Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́

Máa Ṣàtúnyẹ̀wò Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Tó O Kọ́

Máa Ṣàtúnyẹ̀wò Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Tó O Kọ́

Ṣé ó ti ṣe ẹ́ rí pé o ò rántí ohun tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́? Gbogbo wa nirú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ sí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? Máa ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́.

Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, máa dánu dúró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kó o lè wo àwọn kókó pàtàkì inú ẹ̀kọ́ náà. Wo bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe mú káwọn tó ń ka lẹ́tà ẹ̀ kíyè sí ọ̀rọ̀ tó ń sọ, ó ní: “Kókó ọ̀rọ̀ tí à ń sọ nìyí.” (Héb. 8:1) Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn mú káwọn tó ń kàwé ẹ̀ lóye ohun tó ń sọ, kí wọ́n sì rí bí ọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣe bọ́gbọ́n mu tó.

Lẹ́yìn tó o bá ti kẹ́kọ̀ọ́ tán, o lè lo ìṣẹ́jú díẹ̀, bóyá ìṣẹ́jú mẹ́wàá láti fi ronú nípa àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó o ti kọ́. Tó ò bá lè rántí nǹkan tó o kọ́, wo àwọn ìsọ̀rí ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan tàbí kó o ka gbólóhùn tó máa ń bẹ̀rẹ̀ ìpínrọ̀ kó o lè rántí ẹ̀kọ́ náà. Tó o bá kọ́ ohun tuntun, gbìyànjú láti ṣàlàyé ẹ̀ lọ́rọ̀ ara ẹ. Tó o bá ń tún àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì ohun tó o kọ́ yẹ̀ wò, wàá máa rántí àwọn ẹ̀kọ́ náà, wàá sì tún rí bí wọ́n ṣe máa ṣe ẹ́ láǹfààní.