Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 39

O Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Tí Èèyàn Ẹ Kan Bá Fi Jèhófà Sílẹ̀

O Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Tí Èèyàn Ẹ Kan Bá Fi Jèhófà Sílẹ̀

“Ẹ wo iye ìgbà tí wọ́n . . . bà á nínú jẹ́.”​—SM. 78:40.

ORIN 102 Ran Àwọn Aláìlera Lọ́wọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Báwo ló ṣe rí lára àwọn kan nígbà tí wọ́n yọ ẹnì kan nínú ìdílé wọn lẹ́gbẹ́?

ṢÉ WỌ́N ti yọ ẹnì kan nínú ìdílé ẹ lẹ́gbẹ́ rí? Ká sòótọ́, ó máa ń dunni gan-an. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Hilda sọ pé: “Nígbà tí ọkọ mi kú lẹ́yìn ọdún mọ́kànlélógójì (41) tá a ti ṣègbéyàwó, mo ronú pé kò sóhun tó lè dùn mí tóyẹn láyé yìí. * Àmọ́ nígbà tí ọmọ mi fi Jèhófà sílẹ̀, tó sì tún fi ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀ sílẹ̀, ọkàn mi gbọgbẹ́, kódà ó dùn mí ju ikú ọkọ mi lọ.”

Jèhófà mọ bó ṣe máa ń rí lára tí ẹnì kan téèyàn fẹ́ràn bá fi òtítọ́ sílẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 2-3) *

2-3. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 78:40, 41, báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà táwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ bá kẹ̀yìn sí i?

2 Ẹ wo bó ṣe máa dun Jèhófà tó nígbà táwọn áńgẹ́lì kan kẹ̀yìn sí i. (Júùdù 6) Ẹ tún wo bó ṣe máa ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́ tó nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí i léraléra. (Ka Sáàmù 78:40, 41.) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó máa ń dun Baba wa ọ̀run tí ẹnì kan tó o nífẹ̀ẹ́ bá fi òtítọ́ sílẹ̀. Ó mọ bí ẹ̀dùn ọkàn ẹ ṣe pọ̀ tó, ó sì dájú pé á dúró tì ẹ́, á sì fún ẹ lókun kó o lè fara dà á.

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun tá a lè ṣe kí Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ tí ẹnì kan tá a fẹ́ràn bá fi òtítọ́ sílẹ̀. Àá tún rí bá a ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn míì tí wọ́n ti yọ èèyàn wọn lẹ́gbẹ́. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò èrò tí kò yẹ ká ní.

MÁ ṢE MÁA DÁ ARA Ẹ LẸ́BI

4. Báwo ló ṣe máa ń rí lára ọ̀pọ̀ òbí tí ọmọ wọn bá fi Jèhófà sílẹ̀?

4 Tí ọmọ kan bá fi Jèhófà sílẹ̀, àwọn òbí sábà máa ń ronú pé ohun kan wà tó yẹ káwọn ṣe táwọn ò ṣe. Arákùnrin Luke tí wọ́n yọ ọmọ ẹ̀ lẹ́gbẹ́ sọ pé: “Lẹ́yìn tọ́rọ̀ yẹn ṣẹlẹ̀, mo máa ń dá ara mi lẹ́bi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lálàákálàá. Nígbà míì sì rèé, mo máa ń sunkún débi pé àyà á bẹ̀rẹ̀ sí í dùn mí.” Tẹkúntẹkún ni Arábìnrin Elizabeth tírú ẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí fi sọ pé: “Ṣé kì í ṣe pé èmi ni mi ò tọ́ ọmọ mi dáadáa ṣá? Kò jọ pé mo kọ́ ọ kí òtítọ́ lè jinlẹ̀ nínú ẹ̀ débi táá fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.”

5. Ọwọ́ ta ló wà bóyá ẹnì kan máa sin Jèhófà tàbí kò ní ṣe bẹ́ẹ̀?

5 Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà ti fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní òmìnira láti yan ohun tá a fẹ́. Ìyẹn fi hàn pé àwa fúnra wa la máa pinnu bóyá a máa sìn ín tàbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí tí ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló tọ́ àwọn ọ̀dọ́ kan dàgbà, síbẹ̀ àwọn ọ̀dọ́ náà pinnu láti sin Jèhófà, wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ sí i. Àwọn ọ̀dọ́ míì sì wà tó jẹ́ pé àwọn òbí wọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wọn. Síbẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ náà fi Jèhófà sílẹ̀ nígbà tí wọ́n dàgbà. Kókó ibẹ̀ ni pé, kálukú ló máa pinnu bóyá òun máa sin Jèhófà. (Jóṣ. 24:15) Torí náà, ẹ̀yin òbí tọ́mọ yín ti fi Jèhófà sílẹ̀, ẹ má ṣe ronú láé pé ẹ̀yin lẹ fa ohun tó ṣẹlẹ̀ náà!

6. Báwo ló ṣe máa rí lára ọ̀dọ́ kan tí ọ̀kan nínú àwọn òbí ẹ̀ bá fi Jèhófà sílẹ̀?

6 Nígbà míì, bàbá kan tàbí ìyá kan lè fi Jèhófà àti ìdílé ẹ̀ sílẹ̀. (Sm. 27:10) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kì í rọrùn fáwọn ọmọ torí pé ojú òbí làwọn ọmọ máa ń wò, àpẹẹrẹ wọn sì ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé. Esther tí wọ́n yọ bàbá ẹ̀ lẹ́gbẹ́ sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń sunkún torí kì í ṣe pé ìgbàgbọ́ bàbá mi kàn ń jó rẹ̀yìn, ṣe ni wọ́n dìídì pinnu pé àwọn ò sin Jèhófà mọ́. Torí mo nífẹ̀ẹ́ bàbá mi gan-an, mo máa ń ṣàníyàn nípa bí nǹkan ṣe rí fún wọn lẹ́yìn tí wọ́n yọ wọ́n lẹ́gbẹ́. Kódà, ṣe làyà mi máa ń já lójijì láìnídìí.”

7. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n yọ òbí wọn lẹ́gbẹ́?

7 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, tó bá jẹ́ pé wọ́n ti yọ ọ̀kan nínú àwọn òbí yín lẹ́gbẹ́, ẹ kú ìfaradà, a mọ̀ pé kò rọrùn fún yín. Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé Jèhófà mọ bọ́rọ̀ náà ṣe dùn yín tó. Ó nífẹ̀ẹ́ yín, ó sì mọrírì bẹ́ ẹ ṣe jẹ́ adúróṣinṣin láìka ohun tó ṣẹlẹ̀ sí. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ sì rí lára àwa ará yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Rántí pé, ìwọ kọ́ lo lẹ̀bi ìpinnu táwọn òbí ẹ ṣe. Bá a sì ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, Jèhófà ti fún kálukú lómìnira láti yan ohun tó wù ú. Torí náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan tó bá ti ya ara ẹ̀ sí mímọ́, tó sì ti ṣèrìbọmi ló máa “ru ẹrù ara rẹ̀.”​—Gál. 6:5.

8. Kí làwọn tó kù nínú ìdílé lè ṣe bí wọ́n ṣe ń dúró de ìgbà tí ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà máa pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà? (Tún wo àpótí náà “ Jọ̀wọ́ Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà.”)

8 Tí ẹni tá a nífẹ̀ẹ́ bá fi Jèhófà sílẹ̀, a sábà máa ń nírètí pé lọ́jọ́ kan, ẹni náà máa pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Àmọ́ kí lo lè máa ṣe bó o ṣe ń dúró de ìgbà yẹn? Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí ìgbàgbọ́ ẹ lè túbọ̀ lágbára. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fáwọn tó kù nínú ìdílé títí kan ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, wàá ní okun láti fara da ẹ̀dùn ọkàn rẹ. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn nǹkan pàtó tó o lè ṣe kí ìgbàgbọ́ ẹ lè túbọ̀ lágbára.

OHUN TÓ O LÈ ṢE KÍ ÌGBÀGBỌ́ Ẹ LÈ TÚBỌ̀ LÁGBÁRA

9. Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kí ìgbàgbọ́ ẹ lè túbọ̀ lágbára? (Tún wo àpótí náà “ Àwọn Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Tó Lè Tù Ẹ́ Nínú Tí Ẹnì Kan Nínú Ìdílé Ẹ Bá Fi Jèhófà Sílẹ̀.”)

9 Máa ṣe ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ó ṣe pàtàkì kó o máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tìẹ àti tàwọn tó kù nínú ìdílé ẹ túbọ̀ lágbára. Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó ò ń ṣàṣàrò lórí ẹ̀, tó o sì ń lọ sípàdé déédéé. Joanna tí bàbá ẹ̀ àti ẹ̀gbọ́n ẹ̀ fi òtítọ́ sílẹ̀ sọ pé: “Ara máa ń tù mí tí mo bá kà nípa àwọn tí Bíbélì mẹ́nu kàn, bí Ábígẹ́lì, Ẹ́sítà, Jóòbù, Jósẹ́fù àti Jésù. Àpẹẹrẹ wọn máa ń fún mi níṣìírí, ó sì máa ń jẹ́ kí n ní èrò tó tọ́ táá jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn orin wa míì tún máa ń fún mi lókun.”

10. Báwo ni Sáàmù 32:6-8 ṣe lè fún wa lókun láti fara dà á?

10 Sọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà. Ìgbàkigbà tó o bá tún ní ìdààmú ọkàn, má ṣe dákẹ́ àdúrà. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fi ojú tó fi ń wo nǹkan wò ó àti pé kó ‘fún ẹ ní ìjìnlẹ̀ òye, kó sì kọ́ ẹ ní ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.’ (Ka Sáàmù 32:6-8.) Òótọ́ ni pé ó lè ṣòro fún ẹ láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ gẹ́lẹ́ fún Jèhófà. Àmọ́ jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ọ̀rọ̀ ẹ yé e, ó sì mọ bọ́rọ̀ náà ṣe ń dùn ẹ́ tó. Bákan náà, ó nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an, ó sì fẹ́ kó o sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún òun.​—Ẹ́kís. 34:6; Sm. 62:7, 8.

11. Kí ni Hébérù 12:11 sọ tó jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká fara mọ́ ìbáwí Jèhófà? (Tún wo àpótí náà “ Bí Ìyọlẹ́gbẹ́ Ṣe Ń Jẹ́ Ká Mọ̀ Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa.”)

11 Fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìpinnu táwọn alàgbà bá ṣe. Jèhófà ló ṣètò pé kí wọ́n máa yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́. Ètò onífẹ̀ẹ́ yìí máa ṣe gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ láǹfààní títí kan oníwà àìtọ́ náà. (Ka Hébérù 12:11.) Àwọn kan nínú ìjọ lè sọ pé kò yẹ káwọn alàgbà yọ ẹni náà lẹ́gbẹ́. Àmọ́ rántí pé, àwọn tó máa ń ṣàríwísí yìí kì í sábà mẹ́nu kan àwọn nǹkan tí ò dáa tí oníwà àìtọ́ náà ṣe. Òótọ́ kan ni pé, a ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Torí náà, ohun tó máa bọ́gbọ́n mu ni pé kó o fara mọ́ ìpinnu táwọn alàgbà náà ṣe, kó o sì gbà pé wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. Ká tún fi sọ́kàn pé kì í ṣe èèyàn ni wọ́n ń ṣojú fún bí wọ́n ṣe ń dájọ́, “Jèhófà ni.”​—2 Kíró. 19:6.

12. Àǹfààní wo làwọn kan ti rí torí pé wọ́n fara mọ́ ìbáwí Jèhófà?

12 Tó o bá fara mọ́ ìpinnu táwọn alàgbà ṣe láti yọ ẹnì kan nínú ìdílé ẹ lẹ́gbẹ́, ìyẹn lè mú kẹ́ni náà pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Elizabeth tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti má ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ọmọ mi. Àmọ́ lẹ́yìn tó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, òun fúnra ẹ̀ gbà pé ó dáa bí wọ́n ṣe yọ òun lẹ́gbẹ́. Nígbà tó yá, ó sọ pé ọ̀pọ̀ nǹkan lòun kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ náà. Ìyẹn jẹ́ kí n rí i pé ìbáwí Jèhófà ló dáa jù.” Mark ọkọ ẹ̀ fi kún un pé: “Nígbà tó yá, ọmọ wa sọ fún mi pé lára ohun tó mú kó wu òun láti pa dà ni bí a ò ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú òun lásìkò yẹn. Inú mi dùn gan-an pé Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onígbọràn.”

13. Kí lá jẹ́ kó o lè fara da ẹ̀dùn ọkàn ẹ?

13 Fọ̀rọ̀ lọ àwọn ọ̀rẹ́ tó mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. Tó o bá ń wà pẹ̀lú àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn tí wọ́n sì nírìírí, wọ́n á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dà á. (Òwe 12:25; 17:17) Joanna tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nínú mi lọ́hùn-ún, ṣe ló dà bíi pé mo dá wà. Àmọ́ nígbà tí mo fọ̀rọ̀ lọ àwọn ọ̀rẹ́ mi tí mo fọkàn tán, ṣe lara tù mí pẹ̀sẹ̀.” Ká wá sọ pé láìmọ̀ àwọn kan nínú ìjọ sọ ohun tó tún dá kún ẹ̀dùn ọkàn ẹ ńkọ́, kí lo lè ṣe?

14. Kí nìdí tó fi yẹ ká ‘máa fara dà á fún ara wa, ká sì máa dárí ji ara wa fàlàlà’?

14 Ohun kan ni pé, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa sọ ohun táá mú kára tù ẹ́. Torí náà, máa mú sùúrù fáwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. (Jém. 3:2) Torí pé aláìpé ni gbogbo wa, má jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu pé àwọn kan lè má mọ ohun tí wọ́n máa sọ tàbí káwọn míì tiẹ̀ sọ ohun tó máa dùn ẹ́ láìmọ̀. Rántí ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa, pé: “Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà, kódà tí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì.” (Kól. 3:13) Arábìnrin kan tí wọ́n yọ ọmọ ẹ̀ lẹ́gbẹ́ sọ pé: “Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ láti dárí ji àwọn ará tí wọ́n fẹ́ tù mí nínú, àmọ́ tí wọ́n dá kún ẹ̀dùn ọkàn mi láìmọ̀.” Báwo làwọn ará nínú ìjọ ṣe lè pèsè ìtùnú fún ìdílé ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́?

BÍ ÀWỌN ARÁ ÌJỌ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́

15. Kí la lè ṣe láti pèsè ìtùnú fún ìdílé ẹnì kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ lẹ́gbẹ́?

15 Máa fìfẹ́ hàn sí ìdílé ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́, kó o sì máa ṣenúure sí wọn. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Miriam sọ pé ẹ̀rù ba òun láti lọ sípàdé lẹ́yìn tí wọ́n yọ àbúrò òun lẹ́gbẹ́. Ó ní: “Ọkàn mi ò balẹ̀ torí mi ò mọ ohun táwọn èèyàn máa sọ. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ará ló bá mi kẹ́dùn, wọn ò sì sọ nǹkan burúkú nípa àbúrò mi tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́. Wọ́n jẹ́ kára tù mí gan-an lásìkò yẹn, ọpẹ́lọpẹ́ wọn lára mi.” Arábìnrin míì sọ pé: “Lẹ́yìn tí wọ́n yọ ọmọ wa lẹ́gbẹ́, àwọn ará nínú ìjọ wá tù wá nínú. Àwọn kan nínú wọn sọ fún wa pé àwọn ò mọ ohun táwọn lè sọ. A jọ sunkún, àwọn kan sì tún kọ lẹ́tà ìtùnú sí mi. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn tù mí nínú gan-an.”

16. Báwo làwọn ará nínú ìjọ ṣe lè dúró ti ìdílé ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́?

16 Ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti dúró ti ìdílé ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́. Àsìkò yìí gan-an ni wọ́n nílò ìfẹ́ àti ìṣírí látọ̀dọ̀ àwọn ará. (Héb. 10:24, 25) Nígbà míì, ìdílé àwọn tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ máa ń ronú pé àwọn kan nínú ìjọ máa ń yẹra fún àwọn, wọ́n sì máa ń hùwà bíi pé gbogbo ìdílé àwọn ni wọ́n yọ lẹ́gbẹ́. A ò gbọ́dọ̀ ṣe ohun táá jẹ́ kí wọ́n nírú èrò bẹ́ẹ̀ láé! Ní pàtàkì jù lọ, a gbọ́dọ̀ máa gbóríyìn fáwọn ọ̀dọ́ táwọn òbí wọn ti fi òtítọ́ sílẹ̀, ká sì máa fún wọn níṣìírí. Arábìnrin Maria tí wọ́n yọ ọkọ ẹ̀ lẹ́gbẹ́, tó sì tún fi ìdílé náà sílẹ̀ sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ mi wá mi wálé, wọ́n bá wa dáná, wọ́n sì bá mi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ mi. Wọ́n mọ bí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe dùn mí tó, kódà a jọ sunkún. Wọ́n tún gbèjà mi nígbà táwọn kan ń sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa mi. Kí n sòótọ́, wọ́n tù mí nínú gan-an.”​—Róòmù 12:13, 15.

Àwọn ará ìjọ lè pèsè ìtùnú fún ìdílé ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 17) *

17. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè tu àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú?

17 Ẹ̀yin alàgbà, ẹ máa wáyè láti fún ìdílé àwọn tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ lókun, kẹ́ ẹ sì máa tù wọ́n nínú torí ojúṣe pàtàkì tí Jèhófà ti gbé fún yín ni. (1 Tẹs. 5:14) Lára ohun tẹ́ ẹ lè ṣe ni pé, kẹ́ ẹ máa bá wọn sọ̀rọ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé. Bákan náà, ẹ máa bẹ̀ wọ́n wò, kẹ́ ẹ sì gbàdúrà fún wọn. Ẹ tún lè bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí kẹ́ ẹ pè wọ́n wá sí ìjọsìn ìdílé yín. Ó ṣe pàtàkì káwọn alàgbà máa bójú tó àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn, kí wọ́n sì máa fi àánú àti ìfẹ́ hàn sí wọn.​—1 Tẹs. 2:7, 8.

MÁ SỌ̀RÈTÍ NÙ KÓ O SÌ GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ

18. Kí ni 2 Pétérù 3:9 sọ pé Jèhófà fẹ́ káwọn oníwà àìtọ́ ṣe?

18 Bíbélì sọ pé Jèhófà “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (Ka 2 Pétérù 3:9.) Bí ẹnì kan bá tiẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ẹ̀mí ẹ̀ ṣì ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Rántí pé nǹkan ńlá ló ná Jèhófà láti ra ẹnì kọ̀ọ̀kan wa pa dà, ìyẹn sì ni ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Jèhófà máa ń fìfẹ́ ran àwọn tó ti ṣáko lọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ ẹ̀. Ó wù ú gan-an pé kí wọ́n pa dà bá a ṣe rí i nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ọmọ onínàákúnàá. (Lúùkù 15:11-32) Ọ̀pọ̀ àwọn tó fi òtítọ́ sílẹ̀ ló pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà nígbà tó yá. Àwọn tó wà nínú ìjọ sì gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀. Inú Elizabeth tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan dùn gan-an nígbà tí wọ́n gba ọmọ ẹ̀ pa dà. Ó sọ pé: “Mo mọrírì àwọn tó fún wa níṣìírí gan-an nígbà tí wọ́n yọ ọmọ mi lẹ́gbẹ́ tí wọ́n sì rọ̀ wá pé ká má sọ̀rètí nù.”

19. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

19 Gbogbo ìgbà ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ìdí ni pé gbogbo ìgbà ni ìmọ̀ràn ẹ̀ máa ń ṣe wá láǹfààní. Bákan náà, Baba aláàánú ni, ó sì lawọ́. Kódà, ìfẹ́ tó jinlẹ̀ ló ní fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó sì ń sìn ín. Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀ nígbà ìṣòro. (Héb. 13:5, 6) Mark tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Jèhófà ò fi wá sílẹ̀ lọ́nàkọnà. Ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà tá a bá níṣòro.” Kò sí àní-àní pé Jèhófà máa fún ẹ ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” nígbàkigbà tó o bá nílò ẹ̀. (2 Kọ́r. 4:7) Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, tí èèyàn ẹ kan bá fi Jèhófà sílẹ̀, o jẹ́ olóòótọ́, kó o sì nírètí pé ẹni náà máa pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.

ORIN 44 Àdúrà Ẹni Tó Ní Ẹ̀dùn Ọkàn

^ ìpínrọ̀ 5 Ó máa ń dùn wá gan-an tí èèyàn wa kan bá fi Jèhófà sílẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. A tún máa rí àwọn nǹkan pàtó táwọn mọ̀lẹ́bí ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ lè ṣe táá jẹ́ kí wọ́n lè fara da ohun tó ṣẹlẹ̀, kí ìgbàgbọ́ wọn má sì jó rẹ̀yìn. Bákan náà, a tún máa jíròrò ohun táwọn tó wà nínú ìjọ lè ṣe láti tu ìdílé náà nínú, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́.

^ ìpínrọ̀ 1 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ ìpínrọ̀ 79 ÀWÒRÁN: Nígbà tí arákùnrin kan fi Jèhófà àti ìdílé ẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀dùn ọkàn bá ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 81 ÀWÒRÁN: Alàgbà méjì wá fún ìdílé kan níṣìírí.