Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . Ń Sa Agbára”

“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . Ń Sa Agbára”

“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.”​—HÉB. 4:12.

ORIN: 114, 113

1. Kí ló mú kó o gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń sa agbára? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

ÀWA èèyàn Jèhófà mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “yè, ó sì ń sa agbára.” (Héb. 4:12) Ọ̀pọ̀ wa ló ti rí i pé Bíbélì lágbára láti tún ìgbésí ayé èèyàn ṣe. Àwọn Kristẹni kan ti fìgbà kan rí jẹ́ olè, ajoògùnyó tàbí oníṣekúṣe. Àwọn kan tiẹ̀ ti rọ́wọ́ mú gan-an nínú ayé, àmọ́ wọn ò láyọ̀. (Oníw. 2:3-11) Ìgbésí ayé àwọn míì ò nítumọ̀ tẹ́lẹ̀, wọn ò sì nírètí. Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n ń láyọ̀, ìgbésí ayé wọn sì nítumọ̀. A sábà máa ń ka ìrírí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nínú Ilé Ìṣọ́, lábẹ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà,” a sì máa ń gbádùn àwọn ìrírí náà. Bó ti wù kó rí, lẹ́yìn téèyàn bá ṣèrìbọmi, ó ṣì gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run lè túbọ̀ lágbára.

2. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sa agbára ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?

2 Ṣó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ lónìí ló ti yí ìgbésí ayé wọn pa dà lẹ́yìn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Rárá o. Àwọn ìrírí yìí máa ń jẹ́ ká rántí àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n nírètí àtigbé lọ́run. (Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9-11.) Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ irú àwọn tí kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run, ó sọ nípa àwọn Kristẹni yẹn pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn.” Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà yẹn. Síbẹ̀, lẹ́yìn tí àwọn kan di Kristẹni, wọ́n ṣì ń hu àwọn ìwà tí inú Jèhófà ò dùn sí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹni àmì òróró kan nígbà yẹn lọ́hùn-ún tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́, àmọ́ tí wọ́n gbà pa dà lẹ́yìn tó ṣàtúnṣe. (1 Kọ́r. 5:​1-5; 2 Kọ́r. 2:5-8) Ǹjẹ́ inú wa kì í dùn tá a bá ń kà nípa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ran àwọn Kristẹni kan lọ́wọ́ láti borí onírúurú ìṣòro tí wọ́n ní?

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára gan-an. Torí pé Jèhófà ti fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó yẹ ká máa lò ó lọ́nà tó tọ́. (2 Tím. 2:15) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bá a ṣe lè jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ sa agbára (1) nígbèésí ayé wa, (2) nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, àti (3) nígbà tá a bá ń kọ́ni látorí pèpéle. Àwọn ìránnilétí yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Baba wa ọ̀run, a sì mọrírì bó ṣe ń kọ́ wa ká lè ṣe ara wa láǹfààní.​—⁠Aísá. 48:⁠17.

NÍGBÈÉSÍ AYÉ WA

4. (a) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sa agbára láyé wa? (b) Àsìkò wo lo máa ń ka Bíbélì rẹ?

4 Tá a bá fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sa agbára láyé wa, a gbọ́dọ̀ máa kà á lójoojúmọ́. (Jóṣ. 1:⁠8) Òótọ́ ni pé kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé lè mú kí ọwọ́ wa dí gan-an, síbẹ̀ a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ àtimáa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Kódà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ojúṣe pàtàkì tá a ní dí wa lọ́wọ́. (Ka Éfésù 5:15, 16.) Ọ̀pọ̀ lára wa máa ń wáyè ka Bíbélì lójoojúmọ́, ì báà jẹ́ láàárọ̀, lálẹ́ tàbí lásìkò míì tó rọrùn fún wa. Ó máa ń ṣe wá bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”​—Sm. 119:97.

5, 6. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò? (b) Báwo la ṣe lè ṣàṣàrò lọ́nà tí ohun tá a kà fi máa wọ̀ wá lọ́kàn? (d) Àǹfààní wo lo ti rí bó o ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó o sì ń ṣàṣàrò lórí rẹ̀?

5 Yàtọ̀ sí kíka Bíbélì lójoojúmọ́, ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà. (Sm. 1:1-3) Ó dígbà tá a bá ṣàṣàrò ká tó mọ bó ṣe kàn wá àti bá a ṣe lè fi í sílò nígbèésí ayé wa. Ì báà jẹ́ Bíbélì tí wọ́n tẹ̀ jáde tàbí ti orí fóònù là ń kà, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ká jẹ́ kí ohun tá à ń kà wọ̀ wá lọ́kàn.

6 Báwo la ṣe lè ṣàṣàrò lọ́nà tí ohun tá a kà fi máa wọ̀ wá lọ́kàn? Ohun tí ọ̀pọ̀ máa ń ṣe ni pé, tí wọ́n bá ti ka ibì kan nínú Bíbélì, wọ́n á ronú lórí àwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí ni ibi tí mo kà yìí kọ́ mi nípa Jèhófà? Àwọn ìlànà wo ló wà níbi tí mo kà yìí? Báwo ni mo ṣe ń fi wọ́n sílò nígbèésí ayé mi? Apá ibo ló ti yẹ kí n ṣàtúnṣe?’ Tá a bá ń gbàdúrà bá a ṣe ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa fi àwọn nǹkan tá a kà sílò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á túbọ̀ máa sa agbára nígbèésí ayé wa.​—2 Kọ́r. 10:4, 5.

TÁ A BÁ WÀ LÓDE Ẹ̀RÍ

7. Báwo la ṣe lè lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa lóde ẹ̀rí?

7 Báwo la ṣe lè máa lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa lóde ẹ̀rí? Ohun àkọ́kọ́ ni pé ká máa tọ́ka sí Bíbélì lóòrèkóòrè tá a bá ń wàásù tá a sì ń kọ́ni. Ẹ gbọ́ ohun tí arákùnrin kan sọ lórí kókó yìí, ó ní, “Ká sọ pé ìwọ àti Jèhófà lẹ jọ ń wàásù láti ilé dé ilé, ṣé ìwọ nìkan ni wàá máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ àbí wàá jẹ́ kí Jèhófà náà sọ̀rọ̀?” Ohun tó ń sọ ni pé: Tá a bá ń ka Bíbélì ní tààràtà lóde ẹ̀rí, ńṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà bá onílé sọ̀rọ̀. Tá a bá ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó gbéṣẹ́, ó máa wọ onílé lọ́kàn ju ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tá a lè sọ. (1 Tẹs. 2:13) Torí náà, bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo máa ń sapá láti ka ẹsẹ Bíbélì kan, ó kéré tán pẹ̀lú àwọn tí mò ń wàásù fún?’

8. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣàlàyé Bíbélì tá a kà, tá a bá ń wàásù?

8 Tá a bá fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, kì í wulẹ̀ ṣe pé ká kàn ka Bíbélì fún wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ni kò lóye Bíbélì rárá tàbí kó jẹ́ pé nǹkan díẹ̀ ni wọ́n mọ̀ nípa rẹ̀. Bí nǹkan ṣe rí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà nìyẹn. (Róòmù 10:⁠2) Torí náà, kò yẹ ká ronú pé tá a bá ṣáà ti ka Bíbélì fún ẹnì kan, á lóye rẹ̀. Ṣe ló yẹ ká tẹnu mọ́ àwọn apá tá a fẹ́ fún láfiyèsí, a tiẹ̀ lè tún un kà, ká sì fara balẹ̀ ṣàlàyé rẹ̀. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á túbọ̀ wọ àwọn tá à ń wàásù fún lọ́kàn.​—Ka Lúùkù 24:32.

9. Kí nìdí tó fi yẹ ká nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ lọ́nà táá mú kí onílé nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa? Sọ àpẹẹrẹ bá a ṣe lè ṣe é.

9 Bákan náà, ó yẹ ká nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ lọ́nà táá mú kí onílé nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, a lè sọ pé, “Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Ẹlẹ́dàá wa sọ lórí kókó yìí.” Tá a bá ń bá ẹni tí kì í ṣe Kristẹni sọ̀rọ̀, a lè sọ pé, “Ẹ kíyè sí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ.” Tó bá sì jẹ́ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn là ń bá sọ̀rọ̀, a lè béèrè pé, “Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ́ òwe àtijọ́ yìí rí?” Á dáa ká máa kíyè sí irú ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀, ká sì nasẹ̀ ọ̀rọ̀ wa lọ́nà táá jẹ́ kó nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa.​—1 Kọ́r. 9:22, 23.

10. (a) Sọ ìrírí tí arákùnrin kan ní. (b) Sọ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ran ẹnì kan lọ́wọ́ nígbà tó o wà lóde ẹ̀rí?

10 Ọ̀pọ̀ ti rí i pé táwọn bá ka Bíbélì fún àwọn èèyàn lóde ẹ̀rí, ó máa ń nípa lórí wọn gan-an. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Arákùnrin kan lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ bàbá àgbàlagbà kan tó ti ń gba àwọn ìwé ìròyìn wa fún ọ̀pọ̀ ọdún. Kàkà kí arákùnrin yìí kàn fún bàbá yẹn ní Ilé Ìṣọ́ tó jáde kẹ́yìn, ńṣe ló ka 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4 tí wọ́n tọ́ka sí nínú ìwé ìròyìn náà. Ẹsẹ Bíbélì yẹn kà pé: “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo . . . ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” Ẹsẹ Bíbélì yìí wọ bàbá yẹn lọ́kàn débi pé ó ní kí arákùnrin náà tún un kà. Bàbá náà sọ pé òun àti ìyàwó òun nílò ìtùnú gan-an, èyí sì mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àbí ẹ ò rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń sa agbára nígbà tá a bá lò ó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù!​—Ìṣe 19:20.

TÁ A BÁ Ń KỌ́NI LÁTORÍ PÈPÉLE

11. Ojúṣe wo làwọn arákùnrin tó ń kọ́ni látorí pèpéle ní?

11 Gbogbo wa la máa ń gbádùn àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ tá a máa ń ṣe. Olórí ìdí tá a fi máa ń pé jọ ni láti jọ́sìn Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìtọ́ni tá a máa ń gbà níbẹ̀ máa ń ṣe wá láǹfààní gan-an. Ká sòótọ́, àǹfààní ńlá làwọn arákùnrin tó ń kọ́ni lórí pèpéle ní. Síbẹ̀ wọ́n gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé ojúṣe ńlá ló wà léjìká wọn, ó sì yẹ kí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú un. (Ják. 3:1) Wọ́n gbọ́dọ̀ rí i dájú pé gbogbo ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni ni wọ́n gbé ka orí Bíbélì. Torí náà, tó o bá láǹfààní àtikọ́ni látorí pèpéle, báwo lo ṣe lè jẹ́ kí àwùjọ rí agbára tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

12. Báwo ni ẹni tó ń kọ́ni látorí pèpéle ṣe lè rí i dájú pé orí Ìwé Mímọ́ ni àsọyé òun dá lé?

12 Rí i dájú pé orí Ìwé Mímọ́ ni àsọyé rẹ dá lé. (Jòh. 7:16) Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Má ṣe jẹ́ kí ìrírí, àpèjúwe tàbí ọ̀nà tó o gbà sọ àsọyé rẹ gba àfiyèsí àwùjọ ju àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o kà lọ. Bákan náà, ìyàtọ̀ wà nínú kéèyàn ka ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ Bíbélì àti kéèyàn fi Bíbélì kọ́ni. Ká sòótọ́, bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o kà bá ti pọ̀ jù, àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ lè má rí nǹkan kan dì mú. Torí náà, fara balẹ̀ yan àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o máa kà. Lẹ́yìn náà, kà á lọ́nà tó nítumọ̀, ṣàlàyé rẹ̀, ṣàkàwé rẹ̀, kó o sì jẹ́ kí wọ́n rí ẹ̀kọ́ inú rẹ̀. (Neh. 8:8) Tí wọ́n bá ní kó o sọ àsọyé, rí i pé o lóye ìwé àsọyé náà àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ inú rẹ̀. Wo bí àwọn ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ ṣe tan mọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n tọ́ka sí. Lẹ́yìn náà, yan àwọn ẹsẹ Bíbélì tó máa gbé ẹ̀kọ́ náà jáde. (Wàá rí àwọn àbá tó ṣeé múlò nínú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ẹ̀kọ́ 21 sí 23.) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó tọ́.​—Ka Ẹ́sírà 7:10; Òwe 3:13, 14.

13. (a) Báwo ni arábìnrin kan ṣe jàǹfààní látinú bí olùbánisọ̀rọ̀ kan ṣe lo Ìwé Mímọ́ nípàdé? (b) Àǹfààní wo lo ti rí látinú bí olùbánisọ̀rọ̀ kan ṣe ṣàlàyé Bíbélì nípàdé?

13 Arábìnrin kan ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà jàǹfààní látinú bí olùbánisọ̀rọ̀ kan ṣe lo Ìwé Mímọ́ nípàdé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé arábìnrin náà ti fojú winá ọ̀pọ̀ nǹkan lọ́mọdé, síbẹ̀ ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì ti ṣèrìbọmi. Bó ti wù kó rí, ó ṣòro fún un láti gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun. Àmọ́ nígbà tó yá, ó gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun. Kí ló yí i lérò pa dà? Ó ṣàṣàrò lórí ẹsẹ Bíbélì kan tí wọ́n ṣàlàyé nípàdé, ó sì ronú nípa bó ṣe tan mọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì míì. * Bíi ti arábìnrin yìí, ǹjẹ́ ìgbà kan wà tí wọ́n lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan nípàdé ìjọ tàbí láwọn àpéjọ, tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà sì gún ọkàn rẹ ní kẹ́ṣẹ́?​—Neh. 8:12.

14. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

14 Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ó yẹ ká máa dúpẹ́, torí láfikún sí pé Jèhófà fún wa ní Bíbélì, ó tún mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé Ọ̀rọ̀ òun máa wà títí láé. (1 Pét. 1:24, 25) Torí náà, ó yẹ ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ká máa fi ìlànà rẹ̀ sílò, ká sì máa fi ran àwọn míì lọ́wọ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn iyebíye yìí, a sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tó fún wa ní ẹ̀bùn náà.

^ ìpínrọ̀ 13 Wo àpótí náà, “ Nǹkan Yí Pa Dà.