Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Báwo ni ibi àbáwọlé tó wà níwájú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ ṣe ga tó?
Ibi àbáwọlé ni wọ́n máa ń gbà wọ Ibi Mímọ́ nínú tẹ́ńpìlì. Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a ṣe ṣáájú ọdún 2023 sọ pé: “Ibi àbáwọlé tó wà níwájú jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó bá fífẹ̀ ilé náà mu, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́fà (120).” (2 Kíró. 3:4) Àwọn Bíbélì míì náà sọ pé gíga ibi àbáwọlé náà jẹ́ “ọgọ́fà (120) ìgbọ̀nwọ́” tàbí mítà mẹ́tàléláàádọ́ta (53), ìyẹn ni pé á ga tó ilé alájà mẹ́rìndínlógún (16)!
Àmọ́, nígbà tí Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a ṣe lọ́dún 2023 ń sọ̀rọ̀ nípa ibi àbáwọlé tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì, ó sọ pé: “Gíga rẹ̀ . . . jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́” tàbí mítà mẹ́sàn-án. a Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tí wọ́n fi ṣe àtúnṣe yẹn.
Wọn ò sọ bí ibi àbáwọlé náà ṣe ga tó ní 1 Àwọn Ọba 6:3. Jeremáyà tó kọ Bíbélì yìí ò sọ bí ibi àbáwọlé náà ṣe ga tó, àmọ́ ó sọ bó ṣe gùn àti bó ṣe fẹ̀ tó. Lẹ́yìn náà, orí tó tẹ̀ lé e sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn apá pàtàkì inú tẹ́ńpìlì náà, irú bí irin tó fi ṣe Òkun, kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wàá àti òpó bàbà méjì tó wà níwájú ibi àbáwọlé. (1 Ọba 7:15-37) Tí ibi àbáwọlé náà bá ga ju àádọ́ta (50) mítà lọ, tó sì ga ju apá yòókù lára tẹ́ńpìlì náà, kí ló dé tí Jeremáyà ò fi sọ bó ṣe ga tó nínú 1 Àwọn Ọba 6:3? Kódà ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn òpìtàn Júù sọ pé ibi àbáwọlé náà ò ga ju apá yòókù lára tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì lọ.
Àwọn ọ̀mọ̀wé ò gbà pé ògiri tẹ́ńpìlì náà ga tó ọgọ́fà (120) ìgbọ̀nwọ́ tí wọ́n sọ pé ibi àbáwọlé náà jẹ́. Láyé àtijọ́, àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń fi òkúta àti bíríkì kọ́, tó sì ga fíofío máa ń fẹ̀ nísàlẹ̀, á wá kéré lókè. Àpẹẹrẹ kan ni ẹnubodè tẹ́ńpìlì tó wà ní Íjíbítì. Àmọ́ tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì yàtọ̀ ní tiẹ̀. Àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé ògiri ẹ̀ ò fẹ̀ ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́sàn-án lọ. Òpìtàn Theodor Busink tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé sọ pé: “Tá a bá wo bí fífẹ̀ ògiri [àbáwọlé tẹ́ńpìlì] náà ṣe rí, ibi àbáwọlé náà ò lè ga tó ọgọ́fà (120) ìgbọ̀nwọ́.”
Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣàṣìṣe nígbà tí wọ́n ń ṣàdàkọ ọ̀rọ̀ inú 2 Kíróníkà 3:4. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ kan sọ pé “ọgọ́fà” (120) ìgbọ̀nwọ́ ni wọ́n lò nínú ẹsẹ yìí, àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì bíi Codex Alexandrinus tí wọ́n ṣe ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ (1,500) ọdún sẹ́yìn àti Codex Ambrosianus tí wọ́n ṣe ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (1,400) ọdún sẹ́yìn sọ pé “ogún” (20) ìgbọ̀nwọ́ ni wọ́n lò nínú ẹsẹ yẹn. Kí ló lè mú kí adàwékọ kan ṣèèṣì kọ “ọgọ́fà” (120) ìgbọ̀nwọ́? Ohun tó lè mú kó ṣàṣìṣe ni pé bí wọ́n ṣe ń kọ “ọgọ́rùn-ún” àti “ìgbọ̀nwọ́” jọra gan-an lédè Hébérù. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí adàwékọ náà kọ “ọgọ́rùn-ún,” dípò kó kọ “ìgbọ̀nwọ́.”
Òótọ́ ni pé a sapá láti mọ bí tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì ṣe rí gan-an, àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa ni ohun tí tẹ́ńpìlì náà ṣàpẹẹrẹ, ìyẹn tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí. A dúpẹ́ gan-an pé Jèhófà pe gbogbo àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ká lè máa jọ́sìn nínú tẹ́ńpìlì náà!—Héb. 9:11-14; Ìfi. 3:12; 7:9-17.
a Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé jẹ́ ká mọ̀ pé “àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ kan lo ‘ọgọ́fà’ (120) ìgbọ̀nwọ́, àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì àtàwọn Bíbélì kan sì lo ‘ogún (20) ìgbọ̀nwọ́.’”