Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́
Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Àwọn Òye Tuntun Tá A Ní?
Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé à ń gbé lákòókò tí Jèhófà ń jẹ́ ká lóye Bíbélì ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. (Dán. 12:4) Síbẹ̀, ó lè má rọrùn fún wa láti rántí àtúnṣe àlàyé ẹsẹ Bíbélì kan tí ètò Ọlọ́run ṣe. Torí náà, ibo la ti lè rí àwọn àtúnṣe náà àti àlàyé tá a ṣe?
• Tó o bá wo ìwé Watch Tower Publications Index, wàá rí àkòrí náà “Beliefs Clarified.” Gbogbo àtúnṣe tá a ṣe sí òye tá a ní tẹ́lẹ̀ ló wà níbẹ̀, a sì to ọdún tá a ṣe àwọn àtúnṣe náà tẹ̀ léra wọn. Kó o lè rí àwọn àkòrí náà, tẹ “understanding clarified” (rí i pé ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí wà láàárín àmì àyọlọ̀) sínú àpótí tá a fi ń wá ọ̀rọ̀ lórí Watchtower Library tàbí Watchtower ONLINE LIBRARY™.
• Tó o bá wo Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wàá rí àwọn àkòrí tá a pín sí oríṣiríṣi ìsọ̀rí. Lọ sí “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà,” wàá rí àkòrí náà “Ojú Ìwòye àti Ìgbàgbọ́,” lẹ́yìn náà lọ sí “Ìlàlóye Nípa Àwọn Ohun Tá A Gbà Gbọ́.”
Tó o bá fẹ́ dá kẹ́kọ̀ọ́, o ò ṣe mú àkòrí kan tá a ṣàtúnṣe ẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, kó o wá ṣèwádìí nípa òye tuntun tá a ní nípa ẹ̀ àtàwọn ẹsẹ Bíbélì tó jẹ́ ká ṣàtúnṣe òye ti tẹ́lẹ̀?