Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 39

Ṣé Orúkọ Ẹ Wà Nínú “Ìwé Ìyè”?

Ṣé Orúkọ Ẹ Wà Nínú “Ìwé Ìyè”?

“Wọ́n sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀ torí àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà.”—MÁL. 3:16.

ORIN 61 Ẹ Tẹ̀ Síwájú, Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

Àtìgbà ayé Ébẹ́lì ni Jèhófà ti ń kọ orúkọ àwọn èèyàn sínú “ìwé ìyè” (Wo ìpínrọ̀ 1-2)

1.Málákì 3:16 ṣe sọ, ìwé wo ni Jèhófà ti ń kọ tipẹ́, kí ló sì wà nínú ìwé náà?

 ỌJỌ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń kọ ìwé kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Orúkọ àwọn èèyàn ló wà nínú ìwé náà, Ébẹ́lì sì ni ẹlẹ́rìí olóòótọ́ àkọ́kọ́ tí Jèhófà kọ orúkọ ẹ̀ sínú ẹ̀. * (Lúùkù 11:50, 51) Látìgbà yẹn títí di báyìí, Jèhófà ti kọ orúkọ ọ̀pọ̀ àwọn míì sínú ìwé yẹn. Nínú Bíbélì, àwọn orúkọ tá a pe ìwé náà ni “ìwé ìrántí,” “ìwé ìyè” àti “àkájọ ìwé ìyè.” Àmọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa pe ìwé náà ní “ìwé ìyè.”—Ka Málákì 3:16; Ìfi. 3:5; 17:8.

2. Orúkọ àwọn wo ló wà nínú ìwé ìyè, báwo la sì ṣe lè jẹ́ kí orúkọ wa wà nínú ìwé náà?

2 Orúkọ àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà, tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ la kọ sínú ìwé tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí. Wọ́n máa láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Lónìí, tá a bá fẹ́ kí Jèhófà kọ orúkọ wa sínú ìwé náà, àfi ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ẹ̀, ẹbọ ìràpadà Ọmọ ẹ̀ Jésù Kristi ló sì máa jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe. (Jòh. 3:16, 36) Gbogbo wa la fẹ́ kí orúkọ wa wà nínú ìwé ìyè, bóyá ọ̀run la máa gbé tàbí ayé.

3-4. (a) Tí orúkọ wa bá ti wà nínú ìwé ìyè, ṣé ó dájú pé a máa wà láàyè títí láé nìyẹn? Ṣàlàyé. (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e?

3 Ṣé ohun tí à ń sọ ni pé tí orúkọ wa bá ti wà nínú ìwé ìyè, ó dájú pé a máa wà láàyè títí láé? Ìdáhùn ìbéèrè yìí wà nínú Ẹ́kísódù 32:33. Jèhófà sọ fún Mósè níbẹ̀ pé: “Màá pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ mí rẹ́ kúrò nínú ìwé mi.” Torí náà, Ọlọ́run ṣì lè pa orúkọ àwọn tó ti wà nínú ìwé yẹn rẹ́. Ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà kọ orúkọ náà sílẹ̀ lọ́nà tó ṣeé pa rẹ́. (Ìfi. 3:5, àlàyé ìsàlẹ̀) A gbọ́dọ̀ rí i dájú pé orúkọ wa wà nínú ìwé yìí títí dìgbà tí Ọlọ́run máa kọ ọ́ lọ́nà tí kò ní ṣeé pa rẹ́ mọ́.

4 Ìyẹn lè mú ká béèrè àwọn ìbéèrè kan. Bí àpẹẹrẹ, kí ni Bíbélì sọ nípa àwọn tí orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè àtàwọn tí orúkọ wọn ò sí níbẹ̀? Ìgbà wo ni Jèhófà máa fún àwọn tí orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè ní ìyè àìnípẹ̀kun? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí ò láǹfààní láti mọ Jèhófà kí wọ́n tó kú? Ṣé ó ṣeé ṣe kí orúkọ tiwọn náà wà nínú ìwé yẹn? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e.

ORÚKỌ ÀWỌN WO LÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ NÁÀ?

5-6. (a) Bí Fílípì 4:3 ṣe sọ, àwọn wo ni orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè? (b) Ìgbà wo ni orúkọ wọn máa wà nínú ìwé ìyè títí láé?

5 Orúkọ àwọn wo ló wà nínú ìwé ìyè? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbé àwùjọ àwọn èèyàn márùn-ún kan yẹ̀ wò. Orúkọ àwọn àwùjọ kan wà nínú ìwé yìí, nígbà tí orúkọ àwọn yòókù ò sí níbẹ̀.

6 Àwùjọ àkọ́kọ́ ni àwọn tí Jèhófà yàn láti bá Jésù ṣàkóso lọ́run. Ṣé orúkọ wọn ti wà nínú ìwé ìyè? Bẹ́ẹ̀ ni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn “alábàáṣiṣẹ́” rẹ̀ sọ̀rọ̀ nílùú Fílípì, ó sọ pé orúkọ àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n máa bá Jésù ṣàkóso ti wà nínú ìwé ìyè. (Ka Fílípì 4:3.) Àmọ́ tí wọ́n bá fẹ́ kí orúkọ wọn máa wà nínú ìwé yẹn títí lọ, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ títí dópin. Torí náà, ìgbà tí wọ́n bá gba èdìdì ìkẹyìn ni orúkọ wọn máa wà nínú ìwé ìyè títí láé, ìyẹn sì máa ṣẹlẹ̀ kí wọ́n tó kú tàbí kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀.—Ìfi. 7:3.

7. Kí ni Ìfihàn 7:16, 17 sọ tó jẹ́ ká mọ ìgbà tí orúkọ àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó jẹ́ ara àgùntàn mìíràn máa wà nínú ìwé ìyè títí láé?

7 Àwùjọ kejì ni ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó jẹ́ ara àgùntàn mìíràn. Ṣé orúkọ wọn ti wà nínú ìwé ìyè? Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣé orúkọ wọn ṣì máa wà nínú ìwé ìyè lẹ́yìn tí wọ́n bá la Amágẹ́dọ́nì já? Bẹ́ẹ̀ ni. (Ìfi. 7:14) Jésù sọ pé àwọn tó fìwà jọ àgùntàn máa lọ “sínú ìyè àìnípẹ̀kun.” (Mát. 25:46) Àmọ́ kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà máa fún àwọn tó bá la Amágẹ́dọ́nì já ní ìyè àìnípẹ̀kun torí pé Jèhófà ṣì lè pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò nínú ìwé ìyè. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, ó “máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, ó sì máa darí wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè.” Àwọn tó bá ṣègbọràn sí Kristi, tí Jèhófà sì rí i pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ni orúkọ wọn máa wà nínú ìwé ìyè náà títí láé.—Ka Ìfihàn 7:16, 17.

8. Orúkọ àwọn wo ni ò sí nínú ìwé ìyè, kí ló sì máa ṣẹlẹ̀ sí wọn?

8 Àwùjọ kẹta ni àwọn ewúrẹ́ tí Jèhófà máa pa run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Orúkọ wọn ò sí nínú ìwé ìyè. Jésù sọ pé wọ́n “máa lọ sínú ìparun àìnípẹ̀kun.” (Mát. 25:46) Ẹ̀mí Ọlọ́run darí Pọ́ọ̀lù láti sọ pé, “àwọn yìí máa fara gbá ìyà ìdájọ́ ìparun ayérayé.” (2 Tẹs. 1:9; 2 Pét. 2:9) Ìdájọ́ yìí kan náà làwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ máa gbà. Àwọn náà máa pa run yán-án yán-án, wọn ò ní rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà. Ó dájú pé Jèhófà ò ní jí wọn dìde. (Mát. 12:32; Máàkù 3:28, 29; Héb. 6:4-6) Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwùjọ méjì tí Jèhófà máa jí dìde sí ayé.

ÀWỌN TÍ JÈHÓFÀ MÁA JÍ DÌDE

9. Àwùjọ méjì wo ni Ìṣe 24:15 sọ pé Jèhófà máa jí dìde sí ayé, báwo ni wọ́n sì ṣe yàtọ̀ síra?

9 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwùjọ méjì tí Jèhófà máa jí dìde, tí wọ́n sì máa láǹfààní láti gbé ayé títí láé. Bíbélì pè wọ́n ní “àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo.” (Ka Ìṣe 24:15.) “Àwọn olódodo” ni àwọn tó sin Jèhófà tọkàntọkàn kí wọ́n tó kú. Àmọ́ “àwọn aláìṣòdodo” ò sin Jèhófà kí wọ́n tó kú. Kódà, ìwà burúkú pọ̀ lọ́wọ́ wọn. Torí pé àwùjọ méjèèjì yìí máa jíǹde, ṣé a wá lè sọ pé orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwùjọ kọ̀ọ̀kan.

10. Kí nìdí tí Jèhófà fi máa jí “àwọn olódodo” dìde, àǹfààní wo ni àwọn kan lára wọn sì máa ní? (Tún wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ yìí. Ó sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde sí ayé.)

10 Àwùjọ kẹrin ni “àwọn olódodo.” Orúkọ wọn ti wà nínú ìwé ìyè kí wọ́n tó kú. Àmọ́ ṣé Jèhófà wá yọ orúkọ wọn kúrò nínú ìwé ìyè nígbà tí wọ́n kú ni? Rárá o! Torí lójú Jèhófà, gbogbo wọn ló ṣì “wà láàyè.” Bíbélì sọ pé Jèhófà “kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, àmọ́ ó jẹ́ Ọlọ́run àwọn alààyè, torí lójú rẹ̀, gbogbo wọn wà láàyè.” (Lúùkù 20:38) Ìyẹn ni pé nígbà tí Jèhófà bá jí àwọn olódodo dìde sí ayé, orúkọ wọn máa wà nínú ìwé ìyè bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ṣì lè pa orúkọ wọn rẹ́. (Lúùkù 14:14) Torí náà, ó dájú pé Jèhófà máa yan àwọn kan lára àwọn tó jí dìde láti ṣe “olórí ní gbogbo ayé.”—Sm. 45:16.

11. Kí ló máa pọn dandan pé káwọn “aláìṣòdodo” mọ̀ kí orúkọ wọn tó wọnú ìwé ìyè?

11 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwùjọ karùn-ún, ìyẹn “àwọn aláìṣòdodo.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí wọn ò mọ òfin Jèhófà ni wọn ò ṣe jọ́sìn ẹ̀ kí wọ́n tó kú. Ìdí nìyẹn tí orúkọ wọn ò fi sí nínú ìwé ìyè. Àmọ́ nígbà tí Jèhófà bá jí wọn dìde, ó máa fún wọn láǹfààní kí wọ́n lè fi hàn pé wọ́n fẹ́ kí orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè. Ó máa gba pé ká ran àwọn “aláìṣòdodo” yìí lọ́wọ́ gan-an. Ìdí sì ni pé kí wọ́n tó kú, ìwà tó burú jáì ló kún ọwọ́ wọn. Torí náà, ó máa gba pé ká kọ́ wọn láwọn òfin àti ìlànà Jèhófà, kí wọ́n lè máa fi sílò. Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, Ìjọba Ọlọ́run máa ṣètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá ò ṣe irú ẹ̀ rí nínú ìtàn aráyé.

12. (a) Àwọn wo ló máa kọ́ àwọn aláìṣòdodo lẹ́kọ̀ọ́? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí ò bá fi nǹkan tí wọ́n ń kọ́ sílò?

12 Àwọn wo ló máa kọ́ àwọn aláìṣòdodo lẹ́kọ̀ọ́? Ogunlọ́gọ̀ èèyàn àtàwọn olódodo tí Jèhófà jí dìde ló máa kọ́ wọn. Torí náà, kí Jèhófà tó lè kọ orúkọ àwọn aláìṣòdodo sínú ìwé ìyè, wọ́n gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀, kí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ fún un. Jésù Kristi àtàwọn ẹni àmì òróró á máa fara balẹ̀ kíyè sí àwọn aláìṣòdodo yìí látọ̀run bóyá wọ́n ń fi nǹkan tí wọ́n ń kọ́ sílò. (Ìfi. 20:4) Jèhófà máa pa ẹnikẹ́ni tí ò bá fi àwọn nǹkan tó ń kọ́ sílò, bó tiẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún péré. (Àìsá. 65:20) Jèhófà àti Jésù mọ ohun tó wà lọ́kàn àwa èèyàn, torí náà wọ́n máa rí i dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tó máa fa ìpalára kankan nínú ayé tuntun.—Àìsá. 11:9; 60:18; 65:25; Jòh. 2:25.

ÀJÍǸDE ÌYÈ ÀTI ÀJÍǸDE ÌDÁJỌ́

13-14. (a) Òye wo la ní nípa ohun tí Jésù sọ nínú Jòhánù 5:29 tẹ́lẹ̀? (b) Àlàyé tuntun wo la ti wá ṣe nípa ẹ̀ báyìí?

13 Jésù tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí Jèhófà máa jí dìde sí ayé. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn rẹ̀, tí wọ́n á sì jáde wá, àwọn tó ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.” (Jòh. 5:28, 29) Àmọ́ kí ni Jésù ní lọ́kàn?

14 Tẹ́lẹ̀, òye tá a ní nípa ọ̀rọ̀ Jésù nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ni pé, ohun táwọn èèyàn bá ṣe lẹ́yìn tí wọ́n jí dìde ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, ìyẹn ni pé àwọn kan tó jí dìde máa ṣe ohun rere, nígbà táwọn kan tó jí dìde máa sọ ohun burúkú dàṣà. Àmọ́ ẹ kíyè sí i pé Jésù ò sọ pé àwọn tó wá látinú ibojì ìrántí máa ṣe ohun rere tàbí pé wọ́n máa sọ ohun burúkú dàṣà. Àmọ́ ohun tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó kú ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn “tó ṣe ohun rere” àtàwọn “tó sọ ohun burúkú dàṣà.” Ìyẹn fi hàn pé ohun tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó kú ni Jésù ń sọ. Àlàyé yẹn bọ́gbọ́n mu, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ó ṣe tán, Jèhófà ò ní gba ẹnikẹ́ni láyè láti sọ ohun burúkú dàṣà nínú ayé tuntun. Torí náà, ó dájú pé kí wọ́n tó kú ni wọ́n ti sọ ohun burúkú dàṣà. Àmọ́ kí ni “àjíǹde ìyè” àti “àjíǹde ìdájọ́” tí Jésù sọ túmọ̀ sí?

15. Àwọn wo ló máa ní “àjíǹde ìyè,” kí sì nìdí?

15 Àwọn olódodo tí wọ́n ṣe rere kí wọ́n tó kú máa ní “àjíǹde ìyè” torí pé orúkọ wọn ti wà nínú ìwé ìyè. Ìyẹn túmọ̀ sí pé àjíǹde “àwọn tó ṣe ohun rere” tí Jòhánù 5:29 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ náà ni àjíǹde “àwọn olódodo” tí Ìṣe 24:15 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Òye tuntun tá a ní yìí bá ohun tó wà nínú Róòmù 6:7 mu. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Ẹni tó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” Jèhófà ti pa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn olódodo yẹn rẹ́ nígbà tí wọ́n kú, ṣùgbọ́n kò gbàgbé gbogbo iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe. (Héb. 6:10) Àmọ́ àwọn olódodo tá a jí dìde yìí gbọ́dọ̀ máa jẹ́ olóòótọ́ nìṣó tí wọn ò bá fẹ́ kí orúkọ wọn kúrò nínú ìwé ìyè.

16. Kí ni “àjíǹde ìdájọ́”?

16 Àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà kí wọ́n tó kú ńkọ́? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ nígbà tí wọ́n kú, kò sí àkọsílẹ̀ kankan lọ́dọ̀ Jèhófà tó fi hàn pé wọ́n ṣe iṣẹ́ rere. Torí náà, orúkọ wọn ò sí nínú ìwé ìyè. Ìyẹn sì jẹ́ ká mọ̀ pé àjíǹde “àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà” náà ni àjíǹde “àwọn aláìṣòdodo” tí Ìṣe 24:15 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. “Àjíǹde ìdájọ́” ni wọ́n máa ní. * Ìyẹn ni pé Jésù máa fara balẹ̀ kíyè sí àwọn aláìṣòdodo yìí, ohun tí wọ́n bá sì ṣe ló máa fi dá wọn lẹ́jọ́. (Lúùkù 22:30) Ó máa gba àkókò díẹ̀ kí Jésù tó mọ̀ bóyá orúkọ wọn máa wà nínú ìwé ìyè àbí orúkọ wọn ò ní sí níbẹ̀. Ó dìgbà táwọn aláìṣòdodo yìí bá pa ìwà burúkú tí wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀ tì, tí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà ni orúkọ wọn máa tó wọnú ìwé ìyè.

17-18. Kí ni gbogbo àwọn tí Jèhófà bá jí dìde sí ayé máa ní láti ṣe, kí sì ni “iṣẹ́ ọwọ́” tí Ìfihàn 20:12, 13 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?

17 Yálà àwọn tó jíǹde jẹ́ olódodo tàbí aláìṣòdodo, gbogbo wọn ló gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn òfin tó wà nínú àkájọ ìwé tuntun tí Jèhófà máa fún wa nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Àpọ́sítélì Jòhánù ṣàlàyé ohun tó rí nínú ìran, ó ní: “Mo rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, wọ́n dúró síwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Àmọ́ a ṣí àkájọ ìwé míì; àkájọ ìwé ìyè ni. A fi àwọn ohun tí a kọ sínú àkájọ ìwé náà ṣèdájọ́ àwọn òkú bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.”—Ìfi. 20:12, 13.

18 Báwo ni Jèhófà ṣe máa ṣèdájọ́ àwọn tó jíǹde bí “iṣẹ́ ọwọ́” wọn ṣe rí? Ṣé nǹkan tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó kú ló máa fi dá wọn lẹ́jọ́? Rárá o! Ẹ rántí pé Jèhófà ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n nígbà tí wọ́n kú. Torí náà, “iṣẹ́ ọwọ́ wọn” ò lè jẹ́ nǹkan tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó kú. Dípò bẹ́ẹ̀, nǹkan tí wọ́n bá ṣe lẹ́yìn tá a ti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nínú ayé tuntun ni Jèhófà máa fi dá wọn lẹ́jọ́. Kódà, àwọn ọkùnrin olóòótọ́ bíi Nóà, Sámúẹ́lì, Dáfídì àti Dáníẹ́lì máa ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù Kristi, kí wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà rẹ̀. Tó bá gba pé káwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, ṣé kò wá yẹ káwọn aláìṣòdodo kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀?

19. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kò mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wọn láti tún wà láàyè?

19 Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kò mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wọn láti tún wà láàyè? Ìfihàn 20:15 sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ní: ‘Ẹnikẹ́ni tí a kò rí i pé wọ́n kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè la máa jù sínú adágún iná náà.’ Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn gan-an nìyẹn, Jèhófà máa pa wọ́n run títí láé. Ẹ ò rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí Jèhófà kọ orúkọ wa sínú ìwé ìyè, kó má sì pa á rẹ́ títí láé!

Arákùnrin kan ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi (Wo ìpínrọ̀ 20)

20. Iṣẹ́ pàtàkì wo la máa ṣe nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

20 Ẹ ò rí i pé àkókò àgbàyanu ni ìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi máa jẹ́ fún wa! Àsìkò yẹn la máa dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó gbòòrò jù lọ nínú ìtàn aráyé. Àmọ́ àsìkò yẹn kan náà ni Jèhófà tún máa kíyè sí ìwà àwọn olódodo àtàwọn aláìṣòdodo bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n. (Àìsá. 26:9; Ìṣe 17:31) Báwo la ṣe máa dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa dáhùn ìbéèrè yìí, ó sì máa jẹ́ ká mọyì ètò tí Jèhófà ṣe láti dá wa lẹ́kọ̀ọ́.

ORIN 147 Ọlọ́run Ṣèlérí Ìyè Àìnípẹ̀kun

^ Nínú Jòhánù 5:28, 29, Jésù sọ̀rọ̀ nípa “àjíǹde ìyè” àti “àjíǹde ìdájọ́.” Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò òye tuntun tá a ní nípa ẹsẹ Bíbélì yìí. A máa mọ ohun tí àjíǹde méjèèjì yìí jẹ́, àá sì tún mọ àwọn tí àjíǹde méjèèjì yìí kàn.

^ Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orúkọ àwọn èèyàn sínú ìwé yìí “látìgbà ìpìlẹ̀ ayé,” ìyẹn látìgbà ayé àwọn èèyàn tí wọ́n lè jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù. (Mát. 25:34; Ìfi. 17:8) Torí náà, ó hàn gbangba pé ọkùnrin olóòótọ́ àkọ́kọ́ tí orúkọ ẹ̀ wà nínú ìwé náà ni Ébẹ́lì.

^ Tẹ́lẹ̀, àlàyé tá a ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí ni pé “ìdájọ́” tí Ọlọ́run máa ṣe fáwọn èèyàn yẹn túmọ̀ sí ìdálẹ́bi. Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ náà “ìdájọ́” túmọ̀ sí ìdálẹ́bi. Àmọ́, ó jọ pé ọ̀rọ̀ náà “ìdájọ́” tí Jésù lò níbí ní ìtúmọ̀ tó jùyẹn lọ. Ohun tó túmọ̀ sí ni bí Jésù ṣe máa gbé àwọn èèyàn yẹn yẹ̀ wò bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìwé atúmọ̀ èdè Gíríìkì kan sọ pé ó túmọ̀ sí kí wọ́n “ṣàyẹ̀wò ìwà ẹnì kan fínnífínní.”