Máa Kó Ara Rẹ Níjàánu
“Èso ti ẹ̀mí ni . . . ìkóra-ẹni-níjàánu.”—GÁL. 5:22, 23.
ORIN: 83, 52
1, 2. (a) Kí ló ń ṣẹlẹ̀ torí pé àwọn èèyàn ò ní ìkóra-ẹni-níjàánu? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká sọ̀rọ̀ nípa ìkóra-ẹni-níjàánu?
ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU wà lára àwọn ànímọ́ tí Jèhófà fẹ́ káwa èèyàn rẹ̀ ní. (Gál. 5:22, 23) Jèhófà máa ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu ní gbogbo ọ̀nà láìkù síbì kan. Torí pé aláìpé làwa èèyàn, ìdí nìyẹn tá a fi ń sapá ká lè ní ànímọ́ yìí. Ká sòótọ́, àìní ìkóra-ẹni-níjàánu ló fa ọ̀pọ̀ ìṣòro táwa èèyàn ní lónìí. Bí àpẹẹrẹ, òun ló ń jẹ́ káwọn kan máa fi nǹkan falẹ̀, òun ni kì í jẹ́ kí wọ́n ṣe dáadáa níbi iṣẹ́ tàbí níléèwé. Àìsí ìkóra-ẹni-níjàánu ló ń mú káwọn èèyàn máa bú èébú, kí wọ́n máa mutí yó, kí wọ́n máa fa wàhálà, kí wọ́n tọrùn bọ gbèsè, òun ló sì ń fà á táwọn ìgbéyàwó kan fi ń tú ká. Kódà, àìní ìkóra-ẹni-níjàánu lè mú kéèyàn ṣẹ̀wọ̀n, kéèyàn kó àrùn ìbálòpọ̀, kéèyàn lóyún ẹ̀sín, ó sì lè paná ayọ̀ téèyàn ní, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.—Sm. 34:11-14.
2 Ó ṣe kedere pé àwọn tí kò ní ìkóra-ẹni-níjàánu máa ń fa wàhálà fún ara wọn àti fáwọn ẹlòmíì. Yàtọ̀ síyẹn, ṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń di aláìníjàánu. Láwọn ọdún 1940, wọ́n ṣe ìwádìí nípa báwọn èèyàn ṣe ń kó ara wọn níjàánu tó, àmọ́ ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé àwọn èèyàn ò rídìí tó fi yẹ kí wọ́n máa kóra wọn níjàánu mọ́. Kò sì yà wá lẹ́nu torí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn èèyàn máa jẹ́ “aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu.”—2 Tím. 3:1-3.
3. Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa kó ara wa níjàánu?
Jẹ́n. 3:6) Àìsí ìkóra-ẹni-níjàánu náà ló sì ń kó ọ̀pọ̀ èèyàn sí ìṣòro lónìí.
3 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa kó ara wa níjàánu? Ẹ jẹ́ ká wo ìdí pàtàkì méjì. Àkọ́kọ́, ìwádìí ti fi hàn pé àwọn tó lè kó ara wọn níjàánu kì í sábà kó sí ìṣòro. Ara wọn máa ń balẹ̀, àwọn èèyàn máa ń mú irú wọn lọ́rẹ̀ẹ́, wọn kì í tètè bínú, wọn kì í sì í ní ìdààmú ọkàn bíi tàwọn tí kò lè kóra wọn níjàánu. Ìkejì, a gbọ́dọ̀ máa kó ara wa níjàánu tá a bá fẹ́ borí ìdẹwò àti èròkerò, ká sì máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run nìṣó. Èyí ṣe pàtàkì gan-an, torí pé Ádámù àti Éfà kò kó ara wọn níjàánu ni wọ́n ṣe pàdánù ojúure Jèhófà. (4. Kí ló máa fi wá lọ́kàn balẹ̀ bá a ṣe ń sapá láti kó ara wa níjàánu?
4 Kò sí báwa èèyàn aláìpé ṣe lè kó ara wa níjàánu tá ò ní ṣàṣìṣe. Jèhófà náà mọ̀ bẹ́ẹ̀, ìdí sì nìyẹn tó fi ń ran àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ká lè borí àìpé ẹ̀dá tá a jogún. (1 Ọba 8:46-50) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó ń rí bí àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń sapá láti kó ara wa níjàánu bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún wa, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́. Jèhófà ló fi àpẹẹrẹ tó ga jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ìkóra-ẹni-níjàánu. Torí náà, a máa jíròrò àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, àá wo àpẹẹrẹ àwọn tó kó ara wọn níjàánu àtàwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì. Paríparí rẹ̀, àá jíròrò àwọn nǹkan táá jẹ́ ká lè máa kó ara wa níjàánu.
JÈHÓFÀ FI ÀPẸẸRẸ LÉLẸ̀
5, 6. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé Jèhófà ní ìkóra-ẹni-níjàánu.
5 Jèhófà ò láfiwé tó bá di pé ká kóra ẹni níjàánu torí pé ẹni pípé ni. (Diu. 32:4) Àmọ́ aláìpé làwa èèyàn, síbẹ̀ tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ lára Jèhófà, àá lè kó ara wa níjàánu. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé Jèhófà ní ìkóra-ẹni-níjàánu?
6 Àpẹẹrẹ kan lohun tí Jèhófà ṣe nígbà tí Sátánì ṣọ̀tẹ̀ sí i. Jèhófà rí i pé òun bójú tó ọ̀rọ̀ náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ó dájú pé inú máa bí àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ sóhun tí Sátánì ṣe yẹn, ojú burúkú ni wọ́n sì máa fi wò ó. Kò sí àní-àní pé bó ṣe máa ń rí lára ìwọ náà nìyẹn tó o bá ń ronú nípa àwọn ohun tí ọ̀tẹ̀ Sátánì ti fà fún àwa èèyàn. Àmọ́, Jèhófà ò kù gìrì ṣe nǹkan. Ṣe ló bójú tó ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó tọ́ àti lásìkò tó yẹ. Ṣe ni Jèhófà ń fi sùúrù yanjú ọ̀rọ̀ náà. (Ẹ́kís. 34:6; Jóòbù 2:2-6) Àmọ́, kí nìdí tí Jèhófà fi ń mú sùúrù? Ìdí ni pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run, ohun tó fẹ́ ni pé “kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”—2 Pét. 3:9.
7. Kí la rí kọ́ lára Jèhófà?
7 Àpẹẹrẹ Jèhófà kọ́ wa pé kò yẹ ká máa kù gìrì ṣe nǹkan, ó sì yẹ ká máa ro ọ̀rọ̀ tá a fẹ́ sọ dáadáa. Tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì, ó yẹ kó o fara balẹ̀ ronú kó o lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n kó o má bàa ṣi ọ̀rọ̀ sọ tàbí ṣìwà hù. (Sm. 141:3) Ó rọrùn láti ṣìwà hù tínú bá ń bíni, ọ̀pọ̀ sì ti kábàámọ̀ ohun tí wọ́n ṣe.—Òwe 14:29; 15:28; 19:2.
ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ ỌLỌ́RUN TÓ KÓ ARA WỌN NÍJÀÁNU ÀTÀWỌN TÍ KÒ ṢE BẸ́Ẹ̀
8. (a) Ibo la ti lè rí àpẹẹrẹ àwọn tó lo ìkóra-ẹni-níjàánu? (b) Kí ló ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ nígbà tó kojú ìdẹwò? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
8 Àwọn àpẹẹrẹ wo la rí nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa kó ara wa níjàánu? Ó dájú pé wàá rántí ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó kó ara wọn níjàánu lójú àdánwò. Ọ̀kan lára wọn ni Jẹ́n. 39:6, 9; ka Òwe 1:10.
Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù. Ó kó ara rẹ̀ níjàánu nígbà tó ń ṣiṣẹ́ nílé Pọ́tífárì, ìyẹn ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ Fáráò. Ìyàwó Pọ́tífárì ń fa ojú Jósẹ́fù mọ́ra torí pé ó dáa lọ́mọkùnrin, ó sì dùn-ún wò. Kí ló ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ tí kò fi kó sínú ìdẹwò yìí? Ó dájú pé ó ti ronú lórí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tóun bá bá obìnrin náà ṣe. Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà dójú ẹ̀, ṣe ni Jósẹ́fù sá kúrò lọ́dọ̀ obìnrin náà. Jósẹ́fù wá sọ pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?”—9. Kí lo lè ṣe tó ò fi ní kó sínú ìdẹwò?
9 Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù? Ó lè gba pé ká sá tá ò bá fẹ́ rú òfin Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, kí àwọn kan tó di Ẹlẹ́rìí, wọ́n jẹ́ alájẹkì, ọ̀mùtí, amusìgá, ajoògùnyó, oníṣekúṣe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kódà lẹ́yìn tí wọ́n ṣèrìbọmi, ó lè máa ṣe wọ́n bíi pé kí wọ́n tún lọ́wọ́ sáwọn ìwà yẹn. Tírú ẹ̀ bá wá sí ẹ lọ́kàn, ronú lórí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àjọṣe àárín ìwọ àti Jèhófà tí o kò bá kóra rẹ níjàánu tó o sì ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra. Á dáa kó o ronú lórí àwọn ipò tó lè dẹ ẹ́ wò, kó o sì yẹra fún àwọn ipò náà. (Sm. 26:4, 5; Òwe 22:3) Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé o kojú ìdẹwò, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n kó o lè kóra rẹ níjàánu.
10, 11. (a) Ìdẹwò wo làwọn ọ̀dọ́ ń kojú níléèwé? (b) Kí ló lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ tí wọ́n bá kojú ìdẹwò láti ṣe ìṣekúṣe?
10 Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń kojú irú àdánwò tí Jósẹ́fù kojú. Àpẹẹrẹ kan ni ti ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Kim. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ ló máa ń ṣèṣekúṣe, tí wọ́n bá wá dé iléèwé, wọ́n á máa fọ́nu nípa bí wọ́n ṣe gbádùn ara wọn ní òpin ọ̀sẹ̀. Àmọ́ Kim ní tiẹ̀ kì í rí nǹkan sọ tí wọ́n bá ti dá ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀. Ó sọ pé bóun ò ṣe rẹ́ni fojú jọ láàárín wọn máa ń jẹ́ kó dà bíi pé “kò sẹ́ni tó rí tòun rò àti pé òun dá wà.” Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tún máa ń fojú ọ̀dẹ̀ wò ó torí kò lẹ́ni tó ń fẹ́. Kim mọ̀ pé téèyàn bá wà lọ́dọ̀ọ́, ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ máa ń lágbára gan-an, torí náà ó pinnu pé òun kò ní yan ọ̀rẹ́kùnrin. (2 Tím. 2:22) Àwọn ọmọ iléèwé rẹ̀ máa ń bi í pé ṣé lóòótọ́ ni kò tíì mọ ọkùnrin. Á wá lo àǹfààní yẹn láti ṣàlàyé ìdí tóun kò fi tíì ní ìbálọ̀pọ̀. Àmúyangàn ni ẹ̀yin ọ̀dọ́ wa jẹ́ bẹ́ ò ṣe jẹ́ kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni mú kẹ́ ẹ ṣèṣekúṣe, Jèhófà sì mọyì yín pẹ̀lú!
11 Bíbélì sọ àpẹẹrẹ àwọn tí kò kóra wọn níjàánu, tí wọ́n sì ṣèṣekúṣe. Ó tún sọ àbájáde burúkú tó máa ń tìdí irú ìwà bẹ́ẹ̀ yọ. Téèyàn bá kojú irú àdánwò tí Kim kojú, á dáa kó ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́kùnrin tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ìwé Òwe orí 7. Á dáa kó tún ronú lórí ohun tí Ámínónì ṣe àtohun tó gbẹ̀yìn ìwàkiwà tó hù. (2 Sám. 13:1, 2, 10-15, 28-32) Torí náà, tí ẹ̀yin òbí bá fẹ́ káwọn ọmọ yín jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí wọ́n sì ní ìkóra-ẹni-níjàánu tó bá di ọ̀rọ̀ ìfẹ́sọ́nà, a rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ jíròrò kókó yìí pẹ̀lú wọn, kẹ́ ẹ lo àwọn àpẹẹrẹ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò yìí nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìjọsìn ìdílé yín.
12. (a) Báwo ni Jósẹ́fù ṣe kóra rẹ̀ níjàánu níṣojú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀? (b) Àwọn ipò wo ló ti gba pé ká kó ara wa níjàánu?
12 Ìgbà míì tún wà tí Jósẹ́fù lo ìkóra-ẹni-níjàánu. Nígbà táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wá ra oúnjẹ ní Íjíbítì, Jósẹ́fù ò jẹ́ kí wọ́n tètè mọ̀ pé àbúrò wọn lòun, kó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Nígbà tí ẹkún ń gbọ̀n ọ́n, tí kò sì lè mú un mọ́ra mọ́, ó wá ibì kan lọ láti sunkún. (Jẹ́n. 43:30, 31; 45:1) Tí Kristẹni kan tàbí ẹlòmíì tó o fẹ́ràn bá ṣe ohun tó dùn ẹ́, rántí àpẹẹrẹ Jósẹ́fù kó o sì kó ara rẹ níjàánu, èyí ò ní jẹ́ kó o ṣìwà hù. (Òwe 16:32; 17:27) Tí wọ́n bá yọ ẹnì kan nínú ìdílé rẹ lẹ́gbẹ́, ó ṣe pàtàkì kó o kó ara rẹ níjàánu, kó má bàa di pé ò ń bá onítọ̀hún ṣe wọléwọ̀de. Kò rọrùn kéèyàn kó ara rẹ̀ níjàánu nírú àwọn ipò yìí, àmọ́ wàá ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá gbà pé ohun tí Jèhófà ní kó o ṣe nìyẹn àti pé àpẹẹrẹ rẹ̀ lò ń tẹ̀ lé.
13. Kí la rí kọ́ lára Ọba Dáfídì?
13 Àpẹẹrẹ àtàtà míì tí Bíbélì tún sọ ni ti Ọba Dáfídì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára wà lọ́wọ́ rẹ̀, kò ṣìwà hù nígbà tí Sọ́ọ̀lù àti Ṣíméì ṣe ohun tó dùn ún. (1 Sám. 26:9-11; 2 Sám. 16:5-10) Àmọ́, àwọn ìgbà kan wà tí Dáfídì kò kó ara rẹ̀ níjàánu. A lè rántí ìgbà tó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Bátí-ṣébà àti ìgbà tó fẹ́ lọ pa gbogbo ilé Nábálì run. (1 Sám. 25:10-13; 2 Sám. 11:2-4) Síbẹ̀, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Dáfídì. Àkọ́kọ́, àwọn alábòójútó nínú ètò Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ní ìkóra-ẹni-níjàánu, kí wọ́n má bàa ṣi agbára wọn lò. Ìkejì ni pé kò yẹ káwa Kristẹni dá ara wa lójú jù, bíi pé a ò lè kó sínú ìdẹwò.—1 Kọ́r. 10:12.
ÀWỌN OHUN TÓ O LÈ ṢE
14. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwa náà máa fara balẹ̀ nírú àwọn ipò bẹ́ẹ̀?
14 Kí lo lè ṣe kó o lè túbọ̀ ní ìkóra-ẹni-níjàánu? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Luigi. Ọkùnrin kan fi mọ́tò kọlu mọ́tò Luigi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin yẹn ló jẹ̀bi, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í bú Luigi, tó sì fẹ́ bá a jà. Luigi gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kóun lè fara balẹ̀ yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ gbogbo bí Luigi ṣe ń pẹ̀tù sí ọkùnrin náà, ṣe niṣan rẹ̀ ń le sí i. Luigi bá kọ nọ́ńbà mọ́tò ọkùnrin náà, ó sì kúrò níbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin náà ṣì ń pariwo. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, Luigi lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ obìnrin kan, ló bá rí i pé ọkùnrin onímọ́tò ọjọ́sí lọkọ obìnrin náà! Ojú ti ọkùnrin náà gan-an, ló bá bẹ Luigi pé kó má bínú. Kódà, ọkùnrin náà ṣèlérí pé òun á kàn sí iléeṣẹ́ ìbánigbófò tí Luigi ń lò kí wọ́n lè tètè bá a tún mọ́tò rẹ̀ ṣe. Ọkùnrin náà tiẹ̀ tún dá sí ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n wá ṣe, ó sì mọyì ohun tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ náà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí wá jẹ́ kí Luigi rí i pé bóun ṣe fara balẹ̀ lọ́jọ́ yẹn dáa gan-an, ìyẹn ló sì jẹ́ kó rọrùn fún òun láti wàásù fún ọkùnrin náà.—Ka 2 Kọ́ríńtì 6:3, 4.
15, 16. Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè mú kí ìwọ àti ìdílé rẹ ní ìkóra-ẹni-níjàánu?
15 Tá a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, á jẹ́ ká túbọ̀ ní ìkóra-ẹni-níjàánu. Ẹ rántí ohun tí Ọlọ́run sọ fún Jóṣúà pé: “Ìwé òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, kí o sì máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí o lè kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀; nítorí nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n.” (Jóṣ. 1:8) Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè mú kó o ní ìkóra-ẹni-níjàánu?
16 Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ àwọn àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń kó ara wa níjàánu àti ohun tó lè yọrí sí tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ó nídìí tí Jèhófà fi jẹ́ káwọn ìtàn yìí wà lákọọ́lẹ̀. (Róòmù 15:4) Ẹ ò rí i pé ó máa ṣe wá láǹfààní gan-an tá a bá ń kà wọ́n, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ wọn, tá a sì ń ṣàṣàrò nípa wọn! Máa ronú nípa ẹ̀kọ́ tí ìwọ àti ìdílé rẹ lè rí kọ́. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fi ohun tó wà nínú Bíbélì sílò. Tó o bá rí i pé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti kó ara ẹ níjàánu láwọn apá ibì kan, gbà pé ibi tó o kù sí nìyẹn, kó o sì wá nǹkan ṣe nípa rẹ̀. Torí náà, gbàdúrà sí Jèhófà nípa ọ̀rọ̀ náà, kó o sì sapá láti ṣàtúnṣe. (Ják. 1:5) Tó o bá ṣèwádìí nípa ohun tó o fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.
17. Báwo làwọn òbí ṣe lè mú káwọn ọmọ wọn ní ìkóra-ẹni-níjàánu?
17 Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ káwọn náà lè ní ìkóra-ẹni-níjàánu? Àwọn òbí mọ̀ pé a kì í bí ànímọ́ rere mọ́ni, èèyàn máa kọ́ ọ ni. Torí náà, ó yẹ káwọn òbí fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn. (Éfé. 6:4) Tẹ́ ẹ bá kíyè sí pé kò rọrùn fáwọn ọmọ yín láti kó ara wọn níjàánu, ẹ wò ó bóyá ẹ̀ ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn. Lára ọ̀nà tẹ́ ẹ lè gbà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ni pé kẹ́ ẹ máa lọ sóde ẹ̀rí déédéé, kẹ́ ẹ máa lọ sípàdé déédéé, kẹ́ ẹ sì máa ṣe ìjọsìn ìdílé yín déédéé. Ẹ jẹ́ káwọn ọmọ yín mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo nǹkan tí wọ́n fẹ́ lẹ máa fún wọn. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà fún Ádámù àti Éfà náà lófin, òfin yìí ló sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ kọjá àyè ara wọn, àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún Jèhófà. Bó ṣe rí nínú ìdílé náà nìyẹn, tẹ́ ẹ bá ń kọ́ àwọn ọmọ yín, tẹ́ ẹ sì ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀, àwọn ọmọ yín á lè máa kó ara wọn níjàánu. Lára àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ kẹ́ ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín ni pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò.—Ka Òwe 1:5, 7, 8.
18. Kí nìdí tó fi yẹ kó o fọgbọ́n yan àwọn tó o máa bá kẹ́gbẹ́?
18 Yálà òbí ni ẹ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó yẹ kó o máa fọgbọ́n yan àwọn tó ò ń bá kẹ́gbẹ́. Àwọn tó máa jẹ́ kó o fọwọ́ gidi mú ìjọsìn Ọlọ́run tí kò sì ní kó ẹ sí wàhálà ni kó o máa bá kẹ́gbẹ́. (Òwe 13:20) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń ní ìkóra-ẹni-níjàánu, tó o bá ń bá wọn kẹ́gbẹ́, ìwọ náà á máa kóra rẹ níjàánu. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn náà máa jàǹfààní látinú ìwà rere rẹ. Tó bá mọ́ ẹ lára láti máa kó ara rẹ níjàánu, wàá gbádùn ìgbésí ayé rẹ, wàá múnú Ọlọ́run dùn, wàá sì gbádùn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì.