Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Kí Jèhófà Máa Tọ́ Ẹ Sọ́nà

Jẹ́ Kí Jèhófà Máa Tọ́ Ẹ Sọ́nà

Ọ̀DỌ́BÌNRIN KAN ṢÈPINNU TÓ BỌ́GBỌ́N MU LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ POLAND

“ỌMỌ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ni mí nígbà tí mo ṣèrìbọmi, oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà sì ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Lẹ́yìn ọdún kan, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Nígbà tí mo kúrò nílé ẹ̀kọ́ girama, mo pinnu láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Mo fẹ́ kúrò nílùú ìbílẹ̀ mi, kí n sì rìn jìnnà sí ìyá ìyá mi tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ nígbà tí alábòójútó àyíká sọ fún mi pé ìlú ìbílẹ̀ mi gan-an ni ìpínlẹ̀ ìwàásù mi, inú mi ò dùn rárá, síbẹ̀ mi ò jẹ́ kó mọ bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe rí lára mi. Ìbànújẹ́ wá sorí mi kodò, mo wábì kan lọ, mo sì ń ronú nípa ohun tó sọ. Mo wá sọ fún ẹni tá a jọ ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà pé: ‘Ó dà bíi pé mo ti fẹ́ máa ṣe bíi ti Jónà. Àmọ́ nígbà tó yá, Jónà pa dà lọ sí Nínéfè tí Jèhófà rán an lọ. Torí náà, ibi tí wọ́n ní kémi náà ti ṣiṣẹ́ ni màá ti ṣiṣẹ́.’

“Ọdún kẹrin rèé tí mo ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú mi, mo sì ti wá rí i pé ó bọ́gbọ́n mu bí mo ṣe tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n fún mi. Ojú tí mo fi ń wo nǹkan gan-an ni ìṣòro tí mo ní tẹ́lẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, iṣẹ́ ìsìn mi ti ń fún mi láyọ̀, kódà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́rìnlélógún [24] ni mò ń darí lóṣooṣù. Ohun míì tó tún múnú mi dùn ni pé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìyá ìyá mi lẹ́kọ̀ọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀. Ọpẹ́ ni fún Jèhófà.”

ÌPINNU TÓ SÈSO RERE LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ FÍJÌ

Ohun kan wáyé tó gba pé kí obìnrin kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Fíjì ṣe ìpinnu. Òpin ọ̀sẹ̀ tí àpéjọ àgbègbè bọ́ sí ni ọ̀kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí ọkọ rẹ̀ fẹ́ ṣe ọjọ́ ìbí. Ọkọ rẹ̀ gbà pé kó lọ sí àpéjọ náà. Ó wá sọ fún ọkọ rẹ̀ pé òun á wá bá a lọ́hùn-ún tí àpéjọ náà bá parí. Àmọ́ lẹ́yìn tó dé láti àpéjọ, ó pinnu pé kò ní dáa bí òun bá lọ́wọ́ sí ohun tó máa da ẹ̀rí ọkàn òun láàmú. Torí náà, kò lọ.

Níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí náà, ọkọ rẹ̀ sọ fáwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ pé ìyàwó òun máa wá tó bá ti kúrò ní “ìpàdé àwọn Ajẹ́rìí” tó lọ, ni wọ́n bá sọ fún un pé, “Kò ní wá, àwọn Ajẹ́rìí kì í ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí.” *

Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an náà ni wọ́n ti sọ yẹn, ìyàwó rẹ̀ ò yọjú. Inú ọkùnrin náà dùn pé ìyàwó òun fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn ohun tó gbà gbọ́, àti pé ìyàwó òun kì í ṣe ohun tó máa da ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ láàmú. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fún obìnrin náà láǹfààní láti wàásù fún ọkọ rẹ̀ àtàwọn míì. Èyí mú kí ọkọ rẹ̀ gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 7 Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ December 15, 2001.