Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 40

‘Wọ́n Ń Sọ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Di Olódodo’

‘Wọ́n Ń Sọ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Di Olódodo’

“Àwọn tí wọ́n . . . ń mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo máa tàn bí ìràwọ̀, títí láé àti láéláé.”—DÁN. 12:3.

ORIN 151 Òun Yóò Pè

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Àwọn nǹkan àgbàyanu wo ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?

 Ẹ Ò RÍ I pé ọjọ́ àgbàyanu lọjọ́ yẹn máa jẹ́ nígbà tí Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀ sí í jí àwọn èèyàn dìde nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi! Gbogbo àwọn téèyàn wọn ti kú lara wọn á ti wà lọ́nà láti rí àwọn èèyàn wọn tó ti kú. Bó ṣe rí lára Jèhófà náà nìyẹn. (Jóòbù 14:15) Ẹ wo bínú àwọn èèyàn ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn èèyàn wọn tó ti kú. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, “àwọn olódodo” tórúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè máa ní “àjíǹde ìyè.” (Ìṣe 24:15; Jòh. 5:29) Ó sì ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn wa wà lára àwọn tó máa kọ́kọ́ jí dìde sí ayé lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì. * Yàtọ̀ síyẹn, “àwọn aláìṣòdodo” ìyẹn àwọn tí kò láǹfààní láti mọ Jèhófà tàbí láti jọ́sìn ẹ̀ kí wọ́n tó kú máa ní “àjíǹde ìdájọ́.”

2-3. (a) Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá ò ṣerú ẹ̀ rí wo ni Àìsáyà 11:9, 10 sọ pé ó máa wáyé nínú ayé tuntun? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Gbogbo àwọn tó bá jí dìde la máa dá lẹ́kọ̀ọ́. (Àìsá. 26:9; 61:11) Torí náà, a máa bẹ̀rẹ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá ò ṣerú ẹ̀ rí nínú ìtàn aráyé. (Ka Àìsáyà 11:9, 10.) Kí nìdí? Ìdí kan ni pé àwọn tó bá jíǹde máa ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù Kristi, ohun tí Ìjọba Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé, ìràpadà, bí Jèhófà ṣe máa dá orúkọ ẹ̀ láre àti ìdí tó fi jẹ́ pé òun nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Kódà, nígbà táwọn olódodo náà bá jíǹde, wọ́n máa ní láti kẹ́kọ̀ọ́ àwọn nǹkan tí Jèhófà ti jẹ́ káwọn èèyàn ẹ̀ mọ̀ nípa ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé. Àwọn kan lára wọn ti kú tipẹ́tipẹ́ kí Bíbélì tó wà lódindi. Ẹ ò rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn olódodo àtàwọn aláìṣòdodo máa ní láti kọ́ nínú ayé tuntun.

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Báwo la ṣe máa ṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá ò ṣe irú ẹ̀ rí yìí? Báwo ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣe máa pinnu bóyá orúkọ ẹnì kan máa wà nínú ìwé ìyè títí láé tàbí kò ní sí níbẹ̀? Àwọn ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì gan-an, ó sì yẹ ká wá ìdáhùn wọn. Bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wà nínú ìwé Dáníẹ́lì àti ìwé Ìfihàn tó jẹ́ ká ṣàtúnṣe òye wa nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà àjíǹde. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 12:1, 2.

“ÀWỌN TÓ Ń SÙN NÍNÚ ERÙPẸ̀ . . . MÁA JÍ”

4-5. Kí ni Dáníẹ́lì 12:1 sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lákòókò òpin?

4 Ka Dáníẹ́lì 12:1. Ìwé Dáníẹ́lì jẹ́ ká mọ bí àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lásìkò òpin yìí ṣe máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra wọn. Bí àpẹẹrẹ, Dáníẹ́lì 12:1 sọ pé Jésù Kristi tó jẹ́ Máíkẹ́lì “dúró nítorí àwọn èèyàn” Ọlọ́run. Apá kan lára àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ti ṣẹ nígbà tí Jésù di Ọba Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1914.

5 Àmọ́ nínú ìran tí Dáníẹ́lì rí, áńgẹ́lì kan tún sọ fún un pé Jésù “máa dìde” ní ‘àkókò wàhálà, èyí tí irú rẹ̀ kò wáyé rí látìgbà tí orílẹ̀-èdè ti wà títí di àkókò yẹn.’ “Àkókò wàhálà” náà ni Mátíù 24:21 pè ní “ìpọ́njú ńlá.” Jésù máa dìde láti gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ ní òpin àkókò wàhálà náà, ìyẹn nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Ìwé Ìfihàn pe àwọn èèyàn tí Jésù máa gbèjà ní ogunlọ́gọ̀ èèyàn “tó wá látinú ìpọ́njú ńlá náà.”—Ìfi. 7:9, 14.

6. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ogunlọ́gọ̀ èèyàn bá la ìpọ́njú ńlá já? Ṣàlàyé. (Tún wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” inú Ilé Ìṣọ́ yìí tó sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde sí ayé.)

6 Ka Dáníẹ́lì 12:2. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn bá ti la àkókò wàhálà náà já? Àlàyé tá a ṣe nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ ni pé àjíǹde ìṣàpẹẹrẹ tàbí bí àwa èèyàn Ọlọ́run ṣe rí okun gbà pa dà láti máa jọ́sìn Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ló ń sọ nípa ẹ̀. * Àmọ́, ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ kọ́ nìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àjíǹde tó máa wáyé nínú ayé tuntun ló ń sọ nípa ẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé wọ́n tún lo ọ̀rọ̀ náà “iyẹ̀pẹ̀” ìyẹn erùpẹ̀ nínú Jóòbù 17:16, ohun kan náà lòun àti “Isà Òkú” sì jẹ́. Èyí fi hàn pé àjíǹde tí Dáníẹ́lì 12:2 ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ máa wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn bá ti dópin àti lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì.

7. (a) Báwo làwọn kan ṣe máa jíǹde sí “ìyè àìnípẹ̀kun”? (b) Báwo ló sì ṣe jẹ́ “àjíǹde tó dáa jù”?

7 Kí ni Dáníẹ́lì 12:2 ń sọ nígbà tó ní wọ́n máa jí àwọn èèyàn kan dìde sí “ìyè àìnípẹ̀kun”? Ohun tó ń sọ ni pé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àwọn tí wọ́n jí dìde, tí wọ́n ti mọ Jèhófà, tí wọ́n sì ti pinnu pé àwọn á máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà nìṣó àti pé àwọn á máa gbọ́ràn sí òun àti Jésù lẹ́nu ló máa gba ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 17:3) “Àjíǹde tó dáa jù” ló máa jẹ́ torí ó yàtọ̀ sáwọn àjíǹde tó ti wáyé ṣáájú àkókò yìí. (Héb. 11:35) Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn èèyàn aláìpé tó jíǹde nígbà yẹn pa dà kú.

8. Báwo la ṣe máa jí àwọn kan dìde “sí ẹ̀gàn àti sí ìkórìíra ayérayé”?

8 Àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn tí Jèhófà bá jí dìde ló máa fara mọ́ ohun tí wọ́n bá ń kọ́ wọn. Dáníẹ́lì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa jí àwọn kan dìde “sí ẹ̀gàn àti sí ìkórìíra ayérayé.” Torí pé wọ́n máa ya ọlọ̀tẹ̀, orúkọ wọn ò ní sí nínú ìwé ìyè, wọn ò sì ní gba ìyè àìnípẹ̀kun. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ìkórìíra ayérayé” tàbí ìparun yán-án yán-án ni wọ́n máa gbà. Torí náà, ohun tí Dáníẹ́lì 12:2 ń sọ ni pé, ohun táwọn tó jí dìde bá ṣe lẹ́yìn tá a jí wọn dìde ló máa pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. * (Ìfi. 20:12) Àwọn kan máa gba ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn kan á sì pa run.

‘WỌ́N Ń SỌ Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ DI OLÓDODO’

9-10. Nǹkan míì wo ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá, àwọn wo ló sì “máa tàn yinrin bí òfúrufú”?

9 Ka Dáníẹ́lì 12:3. Nǹkan míì wo ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí “àkókò wàhálà” tó ń bọ̀ bá dópin? Lẹ́yìn tí Dáníẹ́lì 12:2 sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó jíǹde, ẹsẹ kẹta wá sọ nǹkan míì tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá.

10 Àwọn wo ló “máa tàn yinrin bí òfúrufú”? A rí ìdáhùn ìbéèrè yìí nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 13:43, ó sọ pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo máa tàn yòò bí oòrùn nínú Ìjọba Baba wọn.” Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ọmọ Ìjọba náà,” ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró tó máa bá a ṣàkóso nínú Ìjọba ọ̀run. (Mát. 13:38) Torí náà, àwọn ẹni àmì òróró àti iṣẹ́ tí wọ́n máa ṣe nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi ni Dáníẹ́lì 12:3 ń sọ nípa ẹ̀.

Àwọn ẹni àmì òróró máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jésù Kristi láti darí ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó máa wáyé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi (Wo ìpínrọ̀ 11)

11-12. Iṣẹ́ wo làwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa ṣe nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?

11 Báwo làwọn ẹni àmì òróró ṣe máa sọ ‘ọ̀pọ̀lọpọ̀ di olódodo?’ Àwọn ẹni àmì òróró máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jésù Kristi láti darí ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó máa wáyé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Yàtọ̀ sí pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa jẹ́ ọba, wọ́n á tún jẹ́ àlùfáà. (Ìfi. 1:6; 5:10; 20:6) Torí náà, wọ́n máa ṣèrànwọ́ láti mú “àwọn orílẹ̀-èdè lára dá.” Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n á sọ aráyé di pípé. (Ìfi. 22:1, 2; Ìsík. 47:12) Ẹ ò rí i pé inú àwọn ẹni àmì òróró máa dùn gan-an!

12 Àwọn wo ló máa wà lára “ọ̀pọ̀lọpọ̀” tí wọ́n máa sọ di olódodo? Àwọn tó bá jíǹde àtàwọn tó bá la Amágẹ́dọ́nì já ni, títí kan àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí nínú ayé tuntun. Nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá máa fi parí, gbogbo èèyàn tó wà láyé á ti di pípé. Torí náà, ìgbà wo ni Jèhófà máa kọ orúkọ wọn sínú ìwé ìyè tí kò sì ní ṣeé pa rẹ́ mọ́?

ÌDÁNWÒ ÌKẸYÌN

13-14. Kí ni gbogbo àwọn ẹni pípé tó wà láyé gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n tó lè gba ìyè àìnípẹ̀kun?

13 Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé torí ẹnì kan ti di pípé kò sọ pé ọwọ́ ẹni náà ti tẹ ìyè àìnípẹ̀kun nìyẹn. Ṣé ẹ rántí Ádámù àti Éfà? Ẹni pípé ni wọ́n, àmọ́ kí Jèhófà tó lè fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n jẹ́ onígbọràn sí i. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé wọn ò gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu.—Róòmù 5:12.

14 Irú ẹni wo làwọn tó bá wà láyé lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi máa jẹ́? Gbogbo wọn á ti di pípé. Ṣé gbogbo àwọn ẹni pípé yẹn ló máa fara mọ́ àkóso Jèhófà títí láé? Àbí àwọn kan máa dà bí Ádámù àti Éfà tí wọ́n di aláìṣòótọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni wọ́n? Ó yẹ ká dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

15-16. (a) Ìgbà wo ni gbogbo èèyàn máa láǹfààní láti fi hàn pé àwọn fẹ́ kí Jèhófà máa ṣàkóso àwọn? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìdánwò ìkẹyìn náà?

15 Jèhófà máa fi Sátánì sẹ́wọ̀n ẹgbẹ̀rún ọdún (1,000) kan, kò sì ní lè ṣi àwọn èèyàn lọ́nà lásìkò yẹn. Àmọ́ tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá parí, Jèhófà máa tú u sílẹ̀. Á wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbìyànjú láti ṣi àwọn èèyàn pípé lọ́nà. Lásìkò ìdánwò yẹn, gbogbo àwọn èèyàn pípé ló máa láǹfààní láti fi hàn bóyá Jèhófà ni wọ́n fẹ́ kó máa ṣàkóso wọn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (Ìfi. 20:7-10) Ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ṣe ló máa pinnu bóyá orúkọ wọn máa wà nínú ìwé ìyè títí láé àbí kò ní sí níbẹ̀.

16 Bíbélì sọ pé àwọn kan máa jẹ́ aláìṣòótọ́ bíi ti Ádámù àti Éfà, wọn ò sì ní fara mọ́ àkóso Jèhófà. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn? Ìfihàn 20:15 sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ní: “A ju ẹnikẹ́ni tí a kò rí i pé wọ́n kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè sínú adágún iná náà.” Àbẹ́ ò rí nǹkan, gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí ló máa pa run yán-án yán-án. Àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn pípé máa yege ìdánwò ìkẹyìn. Lẹ́yìn náà, orúkọ wọn máa wà nínú ìwé ìyè títí láé, kò sì ní ṣe é pa rẹ́ mọ́.

“ÀKÓKÒ ÒPIN”

17. Kí ni áńgẹ́lì kan sọ fún Dáníẹ́lì pé ó máa ṣẹlẹ̀ lásìkò wa yìí? (Dáníẹ́lì 12:4, 8-10)

17 Inú wa ń dùn bá a ṣe ń ronú nípa àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn! Àmọ́, áńgẹ́lì yẹn tún sọ fún Dáníẹ́lì nípa àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ ní “àkókò òpin.” (Ka Dáníẹ́lì 12:4, 8-10; 2 Tím. 3:1-5) Áńgẹ́lì náà sọ fún Dáníẹ́lì pé: ‘Ìmọ̀ tòótọ́ máa pọ̀ gan-an.’ Tó bá dìgbà yẹn, àwọn èèyàn Ọlọ́run máa túbọ̀ lóye àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì. Áńgẹ́lì yẹn sọ pé lásìkò yẹn, “àwọn ẹni burúkú máa hùwà burúkú, kò sì ní yé ìkankan nínú àwọn ẹni burúkú.”

18. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn burúkú láìpẹ́?

18 Lónìí, ó lè jọ pé àwọn èèyàn burúkú ń mú iṣẹ́ ọwọ́ wọn jẹ. (Mál. 3:14, 15) Àmọ́ láìpẹ́, Jésù máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn tó fìwà jọ ewúrẹ́, á sì yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tó fìwà jọ àgùntàn. (Mát. 25:31-33) Àwọn èèyàn burúkú yìí ò ní la ìpọ́njú ńlá já, Jèhófà ò sì ní jí wọn dìde sínú ayé tuntun. Orúkọ wọn ò ní sí nínú “ìwé ìrántí” tí Málákì 3:16 sọ nípa ẹ̀.

19. Kí ló yẹ ká ṣe báyìí, kí sì nìdí? (Málákì 3:16-18)

19 Àsìkò yìí gan-an ló yẹ kó máa hàn nínú ìwà wa pé a ò sí lára àwọn èèyàn burúkú. (Ka Málákì 3:16-18.) Jèhófà ti ń kó àwọn tó kà sí “ohun ìní [ẹ̀] pàtàkì” jọ báyìí. Ó sì dájú pé gbogbo wa la fẹ́ wà lára wọn.

Ẹ ò rí bí inú wa ṣe máa dùn tó nígbà tí Dáníẹ́lì, àwọn èèyàn wa àtàwọn èèyàn míì tó ti kú bá jí “dìde” láti gba ìpín wọn nínú ayé tuntun! (Wo ìpínrọ̀ 20)

20. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún Dáníẹ́lì kẹ́yìn, kí sì nìdí tó o fi ń retí ìgbà tí Jèhófà máa mú ìlérí yẹn ṣẹ?

20 Lóòótọ́, àsìkò táwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ tẹ̀ léra wọn là ń gbé yìí. Àmọ́, àwọn nǹkan àgbàyanu tó jùyẹn lọ máa tó ṣẹlẹ̀. Láìpẹ́, kò ní sí ẹnì kankan tó máa hùwà ibi mọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Dáníẹ́lì máa ṣẹ pé: “Wàá dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.” (Dán. 12:13) Ṣé ò ń retí ìgbà tí Dáníẹ́lì àtàwọn èèyàn ẹ tó ti kú máa pa dà jí “dìde”? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣe gbogbo nǹkan tó o lè ṣe, kó o sì jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé orúkọ ẹ máa wà nínú ìwé ìyè títí láé.

ORIN 80 ‘Tọ́ Ọ Wò, Kó O sì Rí I Pé Ẹni Rere Ni Jèhófà’

^ Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ òye tuntun tá a ní nípa ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó gbòòrò jù lọ tí Dáníẹ́lì 12:2, 3 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. A máa sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí máa wáyé, àwọn tó máa dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn tá a máa dá lẹ́kọ̀ọ́. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣe máa múra àwọn tó wà láyé sílẹ̀ kí wọ́n lè yege ìdánwò ìkẹyìn lẹ́yìn tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá parí.

^ Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn tó bá kú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ló máa kọ́kọ́ jíǹde. Lẹ́yìn náà, àwọn tó kú ṣáájú wọn tí wọ́n sì gbé ayé lásìkò kan náà á máa jíǹde tẹ̀ léra wọn títí tó máa fi kan àwọn tó gbé ayé nígbà ayé Ébẹ́lì. Tó bá jẹ́ pé bí Jèhófà ṣe máa ṣe é nìyẹn, á jẹ́ pé àwọn tó gbé ayé lásìkò kan náà máa láǹfààní láti rí àwọn tí wọ́n mọ̀, wọ́n á sì lè kí wọn káàbọ̀. Èyí ó wù ó jẹ́, nígbà tí Ìwé Mímọ́ ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde ti ọ̀run, ó sọ pé kálukú máa jíǹde ní “àyè rẹ̀.” Torí náà, ó ṣeé ṣe káwọn tó máa jíǹde sí ayé náà jíǹde tẹ̀ léra wọn.—1 Kọ́r. 14:33; 15:23.

^ Àlàyé yìí jẹ́ àtúnṣe ohun tá a ṣàlàyé nínú ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! orí 17 àti Ilé Ìṣọ́ July 1, 1987, ojú ìwé 21-25.

^ Àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ náà “àwọn olódodo” àti “àwọn aláìṣòdodo” tó wà nínú Ìṣe 24:15 àtàwọn ọ̀rọ̀ náà “àwọn tó ṣe ohun rere” àti “àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà” tó wà nínú Jòhánù 5:29 ń sọ nípa ohun táwọn tó jíǹde ṣe kí wọ́n tó kú.