Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 37

‘Má Ṣe Dẹwọ́’ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

‘Má Ṣe Dẹwọ́’ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

“Fún irúgbìn rẹ ní àárọ̀, má sì dẹwọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.”​—ONÍW. 11:6.

ORIN 68 Máa Fún Irúgbìn Ìjọba Náà

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Báwo lọ̀rọ̀ tó wà nínú Oníwàásù 11:6 ṣe kan iṣẹ́ ìwàásù?

LÁWỌN orílẹ̀-èdè kan, ó máa ń yá àwọn èèyàn lára láti gbọ́ ìhìn rere. Kódà, ṣe ló dà bíi pé ohun tí wọ́n nílò gan-an nìyẹn. Láwọn ilẹ̀ míì, àwọn èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì. Kí làwọn èèyàn máa ń ṣe lágbègbè yín? Yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé ká máa wàásù nìṣó títí iṣẹ́ náà máa fi parí.

2 Tó bá tó àsìkò lójú Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù náà máa parí, “òpin yóò [sì] dé.” (Mát. 24:​14, 36) Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, báwo la ṣe lè ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ Bíbélì tó ní ká ‘má ṣe dẹwọ́’? *​—Ka Oníwàásù 11:6.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a ti jíròrò nǹkan mẹ́rin tó yẹ ká ṣe ká lè di akéde tó já fáfá tàbí “apẹja èèyàn.” (Mát. 4:19) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun mẹ́ta tí gbogbo wa lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé àá máa wàásù nìṣó láìka ohun tá à ń kojú sí. Bákan náà, a máa rí ìdí tó fi yẹ ká (1) gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, (2) ká máa ṣe sùúrù, àti (3) ká nígbàgbọ́ tó lágbára.

GBÁJÚ MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù tí Jèhófà ní ká ṣe?

4 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn nǹkan táá máa ṣẹlẹ̀ táá jẹ́ ká mọ̀ pé a ti wà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn nǹkan yìí sì lè mú ká má pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìwàásù mọ́. Torí náà, ó kìlọ̀ fún wa pé ká “máa ṣọ́nà.” (Mát. 24:42) Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí jọ àwọn nǹkan tí kò jẹ́ káwọn èèyàn tẹ́tí sí Nóà nígbà tó ń kìlọ̀ fún wọn. (Mát. 24:​37-39; 2 Pét. 2:5) Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká gbájú mọ́ iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wa.

5. Kí ni Ìṣe 1:​6-8 sọ tó jẹ́ ká mọ ibi tí iṣẹ́ ìwàásù náà máa dé?

5 Ọwọ́ pàtàkì ló yẹ ká fi mú iṣẹ́ ìwàásù náà lónìí. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù náà máa gbòòrò gan-an, ọ̀pọ̀ ọdún la sì máa fi ṣe é lẹ́yìn tóun bá kú. (Jòh. 14:12) Àmọ́ lẹ́yìn tí Jésù kú, àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pa dà sídìí ẹja pípa. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó jẹ́ kí wọ́n rí ẹja pa lọ́nà ìyanu. Jésù wá fi àsìkò yẹn sọ fún wọn pé iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe pàtàkì ju iṣẹ́ èyíkéyìí míì lọ. (Jòh. 21:​15-17) Nígbà tó kù díẹ̀ kó gòkè lọ sọ́run, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù náà máa kọjá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, kódà á dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé. (Ka Ìṣe 1:​6-8.) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jésù fi ìran kan han àpọ́sítélì Jòhánù nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ “ní ọjọ́ Olúwa.” * Lára ohun tí Jòhánù rí ni áńgẹ́lì tó ń darí àwọn tó ń wàásù “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” fún “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn.” (Ìfi. 1:10; 14:6) Kò sí àní-àní pé Jèhófà fẹ́ ká ṣiṣẹ́ ìwàásù náà ní kíkún títí dìgbà tó fi máa parí.

6. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù?

6 Àá lè gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù tá a bá ń ronú nípa àwọn ohun tí Jèhófà ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí ló ń pèsè fún wa nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa, yálà èyí tí wọ́n tẹ̀ jáde tàbí èyí tó wà lórí ẹ̀rọ títí kan àwọn àtẹ́tísí, fídíò àti ètò Tẹlifíṣọ̀n JW. Ẹ tiẹ̀ wò ó ná: Lórí ìkànnì wa, a lè rí ìsọfúnni kà ní èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000)! (Mát. 24:​45-47) Yàtọ̀ síyẹn, àwa èèyàn Jèhófà tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ wà níṣọ̀kan kárí ayé nínú ayé tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ní ti ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀sìn àti ìṣòwò. Bí àpẹẹrẹ, ní Friday, April 19, 2019, gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé la jọ wo fídíò kan náà tó jíròrò ẹsẹ ojúmọ́ ti ọjọ́ yẹn. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, àwa tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mọ́kànlélógún (20,919,041) la pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi. Inú wa dùn pé àwọn nǹkan àgbàyanu yìí ṣojú wa, a sì ń kópa nínú wọn. Èyí wá mú ká túbọ̀ gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù náà.

Jésù ò jẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ láti wàásù ìhìn rere (Wo ìpínrọ̀ 7)

7. Báwo ni àpẹẹrẹ Jésù ṣe lè mú ká gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù?

7 Ohun míì tó máa jẹ́ ká gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ni pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Kò jẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ láti wàásù ìhìn rere. (Jòh. 18:37) Kò jẹ́ kí “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn” tí Sátánì fi hàn án wọ òun lójú. Bákan náà, kò gbà káwọn èèyàn fi òun jọba. (Mát. 4:​8, 9; Jòh. 6:15) Kò jẹ́ kí àwọn ohun ìní tara wọ òun lójú, kò sì jẹ́ kí àtakò dá ìwàásù ìhìn rere náà dúró. (Lúùkù 9:58; Jòh. 8:59) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni nímọ̀ràn pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù kó má ‘bàa rẹ̀ wá, ká má sì sọ̀rètí nù.’ Ìyẹn lá jẹ́ ká gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ta kò wá.​—Héb. 12:3.

MÁA MÚ SÙÚRÙ

8. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn máa ṣe sùúrù, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì nísinsìnyí?

8 Ẹni tó ní sùúrù máa ń fi pẹ̀lẹ́tù dúró de nǹkan, ó sì máa ń ní àmúmọ́ra títí dìgbà tí ipò nǹkan fi máa yí pa dà. A nílò sùúrù yálà à ń dúró kí ipò nǹkan yí pa dà ni o tàbí à ń retí pé kí ọwọ́ wa tẹ nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, ó wu wòlíì Hábákúkù gan-an pé kí ìwà burúkú tó gbilẹ̀ ní Júdà tètè dópin. (Háb. 1:2) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà retí pé kí Ìjọba Ọlọ́run “fara hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀” kó sì dá wọn nídè lọ́wọ́ àwọn ará Róòmù. (Lúùkù 19:11) Ó wu àwa náà pé kí Ìjọba Ọlọ́run tètè mú ìwà burúkú kúrò láyé, kó sì mú ayé tuntun òdodo wá. (2 Pét. 3:13) Àmọ́, a gbọ́dọ̀ mú sùúrù títí dìgbà tó bá tó àsìkò lójú Jèhófà. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò bí Jèhófà ṣe ń kọ́ wa láti máa mú sùúrù.

9. Sọ àpẹẹrẹ tó fi hàn pé Jèhófà ní sùúrù.

9 Jèhófà ló fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lélẹ̀ tó bá di pé ká ní sùúrù. Ó fún Nóà “oníwàásù òdodo” ní àkókò tó pọ̀ tó láti fi kan ọkọ̀ áàkì kó sì wàásù. (2 Pét. 2:5; 1 Pét. 3:20) Jèhófà fara balẹ̀ tẹ́tí sí Ábúráhámù nígbà tó ń béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ léraléra pé kí nìdí tó fi máa pa Sódómù àti Gòmórà run. (Jẹ́n. 18:​20-33) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ọdún ni Jèhófà fi mú sùúrù fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí wọ́n ya aláìgbọràn. (Neh. 9:​30, 31) Bákan náà, Jèhófà ń mú sùúrù lónìí kí gbogbo àwọn tó fẹ́ kó wá sọ́dọ̀ òun lè “ronú pìwà dà.” (2 Pét. 3:9; Jòh. 6:44; 1 Tím. 2:​3, 4) Àwọn àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwa náà máa mú sùúrù bá a ṣe ń wàásù tá a sì ń kọ́ni. Yàtọ̀ sí àpẹẹrẹ rẹ̀, Jèhófà kọ́ wa bá a ṣe lè máa ní sùúrù nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Bí àgbẹ̀ kan tó ń ṣiṣẹ́ kára ṣe máa ń mú sùúrù, àwa náà ń mú sùúrù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa (Wo ìpínrọ̀ 10-11)

10. Kí ni àpẹẹrẹ àgbẹ̀ tó wà nínú Jémíìsì 5:​7, 8 kọ́ wa?

10 Ka Jémíìsì 5:​7, 8A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun táwọn àgbẹ̀ máa ń ṣe. Lóòótọ́, àwọn irúgbìn kan tètè máa ń hù. Àmọ́ ó máa ń pẹ́ káwọn irúgbìn kan tó so èso, pàápàá àwọn igi eléso. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń tó oṣù mẹ́fà káwọn irúgbìn kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì tó so èso. Ẹ̀yìn òjò àkọ́rọ̀ ni àgbẹ̀ kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì máa ń gbin irúgbìn, ó sì máa ń kórè lẹ́yìn òjò àrọ̀kẹ́yìn. (Máàkù 4:28) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa mú sùúrù bíi ti àwọn àgbẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn.

11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa mú sùúrù tá a bá fẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù wa méso jáde?

11 Àwa èèyàn aláìpé máa ń fẹ́ kí iṣẹ́ wa tètè sèso. Síbẹ̀, tá a bá jẹ́ àgbẹ̀, tá a sì fẹ́ kí irúgbìn wa sèso, a gbọ́dọ̀ tulẹ̀, ká gbin irúgbìn, ká máa ro ó, ká sì máa bomi rin ín. Bí iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe rí náà nìyẹn. Ó máa ń gba àkókò ká tó lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ láti fa ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu kúrò lọ́kàn wọn, kí wọ́n sì máa fìfẹ́ hàn. Tá a bá ń mú sùúrù, a ò ní rẹ̀wẹ̀sì táwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ tẹ́tí sí wa. Kódà táwọn èèyàn bá tẹ́tí sí wa, a ṣì nílò sùúrù torí pé a ò lè fipá mú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa láti tẹ̀ síwájú. Ó ṣe tán, ìgbà kan wà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà ò tètè lóye ohun tó kọ́ wọn. (Jòh. 14:9) Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé tá a bá tiẹ̀ gbìn tá a sì bomi rin, Jèhófà nìkan ló lè mú kó dàgbà.​—1 Kọ́r. 3:6.

12. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń mú sùúrù tá a bá ń wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí?

12 Ó sábà máa ń ṣòro láti mú sùúrù tá a bá ń wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Àmọ́, ìlànà tó wà nínú Oníwàásù 3:​1, 7 lè ràn wá lọ́wọ́. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Ohun gbogbo ni àkókò wà fún. . . . Ìgbà dídákẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.” Láìsọ̀rọ̀, a lè jẹ́ kí ìwà wa wàásù fún wọn, síbẹ̀ ká wà lójúfò láti bá wọn sọ̀rọ̀ nígbà tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ. (1 Pét. 3:​1, 2) A gbọ́dọ̀ mú sùúrù fún gbogbo èèyàn títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wa tá a bá ń wàásù tá a sì ń kọ́ni.

13-14. Àpẹẹrẹ àwọn tó mú sùúrù wo la lè tẹ̀ lé?

13 A lè kọ́ bá a ṣe lè mú sùúrù látinú àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ kan nínú Bíbélì àti lóde òní. Bí àpẹẹrẹ, ó wu Hábákúkù gan-an pé kí ìwà burúkú tètè dópin, síbẹ̀ ó pinnu pé: “Ibi tí mo ti ń ṣe olùṣọ́ ni èmi yóò dúró sí.” (Háb. 2:1) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ pé òun máa “parí” iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun. Síbẹ̀, ó mú sùúrù bó ṣe ń “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.”​—Ìṣe 20:24.

14 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ tọkọtaya kan tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gílíádì. Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ lórílẹ̀-èdè tí wọ́n rán wọn lọ, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn ará níbẹ̀. Torí náà, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́wọ́ kejì, àwọn tí wọ́n jọ kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gílíádì máa ń fi àwọn ìrírí alárinrin tí wọ́n ní ránṣẹ́ sí wọn nípa bí wọ́n ṣe ń darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ tẹ́tí sí wọn, tọkọtaya náà ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ láìṣàárẹ̀. Lẹ́yìn odindi ọdún mẹ́jọ tí wọ́n fi wàásù ní ìpínlẹ̀ tí wọn ò ti tẹ́tí sí wọn, inú wọn dùn gan-an nígbà tí ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn ṣèrìbọmi. Kí la rí kọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ yìí? Àwọn olóòótọ́ yìí ò rẹ̀wẹ̀sì, wọn ò sì dẹwọ́. Èyí mú kí Jèhófà bù kún wọn torí sùúrù tí wọ́n ní. Torí náà, ẹ jẹ́ ká “máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tí ìgbàgbọ́ àti sùúrù mú kí wọ́n jogún àwọn ìlérí náà.”​—Héb. 6:​10-12.

NÍ ÌGBÀGBỌ́ TÓ LÁGBÁRA

15. Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe máa mú ká túbọ̀ pinnu pé àá máa wàásù nìṣó?

15 A gba ìhìn rere náà gbọ́, torí náà ó máa ń yá wa lára láti sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíì. Bákan náà, a gba àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì gbọ́. (Sm. 119:42; Àìsá. 40:8) Yàtọ̀ síyẹn, a ti rí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó nímùúṣẹ ní ọjọ́ wa. A ti rí ọ̀pọ̀ tó yí ìgbésí ayé wọn pa dà lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìlànà Bíbélì sílò. Àwọn nǹkan yìí mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé gbogbo èèyàn ló yẹ kó gbọ́ ìhìn rere náà.

16. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 46:​1-3, báwo ni ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti Jésù ṣe lè mú ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù?

16 A tún nígbàgbọ́ nínú Jèhófà tó fún wa ní ìhìn rere náà àti Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba náà. (Jòh. 14:1) Ohun yòówù ká kojú, Jèhófà máa jẹ́ ibi ààbò àti okun wa. (Ka Sáàmù 46:​1-3.) Bákan náà, ó dá wa lójú pé Jésù ló ń darí iṣẹ́ yìí látọ̀run, ó sì ń lo agbára tí Jèhófà fún un.​—Mát. 28:​18-20.

17. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká rídìí tó fi yẹ ká máa wàásù.

17 Ìgbàgbọ́ tá a ní ń mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún wa láwọn ọ̀nà tá ò retí. (Oníw. 11:6) Bí àpẹẹrẹ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló máa ń kọjá níbi tá a pàtẹ àwọn ìwé wa sí. Ṣé ọ̀nà tá à ń gbà wàásù yìí ń so èso? Bẹ́ẹ̀ ni! Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2014 sọ ìrírí ọ̀dọ́bìnrin kan tó wà ní yunifásítì tó fẹ́ kọ àròkọ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò rí Gbọ̀ngàn Ìjọba kankan, àmọ́ ó rí ibi tá à ń pàtẹ ìwé wa sí nínú ilé ìwé wọn, ó sì rí ìwé tó fẹ́ lò fún àròkọ náà níbẹ̀. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kódà ó ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé báyìí. Irú àwọn ìrírí yìí máa ń fún wa níṣìírí láti tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù torí ó jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ṣì wà.

PINNU PÉ O Ò NÍ DẸWỌ́

18. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé a máa parí iṣẹ́ ìwàásù náà lásìkò tí Jèhófà fẹ́?

18 Ó dájú pé a máa parí iṣẹ́ ìwàásù yìí lásìkò. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà. Jèhófà fi hàn pé Olùpàkókòmọ́ ni òun. Ọgọ́fà ọdún (120) ṣáájú Ìkún Omi ni Jèhófà ti pinnu ọjọ́ tí òun máa pa àwọn èèyàn burúkú náà run. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Nóà pé kó kan ọkọ̀ áàkì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì (40) sí àádọ́ta (50) ọdún kí Ìkún Omi náà tó bẹ̀rẹ̀, Nóà ò dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un. Bí àwọn èèyàn ò tiẹ̀ tẹ́tí sí i, ó ń kìlọ̀ fún wọn títí dìgbà tí Jèhófà sọ fún un pé kó kó àwọn ẹran sínú ọkọ̀ náà. Nígbà tó sì tó àkókò, “Jèhófà ti ilẹ̀kùn pa.”​—Jẹ́n. 6:3; 7:​1, 2, 16.

19. Kí ló dá wa lójú pé ó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́?

19 Láìpẹ́, Jèhófà máa fòpin sí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe yìí, á “ti ilẹ̀kùn pa” mọ́ ayé Sátánì, ayé tuntun á sì wọlé dé. Títí dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká fara wé Nóà, Hábákúkù àtàwọn míì tí kò dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wọn. Ẹ jẹ́ ká gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, ká máa mú sùúrù, ká sì nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà pé á mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ.

ORIN 75 “Èmi Nìyí! Rán Mi!”

^ ìpínrọ̀ 5 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a ti jíròrò bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè tẹ̀ síwájú láti di akéde Ìjọba Ọlọ́run. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun mẹ́ta tí gbogbo wa lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé àá máa wàásù nìṣó títí dìgbà tí Jèhófà bá sọ pé ó tó, yálà a ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde àbí a ti pẹ́ nínú òtítọ́.

^ ìpínrọ̀ 2 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Tá a bá sọ pé ‘má ṣe dẹwọ́,’ ṣe là ń rọ̀ wá pé ká máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó títí dìgbà tí Jèhófà á fi sọ pé iṣẹ́ náà ti parí.

^ ìpínrọ̀ 5 “Ọjọ́ Olúwa” bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jésù di Ọba lọ́dún 1914, á sì parí nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀ bá dópin.