ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 44
Ṣé Wọ́n Máa Sin Jèhófà Tí Wọ́n Bá Dàgbà?
“Ọgbọ́n Jésù wá ń pọ̀ sí i, ó ń dàgbà sí i, ó sì ń rí ojúure Ọlọ́run àti èèyàn.”—LÚÙKÙ 2:52.
ORIN 134 Ọmọ Jẹ́ Ohun Ìní Tí Ọlọ́run Fi Síkàáwọ́ Òbí
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Ìpinnu tó dáa jù wo lẹnì kan lè ṣe?
LỌ́PỌ̀ ìgbà, ìpinnu táwọn òbí bá ṣe máa ń nípa lórí àwọn ọmọ wọn jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Táwọn òbí bá ṣe ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu, ó lè fa ìṣòro fáwọn ọmọ wọn. Àmọ́ tí wọ́n bá ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, wọ́n á mú kó ṣeé ṣe fáwọn ọmọ wọn láti yan ìgbésí ayé tó dáa jù. Kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, àwọn ọmọ náà gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Ìpinnu tó dáa jù tẹ́nì kan lè ṣe ni pé kó sin Jèhófà Baba wa ọ̀run.—Sm. 73:28.
2. Ìpinnu tó dáa wo ni Jésù àtàwọn òbí ẹ̀ ṣe?
2 Ohun táwọn òbí Jésù fẹ́ ni pé káwọn ọmọ wọn sin Jèhófà, àwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe sì fi hàn bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 2:40, 41, 52) Jésù náà ṣe àwọn ìpinnu tó jẹ́ kó lè ṣe àwọn ohun tí Jèhófà tìtorí ẹ̀ rán an wá sáyé. (Mát. 4:1-10) Bí Jésù ṣe ń dàgbà, ó fi hàn pé òun jẹ́ onínúure, adúróṣinṣin àti onígboyà. Irú ọmọ àmúyangàn bẹ́ẹ̀ làwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sì máa fẹ́ láti ní.
3. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí: Àwọn ìpinnu wo ni Jèhófà ṣe nípa Jésù? Kí làwọn òbí lè kọ́ látinú ìpinnu tí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe? Bákan náà, kí làwọn ọ̀dọ́ lè kọ́ látinú àwọn ìpinnu tí Jésù ṣe?
Ẹ KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ ÀPẸẸRẸ JÈHÓFÀ
4. Ìpinnu pàtàkì wo ni Jèhófà ṣe nípa Jésù?
4 Àwọn òbí tó dáa jù ni Jèhófà yàn fún Jésù. (Mát. 1:18-23; Lúùkù 1:26-38) Àwọn ọ̀rọ̀ àtọkànwá tí Màríà sọ nínú Bíbélì jẹ́ ká rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an. (Lúùkù 1:46-55) Bákan náà, bí Jósẹ́fù ṣe ṣègbọràn sí ìtọ́ni Jèhófà fi hàn pé ó bẹ̀rù Jèhófà, ó sì fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú ẹ̀ dùn.—Mát. 1:24.
5-6. Kí ni Jèhófà jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí Ọmọ rẹ̀?
5 Ẹ kíyè sí i pé kì í ṣe àwọn òbí tó lówó ni Jèhófà yàn pé kó bí Jésù. Àwọn ohun tí Jósẹ́fù àti Màríà fi rúbọ lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù fi hàn pé tálákà ni wọ́n. (Lúùkù 2:24) Ó ṣeé ṣe kí Jósẹ́fù ní ṣọ́ọ̀bù kékeré kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé rẹ̀ níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ káfíńtà. Kò sí àní-àní pé wọn ò gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ, torí nígbà tó yá, àwọn ọmọ wọn tó méje tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.—Mát. 13:55, 56.
6 Àwọn ìgbà kan wà tí Jèhófà dáàbò bo ọmọ ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ pa á, àmọ́ kò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro. (Mát. 2:13-15) Bí àpẹẹrẹ, àwọn mọ̀lẹ́bí Jésù kan ò kọ́kọ́ gbà pé òun ni Mèsáyà. Ẹ wo bíyẹn ṣe máa dun Jésù tó. (Máàkù 3:21; Jòh. 7:5) Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí Jésù ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ nígbà tí Jósẹ́fù kú, ó sì dájú pé ìyẹn máa mú kí nǹkan nira fún un. Kódà, ó lè gba pé kó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ tí bàbá ẹ̀ fi sílẹ̀ torí pé òun ni àkọ́bí. (Máàkù 6:3) Bí Jésù ṣe ń dàgbà, ó di dandan pé kó ṣiṣẹ́ kára kó lè gbọ́ bùkátà ìdílé wọn. Torí náà, ó mọ ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn ṣiṣẹ́ kára kó sì rẹ èèyàn tẹnutẹnu.
7. (a) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ káwọn tọkọtaya bi ara wọn? (b) Kí ni Òwe 2:1-6 sọ tó máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn yanjú?
7 Tẹ́ ẹ bá ti ṣègbéyàwó tẹ́ ẹ sì fẹ́ bímọ, ó yẹ kẹ́ ẹ bi ara yín pé: ‘Ṣé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ṣé òtítọ́ sì jinlẹ̀ nínú wa débi tí àá fi lè bójú tó ọmọ tí Jèhófà máa fún wa?’ (Sm. 127:3, 4) Tó o bá sì ti bímọ, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mò ń kọ́ àwọn ọmọ mi pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ kára?’ (Oníw. 3:12, 13) ‘Ṣé mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n lè dáàbò bo àwọn ọmọ mi lọ́wọ́ ewu àti èròkerò tó kúnnú ayé Sátánì yìí?’ (Òwe 22:3) Kò ṣeé ṣe láti gba àwọn ọmọ lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro tí wọ́n máa kojú. Àmọ́ o lè fìfẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń dàgbà láti máa fi ìlànà Ọlọ́run sílò tí wọ́n bá kojú ìṣòro, torí kò sí bí wọn ò ṣe ní níṣòro. (Ka Òwe 2:1-6.) Bí àpẹẹrẹ, bí mọ̀lẹ́bí yín kan bá fi òtítọ́ sílẹ̀, lo Bíbélì láti jẹ́ káwọn ọmọ rẹ mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. (Sm. 31:23) Tó bá sì jẹ́ pé ẹnì kan ló kú, ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa tu àwọn ọmọ rẹ nínú fún wọn, tó sì máa jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀.—2 Kọ́r. 1:3, 4; 2 Tím. 3:16.
Ẹ KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ ÀPẸẸRẸ JÓSẸ́FÙ ÀTI MÀRÍÀ
8. Báwo ni Jósẹ́fù àti Màríà ṣe fi ìlànà tó wà nínú Diutarónómì 6:6, 7 sílò?
8 Jósẹ́fù àti Màríà fi ìlànà Ọlọ́run tọ́ Jésù débi tó fi rí ojúure Ọlọ́run bó ṣe ń dàgbà. (Ka Diutarónómì 6:6, 7.) Jósẹ́fù àti Màríà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, ohun tó sì jẹ wọ́n lógún ni báwọn ọmọ wọn náà ṣe máa nírú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ fún Jèhófà.
9. Àwọn ìpinnu pàtàkì wo ni Jósẹ́fù àti Màríà ṣe?
9 Àwọn nǹkan tẹ̀mí ni Jósẹ́fù àti Màríà máa ń ṣe nínú ìdílé wọn. Ó dájú pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n máa ń lọ sípàdé nínú sínágọ́gù tó wà ní Násárẹ́tì, wọ́n sì máa ń lọ sí àjọyọ̀ Ìrékọjá ní Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún. (Lúùkù 2:41; 4:16) Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa sọ ìtàn àwọn èèyàn Ọlọ́run fún Jésù àtàwọn àbúrò rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń dé àwọn ibi tí Bíbélì mẹ́nu kàn. Báwọn ọmọ wọn ṣe ń pọ̀ sí i, ó ṣeé ṣe kó má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún Jósẹ́fù àti Màríà láti máa ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí déédéé. Àmọ́ torí pé ìjọsìn Jèhófà ló gbawájú láyé wọn, wọn ò jẹ́ kí nǹkan míì gbà wọ́n lọ́kàn.
10. Kí lẹ̀yin òbí lè kọ́ lára Jósẹ́fù àti Màríà?
10 Kí lẹ̀yin òbí tẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lè kọ́ lára Jósẹ́fù àti Màríà? Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kẹ́ ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín lọ́rọ̀ àti níṣe pé ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú. Ẹ fi sọ́kàn pé ẹ̀bùn tó dáa jù tẹ́ ẹ lè fún àwọn ọmọ yín ni pé kẹ́ ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ẹ̀kọ́ pàtàkì míì tẹ́ ẹ lè kọ́ wọn ni pé kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, kí wọ́n máa gbàdúrà déédéé, kí 1 Tím. 6:6) Lóòótọ́, ẹ gbọ́dọ̀ pèsè àwọn ohun tara táwọn ọmọ yín nílò. (1 Tím. 5:8) Àmọ́, ẹ rántí pé àjọṣe tó dáa táwọn ọmọ yín ní pẹ̀lú Jèhófà ló máa mú kí wọ́n la ayé búburú yìí já wọnú ayé tuntun, kì í ṣe àwọn nǹkan tara tẹ́ ẹ pèsè fún wọn. *—Ìsík. 7:19; 1 Tím. 4:8.
wọ́n máa lọ sípàdé déédéé, kí wọ́n sì máa wàásù déédéé. (11. (a) Báwo ni ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Tímótì 6:17-19 ṣe máa ran àwọn òbí tó ń tọ́mọ lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó tọ́? (b) Àwọn nǹkan wo lẹ lè fi ṣe àfojúsùn nínú ìdílé yín, ìbùkún wo lẹ sì máa rí? (Wo àpótí náà “ Àwọn Nǹkan Wo Lẹ Lè Fi Ṣe Àfojúsùn Yín?”)
11 Ẹ wo bí inú wa ṣe máa ń dùn tó bá a ṣe ń rí àwọn òbí tó ń ṣe ìpinnu tó mú kí ìdílé wọn túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà! Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀. Wọ́n máa ń lọ sípàdé àtàwọn àpéjọ déédéé. Wọ́n jọ máa ń lọ sóde ẹ̀rí. Kódà, àwọn ìdílé kan máa ń lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé. Àwọn míì máa ń ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì tàbí kí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ níbi tá a ti ń kọ́ àwọn ilé ètò Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn ìdílé bẹ́ẹ̀ máa ń yááfì, wọ́n sì máa ń kojú àwọn ìṣòro kan. Àmọ́ Jèhófà máa ń bù kún wọn gan-an. (Ka 1 Tímótì 6:17-19.) Ohun tí àwọn ọmọ tí wọ́n tọ́ nínú ìdílé bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe nìyẹn táwọn náà bá dàgbà, wọn kì í sì í kábàámọ̀! *—Òwe 10:22.
Ẹ KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ ÀPẸẸRẸ JÉSÙ
12. Kí ni Jésù ṣe bó ṣe ń dàgbà?
12 Ìgbà gbogbo ni Jèhófà Baba Jésù máa ń ṣèpinnu tó tọ́, àwọn òbí tó tọ́ ọ dàgbà náà sì máa ń ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Àmọ́ bí Jésù ṣe ń dàgbà, ó di dandan kóun náà ṣèpinnu fúnra ẹ̀. (Gál. 6:5) Torí pé èèyàn bíi tiwa ni, òun náà ní òmìnira láti yan ohun tó fẹ́. Ó lè pinnu pé ohun tó wu òun ni òun máa ṣe láìfi ti Jèhófà pè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ lòun máa ṣe. (Jòh. 8:29) Kí làwọn ọ̀dọ́ lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù?
13. Ìpinnu pàtàkì wo ni Jésù ṣe nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́?
13 Àtìgbà tí Jésù ti wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti pinnu pé òun á máa ṣègbọràn sáwọn òbí òun. Kò kọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu rí, kó wá máa ronú pé òun gbọ́n jù wọ́n lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló “ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.” (Lúùkù 2:51) Torí pé Jésù ni àkọ́bí, kò sí àní-àní pé ó fi ọwọ́ gidi mú ojúṣe tó ní. Ó dájú pé ó fojú sí iṣẹ́ tí Jósẹ́fù bàbá rẹ̀ kọ́ ọ kó lè ti ìdílé wọn lẹ́yìn.
14. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé?
Lúùkù 2:8-19, 25-38) Yàtọ̀ sóhun tí àwọn òbí rẹ̀ sọ fún un, Jésù fúnra ẹ̀ fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé? Ohun tó wáyé láàárín òun àtàwọn olùkọ́ tó wà ní Jerúsálẹ́mù ló jẹ́ ká mọ̀. Bíbélì ròyìn pé “ẹnu ń ya gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí òye tó ní àti bó ṣe ń dáhùn.” (Lúùkù 2:46, 47) Kódà, ọmọ ọdún méjìlá (12) péré ni nígbà tó ti dá a lójú pé Jèhófà ni Bàbá òun.—Lúùkù 2:42, 43, 49.
14 Ó ṣeé ṣe káwọn òbí Jésù sọ àwọn nǹkan ìyanu tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bí Jésù fún un àtohun táwọn áńgẹ́lì sọ nípa ẹ̀. (15. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ohun tí Jèhófà fẹ́ lòun ń ṣe?
15 Nígbà tí Jésù mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun ṣe, ó pinnu pé ohun tí òun máa ṣe nìyẹn. (Jòh. 6:38) Ó mọ̀ pé àwọn èèyàn máa kórìíra òun, ìyẹn sì lè má rọrùn fún un. Síbẹ̀, ó pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ lòun máa ṣe. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi ní 29 S.K., ohun tó ṣe pàtàkì sí i jù ni bó ṣe máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà. (Héb. 10:5-7) Kódà nígbà tó ń kú lọ lórí òpó igi oró, kò bọ́hùn.—Jòh. 19:30.
16. Sọ ẹ̀kọ́ tí ẹ̀yin ọmọ lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù.
16 Máa gbọ́ràn sí àwọn òbí ẹ lẹ́nu. Bíi ti Jósẹ́fù àti Màríà, àwọn òbí ẹ náà kì í ṣe ẹni pípé. Síbẹ̀, àwọn òbí ẹ ni Jèhófà yàn pé kí wọ́n máa dáàbò bò ẹ́, kí wọ́n máa dá ẹ lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì máa tọ́ ẹ sọ́nà. Tó o bá ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, tó o sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn, nǹkan “máa lọ dáadáa fún ọ.”—Éfé. 6:1-4.
17. Bó ṣe wà nínú Jóṣúà 24:15, ìpinnu wo lẹ̀yin ọ̀dọ́ gbọ́dọ̀ ṣe fúnra yín?
17 Pinnu ẹni tó o máa sìn. Ìwọ fúnra ẹ gbọ́dọ̀ mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́, ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe àtohun tó fẹ́ kó o fayé ẹ ṣe. (Róòmù 12:2) Ìgbà yẹn ni wàá tó lè ṣèpinnu tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé ẹ, ìyẹn sì ni pé kó o sin Jèhófà. (Ka Jóṣúà 24:15; Oníw. 12:1) Tó o bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, wàá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìgbàgbọ́ ẹ á sì túbọ̀ lágbára.
18. Ìpinnu míì wo lẹ̀yin ọ̀dọ́ gbọ́dọ̀ ṣe, kí sì nìdí?
1 Tím. 6:9, 10) Lọ́wọ́ kejì, tó o bá gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu, tó o sì pinnu pé ìfẹ́ rẹ̀ ni wàá fi sípò àkọ́kọ́ láyé ẹ, wàá ṣàṣeyọrí, wàá sì “máa hùwà ọgbọ́n.”—Jóṣ. 1:8.
18 Pinnu pé ìfẹ́ Jèhófà ni wàá fi sípò àkọ́kọ́ láyé ẹ. Ohun tí ayé Sátánì ń sọ ni pé tó o bá ń lo ẹ̀bùn tó o ní fún àǹfààní ara ẹ, wàá láyọ̀. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé ṣe làwọn tó ń lé nǹkan ìní tara máa ń “fi ìrora tó pọ̀ gún gbogbo ara wọn.” (ÌPINNU WO LẸ MÁA ṢE?
19. Kí ló yẹ kẹ́yin òbí máa fi sọ́kàn?
19 Ẹ̀yin òbí, ẹ ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ bá lè ṣe káwọn ọmọ yín lè sin Jèhófà. Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé e, á sì ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. (Òwe 3:5, 6) Ẹ rántí pé àwọn nǹkan tẹ́ ẹ bá ń ṣe làwọn ọmọ yín máa rántí ju ohun tẹ́ ẹ bá ń sọ fún wọn lọ. Torí náà, ẹ máa ṣe àwọn ìpinnu táá jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn ọmọ yín láti rí ojúure Jèhófà.
20. Ìbùkún wo lẹ̀yin ọ̀dọ́ máa gbádùn tẹ́ ẹ bá pinnu pé Jèhófà lẹ máa sìn?
20 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, òótọ́ ni pé àwọn òbí yín lè ràn yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nígbèésí ayé yín. Àmọ́ ó kù sọ́wọ́ yín tẹ́ ẹ bá máa rí ojúure Jèhófà. Torí náà ẹ fara wé Jésù, kẹ́ ẹ sì pinnu pé Jèhófà Baba yín ọ̀run lẹ máa sìn. Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ní báyìí ìgbésí ayé yín á ládùn á sì lóyin. (1 Tím. 4:16) Tó bá sì dọjọ́ iwájú, ẹ̀ẹ́ gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun, ẹ̀ẹ́ sì láyọ̀ títí láé!
ORIN 133 Sin Jèhófà Nígbà Ọ̀dọ́
^ ìpínrọ̀ 5 Ohun táwọn òbí Kristẹni fẹ́ ni pé káwọn ọmọ wọn máa fayọ̀ sin Jèhófà bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Àwọn ìpinnu wo ló yẹ kí wọ́n ṣe táá jẹ́ káwọn ọmọ wọn lè sin Jèhófà? Àwọn ìpinnu wo ló yẹ káwọn ọmọ ṣe táá jẹ́ kí wọ́n sin Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
^ ìpínrọ̀ 11 Wo àpótí náà “Abiyamọ Gidi Làwọn Òbí Mi” nínú Jí!, October 2011, ojú ìwé 20 àti àpilẹ̀kọ náà “Lẹ́tà Pàtàkì Sáwọn Òbí Wọn” nínú Jí!, July 8, 1999, ojú ìwé 30.
^ ìpínrọ̀ 66 ÀWÒRÁN: Ó dájú pé àtikékeré ni Màríà ti ń kọ́ Jésù pé kó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bíi ti Màríà, ó yẹ kí ẹ̀yin ìyá náà máa kọ́ àwọn ọmọ yín pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.
^ ìpínrọ̀ 68 ÀWÒRÁN: Ó dájú pé inú Jósẹ́fù máa ń dùn láti kó ìdílé ẹ̀ lọ sí sínágọ́gù. Bíi ti Jósẹ́fù, ó yẹ kí inú ẹ̀yin bàbá náà máa dùn láti kó ìdílé yín lọ sípàdé.
^ ìpínrọ̀ 70 ÀWÒRÁN: Jésù kọ́ṣẹ́ ọwọ́ látọ̀dọ̀ bàbá ẹ̀. Bíi ti Jésù, ó yẹ kẹ́yin ọ̀dọ́ náà máa fojú sí iṣẹ́ táwọn bàbá yín bá ń ṣe.