Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Táwa Kristẹni Kì í Fi í Jagun Báwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Àtijọ́ Ṣe Jagun?

Kí Nìdí Táwa Kristẹni Kì í Fi í Jagun Báwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Àtijọ́ Ṣe Jagun?

NÍGBÀ Ogun Àgbáyé Kejì, ọmọ ogun Násì kan pariwo mọ́ àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan pé: “Tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá sọ pé òun ò ní bá orílẹ̀- èdè Faransé àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jà, a máa pa gbogbo yín ni o!” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn sójà Násì tó dìhámọ́ra ogun dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, kò sẹ́nì kankan lára àwọn arákùnrin wa tó ṣe ohun tí wọ́n sọ. Ẹ ò rí i pé ohun tí wọ́n ṣe yẹn gba ìgboyà gan-an! Àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́. A kì í dá sọ́rọ̀ ogun tó ń lọ nínú ayé. Kódà, tí wọ́n bá halẹ̀ mọ́ wa pé wọ́n máa pa wá, a ò ní jagun.

Àmọ́ lónìí, kì í ṣe gbogbo àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni ló gbà bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ló gbà pé ó yẹ káwọn Kristẹni máa jà fún orílẹ̀-èdè wọn. Wọ́n lè sọ pé: ‘Ṣebí èèyàn Ọlọ́run làwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, wọ́n sì jagun, kí ló wá dé táwa Kristẹni ò fi jagun lónìí?’ Tí wọ́n bá bi ẹ́ ní ìbéèrè yẹn, kí lo máa sọ? O lè ṣàlàyé fún wọn pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe nígbà yẹn yàtọ̀ sí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe lónìí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbé nǹkan márùn-ún kan yẹ̀ wò.

1. ORÍLẸ̀-ÈDÈ KAN NI GBOGBO ÀWỌN ÈÈYÀN ỌLỌ́RUN

Nígbà àtijọ́, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nìkan ni Jèhófà yàn pé kó jẹ́ èèyàn òun. Kódà, ó pè wọ́n ní “ohun ìní mi pàtàkì nínú gbogbo èèyàn.” (Ẹ́kís. 19:5) Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run tún fún wọn ní ilẹ̀ tí wọ́n á máa gbé. Torí náà, tí Ọlọ́run bá sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ bá àwọn orílẹ̀-èdè míì jà, kì í ṣe àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà ni wọ́n máa lọ bá jà, tí wọ́n sì máa pa. *

Lóde òní, àwa tá à ń jọ́sìn Jèhófà wá látinú “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n.” (Ìfi. 7:9) Torí náà, táwọn èèyàn Ọlọ́run bá lọ jagun, ṣe ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn èèyàn Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè míì.

2. JÈHÓFÀ LÓ MÁA Ń PÀṢẸ FÁWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ PÉ KÍ WỌ́N LỌ JAGUN

Nígbà àtijọ́, Jèhófà ló máa ń sọ ìgbà àti ìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi gbọ́dọ̀ lọ sógun. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n bá àwọn ọmọ Kénáánì jà nítorí pé wọ́n ń jọ́sìn ẹ̀mí èṣù, wọ́n ń ṣèṣekúṣe tó burú jáì, wọ́n sì ń fi ọmọ wọn rúbọ. Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n pa àwọn èèyàn burúkú yẹn kúrò lórí ilẹ̀ tóun ṣèlérí pé òun máa fún wọn, kí ìwà wọn má bàa ràn wọ́n. (Léf. 18:24, 25) Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Ọlọ́run fọwọ́ sí i pé kí wọ́n jagun kí wọ́n lè gba ara wọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. (2 Sám. 5:17-25) Àmọ́, kò sígbà tí Jèhófà jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì pinnu fúnra wọn láti lọ jagun, Jèhófà ló máa ń pinnu ìgbà tí wọ́n máa lọ. Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá fagídí lọ jagun, ìgbẹ̀yìn ẹ̀ kì í dáa rárá.​—Nọ́ń. 14:41-45; 2 Kíró. 35:20-24.

Lóde òní, Jèhófà ò sọ pé káwọn èèyàn máa lọ jagun. Ìdí táwọn orílẹ̀-èdè fi ń jagun ni pé ohun tí wọ́n ń fẹ́ ni wọ́n ń wá, kì í ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé wọ́n fẹ́ gba ilẹ̀ púpọ̀ sí i, wọ́n fẹ́ túbọ̀ dolówó tàbí torí pé wọ́n fẹ́ túbọ̀ lẹ́nu nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú. Àmọ́ àwọn tó sọ pé àwọn ń jà nítorí Ọlọ́run ńkọ́? Wọ́n sọ pé àwọn ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí káwọn lè dáàbò bo ẹ̀sìn wọn tàbí kí wọ́n lè pa àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló máa dáàbò bo àwọn tó ń sìn ín, ó sì máa pa àwọn ọ̀tá ẹ̀ run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú. (Ìfi. 16:14, 16) Tó bá dìgbà yẹn, àwọn áńgẹ́lì ló máa ja ogun náà, kì í ṣe àwọn èèyàn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run.​—Ìfi. 19:11-15.

3. ÀWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ Ò PA ÀWỌN TÓ NÍGBÀGBỌ́ NÍNÚ ỌLỌ́RUN

Ṣé àwọn tó ń bára wọn jagun lónìí máa ń dá àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run sí bí Ọlọ́run ṣe ní kí wọ́n dá Ráhábù àti ìdílé ẹ̀ sí?

Nígbà àtijọ́, àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì máa ń fàánú hàn sáwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, àwọn tí Jèhófà bá dá lẹ́bi nìkan ni wọ́n máa ń pa. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ló ní kí wọ́n lọ pa ìlú Jẹ́ríkò run, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá ẹ̀mí Ráhábù àti ìdílé ẹ̀ sí torí pé ó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. (Jóṣ. 2:9-16; 6:16, 17) Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà ní kí wọ́n dá ìlú Gíbíónì sí torí pé àwọn ará Gíbíónì bẹ̀rù Ọlọ́run.​—Jóṣ. 9:3-9, 17-19.

Lóde òní, àwọn orílẹ̀-èdè tó ń bára wọn jagun kì í dá ẹ̀mí àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run sí. Kódà, wọ́n máa ń pa àwọn aráàlú tí ò mọwọ́ mẹsẹ̀.

4. ÀWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ MÁA Ń TẸ̀ LÉ ÒFIN TÍ ỌLỌ́RUN FÚN WỌN NÍGBÀ OGUN

Nígbà àtijọ́, Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé òfin tí òun bá fún wọn nígbà ogun. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run máa ń sọ fún wọn nígbà míì pé kí wọ́n bá orílẹ̀-èdè tí wọ́n fẹ́ bá jà sọ “ọ̀rọ̀ àlàáfíà.” (Diu. 20:10) Jèhófà tún retí pé kí àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì àti ibùdó wọn wà ní mímọ́ tónítóní, kí wọ́n má sì ṣèṣekúṣe. (Diu. 23:9-14) Àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè tó kù máa ń fipá bá àwọn obìnrin ìlú tí wọ́n bá ṣẹ́gun lò pọ̀, àmọ́ Jèhófà sọ pé àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ ṣerú ẹ̀ láé. Kódà, Jèhófà sọ pé wọn ò lè fẹ́ obìnrin tí wọ́n bá mú lẹ́rú àfi lẹ́yìn oṣù kan.​—Diu. 21:10-13.

Lóde òní, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ti ṣàdéhùn ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe àtohun tí wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe nígbà ogun. Lóòótọ́, ìdí tí wọ́n fi ṣe irú àwọn àdéhùn bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ dáàbò bo àwọn aráàlú, àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé wọn kì í sábà tẹ̀ lé àwọn òfin náà.

5. ỌLỌ́RUN MÁA Ń JÀ NÍTORÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ RẸ̀

Ṣé Ọlọ́run ṣì ń jà fáwọn orílẹ̀-èdè lónìí bó ṣe jà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nílùú Jẹ́ríkò?

Nígbà àtijọ́, Jèhófà máa ń jà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kódà ó sábà máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́gun lọ́nà ìyanu. Bí àpẹẹrẹ, báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun ìlú Jẹ́ríkò? Jèhófà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì “kígbe tantan láti jagun, ògiri ìlú náà wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ,” ìyẹn sì jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti ṣẹ́gun ìlú náà. (Jóṣ. 6:20) Báwo ni wọ́n ṣe ṣẹ́gun àwọn Ámórì? Bíbélì sọ pé “Jèhófà rọ̀jò òkúta yìnyín ńláńlá lé wọn lórí láti ọ̀run . . . Kódà, àwọn tí yìnyín náà pa pọ̀ ju àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa lọ.”​—Jóṣ. 10:6-11.

Lóde òní, Jèhófà kì í jà fún orílẹ̀-èdè kankan mọ́. Ìdí sì ni pé Ìjọba rẹ̀ tí Jésù ń ṣàkóso “kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòh. 18:36) Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé Sátánì ló ń darí gbogbo ìjọba èèyàn. Àwọn ogun burúkú tí wọ́n ń jà láyé fi hàn pé Sátánì ni ẹni ibi tó ń darí wọn.​—Lúùkù 4:5, 6; 1 Jòh. 5:19.

ÈÈYÀN ÀLÀÁFÍÀ LÀWA KRISTẸNI TÒÓTỌ́

A ti rí i pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe yàtọ̀ sóhun tó fẹ́ káwa Kristẹni tòótọ́ ṣe lónìí. Àmọ́, àwọn ohun tá a sọ yìí nìkan kọ́ ni ìdí tá à kì í fi í jagun. Àwọn ìdí míì wà. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn tí òun kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ò “ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́,” ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kí wọ́n lọ máa jagun. (Àìsá. 2:2-4) Yàtọ̀ síyẹn, Kristi náà sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun “kì í ṣe apá kan ayé,” wọn ò sì gbọ́dọ̀ dá sọ́rọ̀ ogun táwọn èèyàn ń bá ara wọn jà.​—Jòh. 15:19.

Jésù tún sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ṣe nǹkan tó jùyẹn lọ. Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n yẹra fún ohun tó lè mú kí wọ́n di àwọn èèyàn sínú, ohun tó lè mú kí wọ́n bínú tàbí bá ara wọn jagun. (Mát. 5:21, 22) Yàtọ̀ síyẹn, ó sọ pé kí wọ́n máa “wá àlàáfíà,” kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn.​—Mát. 5:9, 44.

Báwo làwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò? Kò dájú pé a rí ẹnì kankan nínú wa tó máa fẹ́ lọ jagun, àmọ́ ṣé kì í ṣe pé a kórìíra àwọn èèyàn lọ́kàn wa tíyẹn sì ń dá ìjà tàbí ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ? Torí náà, tírú èrò bẹ́ẹ̀ bá wá sí wa lọ́kàn, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti gbé e kúrò lọ́kàn kíá.​—Jém. 4:1, 11.

Dípò ká máa lọ́wọ́ sí ìjà táwọn orílẹ̀-èdè ń bá ara wọn jà, ó yẹ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí àlàáfíà àti ìfẹ́ lè wà láàárín wa. (Jòh. 13:34, 35) Torí náà, bá a ṣe ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí Jèhófà máa fòpin sí gbogbo ogun, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ogun táwọn èèyàn ń bá ara wọn jà.​—Sm. 46:9.

^ Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì kan máa ń bá ara wọn jà, àmọ́ inú Jèhófà ò dùn sí i. (1 Ọba 12:24) Ṣùgbọ́n nígbà míì, Jèhófà máa ń fọwọ́ sí irú àwọn ogun bẹ́ẹ̀ nítorí pé àwọn ẹ̀yà kan ti kẹ̀yìn sí i tàbí nítorí pé wọ́n ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì.​—Oníd. 20:3-35; 2 Kíró. 13:3-18; 25:14-22; 28:1-8.