Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Àgbàlagbà​—Jèhófà Mọyì Iṣẹ́ Yín

Ẹ̀yin Àgbàlagbà​—Jèhófà Mọyì Iṣẹ́ Yín

KÁRÍ ayé, àwọn alàgbà mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run. Inú wa sì dùn pé Jèhófà fi wọ́n jíǹkí wa! Àmọ́ láìpẹ́ yìí, ètò Ọlọ́run ṣe àyípadà kan. Wọ́n sọ pé káwọn alàgbà tó ti dàgbà gbé àwọn ojúṣe pàtàkì tí wọ́n ń bójú tó fáwọn alàgbà tó kéré sí wọn lọ́jọ́ orí. Lọ́nà wo?

Ètò Ọlọ́run sọ pé káwọn alábòójútó àyíká àtàwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run gbé àwọn ojúṣe pàtàkì yìí sílẹ̀ tí wọ́n bá ti pé ẹni àádọ́rin (70) ọdún, káwọn tọ́jọ́ orí wọn ò tóyẹn lè máa bójú tó iṣẹ́ náà. Bákan náà, àwọn alàgbà tó ń bójú tó àwọn iṣẹ́ míì, irú bí olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka àti olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà máa fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ tí wọ́n bá ti pé ẹni ọgọ́rin (80) ọdún. Kí làwọn alàgbà tó ti dàgbà yìí ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa ìyípadà náà? Wọ́n fara mọ́ ìyípadà yìí, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti ètò rẹ̀.

Ken tó jẹ́ olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta (49) sọ pé: “Gbogbo ara ni mo fi fara mọ́ ìyípadà yìí. Mo rántí pé láàárọ̀ ọjọ́ kan, mo bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ẹni tó kéré sí mi lọ́jọ́ orí máa bójú tó iṣẹ́ yìí, ó yà mí lẹ́nu pé ọjọ́ yẹn gan-an ni mo gbọ́ nípa ìyípadà yìí.” Bọ́rọ̀ ṣe rí lára Ken náà ló ṣe rí lára ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà tó ń fòótọ́ inú sin Jèhófà kárí ayé. Àmọ́ ká sòótọ́, ìyípadà yìí ò rọrùn torí pé àwọn alàgbà yìí nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, ó sì máa ń wù wọ́n láti máa sin àwọn arákùnrin wọn.

Esperandio tó jẹ́ olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ rẹ̀ sọ pé: “Ó kọ́kọ́ dùn mí díẹ̀.” Àmọ́ ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé ó yẹ kí n wáyé tọ́jú ara mi.” Síbẹ̀, Esperandio ṣì ń fòótọ́ inú sin Jèhófà, àwọn ará ìjọ sì mọyì rẹ̀ gan-an.

Àwọn kan ti ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò fún ọ̀pọ̀ ọdún kí ètò Ọlọ́run tó yí iṣẹ́ wọn pa dà. Báwo ni ìyípadà yìí ṣe rí lára wọn? Allan tó ti ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò fún ọdún méjìdínlógójì (38) sọ pé: “Nígbà tí mo gbọ́, ó kọ́kọ́ rẹ̀ mí wá.” Síbẹ̀, Allan ń fòótọ́ sin Jèhófà nìṣó, torí ó gbà pé ó dáa bí ètò Ọlọ́run ṣe ń dá àwọn tó kéré lọ́jọ́ orí lẹ́kọ̀ọ́.

Russell tó jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò àti olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run fún ogójì (40) ọdún sọ pé inú òun àti ìyàwó òun ò dùn nígbà táwọn kọ́kọ́ gbọ́ nípa ìyípadà náà. Russell sọ pé: “À ń gbádùn iṣẹ́ wa gan-an, a sì ronú pé a ṣì lókun láti máa báṣẹ́ náà lọ.” Síbẹ̀, wọ́n fara mọ́ ìyípadà náà, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Ní báyìí, àwọn ará ìjọ wọn ń jàǹfààní látinú ìrírí wọn.

Tó bá jẹ́ pé ìyípadà yìí ò kàn ẹ́, ìtàn tó wà nínú 2 Sámúẹ́lì lè jẹ́ kó o mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn tí ìyípadà náà kàn.

ỌKÙNRIN KAN TÓ MỌ̀WỌ̀N ARA RẸ̀

Ronú nípa ìgbà tí Ábúsálómù ọmọ Ọba Dáfídì dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ bàbá rẹ̀. Dáfídì sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Máhánáímù ní ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì. Dáfídì àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nílò oúnjẹ àtàwọn ohun ìgbẹ́mìíró míì. Ǹjẹ́ o rántí ohun tó ṣẹlẹ̀?

Àwọn ọkùnrin mẹ́ta lágbègbè náà wá pèsè àwọn nǹkan tí Dáfídì nílò. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n kó ibùsùn, onírúurú oúnjẹ àtàwọn nǹkan èlò míì wá fún wọn. Lára àwọn ọkùnrin mẹ́ta náà ni Básíláì. (2 Sám. 17:27-29) Nígbà táwọn ọmọ ogun Dáfídì ṣẹ́gun Ábúsálómù, Dáfídì pa dà sí Jerúsálẹ́mù, Básíláì wá sìn ín dé Jọ́dánì. Àmọ́ Dáfídì rọ Básíláì pé kó jẹ́ káwọn jọ pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Kódà, Dáfídì sọ pé òun á máa pèsè oúnjẹ fún un déédéé bó tilẹ̀ jẹ́ pé olówó ni Básíláì, kò sì nílò oúnjẹ tí Dáfídì fẹ́ fún un. (2 Sám. 19:31-33) Dáfídì nífẹ̀ẹ́ Básíláì torí àwọn ànímọ́ àtàtà tó ní, ó sì fẹ́ kó wà pẹ̀lú òun kó lè máa gba òun nímọ̀ràn. Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ló máa jẹ́ fún Básíláì láti máa gbé nínú ààfin ọba, kó sì tún máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀!

Àmọ́ torí pé Básíláì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó sọ fún Dáfídì pé òun ti pé ẹni ọgọ́rin (80) ọdún. Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Mo ha lè fi òye mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú?” Kí ni Básíláì ní lọ́kàn? Àgbà ọkùnrin ni Básíláì, ó sì dájú pé ó máa nírìírí gan-an. Torí náà, ó lè fún Dáfídì nímọ̀ràn ọlọ́gbọ́n bí “àwọn àgbà ọkùnrin” ṣe fún Ọba Rèhóbóámù nímọ̀ràn ọlọ́gbọ́n. (1 Ọba 12:6, 7; Sm. 92:12-14; Òwe 16:31) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn nǹkan tí kò lè ṣe torí ara tó ti dara àgbà ló mú kí Básíláì sọ ohun tó sọ. Ó gbà pé òun ò lè gbádùn oúnjẹ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, òun ò sì lè gbọ́ràn dáadáa mọ́. (Oníw. 12:4, 5) Torí náà, Básíláì sọ fún Dáfídì pé kó mú Kímúhámù dání lọ sí Jerúsálẹ́mù torí pé kò tíì dàgbà púpọ̀. Ó sì ṣeé ṣe kí Kímúhámù jẹ́ ọmọ Básíláì.​—2 Sám. 19:35-40.

À Ń MÚRA SÍLẸ̀ DE ỌJỌ́ IWÁJÚ

Ìtàn Básíláì jẹ́ ká rí ohun tó mú kí ètò Ọlọ́run ṣe ìyípadà tá a mẹ́nu kàn lókè. Kì í ṣọ̀rọ̀ ẹnì kan la gbé yẹ̀ wò tá a fi ṣe ìyípadà yìí. Àmọ́ ohun tó máa ṣe àwọn alàgbà láǹfààní kárí ayé la gbé yẹ̀ wò.

Àwọn alàgbà tó ti dàgbà mọ̀ pé bí ètò Ọlọ́run ṣe túbọ̀ ń gbèrú sí i, ó ṣe pàtàkì káwọn alàgbà tó ṣì kéré lọ́jọ́ orí gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn ojúṣe pàtàkì táwọn àgbàlagbà yẹn ń bójú tó tẹ́lẹ̀. Bí Básíláì ṣe dá ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, tí Pọ́ọ̀lù náà sì dá Tímótì lẹ́kọ̀ọ́, bẹ́ẹ̀ náà làwọn arákùnrin tó ti dàgbà máa ń dá àwọn tó ṣì kéré lọ́jọ́ orí lẹ́kọ̀ọ́. (1 Kọ́r. 4:17; Fílí. 2:20-22) Àwọn alàgbà tó kéré lọ́jọ́ orí yìí ti fi hàn pé àwọn tó ẹni tó ṣeé faṣẹ́ lé lọ́wọ́, àwọn sì jẹ́ “ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn” tó lè ‘gbé ara Kristi ró.’​—Éfé. 4:8-12; fi wé Númérì 11:16, 17, 29.

ÀWỌN NǸKAN MÍÌ TẸ́ Ẹ LÈ ṢE

Kárí ayé, ọ̀pọ̀ nínú àwọn àgbàlagbà tó ti fi iṣẹ́ tí wọ́n ń bójú tó sílẹ̀ ti rí i pé àǹfààní ṣì wà fáwọn láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Jèhófà.

Marco tó ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò fún ọdún mọ́kàndínlógún (19) sọ pé: “Nínú ìjọ mi, àwọn arábìnrin kan wà tí ọkọ wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, mò ń lo àǹfààní tí mo ní báyìí láti bá àwọn ọkọ wọn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà.”

Geraldo tó ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò fún ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n (28) sọ pé: “Ohun tá a pinnu ni pé, a máa lo àǹfààní tá a ní láti ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́, ká sì túbọ̀ láwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Geraldo wá fi kún un pé, ní báyìí àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lòun àtìyàwó òun ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ọ̀pọ̀ àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ ló sì ti ń wá sípàdé.

Allan tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “A ti wá láǹfààní láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ní báyìí, à ń gbádùn ìwàásù níbi térò pọ̀ sí àti láwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ajé. A tún máa ń wàásù fáwọn aládùúgbò wa, kódà méjì nínú wọn ti wá sípàdé rí.”

Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà ti ṣiṣẹ́ ribiribi nínú ètò Ọlọ́run sẹ́yìn, tí ìyípadà tí ètò Ọlọ́run ṣe sì kàn ẹ́, ọ̀nà pàtàkì kan wà tó o lè gbà ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà. O lè fi àwọn ìrírí alárinrin tó o ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà dá àwọn ọ̀dọ́kùnrin lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ. Russell tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Jèhófà ń lo àwọn ọ̀dọ́ tó múra tán láti ṣiṣẹ́, ó sì ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Torí pé àwọn ọ̀dọ́ yìí lókun, wọ́n lè kọ́ni dáadáa kí wọ́n sì ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn. Ká sòótọ́, gbogbo wa là ń jàǹfààní látinú ìyípadà yìí!”​—Wo àpótí náà “ Ran Àwọn Ọ̀dọ́kùnrin Lọ́wọ́ Láti Lo Ẹ̀bùn Wọn ní Kíkún.”

JÈHÓFÀ MỌYÌ IṢẸ́ YÍN

Tó bá jẹ́ pé o ti fi iṣẹ́ tó ń bójú tó sílẹ̀ torí ìyípadà tí ètò Ọlọ́run ṣe yìí, má bọkàn jẹ́. Ó dájú pé iṣẹ́ ìsìn tó o ti ṣe látọdún yìí wá ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ gan-an, o sì lè ṣe púpọ̀ sí i. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé gbogbo àwọn ará nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, wọn ò sì ní gbàgbé ẹ láé.

Ní pàtàkì jù lọ, Jèhófà ò lè gbàgbé gbogbo ohun tẹ́ ẹ ti ṣe láé. Bíbélì sọ pé kò ní “gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.” (Héb. 6:10) Ọ̀rọ̀ Bíbélì yẹn jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ń rántí gbogbo iṣẹ́ tá a ti ṣe. A ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà débi pé títí láé lá máa rántí gbogbo ohun tá a ti ṣe sẹ́yìn àtèyí tá à ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ fún ìfẹ́ rẹ̀!

Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ́ ṣì ni ẹ́, má ṣe ronú pé ìyípadà tí ètò Ọlọ́run ṣe yìí kò kàn ẹ́. Ìdí ni pé ìwọ náà máa jàǹfààní nínú ètò tuntun yìí. Lọ́nà wo?

Tó o bá mọ arákùnrin àgbàlagbà kan tó ti fi iṣẹ́ tó ń bójú tó sílẹ̀ torí ọjọ́ orí rẹ̀, á dáa kó o sún mọ́ ọn kó o lè jàǹfààní látinú àwọn ìrírí rẹ̀. Máa gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ rẹ̀, kó o sì máa wo bó ṣe ń lo àwọn ìrírí tó ti ní lẹnu iṣẹ́ Jèhófà nísinsìnyí.

Yálà a jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àgbàlagbà tí ìyípadà náà dé bá, tàbí a jẹ́ ọ̀dọ́ tó ń jàǹfààní látinú ìrírí wọn, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà mọyì gbogbo àwọn tó ti fòótọ́ inú sìn ín fún ọ̀pọ̀ ọdún, tí wọ́n sì ń bá a nìṣó láti máa ṣe bẹ́ẹ̀.