Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “ẹni tí a bí ní kògbókògbó” lòun? (1 Kọ́ríńtì 15:8)
Pọ́ọ̀lù sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 15:8 pé: “Ní paríparí rẹ̀, ó fara han èmi náà bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó.” Àlàyé tá a ṣe nípa ẹsẹ Bíbélì yìí tẹ́lẹ̀ ni pé ìran tí Pọ́ọ̀lù rí nípa Jésù nígbà tó wà lọ́run ló ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ṣe ló dà bí ẹni pé Pọ́ọ̀lù láǹfààní láti di ẹni tá a bí tàbí tá a jí dìde sí ọ̀run ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú àkókò tó yẹ kó ṣẹlẹ̀. Àmọ́ nígbà tá a ṣèwádìí sí i nípa ẹsẹ Bíbélì yìí, a rí i pé ó yẹ ká ṣàtúnṣe àlàyé tá a ṣe nípa ẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Òótọ́ ni pé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù di Kristẹni ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ. Àmọ́ kí ló wá ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “ẹni tí a bí ní kògbókògbó” lòun? Onírúurú nǹkan ló ṣeé ṣe kó ní lọ́kàn.
Òjijì ló di Kristẹni, nǹkan sì nira fún un. Ó máa ń ya àwọn òbí lẹ́nu tí wọ́n bá bí ọmọ kan ṣáájú àsìkò tó yẹ kí wọ́n bí i. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù (tá a wá mọ̀ sí Pọ́ọ̀lù nígbà tó yá) ń lọ sí Damásíkù kó lè lọ ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀, kò retí pé òun máa rí Jésù tá a jí dìde nínú ìran. Ìyàlẹ́nu ńlá gbáà ló jẹ́ fún Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni tó fẹ́ lọ ṣe inúnibíni sí nílùú yẹn nígbà tó di Kristẹni. Yàtọ̀ síyẹn, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù ò rọrùn fún un rárá, kódà ó fọ́ lójú fúngbà díẹ̀.—Ìṣe 9:1-9, 17-19.
Ó di Kristẹni “ṣáájú àkókò tó yẹ.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ẹni tí a bí ní kògbókògbó” tún lè túmọ̀ sí “ẹni tí a bí ṣáájú àkókò tó yẹ.” Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀ sọ pé: “Mo dà bí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé.” Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi máa di Kristẹni, Jésù ti pa dà sọ́run. Gbogbo àwọn tí Pọ́ọ̀lù dárúkọ ṣáájú ẹsẹ yìí ló rí, àmọ́ kò rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde kó tó lọ sọ́run. (1 Kọ́r. 15:4-8) Torí náà, bí Jésù ṣe fara han Pọ́ọ̀lù lójijì fún un láǹfààní láti rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde, bó tiẹ̀ jẹ́ pé òjijì ló di Kristẹni.
Ìrẹ̀lẹ̀ ló mú kí Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó sọ. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò níbí máa ń buni kù. Tó bá jẹ́ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nìyẹn, á jẹ́ pé ohun tó ń sọ ni pé òun ò yẹ lẹ́ni tó ń di àpọ́sítélì. Kódà, ó tún sọ pé: “Èmi ló kéré jù nínú àwọn àpọ́sítélì, mi ò sì yẹ lẹ́ni tí à ń pè ní àpọ́sítélì, torí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run. Àmọ́ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́.”—1 Kọ́r. 15:9, 10.
Torí náà, ó jọ pé bí Jésù ṣe fara han Pọ́ọ̀lù lójijì, bó ṣe di Kristẹni láìrò tẹ́lẹ̀ àti bó ṣe rò pé òun ò yẹ lẹ́ni tó ń rí Jésù nínú ìran ló mú kí Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó sọ yẹn. Èyí ó wù ó jẹ́, ó dájú pé Pọ́ọ̀lù mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún un gan-an. Ìran yẹn jẹ́ kó dá a lójú háún-háún pé Jésù ti jíǹde. Abájọ tó fi sábà máa ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn fáwọn èèyàn tó bá ń wàásù nípa àjíǹde Jésù.—Ìṣe 22:6-11; 26:13-18.