dọ́ kan tó máa ń ṣojú ayé. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n á máa ṣe dáadáa lójú àwọn òbí wọn àti lójú àwọn ará ìjọ, àmọ́ ìwà wọn kì í jọ ti ọmọlúàbí tí wọ́n bá wà pẹ̀lú àwọn èèyàn ayé, ohun tí wọ́n sì ń gbé sórí ìkànnì àjọlò kò jọ ti ìránṣẹ́ Jèhófà. Irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ lè máa sọ̀rọ̀kọ́rọ̀, kí wọ́n máa wọ aṣọkáṣọ, kí wọ́n sì máa gbọ́ orinkórin. Wọ́n tiẹ̀ lè máa lo oògùn olóró, kí wọ́n máa fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́ tàbí kí wọ́n máa hu àwọn ìwàkiwà míì tí kò yẹ ọmọlúàbí. Wọ́n rò pé àwọn lè tan àwọn òbí wọn àtàwọn ará ìjọ, káwọn sì tún tan Jèhófà. (Sm. 26:​4, 5) Àmọ́, ara wọn ni wọ́n ń tàn, torí pé Jèhófà mọ̀ tẹ́nì kan bá kàn ń ‘fi ètè lásán bọlá fún un, ṣùgbọ́n tí ọkàn rẹ̀ jìnnà réré sí i.’ (Máàkù 7:6) Ó máa dáa ká fi ìmọ̀ràn Bíbélì sọ́kàn pé: “Má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ ṣe ìlara àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n kí o bẹ̀rù Jèhófà láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”​—Òwe 23:17. *

16. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn kọ ohun tó jẹ́ òótọ́ sínú fọ́ọ̀mù téèyàn bá fẹ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí?

16 Tó o bá fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà déédéé tàbí tó o bá fẹ́ lọ́wọ́ nínú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún míì, irú bí iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, wàá ní láti kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù kan. Ó ṣe pàtàkì kí gbogbo ìdáhùn rẹ jẹ́ òótọ́. O kò gbọ́dọ̀ fi ohunkóhun pa mọ́ nípa ìlera rẹ, eré ìnàjú tó o yàn láàyò tó fi mọ́ ìwà àìtọ́ tó ṣeé ṣe kó o ti hù sẹ́yìn. (Héb. 13:18) Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ti lọ́wọ́ nínú àwọn ìwà àìmọ́ kan rí táwọn alàgbà ò sì tíì mọ̀ nípa rẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe? Sọ fún àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́, ìyẹn á jẹ́ kó o ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ bó o ṣe ń sin Jèhófà.​—Róòmù 9:1; Gál. 6:1.

17. Kí ló yẹ ká ṣe táwọn alátakò bá ń béèrè ìbéèrè nípa àwọn ará lọ́wọ́ wa?

17 Ká sọ pé àwọn aláṣẹ fòfin de iṣẹ́ wa lágbègbè tá à ń gbé, tí wọ́n sì ń béèrè ìsọfúnni nípa àwọn ará lọ́wọ́ rẹ, kí ló yẹ kó o ṣe? Ṣé gbogbo ohun tí wọ́n bá béèrè nípa àwọn ará ló yẹ kó o dáhùn? Kí ni Jésù ṣe nígbà tí gómìnà ará Róòmù ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò? Nígbà míì, Jésù kì í sọ ohunkóhun, ṣe ló máa ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó sọ pé: “Ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníw. 3:​1, 7; Mát. 27:​11-14) Táwa náà bá wà nírú ipò bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká lo ìfòyemọ̀ ká má bàa kó àwọn ará wa sí wàhálà.​—Òwe 10:19; 11:12.

Kí ló máa pinnu ìgbà tó yẹ kó o dákẹ́ àti ìgbà tó yẹ kó o sọ òkodoro òtítọ́? (Wo ìpínrọ̀ 15 àti 16)

18. Kí ló yẹ ká ṣe táwọn alàgbà bá ń bi wá nípa àwọn ará wa?

18 Ká sọ pé ẹnì kan nínú ìjọ dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tó o sì mọ̀ nípa rẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe? Ojúṣe àwọn alàgbà ni láti jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́, torí náà wọ́n lè béèrè ohun tó o mọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́ni náà dá. Kí lo máa ṣe, pàápàá tó bá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ lẹni náà? Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ń gbé ìṣòtítọ́ yọ a máa sọ ohun tí í ṣe òdodo.” (Òwe 12:17; 21:28) Torí náà, o gbọ́dọ̀ sọ gbogbo ohun tó o mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà fáwọn alàgbà, má ṣe ṣẹ́ ọ̀rọ̀ kù, má sì da ojú ọ̀rọ̀ rú. Ìdí ni pé, ó yẹ káwọn alàgbà mọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.​—Ják. 5:​14, 15.

19. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

19 Dáfídì gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Ìwọ ní inú dídùn sí òtítọ́ ní ìhà inú.” (Sm. 51:6) Dáfídì mọ̀ pé téèyàn bá máa sọ òtítọ́, àtinú ọkàn lọ́hùn-ún ló ti máa ń wá. Torí náà, gbogbo ìgbà làwa Kristẹni tòótọ́ máa ń ‘bá ara wa sọ òtítọ́ lẹ́nì kìíní-kejì.’ Ohun míì tó mú ká yàtọ̀ sáwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn èké ni bá a ṣe ń fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

^ ìpínrọ̀ 15 Wo orí 15 nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì. Àkòrí ẹ̀ ni “Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Í Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Mi Kó Ìwà Tí Ò Dáa Ràn Mí?,” àti orí 16 tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “Ta Ló Yẹ Kí N Sọ Fún Bí Mo Bá Ń Yọ́ Ìwà Tí Kò Tọ́ Hù?