1924—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn
ÌWÉ Bulletin a tó jáde ní January 1924 sọ pé: “Níbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, ó máa dáa gan-an tí gbogbo àwọn tó ti fi ara wọn fún Olúwa, tí wọ́n sì ti ṣèrìbọmi . . . bá lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ọlọ́run.” Lọ́dún yẹn, nǹkan méjì làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ṣe kí wọ́n lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò. Àkọ́kọ́, wọ́n ṣe irin iṣẹ́ tí wọ́n á fi máa wàásù. Ìkejì, wọ́n wàásù láìbẹ̀rù.
WỌ́N DÁ ILÉ IṢẸ́ RÉDÍÒ KAN SÍLẸ̀
Ó ti ju ọdún kan lọ táwọn arákùnrin tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ti ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè dá ilé iṣẹ́ rédíò WBBR sílẹ̀ ní Staten Island, nílùú New York. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣán igbó ibi tí wọ́n fẹ́ kọ́ ilé iṣẹ́ náà sí, wọ́n kọ́ ilé táwọn òṣìṣẹ́ á máa gbé àti ilé tí wọ́n máa to irinṣẹ́ sí. Nígbà tí wọ́n kọ́ ilé náà tán, àwọn arákùnrin yẹn wá bẹ̀rẹ̀ sí í to irinṣẹ́ náà pọ̀, kí wọ́n lè máa fi “gbóhùn sáfẹ́fẹ́.” Àmọ́, wọ́n láwọn ìṣòro kan bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ náà lọ.
Nígbà táwọn arákùnrin yẹn fẹ́ ri áńtẹ́nà táá jẹ́ kí wọ́n lè máa gbóhùn sáfẹ́fẹ́, ó nira gan-an. Wọ́n gbọ́dọ̀ gbé áńtẹ́nà tó gùn tó mítà mọ́kànléláàádọ́rùn-ún (91) kọ́ sáàárín igi méjì tí ìkọ̀ọ̀kan wọn gùn tó mítà mọ́kànlélọ́gọ́ta (61). Nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n gbé e kọ́, wọn ò rí i ṣe. Àmọ́ wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín wọ́n rí i ṣe. Arákùnrin Calvin Prosser tó wà lára àwọn tó ṣiṣẹ́ náà sọ pé: “Ká sọ pé a rí i ṣe nígbà àkọ́kọ́ ni, ńṣe la ò bá yin ara wa pé, ‘Ẹ wo iṣẹ́ ribiribi tá a ṣe!’” Dípò bẹ́ẹ̀, Jèhófà ni wọ́n gbógo fún. Ṣùgbọ́n ìṣòro wọn ṣì kù, kò tíì tán.
Nígbà yẹn, wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dá ilé iṣẹ́ rédíò sílẹ̀ kárí ayé ni, kò sì rọrùn láti rí àwọn nǹkan tá a nílò rà. Àmọ́, àwọn arákùnrin rí ẹnì kan lágbègbè wọn tó fẹ́ ta àlòkù ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́, wọ́n sì rà á. Dípò kí wọ́n ra makirofóònù tuntun, èyí tó wà nínú tẹlifóònù ni wọ́n lò. Ní alẹ́ ọjọ́ kan ní February, àwọn arákùnrin yẹn pinnu láti dán àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n ní wò, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá wọ́n ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Ìyẹn sì gba pé kí wọ́n ní ètò kan tí wọ́n máa gbé sáfẹ́fẹ́, torí náà wọ́n kọrin Ìjọba Ọlọ́run. b tó wà ní Brooklyn ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) síbi tí wọ́n ti ń kọrin gbọ́ orin náà lórí rédíò ẹ̀, ó sì fi fóònù pè wọ́n.
Arákùnrin Ernest Lowe rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn nígbà tí wọ́n ń kọrin. Judge RutherfordArákùnrin Rutherford wá sọ fún wọn pé: “Ẹ dákẹ́ jàre, ariwo yín ti pọ̀ jù! Àfi bíi pé ẹ̀ ń han.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kó ìtìjú bá wọn, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n pa ẹ̀rọ tó ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ náà. Àmọ́, ó ti wá dá wọn lójú pé ẹ̀rọ náà ti ń ṣiṣẹ́ dáadáa, àwọn sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó.
Ní February 24, 1924, ìyẹn ọjọ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n gbé ètò sáfẹ́fẹ́, Arákùnrin Rutherford ya ilé iṣẹ́ rédíò náà sí mímọ́, ó sì ní wọ́n á máa fi ṣe “iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tí Kristi gbé lé wọn lọ́wọ́.” Ó sọ pé ìdí tí wọ́n fi dá ilé iṣẹ́ rédíò náà sílẹ̀ ni pé kí wọ́n lè máa fi “kọ́ gbogbo èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n sì lè mọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé, láìka ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí.”
A ò lè gbàgbé ọjọ́ àkọ́kọ́ yẹn torí pé Jèhófà jẹ́ kí gbogbo nǹkan lọ dáadáa. Ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) sì ni ètò Ọlọ́run fi lo ilé iṣẹ́ rédíò WBBR yẹn láti wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn.
WỌ́N FÌGBOYÀ TÚ ÀṢÍRÍ ÀWỌN ÀLÙFÁÀ ṢỌ́Ọ̀ṢÌ
Ní July 1924, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé jọ sílùú Columbus, Ohio láti ṣe àpéjọ agbègbè kan. Kárí ayé làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti wá sí àpéjọ yẹn, wọ́n sì gbọ́ àsọyé ní èdè Lárúbáwá, Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, Jámánì, Gíríìkì, Hungary, Ítálì, Lithuania, Polish, Rọ́ṣíà, Ukraine àtàwọn èdè tí wọ́n ń sọ lágbègbè Scandinavia. Wọ́n fi rédíò gbé apá kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà sáfẹ́fẹ́, wọ́n sì tún ṣètò pé kí ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ Ohio State Journal gbé ohun tó bá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan àpéjọ náà jáde.
Nígbà tó fi máa di Thursday, July 24, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) lọ ló wàásù nílùú tá a ti ṣe àpéjọ náà. Ìwé tí wọ́n fún àwọn èèyàn tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000), wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ pé ọjọ́ yẹn ni “inú àwọn ará dùn jù ní àpéjọ yẹn.”
Ní Friday, July 25, ohun kan ṣẹlẹ̀ nígbà tí Arákùnrin Rutherford ń sọ àsọyé ẹ̀, ó ka ọ̀rọ̀ kan jáde tó fi tú àṣírí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì. Ó sọ pé àwọn olóṣèlú, àwọn olórí ẹ̀sìn àtàwọn
oníṣòwò “ò jẹ́ káwọn èèyàn mọ òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn Ìjọba tí Ọlọ́run máa lò láti bù kún aráyé.” Yàtọ̀ síyẹn, ó tún sọ pé kò yẹ káwọn olóṣèlú, àwọn olórí ẹ̀sìn àtàwọn oníṣòwò “fọwọ́ sí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, kò sì yẹ kí wọ́n sọ pé ‘òun ni ìjọba tí Ọlọ́run máa lò láti yanjú ìṣòro aráyé.’” Torí náà, ó máa gba pé káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígboyà kí wọ́n tó lè wàásù ọ̀rọ̀ yìí fáwọn èèyàn.Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ ń sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní táwọn ará tó wá sí àpéjọ yẹn rí, ó sọ pé: “Ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ogun Olúwa tó wá sí àpéjọ ìlú Columbus ti túbọ̀ lágbára nígbà tí wọ́n fi máa pa dà sílé . . . , wọ́n sì ti nígboyà láti wàásù láìka inúnibíni sí.” Arákùnrun Leo Claus tó lọ sí àpéjọ agbègbè yẹn sọ pé: “Lẹ́yìn tí àpéjọ náà parí, ara wa ti wà lọ́nà láti wàásù ọ̀rọ̀ náà fáwọn èèyàn ní agbègbè wa.”
Ní October, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìléwọ́ kan tó ń jẹ́ Ecclesiastics Indicted, àsọyé tí Arákùnrin Rutherford sọ ló wà nínú ìwé náà. Ní ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Cleveland ní ìpínlẹ̀ Oklahoma, kò pẹ́ tí Frank Johnson fi pín ìwé fún gbogbo èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n yàn fún un, kódà ogún (20) ìṣẹ́jú ló fi dúró de àwọn ará kí wọ́n tó wá bá a. Kò lè dúró síta gbangba torí pé àwọn èèyàn tínú ń bí ń wá a kiri nítorí iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe. Torí náà, Arákùnrin Johnson sá pa mọ́ sínú ṣọ́ọ̀ṣì tó wà nítòsí. Kò sí ẹnì kankan nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà, àmọ́ kó tó máa lọ, ó fi ìwé ìléwọ́ Ecclesiastics Indicted sínú Bíbélì pásítọ̀ wọn àti sórí ìjókòó kọ̀ọ̀kan nínú ṣọ́ọ̀sì náà. Lẹ́yìn tó ṣe tán, ó kúrò níbẹ̀ kíákíá. Nígbà tó rí i pé àkókò ṣì wà, ó lọ sí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì méjì míì, ó sì ṣe ohun kan náà.
Arákùnrin Frank wá tètè pa dà síbi tó ti ń dúró de àwọn ará. Ó sá pa mọ́ sẹ́yìn ilé epo kan, ó sì ń yọjú wòta bóyá àwọn tó ń wá òun máa kọjá. Lóòótọ́, àwọn ọkùnrin tó ń wá a yẹn wa mọ́tò kọjá, àmọ́ wọn ò rí i. Báwọn tó ń wá Frank ṣe lọ tán báyìí làwọn ará tó ń wàásù nítòsí dé, wọ́n sì fi mọ́tò gbé e lọ.
Arákùnrin kan rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Bá a ṣe ń fi ìlú náà sílẹ̀, a gba iwájú ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà kọjá. Àwọn èèyàn tó tó nǹkan bí àádọ́ta (50) ló dúró síwájú ṣọ́ọ̀ṣì kọ̀ọ̀kan. Àwọn kan ń ka ìwé ìléwọ́ náà, àwọn míì sì fi ń han pásítọ̀ wọn. Torí náà, a tètè fibẹ̀ sílẹ̀ kí wàhálà tó ṣẹlẹ̀! Àmọ́, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run wa tó dáàbò bò wá, tó fún wa lọ́gbọ́n tá a fi pín ìwé ìléwọ́ yẹn, tí ò sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ wá.”
ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ FÌGBOYÀ WÀÁSÙ
Láwọn orílẹ̀-èdè míì, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í fìgboyà wàásù bíi tàwọn ará yẹn. Ní àríwá orílẹ̀-èdè Faransé, Arákùnrin Józef Krett wàásù fáwọn ọmọ ilẹ̀ Poland kan tó ń wa kùsà. Ètò Ọlọ́run ní kó sọ àsọyé kan tí àkòrí ẹ̀ jẹ́, “Àwọn Òkú Ò Ní Pẹ́ Jíǹde.” Nígbà tí wọ́n pín ìwé tí wọ́n fi pe àwọn èèyàn wá síbi àsọyé náà, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan kìlọ̀ fáwọn ọmọ ìjọ ẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ lọ. Ohun tí ò fẹ́ káwọn ọmọ ìjọ ẹ̀ ṣe gan-an ni wọ́n ṣe. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé àwọn tó ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) lọ, títí kan àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì yẹn ló wá gbọ́ àsọyé náà! Arákùnrin Krett sọ pé kí àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì náà wá ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́, àmọ́ ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn àsọyé náà, Arákùnrin Krett pín gbogbo ìwé ńlá àti ìwé pẹlẹbẹ tó wà lọ́wọ́ ẹ̀ fáwọn èèyàn yẹn torí pé wọ́n fẹ́ mọ̀ sí i nípa Ọlọ́run.—Émọ́sì 8:11.
Arákùnrin Claude Brown wá sí Áfíríkà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní Gold Coast, tí wọ́n ń pè ní orílẹ̀-èdè Gánà báyìí. Àwọn àsọyé tó sọ àtàwọn ìwé tó pín jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ òtítọ́ lórílẹ̀-èdè náà. John Blankson tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí
wọ́n ṣe ń ṣe oògùn ní ilé ẹ̀kọ́ gíga wá gbọ́ ọ̀kan lára àsọyé Arákùnrin Brown. Kò pẹ́ rárá tó fi mọ̀ pé òun ti rí òtítọ́. Nígbà tó rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Òtítọ́ tí mo mọ̀ múnú mi dùn gan-an, gbogbo ìgbà ni mo sì máa ń sọ ohun tí mò ń kọ́ fáwọn tá a jọ wà nílé ẹ̀kọ́.”Lọ́jọ́ kan, John lọ bá àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Anglican kan, ó sì bi í ní ìbéèrè nípa ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan torí John ti wá mọ̀ pé ẹ̀kọ́ náà ò sí nínú Bíbélì. Ni àlùfáà náà bá lé e dà nù, ó sì pariwo mọ́ ọn pé: “O kì í ṣe Kristẹni, ọmọ Èṣù ni ẹ́. Jáde kúrò ńbí!”
Nígbà tó délé, ó kọ lẹ́tà sí àlùfáà náà, ó sì ní kó wá ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan lójú gbogbo èèyàn. Ni àlùfáà bá ránṣẹ́ sí John pé olùkọ́ àgbà ilé ìwé wọn ní kó máa bọ̀ ní ọ́fíìsì òun. Nígbà tó débẹ̀, olùkọ́ àgbà náà bi í pé, “ṣé lóòótọ́ lo kọ lẹ́tà sí àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Anglican?”
John dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni Sà.”
Ni olùkọ́ àgbà bá ní kí John kọ lẹ́tà sí àlùfáà pé kó má bínú. Torí náà, ó kọ lẹ́tà, ó sì sọ pé:
“Sà, olùkọ́ àgbà ní kí n kọ lẹ́tà sí yín pé kẹ́ ẹ má bínú. Mo gbà láti kọ lẹ́tà náà, àmọ́ ẹ gbọ́dọ̀ sọ fáwọn èèyàn pé ẹ̀kọ́ èké lẹ fi ń kọ́ wọn.”
Ohun tó sọ nínú lẹ́tà náà ya olùkọ́ àgbà lẹ́nu, ló bá ní: “Blankson, ṣé ohun tó o fẹ́ kọ nìyí?”
“Bẹ́ẹ̀ ni Sà. Ohun tí mo fẹ́ kọ nìyẹn.”
“A máa lé ẹ kúrò nílé ìwé yìí ni. Ṣé o rò pé o lè sọ̀rọ̀ bó ṣe wù ẹ́ sí àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ìjọba, kó o sì máa kàwé lọ nílé ìwé ìjọba?”
“Àmọ́ Sà, . . . tẹ́ ẹ bá ń kọ́ wa ní nǹkan, tí ò sì yé wa, a ṣáà máa ń bi yín ní ìbéèrè?”
“Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ máa ń béèrè.”
“Ohun tí mo ṣe nìyẹn o tó ń bí àlùfáà nínú. Wọ́n kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí ò yé mi, mo sì bi wọ́n níbèérè. Ṣé ó wá yẹ kí n kọ lẹ́tà pé kí wọ́n má bínú nígbà tí wọn ò lè dáhùn ìbéèrè mi?”
Bí wọ́n ṣe fi Blankson sílẹ̀ nìyẹn o, wọn ò lé e kúrò nílé ìwé, kò sì kọ lẹ́tà pé kí àlùfáà má bínú.
INÚ ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ DÙN LÁTI ṢE PÚPỌ̀ SÍ I
Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ ń sọ̀rọ̀ nípa gbogbo nǹkan tá a ṣe lọ́dún yẹn, ó ní: “Àwa náà lè sọ bíi ti Dáfídì pé: ‘O gbé agbára ogun wọ̀ mí.’ (Sáàmù 18:39, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.) Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún yẹn fún wa níṣìírí gan-an torí a rí bí Olúwa ṣe ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa . . . Inú àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́ . . . sì ń dùn bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere.”
Nígbà tí ọdún 1924 ń parí lọ, àwọn arákùnrin yẹn ṣètò bí wọ́n ṣe máa ní ilé iṣẹ́ rédíò míì. Ni wọ́n bá kọ́ ilé iṣẹ́ rédíò tuntun kan sítòsí ìlú Chicago. Orúkọ tí wọ́n sọ ilé iṣẹ́ rédíò tuntun náà ni WORD, tó túmọ̀ sí Ọ̀RỌ̀. Torí pé ẹ̀rọ tí wọ́n ń lò níbẹ̀ lágbára gan-an, àwọn èèyàn tó wà níbi tó jìnnà gan-an títí dé àríwá ìlú Kánádà máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n ń gbé sáfẹ́fẹ́.
Nígbà tó fi máa di ọdún 1925, Jèhófà ran àwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ohun tó wà nínú Ìfihàn orí 12. Àmọ́, àwọn kan ò sin Jèhófà mọ́ nítorí òye tuntun yìí. Inú wa dùn pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn Jèhófà nígbà yẹn fara mọ́ òye tuntun yẹn torí pé ó jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́run àti bó ṣe kan àwa èèyàn Jèhófà láyé.