Jẹ́ Kí Àjọṣe Ìwọ àti Jèhófà Pa Dà Gún Régé
LỌ́DỌỌDÚN, ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà tó ronú pìwà dà là ń gbà pa dà sínú ìjọ. “Inú àwọn tó wà ní ọ̀run máa dùn” gan-an tí ẹnì kan bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (Lúùkù 15:7, 10) Tí wọ́n bá ti gbà ẹ́ pa dà sínú ìjọ, mọ̀ dájú pé inú Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì dùn sí ẹ pé o pa dà sínú òtítọ́. Síbẹ̀, bó o ṣe ń sapá láti mú kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà pa dà gún régé, o lè kojú àwọn ìṣòro kan. Àwọn ìṣòro wo ló ṣeé ṣe kó o kojú, kí ló sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?
ÀWỌN ÌṢÒRO WO LO LÈ KOJÚ?
Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n pa dà sínú ìjọ ṣì máa ń ní èrò tí kò tọ́ nípa ara wọn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára Ọba Dáfídì ló rí lára ẹ. Kódà lẹ́yìn tí Jèhófà ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ jì í, ó sọ pé: “Àwọn àṣìṣe mi pọ̀.” (Sm. 40:12; 65:3) Bákan náà lónìí, lẹ́yìn tí ẹnì kan bá ti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ojú ṣì lè máa tì í, kó sì máa dá ara ẹ̀ lẹ́bi fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n yọ Isabelle lẹ́gbẹ́, àmọ́ ó ju ogún (20) ọdún * lọ kó tó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ó sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti gbà pé Jèhófà lè dárí jì mí.” Tó o bá jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì mú ẹ, àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà tún lè má lágbára mọ́. (Òwe 24:10) Torí náà, má ṣe gba ìrẹ̀wẹ̀sì láyè rárá.
Àwọn kan máa ń rò pé ó máa gba ọ̀pọ̀ iṣẹ́ kí àjọṣe àwọn pẹ̀lú Jèhófà tó lè gún régé pa dà. Lẹ́yìn tí wọ́n gba Arákùnrin Antoine pa dà, ó sọ pé: “Ó ń ṣe mí bíi pé mo ti gbàgbé gbogbo ohun tí mo mọ̀ àtohun tí mò ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ìjọsìn Ọlọ́run.” Irú èrò yìí ti jẹ́ káwọn kan fà sẹ́yìn, kò sì jẹ́ kí wọ́n kópa déédéé mọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.
Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ lọ́nà yìí. Ká sọ pé ìjì líle ba ilé ẹnì kan jẹ́. Nǹkan lè tojú sú u tó bá ronú
nípa iṣẹ́ tóun máa ṣe àti àkókò tó máa gba òun láti tún ilé náà ṣe. Bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn tí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tó o dá bá ba àjọṣe ìwọ àti Jèhófà jẹ́. O lè rò pé ó máa gba àkókò àti ìsapá kó o tó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Àmọ́, ìrànlọ́wọ́ wà fún ẹ.Jèhófà rọ̀ wá pé: “Ní báyìí, ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yanjú ọ̀rọ̀ láàárín ara wa.” (Àìsá. 1:18) O ti sapá gan-an láti “yanjú ọ̀rọ̀” tó wà láàárín ìwọ àti Jèhófà, Jèhófà sì mọyì gbogbo ohun tó o ṣe. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ohun tó o ṣe yìí máa jẹ́ kí Jèhófà lè fún Sátánì tó ń pẹ̀gàn rẹ̀ lésì?—Òwe 27:11.
Ohun tó o ṣe yìí fi hàn pé o ti sún mọ́ Jèhófà, òun náà sì ṣèlérí pé òun máa sún mọ́ ẹ. (Jém. 4:8) Àmọ́, ohun tó o máa ṣe kọjá kó o jẹ́ káwọn ará mọ̀ pé o ti pa dà sínú ìjọ. O gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó máa mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà tó jẹ́ Bàbá àti Ọ̀rẹ́ rẹ túbọ̀ jinlẹ̀. Báwo lo ṣe máa ṣe é?
MỌ ÀWỌN OHUN TÓ YẸ KÓ O ṢE LÁTI ṢÀTÚNṢE
Gbìyànjú láti mọ àwọn ibi tó yẹ kó o ti ṣàtúnṣe. Ó dájú pé o ò tíì gbàgbé gbogbo ohun tó o kọ́ nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. Àmọ́, o tún gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o gbọ́dọ̀ máa lọ sípàdé, òde ẹ̀rí, kó o sì máa wà pẹ̀lú àwọn ará. Àwọn nǹkan tó o máa ṣe rèé.
Máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé. Bàbá rẹ ọ̀run mọ̀ pé bí ẹ̀rí ọkàn ẹ ṣe ń dá ẹ lẹ́bi lè mú kó má rọrùn fún ẹ láti gbàdúrà sí òun. (Róòmù 8:26) Síbẹ̀, “máa tẹra mọ́ àdúrà gbígbà,” kó o sì jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé o fẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti òun pa dà gún régé. (Róòmù 12:12) Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Andrej rántí bọ́rọ̀ ṣe rí lára òun. Ó ní: “Ojú tì mí gan-an, mo sì ń dá ara mi lẹ́bi ṣáá. Àmọ́ gbogbo ìgbà tí mo bá ti gbàdúrà lọkàn mi máa ń balẹ̀, tára sì máa ń tù mí pẹ̀sẹ̀.” Tó ò bá mọ ohun tó o máa sọ nínú àdúrà, wo àdúrà ìrònúpìwàdà tí Ọba Dáfídì gbà nínú Sáàmù 51 àti 65.
Máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, ó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á sì jinlẹ̀ sí i. (Sm. 19:7-11) Arákùnrin Felipe sọ pé: “Ohun tó jẹ́ kí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà má lágbára mọ́, tí mo sì já Jèhófà kulẹ̀ ni pé mi ò ní ètò tí mo ṣe láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, mo pinnu láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ torí ìyẹn ló máa ràn mí lọ́wọ́ kí n má bàa tún ṣàṣìṣe.” Ohun tó yẹ kíwọ náà ṣe nìyẹn. Tó o bá fẹ́ mọ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o lè fi ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́, o lè bi ọ̀rẹ́ rẹ kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀.
Jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn ará pa dà gún régé. Ó máa ń ṣe àwọn kan tí wọ́n pa dà sínú ìjọ bíi pé àwọn ará máa fojú burúkú wò wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Larissa sọ pé: “Ojú tì mí gan-an, ó sì ń ṣe mí bíi pé mo ti já àwọn ará kulẹ̀. Ó pẹ́ gan-an kí n tó gbé èrò yìí kúrò lọ́kàn.” Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àwọn alàgbà àtàwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ lè lágbára sí i. (Wo àpótí náà “ Ohun Táwọn Alàgbà Lè Ṣe.”) Inú gbogbo àwọn ará dùn pé o ti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, wọ́n sì fẹ́ kíwọ náà láyọ̀!—Òwe 17:17.
Kí ló lè jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará ìjọ? Máa ṣe gbogbo ohun táwọn ará ń ṣe, máa lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí déédéé. Báwo lèyí ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Arákùnrin Felix sọ pé: “Àwọn ará ti ń retí pé kí n pa dà sínú ìjọ torí pé wọ́n mọyì mi. Wọ́n tún jẹ́ kí n pa dà di ara ìdílé Jèhófà, wọ́n jẹ́ kí n rí i pé ó ti dárí jì mí, wọ́n sì fẹ́ kí n tẹ̀ síwájú.”—Wo àpótí náà “ Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe.”
MÁ ṢE JẸ́ KÓ SÚ Ẹ!
Gbogbo ìgbà tó o bá ń sapá láti mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà pa dà gún régé ni Sátánì á máa kó ọ̀pọ̀ ìṣòro tó dà bí “ìjì líle” bá ọ kó o lè rẹ̀wẹ̀sì. (Lúùkù 4:13) Torí náà, àsìkò yìí gan-an ló yẹ kó o máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára.
Jèhófà sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Màá wá èyí tó sọ nù, màá mú èyí tó rìn lọ pa dà wálé, màá fi aṣọ wé èyí tó fara pa, màá sì tọ́jú èyí tó rẹ̀ kó lè lágbára.” (Ìsík. 34:16) Jèhófà ti ran ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti pa dà ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú rẹ̀. Torí náà, mọ̀ dájú pé Jèhófà fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa ṣe ohun táá jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ lágbára.
^ ìpínrọ̀ 4 A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.