Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 38

Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n ní Àkókò Àlàáfíà

Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n ní Àkókò Àlàáfíà

“Kò sí ìyọlẹ́nu ní ilẹ̀ náà, wọn kò sì bá a jagun ní àwọn ọdún yẹn, torí Jèhófà fún un ní ìsinmi.”​—2 KÍRÓ. 14:6.

ORIN 60 Wọ́n Máa Rí Ìyè Tí Wọ́n Bá Gbọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Ìgbà wo ló máa ń ṣòro láti sin Jèhófà?

ÌGBÀ wo lo rò pé ó máa ń ṣòro jù láti sin Jèhófà, ṣé ìgbà tí nǹkan bá nira ni àbí ìgbà tí kò sí wàhálà? Ó máa ń yá wa lára láti gbára lé Jèhófà tá a bá níṣòro. Àmọ́ kí la máa ń ṣe tí nǹkan bá ń lọ dáadáa fún wa? Ṣé ìjọsìn Jèhófà ló máa ń gbawájú láyé wa ni àbí a máa ń jẹ́ káwọn nǹkan míì gbà wá lọ́kàn? Jèhófà kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí nǹkan míì gbà wọ́n lọ́kàn dípò ìjọsìn òun.​—Diu. 6:​10-12.

Ọba Ásà pa gbogbo ìsìn èké run (Wo ìpínrọ̀ 2) *

2. Kí ni Ọba Ásà ṣe tá a lè fara wé?

2 Àpẹẹrẹ àtàtà ni Ọba Ásà tó bá di pé kéèyàn gbára lé Jèhófà pátápátá. Kì í ṣe ìgbà tí nǹkan nira fún un nìkan ló fi gbogbo ọkàn ẹ̀ sin Jèhófà, ó tún ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí àlàáfíà wà. Bíbélì ròyìn pé àtikékeré ni “Ásà [ti ń] fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà.” (1 Ọba 15:14) Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Ásà gbà fi hàn pé gbogbo ọkàn lòun fi ń jọ́sìn Jèhófà ni pé ó pa gbogbo ìjọsìn èké run nílẹ̀ Júdà. Bíbélì sọ pé: “Ó mú àwọn pẹpẹ àjèjì àti àwọn ibi gíga kúrò, ó fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà sí wẹ́wẹ́, ó sì gé àwọn òpó òrìṣà lulẹ̀.” (2 Kíró. 14:​3, 5) Kódà, ó tún yọ Máákà ìyá rẹ̀ àgbà kúrò ní ipò ìyá ọba. Kí nìdí? Torí pé ìyá náà ń bọ̀rìṣà, ó sì tún ń mú káwọn míì máa ṣe bẹ́ẹ̀.​—1 Ọba 15:​11-13.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Kì í ṣe pé Ásà pa ìsìn èké run nìkan, ó tún mú káwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà pa dà máa jọ́sìn Jèhófà bí Jèhófà ṣe fẹ́. Torí náà, Jèhófà bù kún Ásà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì mú kí àlàáfíà jọba nílẹ̀ náà. * Kódà, fún odindi ọdún mẹ́wàá àkọ́kọ́ tí Ásà fi ṣàkóso, “kò sí ìyọlẹ́nu ní ilẹ̀ náà.” (2 Kíró. 14:​1, 4, 6) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Ásà ṣe fọgbọ́n lo àkókò àlàáfíà yẹn. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò bí àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe fọgbọ́n lo àkókò àlàáfíà táwọn náà ní bíi ti Ásà. Níkẹyìn, a máa dáhùn ìbéèrè yìí: Tó o bá ń jọ́sìn Jèhófà láìsí ìdíwọ́ lórílẹ̀-èdè tó ò ń gbé, báwo lo ṣe lè fọgbọ́n lo àkókò àlàáfíà tẹ́ ẹ ní báyìí?

OHUN TÍ ÁSÀ ṢE LÁKÒÓKÒ ÀLÀÁFÍÀ

4. Kí ni 2 Kíróníkà 14:​2, 6, 7 sọ pé Ásà ṣe lákòókò tí àlàáfíà wà?

4 Ka 2 Kíróníkà 14:​2, 6, 7Ásà sọ fáwọn èèyàn náà pé Jèhófà ti fún wọn “ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó yí [wọn] ká.” Ásà ò ronú pé káwọn máa gbádùn ara wọn lásìkò tí àlàáfíà wà yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ìlú tó wà nílẹ̀ Júdà, àwọn ògiri tó yí wọn ká, àwọn ilé gogoro àtàwọn ẹnubodè. Ó sọ fáwọn èèyàn náà pé: “Ilẹ̀ náà ṣì wà ní ìkáwọ́ wa.” Kí ni Ásà ní lọ́kàn? Ohun tó ní lọ́kàn ni pé àwọn èèyàn lè lọ síbi tó wù wọ́n nílẹ̀ tí Jèhófà fún wọn, wọ́n sì lè ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà láìsí pé àwọn ọ̀tá ń yọ wọ́n lẹ́nu. Ó rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n lo àkókò tí àlàáfíà wà yẹn láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́.

5. Kí nìdí tí Ásà fi kó àwọn ọmọ ogun jọ?

5 Ásà tún lo àkókò àlàáfíà yẹn láti fi kó àwọn ọmọ ogun jọ. (2 Kíró. 14:8) Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọba Ásà mọ̀ pé ojúṣe òun ni láti múra àwọn èèyàn náà sílẹ̀ torí ìṣòro tó lè wáyé lọ́jọ́ iwájú. Ó mọ̀ pé àkókò àlàáfíà yẹn kò ní wà títí láé, bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn.

OHUN TÁWỌN KRISTẸNI ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KÌÍNÍ ṢE LÁKÒÓKÒ ÀLÀÁFÍÀ

6. Kí làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe lákòókò àlàáfíà?

6 Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, síbẹ̀ àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n wà ní àlàáfíà. Kí ni wọ́n ṣe lásìkò àlàáfíà náà? Gbogbo àwọn Kristẹni yẹn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń fìtara wàásù láìjẹ́ kó sú wọn. Ìwé Ìṣe sọ pé wọ́n “ń rìn nínú ìbẹ̀rù Jèhófà.” Wọ́n ń wàásù ìhìn rere náà, ìyẹn sì mú kí wọ́n máa “gbèrú sí i.” Kò sí àní-àní pé Jèhófà bù kún àwọn èèyàn náà torí ìtara tí wọ́n fi wàásù lásìkò tí àlàáfíà wà yẹn.​—Ìṣe 9:​26-31.

7-8. Kí ni Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì ṣe nígbà tí àǹfààní yọ fún wọn láti wàásù? Ṣàlàyé.

7 Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lo gbogbo àǹfààní tó yọ láti wàásù ìhìn rere. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti wàásù ní Éfésù, ó wàásù fáwọn èèyàn ìlú náà, ó sì sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.​—1 Kọ́r. 16:​8, 9.

8 Àǹfààní míì tún yọ fún Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni yòókù láti wàásù lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ olùdarí yanjú ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni. (Ìṣe 15:​23-29) Lẹ́yìn táwọn ìjọ gbọ́ ìpinnu tí ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn túbọ̀ tẹra mọ́ wíwàásù “ìhìn rere ọ̀rọ̀ Jèhófà.” (Ìṣe 15:​30-35) Kí nìyẹn wá yọrí sí? Bíbélì sọ pé “àwọn ìjọ túbọ̀ ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́.”​—Ìṣe 16:​4, 5.

BÁ A ṢE Ń LO ÀKÓKÒ ÀLÀÁFÍÀ TÁ A NÍ LÓNÌÍ

9. Àǹfààní wo lọ̀pọ̀ wa ní lónìí, ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?

9 Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè la ti ń wàásù láìsí ìdíwọ́ lónìí. Ṣé bó ṣe rí lórílẹ̀-èdè tó ò ń gbé nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó o bi ara ẹ pé: ‘Báwo ni mo ṣe ń lo àsìkò tí àlàáfíà wà yìí?’ Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí onírúurú nǹkan ń ṣẹlẹ̀ yìí, àwa èèyàn Jèhófà ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni ju ti ìgbàkigbà rí lọ nínú ìtàn. (Máàkù 13:10) Ọ̀pọ̀ nǹkan la sì lè ṣe nínú iṣẹ́ náà.

Ọ̀pọ̀ ìbùkún làwọn tó lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì tàbí tí wọ́n ń wàásù lédè míì ń gbádùn (Wo ìpínrọ̀ 10-12) *

10. Kí ni 2 Tímótì 4:2 gbà wá níyànjú pé ká ṣe?

10 Báwo lo ṣe lè fọgbọ́n lo àkókò tí àlàáfíà wà yìí? (Ka 2 Tímótì 4:2.) O ò ṣe wò ó bóyá ìwọ tàbí ẹnì kan nínú ìdílé yín lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, bóyá kẹ́ ẹ tiẹ̀ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà? Kì í ṣe àsìkò yìí ló yẹ ká máa kó nǹkan tara jọ, ó ṣe tán àwọn nǹkan yẹn ò ní bá wa la ìpọ́njú ńlá já.​—Òwe 11:4; Mát. 6:​31-33; 1 Jòh. 2:​15-17.

11. Kí làwọn kan ti ṣe kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

11 Ọ̀pọ̀ lára wa ló ti kọ́ èdè tuntun kí wọ́n lè túbọ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Kó lè rọrùn fún wọn láti wàásù fún àwọn tó ń sọ onírúurú èdè, ètò Jèhófà ti ṣe àwọn ìtẹ̀jáde láwọn èdè tó pọ̀ sí i. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2010, ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) èdè la tú àwọn ìtẹ̀jáde wa sí. Àmọ́ ní báyìí, ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) èdè!

12. Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn èèyàn tí wọ́n bá gbọ́ ìhìn rere ní èdè wọn? Sọ àpẹẹrẹ kan.

12 Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn èèyàn tí wọ́n bá gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní èdè wọn? Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe rí lára arábìnrin kan nígbà tó lọ sí àpéjọ agbègbè kan ní Memphis, Tennessee, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Èdè Kinyarwanda tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n fi ṣe àpéjọ náà, ìyẹn èdè tí wọ́n máa ń sọ lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà, Kóńgò (Kinshasa) àti Uganda. Lẹ́yìn àpéjọ náà, ó sọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí mo máa lóye ohun tí wọ́n sọ dáadáa nípàdé látìbẹ̀rẹ̀ dópin láti odindi ọdún mẹ́tàdínlógún (17) tí mo ti kó wá sórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.” Kò sí àní-àní pé àwọn ọ̀rọ̀ tí arábìnrin yìí gbọ́ lédè rẹ̀ ní àpéjọ yẹn wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Tó bá ṣeé ṣe fún ẹ, ṣé o lè kọ́ èdè míì tí wọ́n ń sọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín? Ṣé àwọn kan wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín tó jẹ́ pé èdè míì ní wọ́n lóye jù, ṣé o lè tìtorí wọn kọ́ èdè náà? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

13. Kí làwọn ará wa ní Rọ́ṣíà ṣe lásìkò tí wọ́n lómìnira láti wàásù?

13 Kì í ṣe gbogbo àwọn ará wa ló ní òmìnira láti wàásù. Nígbà míì, ìjọba máa ń ṣòfin tó ń mú kó ṣòro fáwọn ará wa láti wàásù. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n fi ṣenúnibíni sí wọn, ìjọba mú ìfòfindè tí wọ́n fi de iṣẹ́ wa kúrò ní March 1991. Nígbà yẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún (16,000) akéde ló wà lórílẹ̀-èdè náà. Àmọ́ ogún ọdún lẹ́yìn náà, àwọn akéde tó wà níbẹ̀ ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́jọ (160,000)! Ó ṣe kedere pé àwọn ará wa fi ọgbọ́n lo àkókò tí wọ́n ní láti wàásù láìsí ìdíwọ́. Nígbà tó yá, nǹkan tún yí pa dà. Síbẹ̀, wọn ò jẹ́ kí inúnibíni àti ìfòfinde ìjọba mú kí wọ́n ṣíwọ́ àtimáa fìtara jọ́sìn Jèhófà. Wọ́n ń lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n ní láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.

ÀKÓKÒ ÀLÀÁFÍÀ YÌÍ MÁA DÓPIN

Lẹ́yìn tí Ọba Ásà gbàdúrà sí Jèhófà taratara, Jèhófà jẹ́ kí Júdà ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn (Wo ìpínrọ̀ 14-15)

14-15. Báwo ni Jèhófà ṣe fi agbára rẹ̀ han Ásà?

14 Nígbà tó yá, àlàáfíà tó wà nígbà ìṣàkóso Ásà dópin. Ìdí ni pé àwọn ọmọ ogun alágbára tó tó mílíọ̀nù kan ṣígun wá láti ilẹ̀ Etiópíà. Ó sì dá Síírà ọ̀gágun wọn lójú pé òun máa fi Júdà ṣèfà jẹ. Àmọ́ Jèhófà ni Ásà gbẹ́kẹ̀ lé, kì í ṣe àwọn ọmọ ogun tó ní. Ásà bẹ Jèhófà pé: “Ràn wá lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé, a wá ní orúkọ rẹ láti dojú kọ ọ̀pọ̀ èèyàn yìí.”​—2 Kíró. 14:11.

15 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun Etiópíà fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì àwọn ọmọ ogun Júdà, Ásà gbà pé Jèhófà lágbára láti ran àwọn lọ́wọ́, ó sì máa gba àwọn èèyàn rẹ̀ là. Jèhófà kò sì já a kulẹ̀ torí pé Jèhófà àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ fọ́ àwọn èèyàn náà sí wẹ́wẹ́.​—2 Kíró. 14:​8-13.

16. Báwo la ṣe mọ̀ pé àkókò àlàáfíà yìí máa dópin?

16 Lóòótọ́ a ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, àmọ́ ó dá wa lójú pé àsìkò àlàáfíà táwa èèyàn Jèhófà ní báyìí máa tó dópin. Kódà Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ‘gbogbo orílẹ̀-èdè máa kórìíra’ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. (Mát. 24:9) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tím. 3:12) Sátánì “ń bínú gidigidi,” torí náà ṣe là ń tan ara wa jẹ tá a bá ń ronú pé kò ní fìkanra mọ́ wa.​—Ìfi. 12:12.

17. Àwọn nǹkan wo ló ṣeé ṣe kó dán ìgbàgbọ́ wa wò?

17 Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, gbogbo wa pátá la máa kojú àdánwò. Bíbélì sọ pé “ìpọ́njú ńlá máa wà nígbà náà, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di báyìí.” (Mát. 24:21) Tó bá dìgbà yẹn, àwọn mọ̀lẹ́bí wa lè ṣenúnibíni sí wa, ìjọba sì lè fòfin de iṣẹ́ wa. (Mát. 10:​35, 36) Bíi ti Ásà, ṣé a máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ kó sì dáàbò bò wá?

18. Kí ni Hébérù 10:​38, 39 sọ pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí àlàáfíà bá dópin?

18 Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń múra wa sílẹ̀ de ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀. Ó ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa fún wa ní “oúnjẹ [tẹ̀mí] ní àkókò tó yẹ” ká lè máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó láìka àdánwò tó lè dé bá wa sí. (Mát. 24:45) Àmọ́ o, ká tó lè nígbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú Jèhófà, a gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa.​—Ka Hébérù 10:​38, 39.

19-20. Tá a bá fi ohun tó wà nínú 1 Kíróníkà 28:9 sọ́kàn, àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa, kí sì nìdí?

19 Bíi ti Ọba Ásà, àwa náà gbọ́dọ̀ “wá Jèhófà.” (2 Kíró. 14:4; 15:​1, 2) Ìgbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tá a sì ṣèrìbọmi la bẹ̀rẹ̀ sí í wá Jèhófà. Àtìgbà yẹn la ti ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà lè lágbára sí i. Àmọ́ ká lè mọ bí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé mo máa ń lọ sípàdé déédéé?’ Láwọn ìpàdé wa, a máa ń rí okun gbà ká lè máa sin Jèhófà nìṣó, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin sì máa ń gbé wa ró. (Mát. 11:28) A tún lè bi ara wa pé, ‘Ṣé mo máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé?’ Tó o bá ń gbé pẹ̀lú ìdílé rẹ, ṣé ẹ máa ń ṣe ìjọsìn ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? Tó bá sì jẹ́ pé ṣe lò ń dágbé, ṣé o máa ń ṣètò àkókò láti fi kẹ́kọ̀ọ́ bíi pé o wà pẹ̀lú ìdílé rẹ? Bákan náà, ṣé o máa ń wàásù déédéé tó o sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́?

20 Kí nìdí tó fi yẹ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí? Bíbélì sọ pé Jèhófà ń kíyè sí ohun tó wà lọ́kàn wa àtohun tá à ń rò, ó sì yẹ káwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka 1 Kíróníkà 28:9.) Tá a bá rí i pé ó yẹ ká ṣe àwọn àyípadà kan nínú ohun tá à ń lé, ohun tá à ń rò àtàwọn nǹkan tá à ń ṣe, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣàtúnṣe. Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká múra sílẹ̀ de àwọn àdánwò tá a máa tó kojú. Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí yín lọ́wọ́ láti fọgbọ́n lo àkókò àlàáfíà tá a wà báyìí!

ORIN 62 Orin Tuntun

^ ìpínrọ̀ 5 Ṣé ẹ̀ ń jọ́sìn Jèhófà láìsí ìdíwọ́ lórílẹ̀-èdè tó ò ń gbé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe ń lo àkókò àlàáfíà tẹ́ ẹ ní báyìí? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè fara wé Ọba Ásà ti ilẹ̀ Júdà àtàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n fi ọgbọ́n lo àkókò tí kò sí wàhálà láti jọ́sìn Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 3 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: “Àlàáfíà” kọjá pé kò sí ogun. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún àlàáfíà tún túmọ̀ sí kéèyàn ní ìlera tó dáa àti ààbò, kí ọkàn ẹ̀ sì balẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 57 ÀWÒRÁN: Ọba Ásà yọ ìyá rẹ̀ àgbà kúrò nípò ìyá ọba torí pé ó mú káwọn èèyàn máa bọ̀rìṣà. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ṣègbọràn sí Ásà, wọ́n sì fọ́ gbogbo òrìṣà ilẹ̀ náà túútúú.

^ ìpínrọ̀ 59 ÀWÒRÁN: Tọkọtaya kan tó nítara jẹ́ kí nǹkan díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀.