ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 38
Máa Ṣohun Táá Jẹ́ Káwọn Èèyàn Fọkàn Tán Ẹ
“Ẹni tó ṣeé fọkàn tán máa ń pa àṣírí mọ́.”—ÒWE 11:13.
ORIN 101 À Ń Ṣiṣẹ́ Níṣọ̀kan
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Irú ìwà wo ni ẹni tó ṣeé fọkàn tán máa ń hù?
ẸNI tó ṣeé fọkàn tán máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ, ó sì máa ń sọ òótọ́. (Sm. 15:4) Àwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn lè gbára lé e. Irú ẹni tá a sì fẹ́ káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa mọ̀ wá sí nìyẹn. Torí náà, kí la lè ṣe táá jẹ́ káwọn ará fọkàn tán wa?
2. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ṣeé fọkàn tán?
2 A ò lè fipá mú àwọn èèyàn pé kí wọ́n fọkàn tán wa. Ìwà tá a bá ń hù ló máa jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa. Wọ́n máa ń sọ pé ohun tá a bá fara ṣiṣẹ́ fún ló ń pẹ́ lọ́wọ́ ẹni. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ fún un ni. Àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe ló jẹ́ ká fọkàn tán an. Kò ní ṣe ohun tí ò ní jẹ́ ká fọkàn tán an torí “gbogbo ohun tó bá ṣe ló ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.” (Sm. 33:4) Jèhófà sì fẹ́ káwa náà fara wé òun. (Éfé. 5:1) Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa gbé àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan yẹ̀ wò tí wọ́n fara wé Bàbá wọn ọ̀run, tí wọ́n sì fi hàn pé àwọn ṣeé fọkàn tán. Yàtọ̀ síyẹn, àá mọ àwọn nǹkan márùn-ún táá jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa.
KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ JÈHÓFÀ TÓ ṢEÉ FỌKÀN TÁN
3-4. Báwo ni wòlíì Dáníẹ́lì ṣe fi hàn pé òun ṣeé fọkàn tán, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?
3 Wòlíì Dáníẹ́lì fi hàn pé òun ṣeé fọkàn tán, torí náà àpẹẹrẹ rere ló jẹ́ fún wa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Bábílónì mú un nígbèkùn, kò pẹ́ táwọn èèyàn fi rí i pé ó ṣeé fọkàn tán. Àwọn èèyàn túbọ̀ fọkàn tán Dáníẹ́lì nígbà tí Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti sọ ìtúmọ̀ àlá Nebukadinésárì ọba Bábílónì. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Dáníẹ́lì ní láti sọ fún ọba pé inú Jèhófà ò dùn sóhun tó ń ṣe, irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ṣòroó jẹ́ fún ọba. Iṣẹ́ yẹn gba ìgboyà gan-an torí onínúfùfù ni Ọba Nebukadinésárì! (Dán. 2:12; 4:20-22, 25) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Dáníẹ́lì tún fi hàn pé òun ṣeé fọkàn tán nígbà tó túmọ̀ ọ̀rọ̀ àjèjì kan tó fara hàn lára ògiri ààfin ọba Bábílónì. (Dán. 5:5, 25-29) Nígbà tó yá, Dáríúsì ará Mídíà àtàwọn ìjòyè ẹ̀ tún kíyè sí i pé “ẹ̀mí tó ṣàrà ọ̀tọ̀” wà nínú Dáníẹ́lì. Wọ́n gbà pé Dáníẹ́lì “ṣeé fọkàn tán, kì í fiṣẹ́ ṣeré, kò sì hùwà ìbàjẹ́ rárá.” (Dán. 6:3, 4) Ẹ ò rí i pé àwọn alákòóso tó jẹ́ abọ̀rìṣà pàápàá mọ̀ pé Dáníẹ́lì olùjọsìn Jèhófà ṣeé fọkàn tán!
4 Bá a ṣe gbé àpẹẹrẹ Dáníẹ́lì yẹ̀ wò yìí, á dáa ká bi ara wa pé: ‘Irú ẹni wo làwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ mí sí? Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sí ẹni tí kì í fiṣẹ́ ṣeré, tó sì ṣeé fọkàn tán?’ Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ dáhùn àwọn ìbéèrè yìí? Ìdí ni pé táwọn èèyàn bá rí i pé a ṣeé fọkàn tán, wọ́n á yin Jèhófà lógo.
5. Kí nìdí táwọn èèyàn fi fọkàn tán Hananáyà?
5 Lọ́dún 455 Ṣ.S.K., lẹ́yìn tí Gómìnà Nehemáyà tún àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́, ó wá àwọn ọkùnrin tó ṣeé fọkàn tán kí wọ́n lè máa bójú tó ìlú náà. Nehemáyà wá yan Hananáyà lára àwọn ọkùnrin náà pé kó jẹ́ olórí Ibi Ààbò. Bíbélì sọ pé Hananáyà ló “ṣeé fọkàn tán jù lọ, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́ ju ọ̀pọ̀ àwọn míì lọ.” (Neh. 7:2) Hananáyà fọwọ́ pàtàkì mú gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kò sì fẹ́ ṣe ohun tí inú ẹ̀ ò dùn sí. Táwa náà bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tá ò sì fẹ́ ṣe ohun tó máa bà á nínú jẹ́, ìyẹn máa jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.
6. Àwọn nǹkan wo ni Tíkíkù ọ̀rẹ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe tó jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù fọkàn tán an?
6 Àpẹẹrẹ ẹlòmíì tá a máa gbé yẹ̀ wò ni Tíkíkù. Òun àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jọ ṣiṣẹ́, Pọ́ọ̀lù sì fọkàn tán an. Nígbà tí wọ́n sé Pọ́ọ̀lù mọ́lé, Tíkíkù ló ń ràn án lọ́wọ́ torí ó pè é ní “òjíṣẹ́ olóòótọ́.” (Éfé. 6:21, 22) Pọ́ọ̀lù fọkàn tán an pé kì í ṣe pé ó kàn máa fi àwọn lẹ́tà òun jíṣẹ́ fáwọn ará ní Éfésù àti Kólósè nìkan, ó tún máa gbà wọ́n níyànjú, á sì tù wọ́n nínú. Àpẹẹrẹ Tíkíkù jẹ́ ká rántí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tó ṣeé fọkàn tán, tí wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ lónìí láti sún mọ́ Jèhófà.—Kól. 4:7-9.
7. Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ lára àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìjọ ẹ táá mú kó o jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán?
7 Lónìí, a mọyì àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa torí wọ́n ṣeé fọkàn tán. Bíi ti Dáníẹ́lì, Hananáyà àti Tíkíkù, àwọn náà fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wá sí ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀, ọkàn wa máa ń balẹ̀ pé gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n máa ṣe nípàdé lọ́jọ́ yẹn ni wọ́n ti yàn fáwọn ará. Ẹ ò rí i pé àwọn alàgbà máa ń mọyì ẹ̀ gan-an táwọn ará tá a yanṣẹ́ fún bá múra iṣẹ́ wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ náà dáadáa nípàdé! Bí àpẹẹrẹ, ara máa ń yá wa láti pe àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá sípàdé torí a mọ̀ pé ẹni tó fẹ́ sọ àsọyé ti wà ní sẹpẹ́. A tún mọ̀ pé àwọn ìwé tá a máa fi wàásù ti wà nílẹ̀. Àwọn arákùnrin olóòótọ́ yìí ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ wa gan-an, a sì ń dúpẹ́ pé Jèhófà fi wọ́n jíǹkí wa! Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tó máa fi hàn pé a ṣeé fọkàn tán?
MÁA PA ÀṢÍRÍ MỌ́ KÁWỌN ÈÈYÀN LÈ FỌKÀN TÁN Ẹ
8. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká ṣàṣejù tá a bá fẹ́ ran ẹnì kan lọ́wọ́? (Òwe 11:13)
8 A nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a ò sì fẹ́ kí nǹkan kan ṣe wọ́n. Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká ṣàṣejù, kò sì yẹ ká tojú bọ ọ̀rọ̀ wọn. Àwọn kan nínú ìjọ Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ “ń ṣòfófó, wọ́n sì ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀, wọ́n ń sọ àwọn nǹkan tí kò yẹ kí wọ́n sọ.” (1 Tím. 5:13) Ó dájú pé a ò ní fẹ́ ṣe bíi tiwọn. Àmọ́ ká sọ pé ẹnì kan sọ ọ̀rọ̀ àṣírí fún wa ńkọ́, tó sì sọ pé ká má sọ fáwọn èèyàn? Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan lè sọ ìṣòro àìsàn tó ní fún wa tàbí ìṣòro míì tó ní, ó sì sọ fún wa pé ká má sọ̀rọ̀ náà fún ẹlòmíì. Ó yẹ ká ṣe ohun tó sọ. * (Ka Òwe 11:13.) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ipò míì tó ti ṣe pàtàkì pé ká pa àṣírí mọ́.
9. Báwo lẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé ṣe lè fi hàn pé òun ṣeé fọkàn tán?
9 Máa pa àṣírí mọ́ nínú ìdílé. Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé ló yẹ kó máa pa ọ̀rọ̀ àṣírí ìdílé wọn mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìyàwó arákùnrin kan lè ní ìwà kan tó máa ń pa ọkọ ẹ̀ lẹ́rìn-ín. Àmọ́, ṣé ó yẹ kó sọ ọ̀rọ̀ náà fáwọn èèyàn, kó sì wá kó ìtìjú bá ìyàwó ẹ̀? Kò yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀! Ó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀, kò sì ní fẹ́ ṣe ohun tó máa bà á nínú jẹ́. (Éfé. 5:33) Àwọn ọ̀dọ́ máa ń fẹ́ ká bọ̀wọ̀ fáwọn náà. Ó yẹ káwọn òbí fi kókó yìí sọ́kàn, torí ọ̀wọ̀ díẹ̀díẹ̀ lara ń fẹ́. Kò yẹ káwọn òbí máa sọ àṣìṣe ọmọ wọn fáwọn èèyàn torí ìyẹn máa kó ìtìjú bá àwọn ọmọ náà. (Kól. 3:21) Ó yẹ káwọn ọmọ náà gbọ́n, kò sì yẹ kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ àṣírí ìdílé wọn fáwọn èèyàn torí ìyẹn lè kó ìtìjú bá àwọn ará ilé wọn. (Diu. 5:16) Torí náà, tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé bá ń ṣe ipa tiẹ̀ láti pa ọ̀rọ̀ àṣírí mọ́, ìdílé wọn á túbọ̀ wà níṣọ̀kan.
10. Kí ni ọ̀rẹ́ gidi gbọ́dọ̀ máa ṣe? (Òwe 17:17)
10 Máa pa àṣírí mọ́ láàárín ìwọ àti ọ̀rẹ́ ẹ. Nígbà míì, ó lè gba pé ká sọ ohun tó ń ṣe wá fún ẹnì kan tá a jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kára lè tù wá. Ká sòótọ́, kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Ó lè má mọ́ wa lára láti máa sọ̀rọ̀ àṣírí wa fún ẹnikẹ́ni torí a mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ náà fún ẹlòmíì, ìyẹn sì máa dùn wá gan-an. Àmọ́, a máa ń mọyì “ọ̀rẹ́ tòótọ́” tó lè pa àṣírí mọ́.—Ka Òwe 17:17.
11. (a) Kí ló yẹ káwọn alàgbà àtàwọn ìyàwó wọn máa ṣe táá jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wọn? (b) Kí la kọ́ lára alàgbà kan tó pa dà sílé lẹ́yìn tó lọ bójú tó ọ̀rọ̀ àṣírí kan nínú ìjọ? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
11 Máa pa àṣírí mọ́ nínú ìjọ. Àwọn alàgbà tó máa ń pa àṣírí àwọn ará ìjọ mọ́ dà bí “ibi tó ṣeé fara pa mọ́ sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù [àti] ibi ààbò.” (Àìsá. 32:2) Kò sí nǹkan tá ò lè bá wọn sọ torí a mọ̀ pé wọ́n máa ń pa àṣírí mọ́. Kò yẹ ká máa fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n sọ̀rọ̀ àṣírí fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, a mọyì ìyàwó àwọn alàgbà wa torí wọn kì í lọ́ ọkọ wọn nífun kí wọ́n lè sọ̀rọ̀ àṣírí fún wọn. Ká sòótọ́, ara máa tu ìyàwó alàgbà tí ọkọ ẹ̀ ò bá sọ̀rọ̀ àṣírí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin fún un. Ìyàwó alàgbà kan sọ pé: “Mo dúpẹ́ pé ọkọ mi kì í sọ̀rọ̀ àṣírí àwọn tí wọ́n lọ bẹ̀ wò nígbà ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn tàbí àwọn tí wọ́n lọ fi Bíbélì ràn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà, kódà kì í sọ orúkọ wọn fún mi. Mo dúpẹ́ pé mi ò kì í yọ ara mi lẹ́nu lórí ọ̀rọ̀ tí ò kàn mí, tó jẹ́ pé àwọn alàgbà nìkan ló lè yanjú ẹ̀. Ìyẹn ti jẹ́ kí n lè máa bá gbogbo èèyàn sọ̀rọ̀ fàlàlà nínú ìjọ. Ó tún ti jẹ́ kí n fọkàn tán ọkọ mi pé tí mo bá sọ̀rọ̀ àṣírí mi fún un, kò ní sọ fún ẹlòmíì.” Ká sòótọ́, gbogbo wa ló yẹ káwọn èèyàn mọ̀ sí ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Àwọn nǹkan wo ló máa mú ká jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán? Ẹ jẹ́ ká gbé márùn-ún lára wọn yẹ̀ wò.
MÁA ṢE NǸKAN TÁÁ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN FỌKÀN TÁN Ẹ
12. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn kí wọ́n tó lè fọkàn tán wa? Sọ àpẹẹrẹ kan.
12 Nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, wọ́n á fọkàn tán wa. Jésù sọ pé àṣẹ méjì tó tóbi jù lọ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti ọmọnìkejì wa. (Mát. 22:37-39) A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà torí pé ó ṣeé fọkàn tán, ó sì yẹ ká fara wé e. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa náà, a máa ń pa ọ̀rọ̀ àṣírí wọn mọ́. Torí náà, kò yẹ ká sọ ohunkóhun tó máa kó ẹ̀dùn ọkàn àti ìtìjú bá wọn, tó sì máa dùn wọ́n gan-an.—Jòh. 15:12.
13. Báwo ni ìrẹ̀lẹ̀ ṣe máa jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa?
13 Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, àwọn èèyàn máa fọkàn tán wa. Tí Kristẹni kan bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kì í ṣe ẹnu ẹ̀ làwọn èèyàn á ti kọ́kọ́ máa gbọ́ ọ̀rọ̀ àṣírí torí káwọn èèyàn lè gba tiẹ̀. (Fílí. 2:3) Kò ní máa ṣe fọ́rífọ́rí pé òun mọ ọ̀rọ̀ àṣírí táwọn ẹlòmíì ò mọ̀ tó sì jẹ́ pé kò lè sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ síta. Bákan náà, tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, a ò ní máa tan ọ̀rọ̀ kan tí ò jóòótọ́ kálẹ̀ tó sì jẹ́ pé Bíbélì àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run ò ṣàlàyé kankan nípa ẹ̀.
14. Tá a bá jẹ́ olóye, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa?
14 Jẹ́ olóye. Tí Kristẹni kan bá jẹ́ olóye, ó gbọ́dọ̀ mọ ‘ìgbà tó yẹ kéèyàn dákẹ́ àti ìgbà tó yẹ kéèyàn sọ̀rọ̀.’ (Oníw. 3:7) Àwọn kan máa ń sọ pé: “Ẹyin lohùn, tó bá ti bọ́ kì í ṣeé kó mọ́.” Ìyẹn ni pé, àwọn àkókò kan wà tó sàn kéèyàn dákẹ́ ju kó sọ̀rọ̀ lọ. Ìdí nìyẹn tí Òwe 11:12 fi sọ fún wa pé: “Ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa ń dákẹ́.” Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí. Alàgbà tó nírìírí kan wà tí wọ́n sábà máa ń sọ fún pé kó lọ ran àwọn ìjọ tó níṣòro lọ́wọ́. Nígbà tí alàgbà míì ń sọ̀rọ̀ nípa alàgbà yẹn, ó ní: “Ó máa ń kíyè sára gan-an kó má bàa sọ̀rọ̀ àṣírí àwọn ìjọ yẹn síta.” Torí pé alàgbà yẹn jẹ́ olóye, ìyẹn jẹ́ káwọn alàgbà yòókù tí wọ́n jọ wà níjọ máa bọ̀wọ̀ fún un. Ó dá wọn lójú pé kò ní sọ̀rọ̀ àṣírí ìjọ wọn fáwọn èèyàn.
15. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé tá a bá jẹ́ olóòótọ́, àwọn èèyàn máa fọkàn tán wa.
15 Jẹ́ olóòótọ́. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́, àwọn èèyàn máa fọkàn tán wa. A máa ń fọkàn tán ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ torí a mọ̀ pé gbogbo ìgbà ló máa ń sòótọ́. (Éfé. 4:25; Héb. 13:18) Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé o fẹ́ mú ọ̀nà tó ò ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ dáa sí i. O lè sọ fún ẹnì kan pé kó gbọ́ àsọyé ẹ, kó o lè mọ ibi tó yẹ kó o ti ṣàtúnṣe. Ta lo rò pé ó ṣeé fọkàn tán, tó máa sòótọ́ fún ẹ? Ṣé ẹni tó kàn máa sọ̀rọ̀ tó dùn fún ẹ lo máa lọ bá àbí ẹni tó máa sòótọ́ fún ẹ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ? Ó dájú pé ẹni tó máa sòótọ́ fún ẹ ni. Bíbélì sọ pé: “Ìbáwí tí a fúnni níta sàn ju ìfẹ́ tí a fi pa mọ́ lọ. Àwọn ọgbẹ́ tí ọ̀rẹ́ dá síni lára jẹ́ ìṣòtítọ́.” (Òwe 27:5, 6) Òótọ́ tí ọ̀rẹ́ wa sọ fún wa lè má kọ́kọ́ bá wa lára mu, àmọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn lè wá ṣe wá láǹfààní nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.
16. Kí ni Òwe 10:19 sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká máa kó ara wa níjàánu?
16 Máa kó ara ẹ níjàánu. Tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa, a gbọ́dọ̀ máa kó ara wa níjàánu. Tá a bá fi kókó yìí sọ́kàn, á jẹ́ ká lè máa pa ọ̀rọ̀ àṣírí tẹ́nì kan sọ fún wa mọ́. (Ka Òwe 10:19.) Ó lè ṣòro fún wa láti kó ara wa níjàánu nígbà tá a bá ń lo ìkànnì àjọlò. Tá ò bá ṣọ́ra, a lè sọ̀rọ̀ àṣírí kan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lórí ìkànnì láì mọ̀ọ́mọ̀. Táwọn èèyàn bá sì ti mọ ọ̀rọ̀ àṣírí náà, a ò mọ ohun tí wọ́n lè fi ṣe àti jàǹbá tó lè fà. Bákan náà, táwọn alátakò bá ń dọ́gbọ́n tó máa mú ká sọ̀rọ̀ àṣírí tó máa ṣàkóbá fáwọn ará, ó yẹ ká kó ara wa níjàánu, ká má sì sọ nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ táwọn ọlọ́pàá bá ń fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa tàbí tí wọ́n ti ń dí iṣẹ́ wa lọ́wọ́. Tá a bá bá ara wa nírú ipò yìí àti láwọn ipò míì, a lè lo ìlànà Bíbélì tó sọ pé ká “fi ìbonu bo ẹnu” wa. (Sm. 39:1) Ó yẹ ká máa ṣe ohun táá jẹ́ kí gbogbo èèyàn fọkàn tán wa, títí kan àwọn ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tàbí àwọn ẹlòmíì. Torí náà, tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa, a gbọ́dọ̀ máa kó ara wa níjàánu.
17. Kí ló yẹ ká máa ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ máa fọkàn tán ara wa nínú ìjọ?
17 A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá pé Jèhófà jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ àti pé a wà lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kárí ayé tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì fọkàn tán ara wọn! Gbogbo wa ló yẹ ká máa ṣe ohun táá jẹ́ káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa fọkàn tán wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fìfẹ́ hàn, ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká jẹ́ olóye, ká jẹ́ olóòótọ́, ká sì máa kó ara wa níjàánu. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká túbọ̀ máa fọkàn tán ara wa nínú ìjọ. Ìgbà gbogbo la gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fara wé Jèhófà Ọlọ́run, ká sì máa ṣe ohun tó fi hàn pé a ṣeé fọkàn tán.
ORIN 123 Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run
^ Tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa, a gbọ́dọ̀ máa ṣohun tó fi hàn pé a ṣeé fọkàn tán. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fọkàn tán ara wa. Bákan náà, a máa mọ àwọn nǹkan táá jẹ́ káwọn ẹlòmíì fọkàn tán wa.
^ Tá a bá mọ ẹnì kan nínú ìjọ tó dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, ó yẹ ká gbà á níyànjú pé kó lọ sọ fáwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́. Tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwa fúnra wa máa lọ sọ ọ̀rọ̀ náà fáwọn alàgbà torí a fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ìjọ.
^ ÀWÒRÁN: Alàgbà kan ò sọ̀rọ̀ àṣírí tó lọ bójú tó fún ìdílé ẹ̀ nígbà tó délé.