Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwòrán pèpéle àti àkọlé tó wà níbẹ̀

1922—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn

1922—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn

‘ỌLỌ́RUN fi ìṣẹ́gun fún wa nípasẹ̀ Jésù Kristi.’ (1 Kọ́r. 15:57, Bíbélì Mímọ́) Gbólóhùn yìí la fi ṣe ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 1922, ó sì fi àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa san wọ́n lẹ́san tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́. Lọ́dún yẹn, Jèhófà san àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó ń fìtara wàásù lẹ́san. Ọ̀nà tí Jèhófà gbà bù kún wọn ni pé ó jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì fúnra wọn, wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látorí rédíò. Nígbà tó yá lọ́dún 1922 yẹn kan náà, ó tún hàn gbangba pé Jèhófà ń bù kún àwọn èèyàn ẹ̀. Ó jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti kóra jọ síbi àpéjọ mánigbàgbé kan ní Cedar Point, Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àpéjọ yẹn ti jẹ́ kí ètò Ọlọ́run tẹ̀ síwájú látìgbà yẹn títí di báyìí.

“WỌ́N DÁ ÀBÁ KAN TÓ DÁA GAN-AN”

Bí àwọn ará tó ń wàásù ṣe ń pọ̀ sí i, ó gba pé kí wọ́n túbọ̀ tẹ àwọn ìwé tí wọ́n á fi máa wàásù. Àwọn ará tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn ń tẹ ìwé ìròyìn, àmọ́ ilé iṣẹ́ míì níta ló ń bá wọn tẹ ìwé ńlá. Ìgbà kan wà tí ilé iṣẹ́ náà ò lè tẹ iye ìwé ńlá tá a nílò fún oṣù mélòó kan, ìyẹn ò sì jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù tẹ̀ síwájú. Torí náà, Arákùnrin Rutherford bi Arákùnrin Robert Martin tó ń bójú tó ẹ̀ka ìtẹ̀wé ní Bẹ́tẹ́lì pé, ṣé ó máa ṣeé ṣe láti máa tẹ àwọn ìwé ńlá náà nínú Bẹ́tẹ́lì?

Ilé ìtẹ̀wé tó wà ní Concord Street ní Brooklyn, nílùú New York

Ni Arákùnrin Martin bá sọ pé, “àbá tó dáa gan-an nìyẹn o.” Ìyẹn máa gba pé ká ní àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun àti ẹ̀rọ tó ń dìwé pọ̀. Torí náà, àwọn ará lọ gba ilé kan ní 18 Concord Street ní Brooklyn, wọ́n sì ra àwọn ohun èlò ìtẹ̀wé síbẹ̀.

Àmọ́ kì í ṣe inú gbogbo èèyàn ló dùn sí ilé ìtẹ̀wé tuntun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí yìí. Nígbà tí ọ̀gá ilé iṣẹ́ tó ń bá wa tẹ̀wé tẹ́lẹ̀ ṣèbẹ̀wò sí ilé iṣẹ́ tuntun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí náà, ó sọ pé: “Àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tó dáa jù láyé lẹ rà síbí, àmọ́ kò sí ìkankan nínú yín tó mọ̀ ọ́n lò. Mo fún yín lóṣù mẹ́fà péré, gbogbo ẹ̀ á ti dẹnu kọlẹ̀.”

Arákùnrin Martin sọ pé, “Lójú èèyàn, ó jọ pé ohun tó sọ yẹn bọ́gbọ́n mu, àmọ́ a mọ̀ pé Jèhófà máa dúró tì wá, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.” Bí Arákùnrin Martin ṣe sọ gan-an ló rí, torí kò pẹ́ rárá tí ẹ̀rọ ìdìwépọ̀ tuntun tá a rà fi ń di ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìwé lójúmọ́.

Àwọn tó ń tẹ̀wé dúró sídìí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé náà

A WÀÁSÙ FÚN ẸGBẸẸGBẸ̀RÚN ÈÈYÀN LÓRÍ RÉDÍÒ

Yàtọ̀ sí ìwé táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ nígbà yẹn, a tún bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere náà lórí rédíò. Ọ̀sán Sunday, February 26, 1922 ni Arákùnrin Rutherford kọ́kọ́ sọ àsọyé lórí rédíò. Àkòrí ẹ̀ ni: “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé.” Orí rédíò KOG ní Los Angeles, California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ti sọ àsọyé náà.

Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) èèyàn ló gbọ́ àsọyé náà. Kódà àwọn kan kọ lẹ́tà ìdúpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ àsọyé náà. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ lẹ́tà ránṣẹ́ ni Willard Ashford tó ń gbé ní Santa Ana, California. Ó gbóríyìn fún Arákùnrin Rutherford, ó ní àsọyé ẹ̀ tani jí, ó sì wọni lọ́kàn. Ó tún sọ pé: “Àwọn mẹ́ta ló ń ṣàìsàn nínú ìdílé wa, wọn ò sì lè jáde nílé. Torí náà, tí kì í bá ṣe pé orí rédíò lẹ ti sọ ọ́ ni, kò bá má ṣeé ṣe fún wa láti gbọ́ àsọyé yẹn, ká tiẹ̀ sọ pé ìtòsí wa lẹ ti sọ ọ́.”

Àwọn àsọyé míì tún wáyé lórí rédíò láwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Nígbà tí ọdún yẹn máa fi parí, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ fojú bù ú pé “ó kéré tán ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) èèyàn ló ti gbọ́ ìhìn rere náà lórí rédíò.”

Àwọn lẹ́tà ìdúpẹ́ táwọn èèyàn fi ránṣẹ́ jẹ́ káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pinnu pé àwọn máa kọ́ ilé iṣẹ́ rédíò tiwọn sórí ilẹ̀ kan ní Staten Island, tí kò jìnnà sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn. Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ BíbéIì lo ilé iṣẹ́ rédíò WBBR yìí láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ èèyàn níbi tó pọ̀.

“ADV”

Ilé Ìṣọ́ June 15, 1922 sọ pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ṣe àpéjọ kan ní Cedar Point, Ohio láti September 5 sí 13, 1922. Inú gbogbo àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ń dùn ṣìnkìn bí wọ́n ṣe ń dé sí Cedar Point.

Nígbà tí Arákùnrin Rutherford ń sọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀, ó sọ pé: “Ó dá mi lójú pé Olúwa máa . . . bù kún àpéjọ yìí gan-an, ó sì máa jẹ́ ká wàásù dé ibi tó pọ̀ jù lọ láyé.” Gbogbo àwọn tó sọ àsọyé ní àpéjọ yẹn ló fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù.

Àwọn tó wá sí àpéjọ tá a ṣe ní Cedar Point, Ohio lọ́dún 1922

Nígbà tó di Friday, September 8, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ (8,000) èèyàn ló kún inú gbọ̀ngàn àpéjọ náà bámúbámú láti gbọ́ àsọyé tí Arákùnrin Rutherford fẹ́ sọ. Ara àwọn èèyàn ti wà lọ́nà láti gbọ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ADV,” tí wọ́n kọ sára ìwé tí wọ́n fi pè wọ́n wá sí àpéjọ náà. Bí àwọn tó wá sí àpéjọ náà ṣe ń jókòó, wọ́n rí aṣọ kíká kan tó fẹ̀ tí wọ́n gbé kọ́ sórí pèpéle. Arthur Claus, tó wá sí àpéjọ náà láti Tulsa, Oklahoma, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà jókòó síbi tó ti máa gbọ́ àsọyé náà dáadáa torí pé kò sí makirofóònù tàbí gbohùn-gbohùn nígbà yẹn.

“A tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́, a sì ń gbọ́ gbogbo ohun tí Arákùnrin Rutherford ń sọ”

Alága àpéjọ náà ṣèfilọ̀ pé wọn ò ní gba ẹni tó bá pẹ́ dé láyè láti wọnú gbọ̀ngàn àpéjọ náà nígbà tí Arákùnrin Rutherford bá ń sọ àsọyé lọ́wọ́. Nígbà tó di aago mẹ́sàn-án ààbọ̀ àárọ̀, Arákùnrin Rutherford sọ ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 4:17 pé: “Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.” (Bíbélì Mímọ́) Nígbà tí Arákùnrin Rutherford ń sọ̀rọ̀ nípa báwọn èèyàn ṣe máa gbọ́ ìhìn rere náà, ó sọ pé: “Jésù fúnra ẹ̀ sọ pé nígbà tí òun bá pa dà wá, òun máa kó àwọn èèyàn òun jọ, ìyẹn àwọn tó jẹ́ olóòótọ́.”

Arákùnrin Claus tó wà ní gbọ̀ngàn àpéjọ náà rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “A tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́, a sì ń gbọ́ gbogbo ohun tí Arákùnrin Rutherford ń sọ.” Àmọ́, lójijì ó bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ Arthur, ó sì gba pé kó fi gbọ̀ngàn náà sílẹ̀. Inú ẹ̀ ò dùn bó ṣe ń jáde kúrò níbẹ̀ torí ó mọ̀ pé wọn ò ní jẹ́ kóun pa dà wọlé.

Lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀ ara ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá. Ó sọ pé bóun ṣe ń pa dà wọnú gbọ̀ngàn náà, òun ń gbọ́ táwọn èèyàn ń pàtẹ́wọ́ kíkankíkan. Ìyẹn sì jẹ́ kára ẹ̀ yá gágá! Ó sọ pé tó bá tiẹ̀ gba pé kóun gun òrùlé gbọ̀ngàn náà, òun á ṣe bẹ́ẹ̀ kóun lè gbọ́ àsọyé alárinrin náà parí. Ọ̀dọ́ ni Arákùnrin Claus nígbà yẹn, ẹni ọdún mẹ́tàlélógún (23) sì ni. Ó wá ibi tó máa gbà gun gbọ̀ngàn náà títí tó fi dé òrùlé. Nígbà tó débẹ̀, ó rí i pé wọ́n ṣí àwọn fèrèsé ibẹ̀ sílẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kó “gbọ́ àsọyé náà ketekete.”

Àmọ́ Arthur nìkan kọ́ ló wà lórí òrùlé náà. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ náà wà níbẹ̀. Ọ̀kan lára wọn tó ń jẹ́ Frank Johnson wá bá a, ó sì bi í pé, “Ṣé o ní ọ̀bẹ kékeré kan tó mú?”

Ni Arthur bá dá a lóhùn pé, “bẹ́ẹ̀ ni.”

Frank wá sọ pé, “Ọlọ́run ti gbọ́ àdúrà wa, ìwọ ló sì rán wá. Ṣé o rí aṣọ ńlá tí wọ́n so mókè yìí? Àkọlé kan ló wà níbẹ̀. Tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa, tó o bá ti gbọ́ tí Adájọ́ * sọ pé, ‘ẹ fọn rere, ẹ fọn rere,’ kó o gé okùn mẹ́rin tí wọ́n fi so aṣọ yìí.”

Torí náà, Arthur mú ọ̀bẹ lọ́wọ́, ó sì ń dúró dìgbà tí Arákùnrin Rutherford máa kéde ọ̀rọ̀ náà. Kò pẹ́ sígbà yẹn, Arákùnrin Rutherford débi tó ti máa sọ̀rọ̀ náà, ó wá fìtara sọ̀rọ̀ sókè, ó ní: “Ẹ jẹ́ olóòótọ́, kẹ́ ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Olúwa. Ẹ máa ja ìjà náà nìṣó títí Bábílónì Ńlá, ìyẹn gbogbo ìsìn èké máa fi pa run. Ẹ polongo rẹ̀ káàkiri. Ayé gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run àti pé Jésù Kristi ni Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa. Ọjọ́ ńlá lọjọ́ yìí. Ẹ wò ó, Ọba náà ti ń ṣàkóso! Ẹ̀yin ni aṣojú tó ń polongo rẹ̀. Torí náà, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere Ọba náà àti Ìjọba rẹ̀!”

Arthur sọ pé òun àtàwọn arákùnrin yòókù gé àwọn okùn tí wọ́n fi so aṣọ náà, aṣọ náà sì dà wálẹ̀ gẹ̀ẹ̀rẹ̀gẹ̀. Ìgbà náà ni Arákùnrin Rutherford wá sọ pé àwọn lẹ́tà mẹ́ta náà “ADV” túmọ̀ sí “Ẹ Fọn Rere.” Àmọ́, ohun tó wà nínú aṣọ tí wọ́n so mókè náà ni: “Ẹ fọn rere Ọba náà àti Ìjọba rẹ̀.”

IṢẸ́ PÀTÀKÌ KAN

Àpéjọ tí wọ́n ṣe ní Cedar Point ran àwọn ará lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ náà sì yọ̀ǹda ara wọn láti máa wàásù. Ọ̀kan lára àwọn apínwèé-ìsìn-kiri (tá a wá mọ̀ sí aṣáájú-ọ̀nà déédéé báyìí) tó wá láti ìpínlẹ̀ Oklahoma ní Amẹ́ríkà sọ pé, “Agbègbè tí wọ́n ti ń wa èédú la ti ń wàásù, àwọn tálákà sì pọ̀ gan-an níbẹ̀.” Ó sọ pé lọ́pọ̀ ìgbà táwọn èèyàn bá ka ohun tó wà nínú ìwé ìròyìn Golden Age, “wọ́n máa ń bú sẹ́kún.” Ó tún sọ pé, “Inú wa dùn pé a lè ràn wọ́n lọ́wọ́, ká sì tù wọ́n nínú.”

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn rí i pé ó yẹ káwọn fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Lúùkù 10:2. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Ìkórè pọ̀, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ò tó nǹkan.” Bí ọdún náà ṣe ń parí lọ, wọ́n túbọ̀ pinnu pé àwọn máa polongo ìhìn rere Ìjọba náà délé dóko.

^ Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń pe Arákùnrin Rutherford ní “Adájọ́” torí pé ó ti ṣe adájọ́ rí ní ìpínlẹ̀ Missouri, ní Amẹ́ríkà.