Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Fàánú Hàn Bíi Ti Jèhófà

Máa Fàánú Hàn Bíi Ti Jèhófà

“Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́.” ​—Ẹ́KÍS. 34:6.

ORIN: 142, 12

1. Kí ni Jèhófà sọ nípa ara rẹ̀ fún Mósè, kí nìdí tíyẹn sì fi ṣe pàtàkì?

ÌGBÀ KAN wà tí Jèhófà polongo orúkọ rẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ fún Mósè. Ohun tí Jèhófà kọ́kọ́ mẹ́nu kàn ni bóun ṣe jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́. (Ka Ẹ́kísódù 34:5-7.) Jèhófà lè kọ́kọ́ sọ bóun ṣe lágbára tó àti bọ́gbọ́n òun ṣe jinlẹ̀ tó. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ànímọ́ táá jẹ́ kó dá Mósè lójú pé òun máa tì í lẹ́yìn ló sọ. (Ẹ́kís. 33:13) Ǹjẹ́ inú rẹ ò dùn pé àwọn ànímọ́ yìí ni Jèhófà kọ́kọ́ mẹ́nu kàn? Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àánú, ìyẹn ànímọ́ kan tó máa ń jẹ́ kéèyàn bá ẹni tó ń jìyà kẹ́dùn, kéèyàn sì ran onítọ̀hún lọ́wọ́.

2, 3. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé àánú wà lára àwọn ànímọ́ tí Jèhófà dá mọ́ wa? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa fífi àánú hàn?

2 Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ohun tó sì mú káwa èèyàn náà máa fàánú hàn nìyẹn. Kódà àwọn tí kò mọ Ọlọ́run náà máa ń fàánú hàn. (Jẹ́n. 1:27) Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ kan ni tàwọn aṣẹ́wó méjì tí wọ́n ń bára wọn du ọmọ, tí wọ́n sì gbẹ́jọ́ náà wá sọ́dọ̀ Ọba Sólómọ́nì. Nígbà tí Sólómọ́nì pàṣẹ pé kí wọ́n gé ọmọ náà sí méjì, kó lè dán wọn wò, àánú ṣe èyí tó jẹ́ ìyá ọmọ náà gangan. Kíá ló bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n gbọ́mọ náà fún obìnrin kejì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ló lọmọ. (1 Ọba 3:23-27) Àpẹẹrẹ míì ni ti ọmọbìnrin Ọba Fáráò tó dá ẹ̀mí Mósè sí nígbà tó wà lọ́mọdé jòjòló. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọba yìí mọ̀ pé àwọn Hébérù ló lọmọ náà àti pé ṣe ló yẹ kí wọ́n pa á, síbẹ̀ ó káàánú rẹ̀, ó sì gbà á ṣọmọ.​—Ẹ́kís. 2:5, 6.

3 Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa fífi àánú hàn? Ìdí ni pé Bíbélì rọ̀ ẹ́ pé kó o fara wé Jèhófà. (Éfé. 5:⁠1) Síbẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àánú wà lára àwọn ànímọ́ tí Jèhófà dá mọ́ wa, àìpé tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù kì í jẹ́ ká fàánú hàn nígbà míì. Kì í rọrùn fún wa láti pinnu bóyá ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tàbí ká má ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ ìgbà tó yẹ káwọn fàánú hàn àti ìgbà tí kò yẹ. Kí láá jẹ́ kó o mọ̀gbà tó yẹ kó o fàánú hàn? Àkọ́kọ́, fara balẹ̀ ronú lórí bí Jèhófà ṣe fàánú hàn àti báwọn míì náà ṣe ṣe bẹ́ẹ̀. Èkejì, ronú nípa bó o ṣe lè fara wé Jèhófà àti àǹfààní tó o máa rí tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀.

KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA JÈHÓFÀ

4. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi rán àwọn áńgẹ́lì lọ sílùú Sódómù? (b) Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọ rẹ̀?

4 Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà fàánú hàn sáwọn èèyàn. Àpẹẹrẹ kan ni ti Lọ́ọ̀tì. Bíbélì sọ pé ìwà àìníjàánu àwọn ará ìlú Sódómù àti Gòmórà kó ìdààmú ọkàn bá Lọ́ọ̀tì. Ìwà wọn yẹn ló sì mú kí Ọlọ́run pinnu pé òun máa pa àwọn èèyàn burúkú náà. (2 Pét. 2:7, 8) Àmọ́ Ọlọ́run rán àwọn áńgẹ́lì pé kí wọ́n lọ dá Lọ́ọ̀tì nídè, wọ́n sì rọ òun àti ìdílé rẹ̀ pé kí wọ́n sá kúrò nílùú náà. Bíbélì ròyìn pé, “Nígbà tí ó ń lọ́ra ṣáá, nígbà náà, nínú ìyọ́nú Jèhófà lórí rẹ̀, àwọn [áńgẹ́lì] náà gbá ọwọ́ rẹ̀ àti ọwọ́ aya rẹ̀ àti ọwọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì mú, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti mú un jáde àti láti mú un dúró ní òde ìlú ńlá náà.” (Jẹ́n. 19:16) Àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé Jèhófà ń kíyè sí ìṣòro tó ń dé bá àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sìn ín, ó sì mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn.​—Aísá. 63:7-9; Ják. 5:11; 2 Pét. 2:9.

5. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa fàánú hàn?

5 Yàtọ̀ sí pé Jèhófà máa ń fàánú hàn, ó tún ń kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ báwọn náà ṣe lè máa fàánú hàn. Àpẹẹrẹ kan ni òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ohun ìdógò tẹ́nì kan lè gbà. (Ka Ẹ́kísódù 22:26, 27.) Ẹnì kan tí kò lójú àánú lè sọ pé òun á gba aṣọ ìbora ẹni tó yá lówó, tí onítọ̀hún kò sì ní rí aṣọ bora mọ́jú nínú otútù. Àmọ́, Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ hu irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀. Ṣe ló yẹ kí wọ́n máa fàánú hàn síra wọn. Kí la rí kọ́ nínú ìlànà tó wà nínú òfin yẹn? Ohun tá a kọ́ ni pé táwọn ará wa bá wà nínú ìṣòro, ṣe ni ká ràn wọ́n lọ́wọ́ dípò tá a fi máa dágunlá.​—Kól. 3:12; Ják. 2:15, 16; ka 1 Jòhánù 3:17.

6. Kí la rí kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe ń rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣáá pé kí wọ́n yí pa dà?

6 Jèhófà máa ń fàánú hàn sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì kódà nígbà tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọ́n sì ń ránṣẹ́ lòdì sí wọn ṣáá nípasẹ̀ àwọn ońṣẹ́ rẹ̀, ó ń ránṣẹ́ léraléra, nítorí pé ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ àti sí ibùgbé rẹ̀.” (2 Kíró. 36:15) Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà fàánú hàn sáwọn èèyàn tó ṣeé ṣe kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì rí ojúure Ọlọ́run? Ó ṣe tán, Jèhófà ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run nínú ogun Amágẹ́dọ́nì. (2 Pét. 3:9) Torí náà, títí dìgbà tí Jèhófà máa pa àwọn ẹni búburú run, ẹ jẹ́ ká máa rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n yí pa dà, kí Ọlọ́run lè fàánú hàn sí wọn.

7, 8. Kí ló mú kí ìdílé kan gbà pé Jèhófà fàánú hàn sáwọn?

7 Ọ̀pọ̀ ìrírí ló fi hàn pé Jèhófà máa ń fàánú hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Àpẹẹrẹ kan ni ti ọmọ ọdún méjìlá kan tá a máa pe orúkọ rẹ̀ ní Milan. Ohun kan ṣẹlẹ̀ sí òun àti ìdílé rẹ̀ láwọn ọdún 1990 nígbà táwọn èèyàn ń ja ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Lọ́jọ́ kan, òun, àwọn òbí rẹ̀, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin àtàwọn ará míì kúrò ní orílẹ̀-èdè Bosnia kí wọ́n lè lọ ṣe àpéjọ àgbègbè ní orílẹ̀-èdè Serbia. Nígbà tí wọ́n dé ibodè ìlú, àwọn sójà dá ọkọ̀ wọn dúró, wọ́n ní kí ìdílé náà bọ́ sílẹ̀ torí pé ẹ̀yà míì ni wọ́n, wọ́n sì ní kí ọkọ̀ máa gbé àwọn ará yòókù lọ. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ìpàdé yẹn làwọn òbí Milan ti fẹ́ ṣèrìbọmi. Lẹ́yìn tí wọ́n ti dá wọn dúró fún ọjọ́ méjì, ọ̀kan lára àwọn sójà náà kàn sí ọ̀gá rẹ̀ pé kí ni kóun ṣe sí ìdílé náà. Ojú wọn ló ṣe nígbà tí ọ̀gá sójà náà dáhùn lórí aago pé, “Lọ pa wọ́n dànù!”

8 Ẹnu ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n wà táwọn ọkùnrin méjì kan sún mọ́ ìdílé náà, tí wọ́n sì sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn. Wọ́n ní àwọn ará yòókù ló ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àwọn. Wọ́n wá sọ fún Milan àti àbúrò rẹ̀ pé kí wọ́n wọnú mọ́tò àwọn, pé àwọn á gbé wọn kọjá sí òdìkejì, ó ṣe tán, òfin ò mú àwọn ọmọdé. Wọ́n wá sọ fún àwọn òbí Milan pé kí wọ́n rìn gba ẹ̀yìn ibodè yọ sí òdìkejì, pé àwọn á dúró dè wọ́n ńbẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà dà bí àlá lójú Milan, kò mọ̀ bóyá kóun rẹ́rìn-ín àbí kóun sunkún. Àwọn òbí rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin náà pé, “Ṣẹ́ ẹ rò pé wọ́n á sì lajú sílẹ̀ máa wò wá bá a ṣe ń lọ?” Síbẹ̀ wọ́n gbéra, kò sì sí èyíkéyìí lára àwọn sójà náà tó bi wọ́n léèrè ọ̀rọ̀ títí wọ́n fi kúrò ní ibodè náà. Bó ṣe di pé gbogbo wọn pàdé ní òdìkejì nìyẹn, wọ́n sì jọ lọ síbi tí wọ́n ti máa ṣe àpéjọ náà. Wọ́n gbà pé Jèhófà dáhùn àdúrà àwọn. Òótọ́ kan tí Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ ni pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dìídì dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nídè. (Ìṣe 7:58-60) Síbẹ̀, Milan sọ bó ṣe rí lọ́kàn rẹ̀ pé, “Lójú tèmi, mo gbà pé Jèhófà ló dá wa nídè, tó ní káwọn áńgẹ́lì rẹ̀ dí àwọn sójà náà lójú.”​—Sm. 97:10.

9. Báwo ni Jésù ṣe fàánú hàn sáwọn èèyàn tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

9 A tún lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù. Àánú àwọn èrò tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣe é, torí pé “a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” Kí ni Jésù wá ṣe fún wọn? Bíbélì sọ pé: ‘Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.’ (Mát. 9:36; ka Máàkù 6:34.) Ojú tí Jésù fi wo àwọn èèyàn náà yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn Farisí tí kò ṣe tán àtiran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́. (Mát. 12:9-14; 23:4; Jòh. 7:49) Ǹjẹ́ kì í wu ìwọ náà pé kó o ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà bí Jésù ti ṣe?

10, 11. Ǹjẹ́ ìgbà gbogbo ló tọ́ láti fàánú hàn? Ṣàlàyé.

10 Ó tọ́ bí Jèhófà ṣe fàánú hàn nínú àwọn àpẹẹrẹ tá a jíròrò tán yìí. Àmọ́, àwọn ìgbà míì wà tí kò tọ́ láti fàánú hàn. Bí àpẹẹrẹ, Ọba Sọ́ọ̀lù gbà pé ṣe lòun ń ṣàánú Ágágì tó jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà tó dá ẹ̀mí rẹ̀ sí. Yàtọ̀ síyẹn, Sọ́ọ̀lù tún dá èyí tó dára jù lọ lára àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sí. Àmọ́ òdìkejì ohun tí Jèhófà sọ fún un ló ṣe, torí náà Jèhófà kọ̀ ọ́ lọ́ba. (1 Sám. 15:3, 9, 15) Jèhófà jẹ́ Onídàájọ́ òdodo, ó mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn, ó sì mọ ìgbà tí kò tọ́ láti fi àánú hàn. (Ìdárò 2:17; Ìsík. 5:11) Lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa pa gbogbo àwọn tó ń tàpá sí òfin àti ìlànà rẹ̀. (2 Tẹs. 1:6-10) Kì í ṣe ìgbà yẹn ni Jèhófà máa fàánú hàn sí àwọn ẹni burúkú. Kàkà bẹ́ẹ̀, àánú tí Jèhófà ní fáwọn olódodo máa jẹ́ kó pa àwọn ẹni ibi run, á sì dá ẹ̀mí àwọn olódodo sí.

11 Ó ṣe kedere pé kì í ṣe tiwa láti pinnu àwọn tí Jèhófà máa pa run tàbí tó máa dá sí. Iṣẹ́ tiwa ni pé ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nísinsìnyí láti mọ Jèhófà. Torí náà, àwọn ọ̀nà pàtó wo la lè gbà fàánú hàn sáwọn èèyàn? Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ọ̀nà mélòó kan.

BÁ A ṢE LÈ MÁA FÀÁNÚ HÀN LỌ́NÀ TÓ TỌ́

12. Sọ ọ̀nà tó o lè gbà fàánú hàn sáwọn èèyàn.

12 Máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lójoojúmọ́. Lára ohun táwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣe ni pé ká máa fàánú hàn sáwọn aládùúgbò wa àti sáwọn ará wa. (Jòh. 13:34, 35; 1 Pét. 3:8) Ọ̀nà kan tá a lè gbà fàánú hàn ni pé ká máa bá àwọn èèyàn kẹ́dùn. Aláàánú èèyàn máa wá bó ṣe lè ran ẹni tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́. Torí náà, máa kíyè sí àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè bá ẹnì kan tọ́jú ilé, o sì lè bá a jíṣẹ́.​—Mát. 7:12.

Tó o bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ṣe lò ń fàánú hàn sí wọn (Wo ìpínrọ̀ 12)

13. Kí làwa èèyàn Jèhófà máa ń ṣe tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?

13 Máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà àjálù. Wọ́n máa ń sọ pé ojú ló ń rójú ṣàánú. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwa èèyàn Jèhófà máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. (1 Pét. 2:17) Bí àpẹẹrẹ, ìmìtìtì ilẹ̀ àti àkúnya omi tó wáyé lórílẹ̀-èdè Japan lọ́dún 2011 ba nǹkan jẹ́ gan-an. Nígbà tí arábìnrin kan tó ń gbé lágbègbè yẹn rí ipa ribiribi táwọn ará sà láti ṣàtúnṣe àwọn ibi tó bà jẹ́, ó sọ pé “orí òun wú, inú òun sì dùn.” Kódà àwọn ará wá láti àwọn orílẹ̀-èdè míì láti ṣèrànwọ́. Ó wá sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kí n túbọ̀ rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an àti pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, kárí ayé làwọn ará sì ń gbàdúrà fún wa.”

14. Báwo lo ṣe lè ran àwọn àgbàlagbà àtàwọn tó ń ṣàìsàn lọ́wọ́?

14 Máa ran àwọn àgbàlagbà àtàwọn tó ń ṣàìsàn lọ́wọ́. Àánú máa ń ṣe wá tá a bá kíyè sí báwọn èèyàn ṣe ń ṣàìsàn tí wọ́n sì ń darúgbó nítorí àìpé ẹ̀dá. Ṣe ló ń ṣe wá bíi pé káwọn nǹkan yìí ti dohun ìgbàgbé. Ìdí nìyẹn tá a fi ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé. Àmọ́ ní báyìí ná, à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìyá àgbàlagbà kan tó ní àìsàn tó máa ń mú kí arúgbó ṣarán. Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ òǹṣèwé sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan. Lọ́jọ́ yẹn, màmá rẹ̀ ṣèdọ̀tí sára, ibi tó ti ń gbìyànjú àtilọ wẹ̀, àwọn obìnrin méjì kan kanlẹ̀kùn. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn obìnrin náà, wọ́n sì ti máa ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Wọ́n bi màmá náà bóyá á fẹ́ kí wọ́n ran òun lọ́wọ́. Màmá náà dáhùn pé, “Ohun ìtìjú ni, àmọ́ mo fẹ́ kẹ́ ẹ ràn mí lọ́wọ́.” Àwọn arábìnrin náà bá a fọ àwọn ohun tó yẹ ní fífọ̀, lẹ́yìn náà, wọ́n po tíì fún un, wọ́n sì tún jọ sọ̀rọ̀ díẹ̀. Inú ọmọ màmá náà dùn gan-an, ó sì sọ pé: “Mo bẹ́rí fún ẹ̀yin Ajẹ́rìí. Ohun tẹ́ ẹ̀ ń wàásù náà lẹ̀ ń ṣe.” Ṣé àánú àwọn àgbàlagbà àtàwọn tó ń ṣàìsàn máa ń ṣe ẹ́, ṣó o sì máa ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́?​—Fílí. 2:3, 4.

15. Kí ni iṣẹ́ ìwàásù wa ń jẹ́ ká lè ṣe?

15 Máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà. Bá a ṣe ń rí i táwọn èèyàn ń kojú onírúurú ìṣòro ń mú ká fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àtohun tí Ìjọba rẹ̀ máa ṣe fún aráyé. A tún lè jẹ́ kí wọ́n rí ọgbọ́n tó wà nínú kéèyàn máa fi ìlànà Ọlọ́run sílò nígbèésí ayé rẹ̀. (Aísá. 48:17, 18) Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ń bọlá fún Jèhófà, ó sì ń jẹ́ ká máa fàánú hàn sáwọn èèyàn. Torí náà, ṣé o lè fi kún ohun tó ò ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà?​—1 Tím. 2:3, 4.

WÀÁ JÀǸFÀÀNÍTÓ O BÁ Ń FÀÁNÚ HÀN!

16. Àǹfààní wo lẹni tó bá ń ṣàánú máa rí?

16 Àwọn dókítà sọ pé téèyàn bá ń fàánú hàn, á ní ìlera tó dáa, àárín òun àtàwọn míì á sì gún régé. Tó o bá ń ṣàánú àwọn èèyàn, wàá láyọ̀, o ò ní kárísọ, wàá ní alábàárò, o ò sì ní máa ro èrò òdì. Ká sòótọ́, wàá jàǹfààní tó o bá ń fàánú hàn. (Éfé. 4:31, 32) Àwọn Kristẹni tó máa ń fìfẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ máa ń ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, torí wọ́n mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ làwọn ń ṣe. Téèyàn bá lójú àánú, á jẹ́ òbí rere, ọkọ tàbí aya tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, á sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tó ṣeé finú hàn. Ó ṣe tán, béèyàn bá da omi síwájú, á tẹlẹ̀ tútù, lọ́nà kan náà, ẹni bá ń ṣàánú àwọn èèyàn náà máa rí àánú gbà.​—Ka Mátíù 5:7; Lúùkù 6:38.

17. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa fàánú hàn?

17 Kì í ṣe torí ká lè rí àánú gbà nìkan la ṣe ń fàánú hàn sáwọn èèyàn. Ìdí pàtàkì tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a fẹ́ fara wé Jèhófà, Ọlọ́run àánú àti ìfẹ́, a sì fẹ́ máa bọlá fún un. (Òwe 14:31) Òun ló fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti fara wé e, ká máa fìfẹ́ bá àwọn ará wa lò lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ká sì máa fàánú hàn sáwọn aládùúgbò wa.​—Gál. 6:10; 1 Jòh. 4:16.