Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 45

Mọyì Àǹfààní Tó O Ní Láti Jọ́sìn Jèhófà Nínú Tẹ́ńpìlì Tẹ̀mí

Mọyì Àǹfààní Tó O Ní Láti Jọ́sìn Jèhófà Nínú Tẹ́ńpìlì Tẹ̀mí

“Ẹ jọ́sìn Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé.”—ÌFI. 14:7.

ORIN 93 Bù Kún Ìpàdé Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Kí ni áńgẹ́lì kan ń sọ, kí ló sì yẹ ká ṣe?

 KÁ NÍ áńgẹ́lì kan fẹ́ bá ẹ sọ̀rọ̀, ṣé wàá gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ fún ẹ? Lónìí, áńgẹ́lì kan ń bá “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn” sọ̀rọ̀. Kí ni áńgẹ́lì náà ń sọ? Ó ní: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un . . . Ẹ jọ́sìn Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé.” (Ìfi. 14:6, 7) Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ tí gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn. A mà dúpẹ́ o pé àǹfààní ńlá la ní láti máa jọ́sìn Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì ńlá rẹ̀ tẹ̀mí!

2. Kí ni tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti Jèhófà? (Tún wo àpótí náà, “ Kí Ni Tẹ́ńpìlì Náà Kò Jẹ́?”)

2 Kí ni tẹ́ńpìlì náà, ibo sì la ti lè rí àlàyé nípa ẹ̀? Tẹ́ńpìlì tẹ̀mí kì í ṣe ilé tá a ti ń jọ́sìn. Ó jẹ́ ètò tí Jèhófà ṣe ká lè máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó tọ́ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ètò tí Jèhófà ṣe yìí nígbà tó kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ tó jẹ́ Hébérù tó ń gbé ní Jùdíà. b

3-4. Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù tó ń gbé ní Jùdíà, báwo ló sì ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?

3 Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù tó ń gbé ní Jùdíà? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nǹkan méjì ló mú kó kọ ọ́. Ohun àkọ́kọ́ ni pé ó fẹ́ fún wọn níṣìírí. Inú ẹ̀sìn Júù ni ọ̀pọ̀ lára wọn dàgbà sí, ó sì ṣeé ṣe káwọn olórí ẹ̀sìn wọn máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé wọ́n di Kristẹni. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn Kristẹni ò ní tẹ́ńpìlì tí wọ́n ti ń jọ́sìn, wọn ò ní pẹpẹ tí wọ́n ti ń rúbọ sí Ọlọ́run, wọn ò sì ní àwọn àlùfáà tó ń bá wọn rúbọ. Gbogbo nǹkan yìí lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi, kí ìgbàgbọ́ wọn má sì lágbára mọ́. (Héb. 2:1; 3:12, 14) Kódà, àwọn kan lára wọn lè máa ronú láti pa dà sínú ẹ̀sìn Júù.

4 Ìkejì, Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù yẹn kò gbìyànjú láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ tuntun tàbí àwọn ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀, ìyẹn “oúnjẹ líle” tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Héb. 5:11-14) Ó hàn gbangba pé àwọn kan lára wọn ṣì ń tẹ̀ lé Òfin Mósè. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé àwọn ẹbọ tí Òfin náà sọ pé kí wọ́n máa rú kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ‘pa Òfin náà tì.’ Torí náà, Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn láwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀. Ó rán àwọn Kristẹni yẹn létí pé ẹbọ tí Jésù fi ara ẹ̀ rú ni “ìrètí tó dáa jù,” òun ló sì lè mú kí wọ́n “sún mọ́ Ọlọ́run.”—Héb. 7:18, 19.

5. Kí ni ìwé Hébérù jẹ́ ká mọ̀, kí sì nìdí?

5 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé fáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù nípa bí ẹ̀sìn Kristẹni tí wọ́n ń ṣe báyìí ṣe dáa gan-an ju ìjọsìn àwọn Júù tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ lọ. Ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn àwọn Júù jẹ́ “òjìji àwọn ohun tó ń bọ̀, àmọ́ Kristi ni ohun gidi náà.” (Kól. 2:17) Òjìji ni àwòrán tó máa ń jẹ́ ká mọ bí ohun kan ṣe rí. Lọ́nà kan náà, ọ̀nà táwọn Júù ń gbà jọ́sìn láyé àtijọ́ jẹ́ ká mọ bí ìjọsìn tòótọ́ ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, ó yẹ ká lóye ètò tí Jèhófà ṣe láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá ká lè jọ́sìn ẹ̀ bó ṣe fẹ́. Ẹ jẹ́ ká fi “òjìji” (ìyẹn ọ̀nà táwọn Júù ń gbà jọ́sìn láyé àtijọ́) wé “ohun gidi” (ìyẹn ọ̀nà táwọn Kristẹni ń gbà jọ́sìn) bí ìwé Hébérù ṣe ṣàlàyé ẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa túbọ̀ lóye tẹ́ńpìlì tẹ̀mí àti bó ṣe kàn wá.

ÀGỌ́ ÌJỌSÌN

6. Kí ni wọ́n ń ṣe nínú àgọ́ ìjọsìn láyé àtijọ́?

6 Báwọn Júù ṣe jọ́sìn. Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ dá lórí àgọ́ ìjọsìn tí Mósè ṣe lọ́dún 1512 Ṣ.S.K. (Wo àpótí náà “Báwọn Júù Ṣe Jọ́sìn àti Báwọn Kristẹni Ṣe Ń Jọ́sìn.”) Wọ́n ṣe àgọ́ ìjọsìn náà lọ́nà tó ṣeé gbé láti ibì kan sí ibòmíì, gbogbo ibi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń lọ ni wọ́n sì máa ń gbé e lọ. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọdún ni wọ́n fi lo àgọ́ náà, kó tó di pé wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì kan sí Jerúsálẹ́mù. (Ẹ́kís. 25:8, 9; Nọ́ń. 9:22) “Àgọ́ ìjọsìn” yìí tí wọ́n tún ń pè ní “àgọ́ ìpàdé” ni ibi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti máa ń jọ́sìn Ọlọ́run tí wọ́n sì ti máa ń rúbọ. (Ẹ́kís. 29:43-46) Àmọ́, àgọ́ ìjọsìn tún ṣàpẹẹrẹ ohun kan tó dáa jù tó máa ṣe àwọn Kristẹni láǹfààní lọ́jọ́ iwájú.

7. Ìgbà wo ni tẹ́ńpìlì tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀?

7 Báwọn Kristẹni ṣe ń jọ́sìn. Àgọ́ ìjọsìn ayé àtijọ́ jẹ́ “òjìji àwọn nǹkan ti ọ̀run,” ó sì ṣàpẹẹrẹ tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Jèhófà. Pọ́ọ̀lù sọ pé “àgọ́ [tàbí àgọ́ ìjọsìn] yìí jẹ́ àpèjúwe fún àkókò yìí.” (Héb. 8:5; 9:9) Torí náà, nígbà tó fi máa kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù, wọ́n ti ń jọ́sìn nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí. Ọdún 29 S.K. ló bẹ̀rẹ̀. Ọdún yẹn ni Jésù ṣèrìbọmi, tí Jèhófà fẹ̀mí mímọ́ yàn án, tó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ “àlùfáà àgbà” ńlá fún Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí. cHéb. 4:14; Ìṣe 10:37, 38.

ÀLÙFÁÀ ÀGBÀ

8-9.Hébérù 7:23-27 ṣe sọ, ìyàtọ̀ ńlá wo ló wà láàárín àwọn àlùfáà àgbà ti Ísírẹ́lì àti Jésù Kristi tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ńlá?

8 Báwọn Júù ṣe jọ́sìn. Àlùfáà àgbà ló máa ń ṣojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Áárónì ni àlùfáà àgbà àkọ́kọ́ tí Jèhófà yàn fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ya àgọ́ ìjọsìn sí mímọ́. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé “ó di dandan kí ọ̀pọ̀ di àlùfáà tẹ̀ léra torí pé ikú ò jẹ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà lọ.” d (Ka Hébérù 7:23-27.) Torí pé aláìpé làwọn àlùfáà àgbà yẹn, àwọn náà gbọ́dọ̀ máa rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ ńlá ló wà láàárín àwọn àlùfáà àgbà ti Ísírẹ́lì àti Jésù Kristi tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ńlá!

9 Báwọn Kristẹni ṣe ń jọ́sìn. Jésù Kristi Àlùfáà Àgbà wa ni “òjíṣẹ́ . . . àgọ́ tòótọ́, tí Jèhófà gbé kalẹ̀, kì í ṣe èèyàn” ló gbé e kalẹ̀. (Héb. 8:1, 2) Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé “torí pé [Jésù] wà láàyè títí láé, kò sí pé ẹnì kan ń rọ́pò rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ àlùfáà.” Pọ́ọ̀lù tún sọ pé Jésù jẹ́ “aláìlẹ́gbin, ẹni tí a yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,” kò sì dà bí àwọn àlùfáà àgbà ti Ísírẹ́lì torí “kò nílò kó máa rúbọ lójoojúmọ́” nítorí pé kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn pẹpẹ àtàwọn ẹbọ inú ìjọsìn àwọn Júù ṣe yàtọ̀ sí ti ìjọsìn àwọn Kristẹni.

ÀWỌN PẸPẸ ÀTÀWỌN ẸBỌ

10. Kí ni àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú lórí pẹpẹ bàbà ṣàpẹẹrẹ?

10 Báwọn Júù ṣe jọ́sìn. Pẹpẹ kan tí wọ́n fi bàbà ṣe wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn, orí ẹ̀ ni wọ́n ti ń fi ẹran rúbọ sí Jèhófà. (Ẹ́kís. 27:1, 2; 40:29) Àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú yẹn ò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn kúrò pátápátá. (Héb. 10:1-4) Àmọ́, àwọn ẹbọ tí wọ́n rú nínú àgọ́ ìjọsìn yẹn ń ṣàpẹẹrẹ ẹbọ kan ṣoṣo tó máa mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ aráyé kúrò títí láé.

11. Orí pẹpẹ wo ni Jésù ti fi ara ẹ̀ rúbọ? (Hébérù 10:5-7, 10)

11 Báwọn Kristẹni ṣe ń jọ́sìn. Jésù mọ̀ pé Jèhófà rán òun wá sáyé kóun lè fi ẹ̀mí òun ra aráyé pa dà. (Mát. 20:28) Torí náà, nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ó fi gbogbo ara ẹ̀ fún Jèhófà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Jòh. 6:38; Gál. 1:4) Orí pẹpẹ tí Jésù ti fi ara ẹ̀ rúbọ ṣàpẹẹrẹ “ìfẹ́” Ọlọ́run, ìyẹn bó ṣe fẹ́ kí Ọmọ ẹ̀ fi ara ẹ̀ pípé rúbọ. Jésù fi ẹ̀mí ẹ̀ rúbọ “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé” láti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ẹni tó bá nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Ka Hébérù 10:5-7, 10.) Ní báyìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn náà àtohun tí wọ́n ṣàpẹẹrẹ.

IBI MÍMỌ́ ÀTI IBI MÍMỌ́ JÙ LỌ

12. Àwọn wo ló lè wọ inú àwọn yàrá tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn?

12 Báwọn Júù ṣe jọ́sìn. Àgọ́ ìjọsìn àtàwọn tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ sí Jerúsálẹ́mù nígbà tó yá jọra wọn láwọn ọ̀nà kan. Yàrá méjì ló wà nínú wọn, ìyẹn “Ibi Mímọ́” àti “Ibi Mímọ́ Jù Lọ.” Aṣọ ìdábùú tí wọ́n kóṣẹ́ sí ni wọ́n fi pín wọn sí méjì. (Héb. 9:2-5; Ẹ́kís. 26:31-33) Àwọn ohun tó wà nínú Ibi Mímọ́ ni ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi wúrà ṣe, pẹpẹ tí wọ́n fi ń sun tùràrí àti tábìlì búrẹ́dì àfihàn. “Àwọn àlùfáà tí wọ́n fòróró yàn” nìkan ló lè wọ Ibi Mímọ́ láti ṣiṣẹ́ àlùfáà. (Nọ́ń. 3:3, 7, 10) Ohun tó sì wà nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ni àpótí májẹ̀mú tí wọ́n fi wúrà ṣe. Ibẹ̀ ni Jèhófà sì ti máa ń sọ̀rọ̀. (Ẹ́kís. 25:21, 22) Àlùfáà àgbà nìkan ló lè kọjá aṣọ ìdábùú sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ní Ọjọ́ Ètùtù tí wọ́n máa ń ṣe lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. (Léf. 16:2, 17) Ọdọọdún ló máa ń gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran wọ ibẹ̀ láti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ara ẹ̀ àti ti orílẹ̀-èdè náà. Nígbà tó yá, Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ mọ ohun táwọn nǹkan tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn náà ṣàpẹẹrẹ.—Héb. 9:6-8. e

13. Kí ni Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ ṣàpẹẹrẹ nínú ìjọsìn àwọn Kristẹni?

13 Báwọn Kristẹni ṣe ń jọ́sìn. Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ yan díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi, wọ́n sì ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) yìí máa jẹ́ àlùfáà pẹ̀lú Jésù. (Ìfi. 1:6; 14:1) Ibi Mímọ́ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn náà ṣàpẹẹrẹ bí Ọlọ́run ṣe fẹ̀mí yàn wọ́n láti jẹ́ ọmọ ẹ̀ nígbà tí wọ́n wà láyé. (Róòmù 8:15-17) Ibi Mímọ́ Jù Lọ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn náà ṣàpẹẹrẹ ọ̀run, ibi tí Jèhófà ń gbé. “Aṣọ ìdábùú” tó pín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ṣàpẹẹrẹ ara Jésù tí ò jẹ́ kó lè wọlé sọ́run láti ṣiṣẹ́ Àlùfáà Àgbà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí. Jésù fi ara ẹ̀ rúbọ nítorí aráyé, ohun tó ṣe yìí mú kó ṣeé ṣe fáwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn láti gba ìyè lọ́run. Kí wọ́n lè gba èrè wọn lọ́run, àwọn náà ò ní gbé ẹran ara wọn lọ sọ́run. (Héb. 10:19, 20; 1 Kọ́r. 15:50) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, ibẹ̀ sì ni gbogbo àwọn ẹni àmì òróró ti máa dara pọ̀ mọ́ Jésù.

14. Kí ni Hébérù 9:12, 24-26 sọ pé ó mú kí ìjọsìn inú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí dáa ju ìjọsìn àwọn Júù lọ?

14 A ti wá rí i pé ètò tí Jèhófà ṣe ká lè máa ṣe ìjọsìn mímọ́ nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù àti iṣẹ́ àlùfáà rẹ̀ ló dáa jù lọ. Àwọn èèyàn ló ṣe Ibi Mímọ́ Jù Lọ tí àlùfáà àgbà máa ń gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran wọ̀, àmọ́ inú “ọ̀run gangan” ni ibi mímọ́ jù lọ tí Jésù wọ̀, kó lè wá síwájú Jèhófà. Ibẹ̀ ló ti gbé ẹbọ pípé fún Jèhófà torí “ó fi ara rẹ̀ rúbọ kó lè mú ẹ̀ṣẹ̀ [wa] kúrò.” (Ka Hébérù 9:12, 24-26.) Ẹbọ tí Jésù fi ara ẹ̀ rú ni ẹbọ tó ṣeyebíye jù lọ torí ẹbọ náà ló mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò pátápátá. Níbi tá a dé yìí, a máa kọ́ bí gbogbo wa ṣe lè máa jọ́sìn Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí bóyá ọ̀run là ń lọ àbí ayé la máa gbé.

ÀWỌN ÀGBÀLÁ

15. Àwọn wo ló ń ṣiṣẹ́ nínú àgbàlá àgọ́ ìjọsìn?

15 Báwọn Júù ṣe jọ́sìn. Inú àgbàlá kan ni àgọ́ ìjọsìn wà, wọ́n sì ṣe ọgbà yí i ká. Ibẹ̀ ni àwọn àlùfáà ti máa ń ṣiṣẹ́. Pẹpẹ bàbà ńlá kan tí wọ́n ń rú ẹbọ sísun lórí ẹ̀ wà nínú àgbàlá náà, bàsíà kan tí wọ́n fi bàbà ṣe tún wà níbẹ̀. Inú ẹ̀ ni àwọn àlùfáà ti máa ń bu omi láti fi wẹ̀ kí wọ́n tó ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́. (Ẹ́kís. 30:17-20; 40:6-8) Nígbà tó yá, àwọn tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ náà ní àgbàlá kan níta tí àwọn tí kì í ṣe àlùfáà ti lè jọ́sìn Ọlọ́run.

16. Àwọn wo ló ń ṣiṣẹ́ nínú àwọn àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí?

16 Báwọn Kristẹni ṣe ń jọ́sìn. Kí àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró tó lọ bá Jésù ṣiṣẹ́ àlùfáà lọ́run, wọ́n máa ṣiṣẹ́ ní àgbàlá inú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tó wà láyé. Omi tó wà nínú bàsíà ńlá ń rán àwọn ẹni àmì òróró létí pé, ó yẹ kí wọ́n jẹ́ mímọ́ nínú ìwà wọn àti nínú ìjọsìn wọn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ń rán àwa Kristẹni yòókù létí. Ibo wá ni “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó ń ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lẹ́yìn gbágbáágbá ti ń jọ́sìn? Àpọ́sítélì Jòhánù rí wọn tí “wọ́n dúró níwájú ìtẹ́.” Ní ayé níbí, iwájú ìtẹ́ yẹn ló ṣàpẹẹrẹ àgbàlá ìta níbi tí “wọ́n [ti] ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún [Ọlọ́run] tọ̀sántòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.” (Ìfi. 7:9, 13-15) A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà jẹ́ ká máa jọ́sìn òun nínú tẹ́ńpìlì ńlá rẹ̀ tẹ̀mí!

ÀǸFÀÀNÍ TÁ A NÍ LÁTI JỌ́SÌN JÈHÓFÀ

17. Ẹbọ wo la láǹfààní láti rú sí Jèhófà?

17 Gbogbo àwa Kristẹni lónìí láǹfààní láti rúbọ sí Jèhófà bá a ṣe ń lo àkókò wa, okun wa àti ohun ìní wa láti mú kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú. Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ fáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù, ó yẹ “ká máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nípasẹ̀ rẹ̀ nígbà gbogbo, ìyẹn èso ètè wa tó ń kéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba.” (Héb. 13:15) Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti jọ́sìn Jèhófà bá a ṣe ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.

18.Hébérù 10:22-25 ṣe sọ, kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe, kí ni ò sì yẹ ká gbàgbé?

18 Ka Hébérù 10:22-25. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ parí lẹ́tà tó kọ sáwọn Hébérù, ó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe tá a bá ń jọ́sìn Jèhófà. Àwọn nǹkan náà ni: ká máa gbàdúrà sí Jèhófà, ká máa wàásù fáwọn èèyàn, ká máa lọ sípàdé, ká sì máa fún ara wa níṣìírí “ní pàtàkì jù lọ bí [a] ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” Nígbà tí ìwé Ìfihàn ń parí lọ, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni áńgẹ́lì Jèhófà sọ gbólóhùn yìí pé: “Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn!” (Ìfi. 19:10; 22:9) Torí náà, ká má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ tá a kọ́ nípa tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí, ká sì mọyì àǹfààní tá a ní láti máa jọ́sìn Ọlọ́run wa atóbilọ́lá!

ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ

a Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ ni ẹ̀kọ́ nípa tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Jèhófà. Kí ni tẹ́ńpìlì náà? Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí ìwé Hébérù sọ nípa tẹ́ńpìlì yẹn. Ó sì máa jẹ́ kó o túbọ̀ mọyì àǹfààní tó o ní láti jọ́sìn Jèhófà.

b Kó o lè mọ àwọn nǹkan tí ìwé Hébérù sọ, wo fídíò náà Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Hébérù lórí ìkànnì jw.org.

c Ìwé Hébérù nìkan ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó pe Jésù ní Àlùfáà Àgbà.

d Bí ìwé kan ṣe sọ, àwọn àlùfáà àgbà tó tó nǹkan bí ọgọ́rin ó lé mẹ́rìn (84) ló ti jẹ ní Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n fi máa pa tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 70 S. K.

e Kó o lè lóye ohun tí àlùfáà àgbà ń ṣe ní Ọjọ́ Ètùtù wo fídíò náà, Àgọ́ Ìjọsìn lórí ìkànnì jw.org.