Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Jà Fitafita Kó O Lè Rí Ìbùkún Jèhófà

Máa Jà Fitafita Kó O Lè Rí Ìbùkún Jèhófà

“Ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn wọ̀jà o sì borí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.”​JẸ́N. 32:28.

ORIN: 60, 38

1, 2. Àwọn nǹkan wo làwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń bá wọ̀yá ìjà?

ỌJỌ́ pẹ́ táwọn olùjọsìn Jèhófà ti ń sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, bẹ̀rẹ̀ látorí Ébẹ́lì títí di àsìkò wa yìí. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa bí àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni ṣe ń tiraka kí wọ́n lè rí ojúure Jèhófà àti ìbùkún rẹ̀, ó ní wọ́n “fara da ìdíje ńláǹlà lábẹ́ àwọn ìjìyà.” (Héb. 10:​32-34) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ bí àwọn Kristẹni ṣe ń tiraka, ó lo àpẹẹrẹ àwọn tó ń sapá láti gbégbá orókè nínú eré ìdíje táwọn Gíríìkì máa ń ṣe. Lára eré ìdíje bẹ́ẹ̀ ni eré sísá, ìjàkadì àti ẹ̀ṣẹ́ kíkàn. (Héb. 12:​1, 4) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí. Àwa náà ń sá eré ìje ká bàa lè rí ìyè, a sì ń kojú àwọn ọ̀tá tí wọn ò fẹ́ ká pọkàn pọ̀, tí wọ́n fẹ́ gbé wa ṣubú, tí wọ́n sì fẹ́ ká pàdánù ayọ̀ wa àti ìyè ayérayé.

2 Lónìí, àwọn ọ̀tá tá à ń bá wọ̀yá ìjà ni Sátánì àti ayé búburú yìí. (Éfé. 6:12) Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká má ṣe jẹ́ kí “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” nínú ayé yìí kó èèràn ràn wá. Lára wọn ni àwọn ẹ̀kọ́ èké, àwọn ẹ̀kọ́ tó dá lórí èrò àwọn èèyàn aláìpé àtàwọn ìwàkiwà bí ìṣekúṣe, sìgá tàbí igbó mímu, ọtí àmujù àti lílo oògùn olóró. Yàtọ̀ sáwọn nǹkan yìí, a tún ń bá àìpé wa àti ìrẹ̀wẹ̀sì wọ̀yá ìjà, a ò sì gbọ́dọ̀ dẹwọ́.​—2 Kọ́r. 10:3-6; Kól. 3:5-9.

3. Báwo ni Jèhófà ṣe ń kọ́ wa ká lè borí àwọn ọ̀tá wa?

3 Ṣé a lè borí àwọn ọ̀tá alágbára yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ a gbọ́dọ̀ jà fitafita. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé ohun tóun ṣe, ó lo àpẹẹrẹ àwọn tó ń kan ẹ̀ṣẹ́, ó ní: “Bí mo ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ mi jẹ́ láti má ṣe máa gbá afẹ́fẹ́.” (1 Kọ́r. 9:26) Àwa náà gbọ́dọ̀ máa jà fitafita láti borí àwọn ọ̀tá wa bíi tàwọn tó ń kànṣẹ́. Jèhófà ti kọ́ wa láwọn nǹkan tá a lè ṣe, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́. Ó ń tọ́ wa sọ́nà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bákan náà ló ń ràn wá lọ́wọ́ nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa, ìpàdé ìjọ àtàwọn àpéjọ wa. Ìbéèrè náà ni pé, ṣó ò ń fi àwọn ẹ̀kọ́ náà sílò? Tó o bá ń gba àwọn ìtọ́ni yìí láìfi wọ́n sílò, ńṣe ló dà bí ìgbà tó o kàn ń “gbá afẹ́fẹ́,” dípò kó o máa gbá àwọn ọ̀tá rẹ.

4. Kí la lè ṣe tí ibi kò fi ní ṣẹ́gun wa?

4 Ìgbà tá ò fura tàbí tá ò fi bẹ́ẹ̀ lókun nípa tẹ̀mí, làwọn ọ̀tá yìí máa ń fẹ́ kọlù wá, torí náà a ò gbọ́dọ̀ sàsùnpara. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé: “Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:21) Ọ̀rọ̀ ìyànjú náà pé ká má ṣe jẹ́ “kí ibi ṣẹ́gun” wa fi hàn pé a ṣẹ́gun ibi. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá ò bá ṣíwọ́ àtimáa gbógun tì í. Àmọ́, tá a bá dẹra nù pẹ́nrẹ́n tàbí tá a ṣíwọ́ ìjà, wẹ́rẹ́ báyìí ni Sátánì, ayé èṣù yìí àti àìpé wa máa borí wa. Torí náà, má ṣe gbà láé kí Sátánì dẹ́rù bà ẹ́ débi tí wàá fi juwọ́ sílẹ̀!​—⁠1 Pét. 5:⁠9.

5. (a) Kí la gbọ́dọ̀ máa rántí tá a bá fẹ́ rí ìbùkún Ọlọ́run gbà? (b) Àwọn àpẹẹrẹ wo nínú Bíbélì la máa jíròrò?

5 Tá a bá máa mókè nínú ìjà yìí, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé ìdí tá a fi ń ja ìjà náà. Tá a bá fẹ́ rí ojúure Ọlọ́run ká sì rí ìbùkún rẹ̀, àfi ká máa rántí ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tó wà nínú Hébérù 11:6, tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà tá a tú sí “fi taratara wá” túmọ̀ sí kéèyàn fi gbogbo ara àti ọkàn ṣe nǹkan. (Ìṣe 15:17) Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n fi tọkàntara wá ìbùkún Ọlọ́run ló wà nínú Ìwé Mímọ́. Lára wọn ni Jékọ́bù, Rákélì, Jósẹ́fù àti Pọ́ọ̀lù. Àwọn tá a sọ yìí láwọn ìṣòro tó bà wọ́n lọ́kàn jẹ́, tó sì tún tán wọn lókun, síbẹ̀ wọ́n tiraka títí wọ́n fi rí ìbùkún Jèhófà gbà. Báwo la ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ àwọn mẹ́rin tó ja àjàṣẹ́gun yìí?

MÁ ṢE ṢÍWỌ́ KÓ O LÈ RÍ ÌBÙKÚN GBÀ

6. Kí nìdí tí Jékọ́bù ò fi jáwọ́ jíjà fitafita? Èrè wo ló rí gbà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

6 Jékọ́bù jà fitafita, kò sì jáwọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó mọyì àwọn nǹkan tẹ̀mí, ó sì nígbàgbọ́ tó lágbára pé Jèhófà máa bù kún àtọmọdọ́mọ òun. (Jẹ́n. 28:3, 4) Abájọ tó fi jẹ́ pé nígbà tí Jékọ́bù fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọgọ́rùn-ún ọdún, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí ìbùkún Ọlọ́run gbà; kódà ó wọ̀yá ìjà pẹ̀lú áńgẹ́lì Ọlọ́run. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 32:​24-28.) Ṣé agbára Jékọ́bù náà ló pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tó fi lè bá áńgẹ́lì jà tí kò sì jáwọ́? Ó dájú pé kò lágbára ẹ̀! Àmọ́, ó ṣọkàn akin, ó pinnu pé òun ò ní jáwọ́ lára ẹni tí òun ń bá jà! Ọkàn akin tó ṣe yìí sì mérè wá, torí pé ó rí ìbùkún gbà. Áńgẹ́lì náà sọ Jékọ́bù lórúkọ tuntun, ó pè é ní Ísírẹ́lì, (tó túmọ̀ sí “Ẹni tó bá Ọlọ́run wọ̀jà”). Jékọ́bù rí ojúure Jèhófà àti ìbùkún rẹ̀, ohun táwa náà sì ń fẹ́ nìyẹn. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

7. (a) Ìṣòro tó ń bani nínú jẹ́ wo ni Rákélì ní? (b) Kí ni Rákélì ṣe nípa ìṣòro yìí, báwo sì ni Jèhófà ṣe bù kún rẹ̀?

7 Bó ṣe ń wu Jékọ́bù pé kí ìlérí Jèhófà ṣẹ mọ́ òun lára náà ni Rákélì ìyàwó rẹ̀ ń ronú ọ̀nà tí Jèhófà máa gbà mú ìlérí náà ṣẹ. Àmọ́ kọ́kọ́rọ́ kan ba eyín ajá jẹ́. Rákélì ò bímọ. Nígbà yẹn sì rèé, àbùkù gbáà ni bí obìnrin kan ò bá bímọ. Ó ṣe kedere pé ìṣòro tó kọjá agbára rẹ̀ yìí máa bà á nínú jẹ́, ó sì ṣeé ṣe kó kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a. Kí wá ni Rákélì ṣe láti fàyà rán ìṣòro yẹn? Kò sọ̀rètí nù, ìdí nìyẹn tó fi túbọ̀ tẹra mọ́ àdúrà gbígbà. Jèhófà gbọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ Rákélì, ó sì fi ọmọ jíǹkí rẹ̀. Abájọ tí Rákélì fi fìdùnnú sọ nígbà kan pé: “Gídígbò tí a jà ní àjàkú-akátá ni mo . . . jà. Mo sì ti mókè”!​—Jẹ́n. 30:8, 20-24.

8. Ìṣòro wo ni Jósẹ́fù fara dà fún ọ̀pọ̀ ọdún, ẹ̀kọ́ wo la sì rí kọ́ nínú bó ṣe fara da ìṣòro náà?

8 Kò sí àní-àní pé bí Jékọ́bù àti Rákélì ṣe jẹ́ adúróṣinṣin ran Jósẹ́fù ọmọ wọn lọ́wọ́ gan-an, ìyẹn ló jẹ́ kóun náà jólóòótọ́ nígbà tá a dán ìgbàgbọ́ ẹ̀ wò. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] péré ni Jósẹ́fù nígbà tí nǹkan dojú rú fún un. Kí ló ṣẹlẹ̀? Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ń jowú rẹ̀, ni wọ́n bá tà á sóko ẹrú. Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn èèyàn tún fẹ̀sùn èké kàn án, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ dèrò ẹ̀wọ̀n ní Íjíbítì. (Jẹ́n. 37:​23-28; 39:​7-9, 20-21) Síbẹ̀, Jósẹ́fù ò rẹ̀wẹ̀sì, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jẹ́ kínú bí òun débi táá fi máa wọ́nà láti gbẹ̀san. Kàkà bẹ́ẹ̀, àjọṣe òun àti Jèhófà ló gbà á lọ́kàn. (Léf. 19:18; Róòmù 12:​17-21) Ẹ̀kọ́ pàtàkì ni àpẹẹrẹ Jósẹ́fù kọ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, ká tiẹ̀ sọ pé nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ fún wa nígbà tá a wà ní kékeré tàbí bóyá ìṣòro tó ń bá wa fínra báyìí kọjá agbára wa, ẹ jẹ́ ká máa forí tì í, ká má sì bọ́hùn. Ó dájú pé tá ò bá bọ́hùn, Jèhófà máa bù kún wa.​—⁠Ka Jẹ́nẹ́sísì 39:​21-23.

9. Kí lo rí kọ́ lára Jékọ́bù, Rákélì àti Jósẹ́fù táá jẹ́ kó o lè máa sapá láti rí ìbùkún Jèhófà gbà?

9 Ronú díẹ̀ ná nípa ìṣòro tó ń dán ìgbàgbọ́ rẹ wò. Bóyá ṣe ni wọ́n ń rẹ́ ọ jẹ tàbí wọ́n ń ṣẹ̀tanú sí ẹ, ó sì lè jẹ́ pé wọ́n ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́. Àbí kẹ̀, bóyá ẹnì kan fẹ̀sùn èké kàn ẹ́ torí pé onítọ̀hún ń jowú rẹ. Má ṣe jẹ́ káwọn nǹkan yẹn mú kó o bọ́hùn, kàkà bẹ́ẹ̀ máa rántí ohun tó mú kí Jékọ́bù, Rákélì àti Jósẹ́fù máa fayọ̀ sin Jèhófà nígbà ìṣòro. Jèhófà fún wọn lókun, ó sì bù kún wọn torí pé ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń mọyì àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú rẹ̀. Wọn ò dákẹ́ àdúrà, wọ́n sì jà fitafita láti ṣe ohun tó bá àdúrà wọn mu. Àwa ńkọ́? Ayé búburú tá à ń gbé yìí kò ní pẹ́ wá sópin; torí náà kì í ṣe àsìkò yìí ló yẹ ká fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìrètí tá a ní! Ṣé wàá ṣì máa jà fitafita kó o lè rí ojúure Jèhófà, àbí wàá jáwọ́?

MÚRA TÁN LÁTI JÀ FITAFITA KÓ O LÈ RÍ ÌBÙKÚN GBÀ

10, 11. (a) Àwọn ìṣòro wo ló lè gba pé ká jà fitafita láti rí ìbùkún Ọlọ́run gbà? (b) Àwọn nǹkan wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́?

10 Àwọn ìṣòro wo ló lè gba pé ká jà fitafita láti rí ìbùkún Ọlọ́run gbà? Ìṣòro táwọn kan ń bá pò ó ni bí wọ́n ṣe máa borí kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. Ńṣe làwọn míì ń sapá gan-an kí wọ́n lè máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bóyá ìṣòro tó ò ń fara dà ni àìsàn, tàbí kẹ̀, ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kò sẹ́ni tó rí tìẹ rò. A ò sì ní gbàgbé pé kò rọrùn fáwọn míì láti dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wọ́n. Yálà ó ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà bọ̀ tàbí kò tíì pẹ́, gbogbo wa la gbọ́dọ̀ máa jà fitafita kí ohunkóhun má bàa dí wa lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ó sì dájú pé Ọlọ́run máa san wá lẹ́san tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀.

Ṣé ò ń jà fitafita kó o lè rí ìbùkún Ọlọ́run gbà? (Wo ìpínrọ̀ 10 àti 11)

11 Ká sòótọ́, kì í rọrùn láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi kéèyàn sì ṣe ohun tó tọ́ nínú ayé yìí. Ọ̀rọ̀ yìí túbọ̀ ṣe pàtàkì torí pé ọkàn wa lè máa fà sí ohun tí kò tọ́. (Jer. 17:9) Tó bá jẹ́ bó ṣe ń ṣe ẹ́ nìyẹn, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Tó o bá ń gbàdúrà, ẹ̀mí Ọlọ́run máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, wàá lè lókun táá jẹ́ kó o lè ṣe ohun tínú Jèhófà dùn sì, ó sì máa bù kún rẹ. Lẹ́yìn náà, ṣe ohun tó bá àdúrà rẹ mu. Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, máa wáyè láti dá kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé.​—⁠Ka Sáàmù 119:⁠32.

12, 13. Báwo làwọn kan ṣe borí èròkerò?

12 Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ̀mí mímọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde wa ti ràn lọ́wọ́ láti borí èrò tí kò tọ́. Lẹ́yìn tí ọ̀dọ́kùnrin kan ka àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Báwo Lo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́?” nínú Jí! December 8, 2003, ó sọ pé: “Gbogbo bí mo ṣe ń ṣe tó, èròkerò ṣì máa ń wá sí mi lọ́kàn. Nígbà tí mo ka ibì kan nínú àpilẹ̀kọ yẹn tó sọ pé ‘fún ọ̀pọ̀, ogun tí wọ́n ń jà láti borí èròkérò kì í ṣe kékeré rárá,’ mo wá mọ̀ pé kì í ṣe èmi nìkan nirú ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí. Èyí jẹ́ kí n rí i pé ọ̀pọ̀ ló ń jìjàkadì yìí.” Àpilẹ̀kọ míì tó tún ṣe ọ̀dọ́kùnrin yìí láǹfààní ni “Gbígbé Ìgbésí Ayé Tó Yàtọ̀ Sí Ti Ẹ̀dá​—Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ Sí I?” tó wà nínú Jí! October 8, 2003. Ó rántí pé àpilẹ̀kọ yẹn sọ pé ìṣòro táwọn kan ní ti di ‘ẹ̀gún nínú ẹran ara’ wọn. (2 Kọ́r. 12:7) Àti pé tí wọn ò bá jáwọ́ láti máa hùwà òdodo, ó dájú pé nínú ayé tuntun, wọ́n á bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro náà. Ọ̀dọ́kùnrin náà wá sọ pé: “Ohun tí mo kà yẹn wá fi mí lọ́kàn balẹ̀, pé bí mo ṣe ń la ọjọ́ kọ̀ọ̀kan já, ó dájú pé màá lè jẹ́ olóòótọ́. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń lo ètò rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè la ayé búburú yìí já.”

13 Àpẹẹrẹ ẹlòmíì ni ti arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín pé ohun tá a nílò gan-an lẹ máa ń fún wa, ó sì máa ń bọ́ sásìkò. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń ṣe mí bíi pé èmi gan-an lẹ dìídì kọ àwọn àpilẹ̀kọ náà fún. Ọjọ́ pẹ́ tí ọkàn mi ti máa ń fà sóhun tí Jèhófà kórìíra, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń sapá gan-an láti borí ẹ̀. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mo rò pé agbára mi ò ní lè gbé e mọ́. Mo mọ̀ pé aláàánú ni Jèhófà, ó sì máa ń dárí jini, àmọ́ torí pé èròkerò máa ń wá sí mi lọ́kàn ṣáá, ṣe ló dà bíi pé nínú mi lọ́hùn-ún, mi ò kórìíra rẹ̀. Èyí máa ń jẹ́ kó ṣe mí bíi pé mi ò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà lè ràn lọ́wọ́. Ìṣòro yìí ti wá mú kí gbogbo nǹkan sú mi. . . . Àmọ́ nígbà tí mo ka àpilẹ̀kọ tó sọ pé ‘Ǹjẹ́ Ó Wù Ẹ́ Láti Mọ Jèhófà?’ nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 2013, ọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ pé Jèhófà máa ràn mí lọ́wọ́.”

14. (a) Báwo ni ìjà tí Pọ́ọ̀lù ń jà ṣe rí lára rẹ̀? (b) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè borí ìjà tá à ń bá àìpé wa jà?

14 Ka Róòmù 7:21-25. Pọ́ọ̀lù mọ bó ti ṣòro tó pé kéèyàn gbé èròkerò kúrò lọ́kàn kó sì máa bá àìpé ẹ̀dá wọ̀yá ìjà. Àmọ́, ó dá a lójú pé òun á borí ìjà yìí torí pé lemọ́lemọ́ ló ń gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Àwa náà ńkọ́? A lè borí tá a bá ń bá àìpé wa jà. Àmọ́ kí la gbọ́dọ̀ ṣe? Ẹ jẹ́ ká fara wé Pọ́ọ̀lù, ká má ṣe gbára lé ara wa, kàkà bẹ́ẹ̀ ká máa gbára lé Jèhófà nígbà gbogbo, ká sì máa lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà.

15. Báwo ni àdúrà ṣe lè mú ká jẹ́ olóòótọ́ ká sì lè fàyà rán ìṣòro?

15 Nígbà míì, Ọlọ́run lè fàyè gba àwọn nǹkan kan, ká bàa lè fi hàn pé lóòótọ́ lohun kan ń jẹ wá lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ pé àwa tàbí ẹnì kan nínú ìdílé wa ń ṣàìsàn tàbí bóyá ṣe ni wọ́n rẹ́ wa jẹ. Ó dájú pé a ò ní fọ̀rọ̀ àdúrà ṣeré ká lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Tá a bá ń gbàdúrà, ẹ jẹ́ ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa lókun ká lè jẹ́ olóòótọ́, kí ayọ̀ wa má pẹ̀dín, ká sì lè máa fìtara jọ́sìn rẹ̀. (Fílí. 4:13) Ìrírí àwọn tó gbára lé Jèhófà láyé Pọ́ọ̀lù àti lóde òní fi hàn pé àdúrà máa ń jẹ́ kéèyàn rókun gbà, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn lè fàyà rán ìṣòro láì bọ́hùn.

MÁA JÀ FITAFITA KÓ O LÈ RÍ ÌBÙKÚN JÈHÓFÀ

16, 17. Kí lo pinnu láti ṣe?

16 Ohun tí Èṣù fẹ́ ni pé kó o ṣíwọ́ ìjà náà, kó o sì gbà pé o ti fìdí rẹmi. Torí náà, pinnu pé wàá “di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin.” (1 Tẹs. 5:21) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o lè borí nínú ìjà tó ò ń bá Sátánì, ayé Èṣù yìí àti kùdìẹ̀-kudiẹ èyíkéyìí tó o ní jà. Wàá borí tó o bá gbára lé Jèhófà pátápátá láti máa fún ẹ lókun.​—2 Kọ́r. 4:​7-9; Gál. 6:9.

17 Torí náà, má ṣe ṣíwọ́ ìjà tó ò ń jà. Máa tiraka. Máa jà fitafita. Máa fàyà rán an láì bọ́hùn. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa “tú ìbùkún dà sórí [rẹ] ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.”​—Mál. 3:10.