Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 36

Ṣé O Múra Tán Láti Di Apẹja Èèyàn?

Ṣé O Múra Tán Láti Di Apẹja Èèyàn?

“Má bẹ̀rù mọ́. Láti ìsinsìnyí lọ, wàá máa mú àwọn èèyàn láàyè.”​—LÚÙKÙ 5:10.

ORIN 73 Fún Wa Ní Ìgboyà

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ni Jésù ní káwọn apẹja mẹ́rin kan wá ṣe, kí ni wọ́n sì ṣe?

APẸJA ni Pétérù, Áńdérù, Jémíìsì àti Jòhánù. Ẹ wo bó ṣe máa yà wọ́n lẹ́nu tó nígbà tí Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ máa tẹ̀ lé mi, màá sì sọ yín di apẹja èèyàn.” * Kí làwọn ọkùnrin náà wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n pa àwọ̀n wọn tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.” (Mát. 4:​18-22) Ìpinnu tí wọ́n ṣe yẹn ló yí ìgbésí ayé wọn pa dà pátápátá. Dípò kí wọ́n máa pa ẹja, ṣe ni wọ́n ń “mú àwọn èèyàn láàyè.” (Lúùkù 5:10) Ohun kan náà ni Jésù ń ṣe lónìí, ó ń pe gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ pé káwọn náà wá di apẹja èèyàn. (Mát. 28:​19, 20) Ṣéwọ náà ti gbà láti di apẹja èèyàn?

2. Kí nìdí tó fi yẹ kó o tẹ̀ síwájú láti di akéde Ìjọba Ọlọ́run, kí ló sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?

2 Ó ṣeé ṣe kó o ti tẹ̀ síwájú gan-an nínú ẹ̀kọ́ rẹ, ohun tó wá kù báyìí ni pé kó o di akéde Ìjọba Ọlọ́run. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò tíì ṣe tán láti di akéde, ó lè jẹ́ ohun tó fà á ni pé o ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìpinnu náà ti ṣe pàtàkì tó. Torí náà, má rẹ̀wẹ̀sì. Lóòótọ́ Bíbélì sọ pé Pétérù àtàwọn yòókù fi àwọ̀n wọn sílẹ̀ “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.” Àmọ́ Pétérù àti Áńdérù àbúrò rẹ̀ kò ṣèpinnu yẹn láìronú jinlẹ̀. Oṣù mẹ́fà ṣáájú ìgbà yẹn ni wọ́n ti mọ Jésù tí wọ́n sì gbà pé òun ni Mèsáyà. (Jòh. 1:​35-42) Bíi tiwọn, ìwọ náà ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Jésù, ó sì wù ẹ́ pé kó o tẹ̀ síwájú. Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o ronú dáadáa kó o tó di akéde Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ kí ló mú kí Pétérù, Áńdérù àtàwọn míì ṣèpinnu tó tọ́?

3. Àwọn ànímọ́ wo lá jẹ́ kó wù ẹ́ láti di akéde Ìjọba Ọlọ́run?

3 Àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù nífẹ̀ẹ́ ẹja pípa, wọ́n mọṣẹ́ náà dunjú, wọ́n nígboyà, wọ́n sì ní ìkóra-ẹni-níjàánu. Kò sí àní-àní pé àwọn ànímọ́ yìí náà ló jẹ́ kí wọ́n mọ béèyàn ṣe ń sọni dọmọ ẹ̀yìn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí ìwọ náà ṣe lè ní àwọn ànímọ́ yìí kó o sì di akéde Ìjọba Ọlọ́run tó já fáfá.

JẸ́ KÓ TÚBỌ̀ MÁA WÙ Ẹ́ LÁTI WÀÁSÙ

Pétérù àtàwọn yòókù di apẹja èèyàn. Bíi tiwọn, àwa náà ń bá iṣẹ́ pàtàkì náà lọ lónìí (Wo ìpínrọ̀ 4-5)

4. Kí nìdí tí Pétérù fi ń pẹja?

4 Iṣẹ́ ẹja pípa ni Pétérù ń ṣe kó lè bójú tó ìdílé rẹ̀, àmọ́ kì í ṣe torí ẹ̀ nìkan ló ṣe ń pẹja. Ó jọ pé Pétérù nífẹ̀ẹ́ ẹja pípa. (Jòh. 21:​3, 9-15) Nígbà tó yá, ó kọ́ bí wọ́n ṣe ń sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn, ó sì nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ náà. Jèhófà ràn án lọ́wọ́ débi pé ó já fáfá gan-an nínú iṣẹ́ náà.​—Ìṣe 2:​14, 41.

5. Bó ṣe wà nínú Lúùkù 5:​8-11, kí nìdí tí Pétérù fi ń bẹ̀rù, kí ló sì máa jẹ́ káwa náà borí ìbẹ̀rù?

5 Ìdí pàtàkì tá a fi ń wàásù ni pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó máa yá wa lára láti sọ̀rọ̀ ẹ̀ fáwọn míì bí a tiẹ̀ ń ronú pé a ò kúnjú ìwọ̀n láti wàásù. Nígbà tí Jésù pe Pétérù pé kó wá di apẹja èèyàn, ó sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù mọ́.” (Ka Lúùkù 5:​8-11.) Kì í ṣe ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tóun bá dọmọ ẹ̀yìn ló ń ba Pétérù lẹ́rù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó bà á lẹ́rù ni bí Jésù ṣe mú kí wọ́n pa ẹja rẹpẹtẹ lọ́nà ìyanu, ìyẹn sì mú kó ronú pé òun ò yẹ lẹ́ni tó ń bá Jésù ṣiṣẹ́. Lọ́wọ́ kejì, ẹ̀rù lè máa bà ẹ́ torí àwọn nǹkan tó o gbọ́dọ̀ ṣe tó o bá ti dọmọ ẹ̀yìn Jésù. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣe ohun táá mú kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Jésù àtàwọn èèyàn, ìyẹn á sì mú kó túbọ̀ yá ẹ lára láti di akéde Ìjọba Ọlọ́run.​—Mát. 22:​37, 39; Jòh. 14:15.

6. Kí nìdí míì tá a fi ń wàásù?

6 Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìdí míì tá a fi ń wàásù. Àkọ́kọ́, a fẹ́ ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé: “Ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:​19, 20) Ìkejì, à ń wàásù torí pé àwọn èèyàn dà bí àgùntàn “tí a bó láwọ, tí a sì fọ́n ká,” torí náà wọ́n nílò ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lójú méjèèjì. (Mát. 9:36) Bákan náà, Jèhófà fẹ́ kí onírúurú èèyàn ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́ kí wọ́n sì rí ìgbàlà.​—1 Tím. 2:4.

7. Kí ni Róòmù 10:​13-15 sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì?

7 Tá a bá ń ronú nípa àǹfààní táwọn èèyàn máa rí nínú iṣẹ́ ìwàásù wa, á yá wa lára láti máa wàásù. Iṣẹ́ wa yàtọ̀ sí tàwọn apẹja láwọn ọ̀nà kan torí pé ṣe làwọn apẹja máa ń jẹ ẹja tí wọ́n pa tàbí kí wọ́n tà á. Àmọ́, ńṣe làwa máa ń gba àwọn tá à ń wàásù fún là.​—Ka Róòmù 10:​13-15; 1 Tím. 4:16.

TÚBỌ̀ MỌ BÉÈYÀN ṢE Ń WÀÁSÙ

8-9. Kí ni apẹja kan gbọ́dọ̀ mọ̀, kí sì nìdí?

8 Nígbà ayé Jésù, àwọn apẹja máa ń mọ irú ẹja tí wọ́n lè pa. (Léf. 11:​9-12) Wọ́n tún gbọ́dọ̀ mọ ibi tí wọ́n ti lè rẹ́ja pa. Àwọn ẹja sábà máa ń wà níbi tí omi ti bá wọn lára mu tí oúnjẹ sì ti pọ̀. Ṣé àsìkò tó bá ti wu apẹja kan ló lè lọ pẹja? Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí arákùnrin kan tó ń gbé ní ọ̀kan lára àwọn erékùṣù Pàsífíìkì sọ nígbà tó pe míṣọ́nnárì kan pé káwọn jọ lọ pẹja. Míṣọ́nnárì náà sọ pé, “Màá wá bá ẹ láago mẹ́sàn-án àárọ̀ ọ̀la.” Arákùnrin náà dá a lóhùn pé, “Kò yé ẹ, kì í ṣe ìgbà tó bá wù wá la lè lọ pẹja, àsìkò tá a máa rẹ́ja pa la gbọ́dọ̀ lọ.”

9 Lọ́nà kan náà, àwọn apẹja èèyàn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa ń lọ síbi tí wọ́n á ti rí àwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń lọ lásìkò tí wọ́n á rí wọn bá sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù wàásù ní tẹ́ńpìlì, nínú sínágọ́gù, láti ilé dé ilé àti láwọn ọjà. (Ìṣe 5:42; 17:17; 18:4) Àwa náà gbọ́dọ̀ mọ bí nǹkan ṣe rí fáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Ó yẹ ká ṣe tán láti lọ wàásù níbi tá a ti lè rí àwọn èèyàn, ká sì mọ ìgbà tá a lè rí wọn bá sọ̀rọ̀.​—1 Kọ́r. 9:​19-23.

ÀWỌN APẸJA TÓ MỌṢẸ́ WỌN NÍṢẸ́ . . . 1. máa ń lọ síbi tí wọ́n ti lè rẹ́ja pa àti lásìkò tí wọ́n lè rí i pa (Wo ìpínrọ̀ 8-9)

10. Àwọn nǹkan wo ni ètò Jèhófà ti fún wa pé ká máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

10 Ó ṣe pàtàkì pé kí apẹja kan ní irinṣẹ́ kó sì mọ̀ ọ́n lò. Àwa náà gbọ́dọ̀ ní irinṣẹ́ tá a máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Yàtọ̀ síyẹn, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn irinṣẹ́ náà lò dáadáa. Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni tó ṣe kedere nípa bí wọ́n ṣe lè sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. Ó sọ ohun tó yẹ kí wọ́n mú dání, ibi tí wọ́n ti máa wàásù àtohun tí wọ́n máa bá àwọn èèyàn sọ. (Mát. 10:​5-7; Lúùkù 10:​1-11) Lónìí, ètò Jèhófà ti pèsè Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ níbi tá a ti lè rí àwọn nǹkan tá a nílò láti ṣe iṣẹ́ náà yanjú. * Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ń kọ́ wa bá a ṣe lè lò wọ́n lọ́nà tó gbéṣẹ́. Bí wọ́n ṣe ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ yìí ń mú ká lè nígboyà ká sì túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.​—2 Tím. 2:15.

ÀWỌN APẸJA TÓ MỌṢẸ́ WỌN NÍṢẸ́ . . . 2. máa ń lo irinṣẹ́ tó yẹ (Wo ìpínrọ̀ 10)

NÍ ÌGBOYÀ

11. Kí nìdí tó fi yẹ káwa akéde Ìjọba Ọlọ́run nígboyà?

11 Ó ṣe pàtàkì káwọn apẹja nígboyà. Ìdí ni pé ojú ọjọ́ máa ń ṣàdédé yí pa dà lójú omi. Alẹ́ ni wọ́n sábà máa ń pẹja, ìjì sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í jà lójijì. Àwa akéde Ìjọba Ọlọ́run náà nílò ìgboyà. Ó ṣeé ṣe ká kojú ohun tó dà bí ìjì nígbà tá a di akéde, tá a sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé a ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́nà wo? Àwọn ìdílé wa lè ta kò wá, àwọn ọ̀rẹ́ wa lè fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn tá à ń wàásù fún sì lè má tẹ́tí sí wa. Àmọ́ kò yà wá lẹ́nu torí Jésù ti kìlọ̀ pé a máa bá àwọn alátakò pàdé.​—Mát. 10:16.

12. Kí ni Jóṣúà 1:​7-9 sọ pé ó máa jẹ́ ká nígboyà?

12 Kí ló máa jẹ́ kó o nígboyà? Àkọ́kọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jésù ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù yìí látọ̀run. (Jòh. 16:33; Ìfi. 14:​14-16) Láfikún síyẹn, jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tó o ní pé Jèhófà máa bójú tó ẹ túbọ̀ jinlẹ̀. (Mát. 6:​32-34) Bí ìgbàgbọ́ rẹ ṣe ń lágbára sí i, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa nígboyà. Ìgbàgbọ́ tó lágbára tí Pétérù àtàwọn yòókù ní ló mú kí wọ́n pa iṣẹ́ ẹja pípa tì, tí wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù. Lọ́nà kan náà, ìwọ náà fi hàn pé ìgbàgbọ́ tó lágbára lo ní nígbà tó o sọ fún tẹbí-tọ̀rẹ́ rẹ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́, o sì ti ń lọ sípàdé wọn. Kò sí àní-àní pé o ti ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà nígbèésí ayé ẹ kó o lè máa fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò. Ohun tó o ṣe yìí fi hàn pé o nígbàgbọ́ àti ìgboyà. Bó o ṣe túbọ̀ ń nígboyà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé “Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí o bá lọ.”​—Ka Jóṣúà 1:​7-9.

ÀWỌN APẸJA TÓ MỌṢẸ́ WỌN NÍṢẸ́ . . . 3. máa ń lo ìgboyà, wọ́n sì máa ń fara da ojú ọjọ́ tí kò bára dé (Wo ìpínrọ̀ 11-12)

13. Tó o bá ń ṣàṣàrò tó o sì ń gbàdúrà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó o nígboyà?

13 Kí lohun míì tó máa jẹ́ kó o nígboyà? Gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kó o nígboyà. (Ìṣe 4:​29, 31) Jèhófà máa dáhùn àdúrà rẹ, kò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀. Ìgbà gbogbo lá máa tì ẹ́ lẹ́yìn. O tún lè ṣàṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ là láyé àtijọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ronú nípa bó ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí àwọn ìṣòro, tó sì fún ẹ lókun láti ṣe àwọn ìyípadà nígbèésí ayé ẹ. Ó dájú pé Ẹni tó mú káwọn èèyàn rẹ̀ la Òkun Pupa já máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. (Ẹ́kís. 14:13) Torí náà, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Jèhófà wà lẹ́yìn mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?”​—Sm. 118:6.

14. Kí lo rí kọ́ látinú ìrírí Arábìnrin Masae àti Tomoyo?

14 Nǹkan míì táá jẹ́ kó o nígboyà ni pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn tó jẹ́ onítìjú lọ́wọ́ tí wọ́n fi di onígboyà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Masae. Ojú máa ń tì í, ó sì gbà pé òun ò ní lè wàásù láéláé. Lójú ẹ̀, ṣe ni iṣẹ́ ìwàásù dà bí òkè ìṣòro tí kò lè borí. Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ kó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn. Ó ronú nípa bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó, ó sì bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó máa wu òun láti wàásù. Jèhófà sọ òkè ìṣòro ẹ̀ di pẹ̀tẹ́lẹ̀ torí ó borí ìtìjú, ó sì gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Jèhófà ò yí pa dà, ó ṣì ń ran àwọn akéde tuntun lọ́wọ́ káwọn náà lè “jẹ́ onígboyà.” Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Tomoyo. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé, ẹni àkọ́kọ́ tó wàásù fún jágbe mọ́ ọn pé: “Mi ò fẹ́ rí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan nílé mi!” ó sì pa ìlẹ̀kùn dé gbàgà. Tomoyo wá sọ fún ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pé: “Ṣó o gbọ́ nǹkan tó sọ? Mi ò tíì sọ nǹkan kan tó ti mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Ìyẹn mà múnú mi dùn o!” Ní báyìí, Tomoyo ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

NÍ ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU

15. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn kó ara ẹ̀ níjàánu, kí sì nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa kó ara wa níjàánu?

15 Àwọn apẹja tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ máa ń kó ara wọn níjàánu. Tẹ́nì kan bá ń kó ara ẹ̀ níjàánu, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún “máa ń sapá lójú méjèèjì láti ṣe ohun tó mọ̀ pé ó yẹ kóun ṣe.” Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ẹja pípa máa ń rí i pé àwọn tètè jí, àwọn wà nídìí iṣẹ́ náà títí tó fi parí, àwọn sì fara dà á bí ojú ọjọ́ ò tiẹ̀ dáa. Àwa náà gbọ́dọ̀ máa kó ara wa níjàánu tá a bá máa fara dà á ká sì ṣiṣẹ́ ìwàásù náà parí.​—Mát. 10:22.

16. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè ní ìkóra-ẹni-níjàánu?

16 Wọn kì í bí ìkóra-ẹni-níjàánu mọ́ni. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó bá rọ àwa èèyàn lọ́rùn la sábà máa ń ṣe. Torí náà, ó gba ìsapá gan-an kéèyàn tó lè kó ara ẹ̀ níjàánu, kó sì ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, a nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà ká lè ṣe ohun tó ṣòro fún wa láti ṣe. Jèhófà sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.​—Gál. 5:​22, 23.

17. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 9:​25-27 pé òun ṣe kóun lè kó ara òun níjàánu?

17 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń kó ara ẹ̀ níjàánu gan-an. Kódà, ó sọ pé òun máa “ń lu ara [òun] kíkankíkan” kóun bàa lè ṣe ohun tó tọ́. (Ka 1 Kọ́ríńtì 9:​25-27.) Ó gba àwọn míì níyànjú pé kí wọ́n máa kó ara wọn níjàánu kí wọ́n sì máa ṣe ohun gbogbo “lọ́nà tó bójú mu àti létòlétò.” (1 Kọ́r. 14:40) Ó gba ìsapá àti ìkóra-ẹni-níjàánu ká tó lè máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó ká sì máa wàásù déédéé.​—Ìṣe 2:46.

MÁ FI FALẸ̀

18. Kí ló máa jẹ́ kí Jèhófà gbà pé a ṣàṣeyọrí?

18 Iye ẹja tí apẹja kan bá pa ló fi máa ń díwọ̀n bóun ṣe ṣàṣeyọrí tó. Lọ́wọ́ kejì, kì í ṣe iye àwọn tá a ràn lọ́wọ́ láti wá sínú ètò Jèhófà ló ń fi hàn pé a ṣàṣeyọrí. (Lúùkù 8:​11-15) Tá a bá ń wàásù, tá a sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láìjẹ́ kó sú wa, Jèhófà máa gbà pé a ṣàṣeyọrí. Kí nìdí? Ìdí ni pé à ń ṣègbọràn sí òun àti Jésù ọmọ rẹ̀.​—Máàkù 13:10; Ìṣe 5:​28, 29.

19-20. Kí nìdí pàtàkì tó fi yẹ ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù lásìkò tá a wà yìí?

19 Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ó láwọn oṣù kan pàtó tí wọ́n máa ń fàyè gba àwọn èèyàn láti pẹja. Nírú àwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn apẹja máa ń tẹra mọ́ṣẹ́ gan-an táwọn oṣù yẹn bá ti fẹ́ parí. Apẹja èèyàn làwa náà, ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa torí pé òpin ti sún mọ́lé ju ti ìgbàkígbà rí lọ! Àkókò tá a ní láti wàásù ká sì gba àwọn èèyàn là ti dín kù gan-an. Torí náà, má fi iṣẹ́ ìwàásù falẹ̀ rárá, má sì ronú pé ó dìgbà tí nǹkan bá rọrùn fún ẹ kó o tó lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà.​—Oníw. 11:4.

20 Ní báyìí, ṣe ohun táá jẹ́ kó túbọ̀ máa wù ẹ́ láti wàásù, túbọ̀ máa fi kún ìmọ̀ tó o ní, ṣe ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ nígboyà, kó o sì máa kó ara ẹ níjàánu. Dara pọ̀ mọ́ àwọn apẹja èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ tí wọ́n ń wàásù kárí ayé. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí ìdùnnú Jèhófà. (Neh. 8:10) Paríparí ẹ̀, pinnu pé wàá máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù títí dìgbà tí Jèhófà bá sọ pé ó tó. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò nǹkan mẹ́ta táá jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé àá máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó.

ORIN 66 Ẹ Kéde Ìhìn Rere Náà

^ ìpínrọ̀ 5 Jésù pe àwọn apẹja tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ tí wọ́n sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ pé kí wọ́n wá di ọmọ ẹ̀yìn òun. Àwọn tó nírú ànímọ́ yìí ni Jésù ṣì ń pè lónìí pé kí wọ́n wá di apẹja èèyàn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń lọ́ra láti di akéde Ìjọba Ọlọ́run lè ṣe.

^ ìpínrọ̀ 1 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Gbogbo àwọn tó ń wàásù ìhìn rere tí wọ́n sì ń sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn Kristi ni Bíbélì pè ní “apẹja èèyàn.”

^ ìpínrọ̀ 10 Wo àpilẹ̀kọ náà “Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni” nínú Ilé Ìṣọ́ October 2018, ojú ìwé 11-16.