Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Rọ Jọwọrọ’

‘Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Rọ Jọwọrọ’

Má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ rọ jọwọrọ.”​—SEF. 3:16.

ORIN: 81, 32

1, 2. (a) Àwọn ìṣòro wo là ń kojú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, kí sì nìyẹn máa ń fà? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 41:​10, 13 fi dá wa lójú?

ARÁBÌNRIN kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé tí ọkọ rẹ̀ sì tún jẹ́ alàgbà sọ pé: “Ọwọ́ mi máa ń dí gan-an nínú ìjọsìn Jèhófà, mi ò sì fi ọ̀rọ̀ àdúrà àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ ṣeré. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń ṣàníyàn. Kì í jẹ́ kí n rí oorun sùn, ó máa ń mú kó rẹ̀ mí, mo sì máa ń kanra mọ́ àwọn èèyàn. Kódà nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi kílẹ̀ lanu kó sì gbé mi mì.”

2 Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin yẹn ti ṣe ẹ́ rí? Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìṣòro làwa èèyàn ń kojú nínú ayé Èṣù yìí, àwọn ìṣòro náà máa ń mú kéèyàn ṣàníyàn, kéèyàn sì rẹ̀wẹ̀sì. A lè fi àníyàn téèyàn máa ń ní wé ìdákọ̀ró tí kì í jẹ́ kí ọkọ̀ ojú omi kúrò lójú kan. (Òwe 12:25) Kí ló máa ń fa àníyàn? Ó lè jẹ́ pé èèyàn wa kan ṣaláìsí, tàbí ara wa ò fi bẹ́ẹ̀ le, ó lè jẹ́ ìṣòro àtijẹ àtimu torí ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀, ó sì lè jẹ́ pé wọ́n ń ta kò wá torí pé à ń sin Jèhófà. Àwọn ìṣòro yìí lè mú kí nǹkan tojú súni, ó sì máa ń tánni lókun. Kódà, ó lè mú kéèyàn má láyọ̀ mọ́. Àmọ́ o, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.​—⁠Ka Aísáyà 41:​10, 13.

3, 4. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ọwọ́”? (b) Àwọn nǹkan wo ló lè mú kí ọwọ́ ẹnì kan rọ jọwọrọ?

3 Bíbélì sábà máa ń lo àwọn ẹ̀yà ara láti ṣàpèjúwe àwọn nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bíbélì mẹ́nu kan ọwọ́. Tí Bíbélì bá sọ pé wọ́n fún ọwọ́ ẹnì kan lókun, ó túmọ̀ sí pé wọ́n fún onítọ̀hún ní ìṣírí, wọ́n sì fún un lágbára kó lè gbára dì láti ṣe ohun kan. (1 Sám. 23:16; Ẹ́sírà 1:⁠6) Ó tún lè túmọ̀ sí pé kéèyàn nírètí pé ọ̀la máa dáa.

4 Tí Bíbélì bá sọ pé ọwọ́ ẹnì kan rọ jọwọrọ, ó sábà máa ń túmọ̀ sí pé onítọ̀hún rẹ̀wẹ̀sì, nǹkan tojú sú u tàbí pé ó sọ̀rètí nù. (2 Kíró. 15:7; Héb. 12:12) Àwọn nǹkan yìí lè máyé súni. Tó o bá ń kojú àwọn ìṣòro tó ń tánni lókun, tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ tàbí tí kò jẹ́ kó o ṣe dáadáa nínú ìjọsìn Ọlọ́run mọ́, kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Kí ló máa fún ẹ lókun táá sì máa fún ẹ láyọ̀ bó o ṣe ń fara dà á?

‘ỌWỌ́ JÈHÓFÀ KÒ KÚRÚ JÙ LÁTI GBANI LÀ’

5. (a) Kí la lè ṣe tí ìṣòro bá dé, kí ló sì yẹ ká máa rántí? (b) Kí la máa jíròrò báyìí?

5 Ka Sefanáyà 3:​16, 17. Jèhófà Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ kò fẹ́ ká máa bẹ̀rù tàbí ká rẹ̀wẹ̀sì, torí ṣe nìyẹn máa dà bí ìgbà téèyàn jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ rọ jọwọrọ. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi rọ̀ wá pé ká ‘kó gbogbo àníyàn wa lé òun.’ (1 Pét. 5:⁠7) Ẹ jẹ́ ká máa rántí ohun tí Ọlọ́run sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé ọwọ́ òun ‘kò kúrú jù láti gbà’ wọ́n là. (Aísá. 59:⁠1) A máa jíròrò àpẹẹrẹ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ táá jẹ́ ká rí i pé Jèhófà lè fún àwa èèyàn rẹ̀ lókun láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láìka àwọn ìṣòro wa sí, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ronú nípa báwọn àpẹẹrẹ yẹn ṣe lè fún wa lókun.

6, 7. Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ látinú bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámálékì?

6 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì làwọn ọmọ Ámálékì gbéjà kò wọ́n. Mósè sọ pé kí Jóṣúà kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sójú ogun. Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè mú Áárónì àti Húrì lọ sórí òkè kan tí wọ́n á ti lè rí ìjà náà dáadáa. Kí nìdí tí Mósè àtàwọn ọkùnrin méjì yìí fi lọ síbẹ̀? Ṣé arógunsá ni wọ́n ni? Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀!

7 Mósè ṣe ohun kan tó jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́gun. Ó fọwọ́ méjèèjì gbé ọ̀pá Ọlọ́run tòótọ́ sókè. Gbogbo ìgbà tí ọwọ́ Mósè wà lókè ni Jèhófà ń fún ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lókun láti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámálékì. Àmọ́, nígbà tí ọwọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ro Mósè, àwọn ọmọ Ámálékì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́gun. Nígbà tí Áárónì àti Húrì rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n gbé ìgbésẹ̀ kíákíá láti ran Mósè lọ́wọ́. Wọ́n gbé òkúta kan fún Mósè láti fi jókòó, “Áárónì àti Húrì sì gbé àwọn ọwọ́ rẹ̀ ró, ọ̀kan ní ìhà ìhín àti èkejì ní ìhà ọ̀hún, tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọwọ́ rẹ̀ dúró pa sójú kan títí oòrùn fi wọ̀.” Lọ́jọ́ yẹn, Jèhófà lo ọwọ́ agbára rẹ̀, ó sì mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun ogun náà.​—⁠Ẹ́kís. 17:​8-13.

8. (a) Kí ni Ásà ṣe nígbà táwọn ará Etiópíà gbógun ti ilẹ̀ Júdà? (b) Báwo la ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run bíi ti Ásà?

8 Láwọn ọjọ́ Ásà Ọba, Jèhófà tún fi hàn pé ọwọ́ òun ò kúrú láti gbani là. Ọ̀pọ̀ ogun ni Bíbélì mẹ́nu bà, àmọ́ àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ jù tó kóra jọ láti jà ni ti Síírà ará Etiópíà. Ó ní àwọn akíkanjú ọmọ ogun tí ó tó mílíọ̀nù kan. Àwọn ọmọ ogun Etiópíà fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì àwọn ọmọ ogun Ásà. A lè máa ronú pé ó ṣeé ṣe kí Ásà máa ṣàníyàn, kẹ́rù máa bà á, kó wá torí ìyẹn jẹ́ kọ́wọ́ òun rọ jọwọrọ. Àmọ́, Ásà ò jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí òun, ṣe ló yíjú sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Tá a bá ní ká fojú èèyàn wò ó, ó lè dà bíi pé Ásà ò ní lè ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Etiópíà, àmọ́ “lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.” (Mát. 19:26) Ọlọ́run fi agbára ńlá rẹ̀ hàn, ó sì “ṣẹ́gun àwọn ará Etiópíà níwájú Ásà” torí pé ọkàn rẹ̀ pé “pérépéré pẹ̀lú Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀.”​—⁠2  Kíró. 14:​8-13; 1 Ọba 15:⁠14.

9. (a) Kí ni Nehemáyà kò gbà kó dí òun lọ́wọ́ títún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́? (b) Báwo ni Ọlọ́run ṣe dáhùn àdúrà Nehemáyà?

9 Àpẹẹrẹ míì ni ti Nehemáyà. Wo bó ṣe máa rí lára rẹ̀ nígbà tó lọ sí Jerúsálẹ́mù tó sì rí i pé gbayawu ni ìlú náà wà torí pé ògiri tó yí i ká ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wó tán, ọkàn àwọn Júù tó ń gbébẹ̀ ò sì balẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń halẹ̀ mọ́ wọn káwọn tó ń tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́ bàa lè dáṣẹ́ dúró. Ṣé Nehemáyà náà wá jẹ́ kóhun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn mú òun rẹ̀wẹ̀sì débi pé kò lè ṣiṣẹ́ mọ́? Rárá! Bíi ti Mósè, Ásà àtàwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà míì, Nehemáyà kì í fọ̀rọ̀ àdúrà ṣeré, ó sì máa ń gbára lé Jèhófà. Ohun tó ṣe náà nìyẹn nígbà tó dé Jerúsálẹ́mù. Jèhófà gbọ́ àdúrà Nehemáyà, ó sì mú kí ohun tó dà bí òkè ńlá lójú àwọn Júù di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ọlọ́run lo “agbára ńlá” àti “ọwọ́ líle” rẹ̀ láti fún ọwọ́ àwọn Júù tó ti rọ jọwọrọ lókun. (Ka Nehemáyà 1:10; 2:​17-20; 6:⁠9.) Ṣó dá ẹ lójú pé Jèhófà ṣì ń lo “agbára ńlá” àti “ọwọ́ líle” rẹ̀ láti fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní lókun?

JÈHÓFÀ Á FÚN Ẹ LÓKUN

10, 11. (a) Kí ni Sátánì máa ń ṣe láti mú ká dẹwọ́? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà fún wa lókun àti agbára? (d) Àǹfààní wo lo ti rí látinú àwọn ìpàdé wa àtàwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá à ń gbà?

10 Ohun kan ni pé ojoojúmọ́ ni ọwọ́ Sátánì máa ń dí bó ṣe ń wá ọ̀nà láti dá iṣẹ́ ìwàásù àti ìjọsìn wa dúró. Ó máa ń lo àwọn alákòóso, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn apẹ̀yìndà láti parọ́ mọ́ wa àti láti halẹ̀ mọ́ wa. Kí nìdí tó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó ń wọ́nà àtimú ká dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́, Jèhófà lágbára láti fún wa lókun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, á sì ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Kíró. 29:12) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká gbára lé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ká bàa lè borí àwọn àtakò Sátánì àtàwọn ìṣòro tí ayé Èṣù yìí ń gbé kò wá. (Sm. 18:39; 1 Kọ́r. 10:13) Bákan náà, Jèhófà fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ohun míì tún ni àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì tá à ń rí gbà lóṣooṣù. Ọ̀rọ̀ kan tó ń fúnni níṣìírí wà nínú Sekaráyà 8:​9, 13 (kà á). Ìgbà tí wọ́n ń tún tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́ ni wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí, ó sì dájú pé ọ̀rọ̀ yẹn wúlò fún wa gan-an.

11 Ohun míì tó ń fún wa lókun ni ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá à ń kọ́ láwọn ìpàdé wa, àwọn àpéjọ àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá à ń gbà yìí ń mú kó máa wù wá láti ṣe ohun tó tọ́, ó mú ká ní àfojúsùn nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ó sì máa ń jẹ́ ká bójú tó àwọn ojúṣe wa nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Sm. 119:32) Ṣó máa ń wù ẹ́ láti wà láwọn ibi tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ yìí kó o lè máa rókun gbà?

12. Kí làwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe tá a bá fẹ́ jẹ́ ẹni tẹ̀mí?

12 Jèhófà ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámálékì àtàwọn ará Etiópíà, ó sì tún fún Nehemáyà àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ lágbára láti parí ògiri Jerúsálẹ́mù. Á fún àwa náà lókun láti borí àníyàn, á sì tún ràn wá lọ́wọ́ nígbà táwọn èèyàn bá ta kò wá tàbí nígbà tí wọ́n bá kọtí ikún sí iṣẹ́ ìwàásù wa. Ìrànwọ́ yìí á mú ká lè ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí. (1 Pét. 5:10) A ò retí pé kí Jèhófà ṣe iṣẹ́ ìyanu fún wa, àwa náà lóhun tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Lára ẹ̀ ni pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká máa múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ ká sì máa pésẹ̀ síbẹ̀ déédéé, ká máa dá kẹ́kọ̀ọ́, ká sì máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká má fọ̀rọ̀ àdúrà ṣeré. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gba àwọn nǹkan míì láyè láti dí wa lọ́wọ́ ṣíṣe àwọn nǹkan tá a sọ tán yìí, torí pé àwọn nǹkan yẹn ni Jèhófà ń lò láti fún wa lókun àti ìṣírí. Tó o bá kíyè sí i pé o ti ń dẹwọ́ nínú èyíkéyìí lára àwọn ohun tá a sọ yìí, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wàá rí i pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà á jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́, á sì mú kó o ṣe bẹ́ẹ̀. (Fílí. 2:13) Àmọ́, báwo nìwọ náà ṣe lè fáwọn míì lókun?

MÁA FÚN ÀWỌN TÓ TI DẸWỌ́ LÓKUN

13, 14. (a) Kí ló fún arákùnrin kan lókun lẹ́yìn tí ìyàwó rẹ̀ kú? (b) Àwọn ọ̀nà wo làwa náà lè gbà fún àwọn míì lókun?

13 Jèhófà fi àwọn ará kárí ayé jíǹkí wa, wọ́n sì ń fún wa níṣìírí. Ẹ rántí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, pé: “Ẹ mú àwọn ọwọ́ rírọ̀ jọwọrọ àti àwọn eékún tí ó ti di ahẹrẹpẹ nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì máa bá a lọ ní ṣíṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ yín.” (Héb. 12:​12, 13) Ọ̀pọ̀ Kristẹni nígbà yẹn lọ́hùn-ún ló rí irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ gbà. Ohun kan náà ló sì ń ṣẹlẹ̀ lónìí. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí ìyàwó arákùnrin kan kú tó sì tún láwọn ìṣòro míì tó ń pinni lẹ́mìí, ó sọ pé: “Mo wá mọ̀ pé a ò lè yan àwọn àdánwò tó máa dé bá wa, bẹ́ẹ̀ náà la ò lè yan àkókò tá a fẹ́ káwọn àdánwò náà dé tàbí bá a ṣe fẹ́ kí wọ́n jìnnà síra tó. Àdúrà àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ ni kò jẹ́ kí n bọ́hùn. Ìtìlẹ́yìn àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi nípa tẹ̀mí sì ti fún mi ní ìtùnú tó pọ̀. Lékè gbogbo rẹ̀, mo ti wá rí bó ti ṣe pàtàkì tó láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà kí àwọn ipò lílekoko tó dé.”

Gbogbo wa la lè ran ẹlòmíì lọ́wọ́, yálà ọmọdé ni wá tàbí àgbàlagbà (Wo ìpínrọ̀ 14)

14 Nínú ogun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá àwọn ọmọ Ámálékì jà, ṣe ni Áárónì àti Húrì gbé ọwọ́ Mósè sókè títí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣẹ́gun. Ó yẹ káwa náà máa wá ọ̀nà láti fún àwọn míì lókun, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn wo ló yẹ ká fún lókun? Àwọn tí ara wọn ti ń dara àgbà, àwọn tó ń ṣàìsàn, àwọn tí ìdílé wọn ń ṣenúnibíni sí, àwọn tí kò rẹ́ni fojú jọ àtàwọn téèyàn wọn kú. Ká má sì gbàgbé àwọn ọmọ táwọn ọ̀rẹ́ fẹ́ kí wọ́n máa ṣe bíi tiwọn. Àwọn ọ̀rẹ́ wọn yìí lè máa rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n lọ́wọ́ sí àwọn ìwà tí kò tọ́ tàbí kí wọ́n máa lé àtirí towó ṣe, kí wọ́n sì lóókọ láwùjọ. (1 Tẹs. 3:​1-3; 5:​11, 14) Tẹ́ ẹ bá jọ wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí lóde ẹ̀rí, ẹ máa lo àǹfààní yẹn láti gbé ara yín ró. Ẹ sì tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́ ẹ bá jọ ń sọ̀rọ̀ lórí fóònù tàbí tẹ́ ẹ jọ ń jẹun.

15. Kí lọ̀rọ̀ rere tá à ń sọ lè mú káwọn ará wa ṣe?

15 Lẹ́yìn tí Ásà ṣẹ́gun àwọn ará Etiópíà, wòlíì Asaráyà fún òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ níṣìírí, ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígboyà, ẹ má sì jẹ́ kí ọwọ́ yín rọ jọwọrọ, nítorí pé ẹ̀san wà fún ìgbòkègbodò yín.” (2 Kíró. 15:⁠7) Ohun tí wòlíì náà sọ mú kí Ásà ṣe àwọn àtúnṣe kan káwọn èèyàn ilẹ̀ náà lè pa dà máa jọ́sìn Jèhófà. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń sọ̀rọ̀ ìwúrí fáwọn èèyàn, wọ́n á lè máa ṣe dáadáa. Ọ̀rọ̀ wa lè mú kí wọ́n túbọ̀ fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà. (Òwe 15:23) Ká má sì gbàgbé pé bá a ṣe ń nawọ́ nípàdé tá a sì ń dáhùn lọ́nà tó ń gbéni ró, à ń fún àwọn ará wa níṣìírí.

16. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè máa fún àwọn ará lókun bíi ti Nehemáyà? Sọ báwọn ará ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́.

16 Lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, Nehemáyà àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ rí okun gbà láti ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé ọjọ́ méjìléláàádọ́ta [52] péré ni wọ́n fi parí mímọ ògiri Jerúsálẹ́mù! (Neh. 2:18; 6:​15, 16) Kì í ṣe pé Nehemáyà kàn ń darí àwọn tó ń kọ́ ògiri Jerúsálẹ́mù, òun náà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà. (Neh. 5:16) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí láàárín àwa èèyàn Jèhófà lónìí, àwọn alàgbà máa ń ṣe bíi ti Nehemáyà, wọ́n ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ilé tí ètò Ọlọ́run ń lò, wọ́n sì máa ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ń lò ṣe. Bí àwọn alàgbà ṣe ń bá àwọn akéde ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, tí wọ́n sì ń ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ wọn, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fún àwọn ará lókun.​—⁠Ka Aísáyà 35:​3, 4.

‘MÁ ṢE JẸ́ KÍ ỌWỌ́ RẸ RỌ JỌWỌRỌ’

17, 18. Ìṣòro yòówù kó dé, kí ló dá wa lójú?

17 Bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa, ṣe ló ń mú ká túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Ó tún ń mú ká túbọ̀ mọwọ́ ara wa ká sì jọ máa gbé ara wa ró bá a ṣe ń retí àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run. Bá a ṣe ń fún àwọn míì lókun, à ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí ìṣòro kí wọ́n sì ní ìdánilójú pé ọ̀la máa dáa. Yàtọ̀ síyẹn, bá a ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́ ń mú káwa náà lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí, ó sì ń mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Kò sí àní-àní pé ṣe là ń fún ara wa náà lókun.

18 Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì nípa bí Jèhófà ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun tó sì dáàbò bò wọ́n mú ká túbọ̀ nígbàgbọ́ àti ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà. Torí náà, ìṣòro yòówù kó dé, ‘má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ rọ jọwọrọ’! Kàkà bẹ́ẹ̀, ké pe Jèhófà nínú àdúrà, kó o sì jẹ́ kí ọwọ́ ńlá agbára rẹ̀ fún ẹ lókun, kó sì máa ṣamọ̀nà rẹ títí wọnú ayé tuntun lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.​—⁠Sm. 73:​23, 24.