Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Gba Tàwọn Míì Rò Bíi Ti Jèhófà

Máa Gba Tàwọn Míì Rò Bíi Ti Jèhófà

“Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀.”​—SM. 41:1.

ORIN: 130, 107

1. Báwo làwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ara wọn?

ÌFẸ́ ló so àwa èèyàn Ọlọ́run pọ̀ kárí ayé, èyí sì mú ká dà bí ọmọ ìyá. (1 Jòh. 4:16, 21) Kò dìgbà tá a bá ṣe nǹkan ńlá ká tó lè fi ìfẹ́ yìí hàn. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn nǹkan kéékèèké tó lè dà bíi pé kò jọjú tá à ń ṣe fáwọn míì ló máa ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa. Bí àpẹẹrẹ, a lè sọ̀rọ̀ tó máa gbé àwọn míì ró tàbí ká ṣoore fún wọn. Torí náà, tá a bá jẹ́ onínúure, tá a sì ń gba tàwọn míì rò, àá “di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.”​—Éfé. 5:1.

2. Báwo ni Jésù ṣe fìfẹ́ hàn sí àwọn míì bíi ti Baba rẹ̀?

2 Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀ láìkù síbì kan. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára . . . , nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi.” (Mát. 11:28, 29) Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, tá à ń “fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀,” a máa rí ojú rere Jèhófà, ayọ̀ tá a sì máa ní á kọjá àfẹnusọ. (Sm. 41:1) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè máa gba tàwọn míì rò nínú ìdílé, nínú ìjọ àti lóde ẹ̀rí.

MÁA GBA TI ÌDÍLÉ RẸ RÒ

3. Báwo ni ọkọ kan ṣe lè gba ti aya rẹ̀ rò, kó sì tún lóye bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

3 Ó yẹ kí àwọn ọkọ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá di pé kí wọ́n gba ti ìdílé wọn rò. (Éfé. 5:25; 6:4) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé kí àwọn ọkọ máa bá àwọn aya “wọn gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀,” ìyẹn ni pé kí wọ́n máa gba tiwọn rò, kí wọ́n sì lóye bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn. (1 Pét. 3:7.) Bí àpẹẹrẹ, ọkọ tó lóye aya rẹ̀ máa gbà pé olùrànlọ́wọ́ ni ìyàwó òun jẹ́ àti pé àwọn yàtọ̀ síra láwọn ọ̀nà kan, síbẹ̀ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ipò tó rẹlẹ̀ làwọn obìnrin wà. (Jẹ́n. 2:18) Torí náà, irú ọkọ bẹ́ẹ̀ á máa gba ti aya rẹ̀ rò, á máa buyì kún un, á sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Kánádà sọ ohun tí ọkọ rẹ̀ máa ń ṣe, ó sọ pé: “Ọkọ mi kì í fọ̀rọ̀ mi ṣeré, kì í kó ọ̀rọ̀ mi dànù tàbí kó sọ pé, ‘Kò yẹ kó o máa ronú bẹ́ẹ̀ yẹn.’ Ó máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí mi nígbàkigbà tí mo bá ń sọ̀rọ̀. Tí mo bá tiẹ̀ ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó tó sì fẹ́ gbà mí nímọ̀ràn, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́.”

4. Báwo ni ọkọ kan ṣe lè gba ti aya rẹ̀ rò tó bá kan bó ṣe ń ṣe pẹ̀lú àwọn obìnrin míì?

4 Ọkọ tó bá ń gba ti aya rẹ̀ rò á máa kíyè sára tó bá wà pẹ̀lú àwọn obìnrin míì. Bí àpẹẹrẹ, kò ní máa bá àwọn obìnrin míì tage tàbí kó máa ṣe bí ẹni tó gba tiwọn. Irú ọkọ bẹ́ẹ̀ kì í bá àwọn obìnrin míì dọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀ lórí ìkànnì àjọlò tàbí lórí àwọn ìkànnì míì. (Jóòbù 31:1) Dípò bẹ́ẹ̀, á jẹ́ olóòótọ́ sí aya rẹ̀ kì í ṣe torí pé ó nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nìkan, àmọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì kórìíra ohun tó burú.​—Ka Sáàmù 19:14; 97:10.

5. Báwo ni aya kan ṣe lè gba ti ọkọ rẹ̀ rò?

5 Tí ọkọ kan bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi tó jẹ́ orí rẹ̀, ìyẹn máa jẹ́ kó rọrùn fún aya rẹ̀ láti fún un ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (Éfé. 5:22-25, 33) Aya tó bá ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ máa gba ti ọkọ rẹ̀ rò, pàápàá tí ọkọ rẹ̀ bá ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó ń bójú tó nínú ìjọ. Nígbà míì, àwọn iṣẹ́ ìjọ yìí lè gbà á lákòókò, ìgbà míì sì wà tí ọ̀rọ̀ kan á máa jẹ ọkọ rẹ̀ lọ́kàn. Ọkọ kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Tí ìyàwó mi bá kíyè sí i pé ìṣesí mi ti yàtọ̀, á fòye mọ̀ pé nǹkan kan ti ń gbé mi lọ́kàn nìyẹn. Á wá fi ìlànà tó wà ní Òwe 20:5 sílò, ìyẹn sì máa gba pé kó dúró dìgbà tó tọ́ tá a lè jọ jíròrò ọ̀rọ̀ náà, ìyẹn tó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ tá a lè jọ sọ.”

6. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè fún àwọn ọmọdé níṣìírí láti máa gba tàwọn míì rò, ẹ̀kọ́ wo nìyẹn máa kọ́ àwọn ọmọ náà?

6 Táwọn òbí bá ń gba ti ara wọn rò, àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn máa jẹ́ fáwọn ọmọ wọn. Ojúṣe àwọn òbí ni láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè máa gba tàwọn míì rò. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí lè kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n má ṣe máa sáré kiri nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Tí wọ́n bá sì wà níbi àpèjẹ, kí wọ́n jẹ́ kí àwọn àgbàlagbà kọ́kọ́ gba oúnjẹ tiwọn. Síbẹ̀, gbogbo wa nínú ìjọ lè ran àwọn òbí lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ kan bá ṣe ohun tó wú wa lórí, bóyá tó bá wa ṣí ilẹ̀kùn, ó yẹ ká gbóríyìn fún un. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú ọmọ náà máa dùn, á sì jẹ́ kó túbọ̀ wù ú láti máa ṣe nǹkan fáwọn míì. Nípa bẹ́ẹ̀, òun náà á kẹ́kọ̀ọ́ pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”​—Ìṣe 20:35.

‘Ẹ JẸ́ KÍ A GBA TI ARA WA RÒ LẸ́NÌ KÌÍNÍ-KEJÌ’ NÍNÚ ÌJỌ

7. Báwo ni Jésù ṣe gba ti ọkùnrin adití kan rò, àwọn nǹkan wo la sì rí kọ́ lára Jésù?

7 Lọ́jọ́ kan tí Jésù wà ní àgbègbè Dekapólì, àwọn èèyàn ‘mú ọkùnrin adití kan tí ó ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ wá bá a.’ (Máàkù 7:31-35) Dípò kí Jésù wo ọkùnrin náà sàn níṣojú ọ̀pọ̀ èèyàn, ńṣe ló “mú un lọ” sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wò ó sàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó ṣeé ṣe kójú máa ti ọkùnrin náà láàárín èrò torí ipò tó wà. Jésù mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi wò ó sàn ní ìkọ̀kọ̀. Òótọ́ ni pé àwa ò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu lónìí. Àmọ́ ohun kan wà táwa náà lè ṣe, ó yẹ ká máa kíyè sí bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn ará wa ká sì gba tiwọn rò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Héb. 10:24) Jésù mọ bí nǹkan ṣe rí lára adití yẹn, ó sì gba tiẹ̀ rò. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn jẹ́ fún wa!

8, 9. Báwo la ṣe lè gba tàwọn àgbàlagbà àtàwọn aláìlera rò? (Sọ àpẹẹrẹ díẹ̀.)

8 Máa gba tàwọn àgbàlagbà àtàwọn aláìlera rò. Ìfẹ́ la fi ń dá àwa Kristẹni tòótọ́ mọ̀, kì í ṣe bá a ṣe já fáfá tó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. (Jòh. 13:34, 35) Ìfẹ́ yìí ló ń mú ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn àgbàlagbà àtàwọn aláàbọ̀ ara lọ́wọ́ kódà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn fún wa. Lára ohun tá a lè ṣe ni pé, ká gbé wọn wá sípàdé tàbí ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lè ṣe púpọ̀. (Mát. 13:23) Bí àpẹẹrẹ, Michael ò lè rìn, orí àga arọ ló sì máa ń wà látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Síbẹ̀, ó mọrírì bí ìdílé rẹ̀ àtàwọn ará tí wọ́n jọ wà ní àwùjọ ṣe ń ràn án lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Bí gbogbo àwọn ará ṣe gbárùkù tì mí ti mú kó ṣeé ṣe fún mi láti máa lọ sípàdé lọ́pọ̀ ìgbà, kí n sì máa lọ sí òde ẹ̀rí déédéé. Mo tiẹ̀ máa ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù níbi térò pọ̀ sí gan-an.”

9 Lọ́pọ̀ Bẹ́tẹ́lì kárí ayé, a ní àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà àtàwọn tó jẹ́ aláìlera. Àwọn alábòójútó onífẹ̀ẹ́ máa ń gba tàwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ yìí rò, wọ́n sì máa ń ṣètò bí wọ́n á ṣe wàásù nípasẹ̀ lẹ́tà tàbí kí wọ́n wàásù látorí fóònù. Bill tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún (86) máa ń wàásù nípa kíkọ lẹ́tà sáwọn tó ń gbé níbi tó jìnnà gan-an, ó sọ pé: “Inú wa dùn pé a láǹfààní láti máa fi lẹ́tà wàásù.” Nancy tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún sọ pé: “Mi ò kì í wo lẹ́tà kíkọ́ bí ohun tí mò ń ṣe lásìkò ọwọ́dilẹ̀. Mo gbà pé iṣẹ́ ìwàásù ni torí àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ mọ òtítọ́!” Ethel tí wọ́n bí ní 1921 sọ pé: “Ojoojúmọ́ lara máa ń ro mí. Kódà láwọn ọjọ́ míì, àtimúra máa ń nira fún mi.” Láìka gbogbo ìyẹn sí, inú rẹ̀ máa ń dùn bó ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn lórí fóònù, kódà ó ti láwọn ìpadàbẹ̀wò. Barbara tó jẹ́ ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rin (85) sọ pé: “Ó máa ń ṣòro fún mi láti lọ sí òde ẹ̀rí déédéé torí àìlera tó ń bá mi fínra. Ṣùgbọ́n, ìwàásù orí fóònú ti jẹ́ kí n lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. O ṣé o, Jèhófà!” Láàárín ọdún kan péré, àwọn àgbàlagbà wa ọ̀wọ́n yìí ní Bẹ́tẹ́lì kan fi ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan wákàtí (1,228) wàásù, wọ́n kọ lẹ́tà tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,265), wọ́n wàásù fáwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) lórí fóònù, wọ́n sì fi ìtẹ̀jáde tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,315) síta! Ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn bí àwọn ẹni ọ̀wọ́n yìí ṣe lo ara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀!​—Òwe 27:11.

10. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ káwọn ará gbádùn ìpàdé?

10 Máa gba tàwọn míì rò nípàdé. Ó dájú pé a fẹ́ káwọn ará wa gbádùn ìpàdé, àmọ́ kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, ó yẹ ká gba tiwọn rò. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀nà kan ni pé ká tètè máa dé sípàdé, torí tá a bá wọlé nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́, ọkàn àwọn ará lè pínyà kí wọ́n sì pàdánù apá tó ń lọ lọ́wọ́. Òótọ́ ni pé láwọn ìgbà míì, àwọn nǹkan tá ò rò tẹ́lẹ̀ lè mú ká pẹ́. Àmọ́ tó bá ti mọ́ wa lára láti máa pẹ́ dé ìpàdé, ó yẹ ká ṣàtúnṣe, ìyẹn á sì fi hàn pé a gba tàwọn míì rò. Ká fi sọ́kàn pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ló pè wá ká lè wá gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí. (Mát. 18:20) Torí náà, tá a bá ń tètè dé sípàdé, à ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún wọn nìyẹn!

11. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn arákùnrin tó níṣẹ́ nípàdé fi ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 14:40 sílò?

11 Ohun míì tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ máa gba tàwọn ará wa rò ni pé ká fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sọ́kàn pé: “Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.” (1 Kọ́r. 14:40) Àwọn arákùnrin tó níṣẹ́ nípàdé lè fi ìmọ̀ràn yẹn sọ́kàn tí wọn ò bá kọjá àkókò tá a yàn fún iṣẹ́ wọn. Táwọn arákùnrin yìí bá ń parí iṣẹ́ wọn lásìkò, ṣe ni wọ́n ń gba tàwọn olùbánisọ̀rọ̀ tó kù rò. Àmọ́ kì í ṣèyẹn nìkan, wọ́n tún ń gba ti gbogbo ìjọ rò lápapọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará kan ń gbé níbi tó jìnnà gan-an, àwọn míì tiẹ̀ máa ní láti wá ọkọ̀ tó máa gbé wọn pa dà sílé. Ká tún fi sọ́kàn pé àwọn kan wà tí ọkọ tàbí aya wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń retí wọn nílé.

12. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fún àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára ní “ìkàsí tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ nínú ìfẹ́”? (Wo àpótí náà “ Máa fi Ìgbatẹnirò Hàn Sáwọn Tó Ń Múpò Iwájú.”)

12 Iṣẹ́ ńlá làwọn alàgbà ń ṣe torí pé wọ́n máa ń fìtara múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run. Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká fún wọn ní ìkàsí tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:12, 13.) Ó dájú pé o mọyì iṣẹ́ takuntakun táwọn alàgbà ń ṣe nínú ìjọ. Tó o bá mọyì wọn, wàá máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé “wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn [wa] bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn.”​—Héb. 13:7, 17.

MÁA GBA TÀWỌN MÍÌ RÒ LÓDE Ẹ̀RÍ

13. Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe gba tàwọn míì rò?

13 Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jésù pé: “Kò sí esùsú fífọ́ tí òun yóò ṣẹ́; àti ní ti òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó bàìbàì, òun kì yóò fẹ́ ẹ pa.” (Aísá. 42:3) Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an, ó sì máa ń gba tiwọn rò. Ó mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá, ìyẹn àwọn tó dà bí esùsú fífọ́ tàbí òwú àtùpà tó ń jó lọ́úlọ́ú, tó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán. Abájọ tí Jésù fi jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú, ẹni tó ń gba tàwọn míì rò, tó sì máa ń mú sùúrù fún wọn. Kódà, àwọn ọmọdé nífẹ̀ẹ́ Jésù. (Máàkù 10:14) Òótọ́ ni pé òye tiwa kò tó ti Jésù, a ò sì lè mọ̀ọ̀yàn kọ́ bíi tiẹ̀. Síbẹ̀, ó yẹ ká máa gba tàwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa rò. Ìyẹn gba pé, ká mọ bó ṣe yẹ ká bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ìgbà tó yẹ ká lọ sọ́dọ̀ wọn àti bó ṣe yẹ ká pẹ́ tó lọ́dọ̀ wọn.

14. Kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sí bá a ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?

14 Báwo ló ṣe yẹ ká máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀? Lónìí, àwọn oníṣòwò tí ò lójú àánú, àwọn jẹgúdújẹrá olóṣèlú àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí ò mọ̀ ju owó lọ ti fi ojú ọ̀pọ̀ èèyàn rí màbo, ó dà bí ìgbà tí wọ́n ti ‘bó wọn láwọ, tí wọ́n sì fọ́n wọn ká.’ (Mát. 9:36) Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ò fọkàn tán ẹnikẹ́ni, wọ́n ò sì nírètí. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì ká máa gba tiwọn rò, ká sì máa fohùn pẹ̀lẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀ tá a bá ń wàásù fún wọn! Ká sòótọ́, kì í ṣe torí pé a mọ Bíbélì tàbí a mọ bá a ṣe ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀ nìkan lọ̀pọ̀ ṣe ń tẹ́tí sí wa, ṣùgbọ́n wọ́n máa ń kíyè sí i bí ọ̀rọ̀ wọn ṣe máa ń jẹ wá lógún, tá a sì ń gba tiwọn rò.

15. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a gba tàwọn tá à ń wàásù fún rò?

15 Onírúurú ọ̀nà la lè gbà fi hàn pé a gba tàwọn tá à ń wàásù fún rò. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ kọ́ni lọ́nà tó máa wọni lọ́kàn, ó ṣe pàtàkì ká máa béèrè ìbéèrè. Ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ béèrè ìbéèrè tó ń buyì kúnni, tó sì ń fọ̀wọ̀ hàn. Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń gbé lágbègbè táwọn èèyàn ti máa ń tijú sọ pé òun kì í béèrè ìbéèrè tó lè kó ìtìjú bá àwọn tóun ń wàásù fún. Bákan náà, kì í béèrè àwọn ìbéèrè tí ẹni náà ò ní lè dáhùn tàbí tí kò ní gbà. Bí àpẹẹrẹ, kì í béèrè àwọn ìbéèrè bíi, ‘Ṣé ẹ mọ orúkọ Ọlọ́run?’ tàbí, ‘Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sábà máa ń sọ pé, “Bíbélì jẹ́ kí n mọ̀ pé Ọlọ́run ní orúkọ. Ǹjẹ́ mo lè fi orúkọ yẹn hàn yín?” Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àṣà ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan máa ń yàtọ̀ síra. Ó ṣe tán, àwọn èèyàn máa ń sọ pé ‘báyìí là ń ṣe nílẹ̀ wa, èèwọ̀ ibòmíì ni.’ Torí náà, ó yẹ ká máa gba tàwọn èèyàn rò ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn ní gbogbo ìgbà. Ká lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká mọ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa dunjú.

16, 17. Báwo la ṣe lè gba tàwọn tá à ń wàásù fún rò tó bá dọ̀rọ̀ (a) ìgbà tá a máa lọ sọ́dọ̀ wọn? (b) bá a ṣe máa pẹ́ tó lọ́dọ̀ wọn?

16 Ìgbà wo ló yẹ ká lọ wàásù fáwọn èèyàn? Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn tá a fẹ́ lọ wàásù fún ò mọ̀ pé à ń bọ̀. Torí náà, ó yẹ ká wá àwọn èèyàn lọ nígbà tá a mọ̀ pé ó máa rọ̀ wọ́n lọ́rùn. (Mát. 7:12) Bí àpẹẹrẹ, ṣé àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín máa ń pẹ́ kí wọ́n tó jí láwọn òpin ọ̀sẹ̀, bóyá torí wọ́n máa ń fẹ́ sinmi dáadáa? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ lè kọ́kọ́ fi ìjẹ́rìí òpópónà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tàbí kẹ́ ẹ lọ wàásù níbi térò pọ̀ sí, ẹ sì lè lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tẹ́ ẹ ti mọ̀ dáadáa tẹ́lẹ̀.

17 Báwo ló ṣe yẹ ká pẹ́ tó lọ́dọ̀ àwọn èèyàn? Lónìí, ọwọ́ àwọn èèyàn máa ń dí gan-an, torí náà, á dáa ká má ṣe pẹ́ jù lọ́dọ̀ wọn ní pàtàkì nígbà àkọ́kọ́. Ó yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa ṣe ṣókí, ó ṣe tán àwọn èèyàn máa ń sọ pé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ò kágbọ̀n. (1 Kọ́r. 9:20-23) Tí àwọn tá à ń wàásù fún bá rí i pé a gba tiwọn rò, a ò sì lo àkókò tó pọ̀ jù, wọ́n lè fẹ́ tẹ́tí sí wa nígbà míì. Ó dájú pé tá a bá ń fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a máa di “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” Jèhófà sì lè lò wá láti fa ẹnì kan wá sínú òtítọ́.​—1 Kọ́r. 3:6, 7, 9.

18. Àwọn ìbùkún wo la máa rí tá a bá ń gba tàwọn míì rò?

18 Ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa gba tàwọn míì rò nínú ìdílé, nínú ìjọ àti lóde ẹ̀rí. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú. Sáàmù 41:1, 2 sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀; ní ọjọ́ ìyọnu àjálù, Jèhófà yóò pèsè àsálà fún un . . . A óò máa pè é ní aláyọ̀ ní ilẹ̀ ayé.”