Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ṣé mánà àti àparò nìkan làwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ nígbà tí wọ́n wà ní aginjù?
Mánà loúnjẹ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ jù ní gbogbo ogójì (40) ọdún tí wọ́n fi wà ní aginjù. (Ẹ́kís. 16:35) Jèhófà tún pèsè àparò fún wọn nígbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. (Ẹ́kís. 16:12, 13; Nọ́ń. 11:31) Àmọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún jẹ àwọn oúnjẹ míì.
Bí àpẹẹrẹ nígbà míì, Jèhófà máa ń darí wọn lọ sí “ibi ìsinmi” tí wọ́n á ti rí omi mu, tí wọ́n á sì rí oúnjẹ jẹ. (Nọ́ń. 10:33) Ọ̀kan lára ibi tí Jèhófà darí wọn lọ ni Élímù, “níbi tí ìsun omi méjìlá (12) àti àádọ́rin (70) igi ọ̀pẹ wà,” ó sì ṣeé ṣe káwọn igi náà jẹ́ igi ọ̀pẹ déètì. (Ẹ́kís. 15:27) Ìwé kan tó ń jẹ́ Plants of the Bible sọ pé, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò síbi tí igi ọ̀pẹ déètì ò sí, . . . òun ni igi eléso tó wọ́pọ̀ jù nínú aginjù, èèyàn lè jẹ èso ẹ̀, wọ́n lè fi ṣe òróró, wọ́n sì máa ń fi ewé ẹ̀ kọ́lé.”
Ó tún ṣeé ṣe káwọn ọmọ Ísírẹ́lì dúró níbi ìsun omi kan tó tóbi gan-an tó ń jẹ́ Feiran lákòókò wa yìí, ó sì jẹ́ apá kan Àfonífojì Feiran. a Ìwé kan tó ń jẹ́ Discovering the World of the Bible sọ pé: “Àfonífojì olómi yìí gùn tó máìlì mọ́kànlélọ́gọ́rin (81) tàbí àádóje (130) kìlómítà, ó sì wà lára àwọn àfonífojì tó gùn jù, tó rẹwà jù, tó sì gbajúmọ̀ jù ní àwọn àfonífojì Sínáì.” Ìwé yẹn tún sọ pé: “Téèyàn bá rin máìlì méjìdínlọ́gbọ̀n (28) láti ibi tí àfonífojì náà àti òkun ti pà dé, ó máa dé ìsun omi Feiran. Ìsun omi náà jìn tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹsẹ̀ bàtà, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ máìlì mẹ́ta. Àwọn igi ọ̀pẹ déètì pọ̀ gan-an níbẹ̀, ibẹ̀ sì rẹwà débi pé wọ́n fi wé ọgbà Édẹ́nì. Nítorí pé igi ọ̀pẹ déètì pọ̀ gan-an ní àfonífojì yìí, àìmọye èèyàn ló ń gbébẹ̀.”
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kúrò ní Íjíbítì, àwọn nǹkan tí wọ́n kó dání ni àpòrọ́ ìyẹ̀fun, àwọn abọ́ tí wọ́n fi ń po nǹkan, ó tún ṣeé ṣe kí wọ́n kó ọkà, kí wọ́n sì gbé òróró dání. Ká sòótọ́, kò lè pẹ́ rárá táwọn nǹkan yìí á fi tán. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún kó “àwọn agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹran ọ̀sìn” dání. (Ẹ́kís. 12:34-39) Torí pé nǹkan nira gan-an ní aginjù, ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹran ọ̀sìn náà kú. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n lè ti pa àwọn kan jẹ, kí wọ́n sì fi àwọn kan rúbọ, kódà wọ́n fi àwọn kan rúbọ sáwọn ọlọ́run èké. b (Ìṣe 7:39-43) Síbẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣì láwọn ẹran tí wọ́n ń sìn. Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún wọn nígbà tí wọ́n ṣàìgbọràn torí pé wọn ò nígbàgbọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé bó ṣe rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Ogójì (40) ọdún ni àwọn ọmọ yín fi máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn nínú aginjù.” (Nọ́ń. 14:33) Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa fún wàrà lára àwọn ẹran náà, kí wọ́n sì máa pa wọ́n jẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, kò dájú pé ó máa tó wọn jẹ fún ogójì (40) ọdún torí gbogbo wọn tó mílíọ̀nù mẹ́ta (3,000,000). c
Báwo làwọn ẹran ọ̀sìn náà ṣe rí oúnjẹ jẹ, tí wọ́n sì rí omi mu? d Lákòókò yẹn, ó ṣeé ṣe kí òjò tó máa ń rọ̀ pọ̀ gan-an, kíyẹn sì mú kí ewéko tó pọ̀ wà ní aginjù. Ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kìíní sọ pé, ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ọdún sẹ́yìn, “omi tó wà ní agbègbè Arébíà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nígbà yẹn pọ̀ ju omi tó wà níbẹ̀ lásìkò wa yìí. Ọ̀pọ̀ àfonífojì tó jìn, tó ní omi tẹ́lẹ̀ àmọ́ tó ti gbẹ wà níbẹ̀. Ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí pé láwọn ìgbà kan, òjò máa ń rọ̀ gan-an níbẹ̀, tá á sì di odò.” Síbẹ̀, kò sí èèyàn kankan tó ń gbé àfonífojì náà, ibẹ̀ sì máa ń ba èèyàn lẹ́rù. (Diu. 8:14-16) Ká sọ pé Jèhófà ò pèsè omi lọ́nà ìyanu fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni, ó dájú pé àwọn àtàwọn ẹran ọ̀sìn wọn ò bá ti kú dànù.—Ẹ́kís. 15:22-25; 17:1-6; Nọ́ń. 20:2, 11.
Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé Jèhófà fi mánà bọ́ wọn “kí [wọ́n] lè mọ̀ pé kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.”—Diu. 8:3.
a Wo Ilé Ìṣọ́ May 1, 1992, ojú ìwé 24-25.
b Bíbélì sọ ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ẹran rúbọ sí Jèhófà ní aginjù. Ìgbà àkọ́kọ́ ni ìgbà tí wọ́n yan àwọn àlùfáà, ìgbà kejì sì ni ìgbà tí wọ́n ń ṣe Ìrékọjá. Ìgbà méjèèjì yìí sì jẹ́ lọ́dún 1512 Ṣ.S.K., ìyẹn ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì.—Léf. 8:14–9:24; Nọ́ń. 9:1-5.
c Nígbà tí ogójì (40) ọdún táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa lò ní aginjù ti fẹ́ pé, wọ́n kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹran ọ̀sìn bọ̀ lójú ogun. (Nọ́ń. 31:32-34) Síbẹ̀, wọ́n ṣì ń jẹ mánà títí wọ́n fi wọ Ilẹ̀ Ìlérí.—Jóṣ. 5:10-12.
d Kò sí ẹ̀rí pé àwọn ẹran wọn jẹ mánà torí pé ìwọ̀n tí kálukú wọn máa jẹ ni Jèhófà ní kí wọ́n kó.—Ẹ́kís. 16:15, 16.