Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 40

Bíi Ti Pétérù, Má Jẹ́ Kó Sú Ẹ

Bíi Ti Pétérù, Má Jẹ́ Kó Sú Ẹ

“Kúrò lọ́dọ̀ mi, Olúwa, torí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.”—LÚÙKÙ 5:8.

ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Kí ni Pétérù ṣe lẹ́yìn tí Jésù jẹ́ kó rí ọ̀pọ̀ ẹja pa lọ́nà ìyanu?

 GBOGBO òru ni Pétérù fi wá ẹja tó fẹ́ pa, àmọ́ kò rí nǹkan kan pa. Ó yà á lẹ́nu nígbà tí Jésù sọ fún un pé: “Wa ọkọ̀ lọ síbi tí omi ti jìn, kí ẹ sì rọ àwọ̀n yín sísàlẹ̀ láti kó ẹja.” (Lúùkù 5:4) Pétérù ò gbà pé òun lè rí ẹja kankan pa, àmọ́ ó ṣe ohun tí Jésù ní kó ṣe. Ẹja tí Pétérù àtàwọn tó wà pẹ̀lú ẹ̀ rí kó pọ̀ débi pé ṣe ni àwọ̀n náà bẹ̀rẹ̀ sí í fà ya. Nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, ‘ẹnu yà’ wọ́n gan-an. Ni Pétérù bá pariwo pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Olúwa, torí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.” (Lúùkù 5:​6-9) Ó ṣeé ṣe kí Pétérù máa ronú pé òun ò yẹ lẹ́ni tó ń wà lọ́dọ̀ Jésù.

2. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ lára Pétérù?

2 Òótọ́ ni Pétérù sọ torí pé “ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.” Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Pétérù ṣe àwọn nǹkan kan, ó sì sọ àwọn nǹkan kan tó kábàámọ̀ ẹ̀ nígbà tó yá. Ṣé irú ẹ̀ ti ṣe ìwọ náà rí? Ṣé o láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ò ń bá yí àbí àwọn ìwà kan tó wù ẹ́ kó o ti fi sílẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Pétérù máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Lọ́nà wo? Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Jèhófà lè mú kí wọ́n má kọ àwọn àṣìṣe tí Pétérù ṣe sínú Bíbélì, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Dípò ìyẹn, ó jẹ́ káwọn àṣìṣe yẹn wà lákọsílẹ̀ ká lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú wọn. (2 Tím. 3:​16, 17) Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ lára ọkùnrin tó jẹ́ aláìpé tó sì mọ nǹkan lára bíi tiwa yìí, àá rí i pé Jèhófà ò retí pé ká jẹ́ ẹni pípé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, tá a sì láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tá à ń bá yí, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, ká má sì jẹ́ kó sú wa.

3. Kí nìdí tí ò fi yẹ kó sú wa?

3 Kí nìdí tí ò fi yẹ kó sú wa? Àwọn kan máa ń sọ pé kíkọ́ ni mímọ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná: Kí olórin kan tó mọ gìtá ta dáadáa, ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún. Lásìkò yẹn, ó lè ṣe ọ̀pọ̀ àṣìṣe, àmọ́ tó bá tẹra mọ́ ọn, á mọ̀ ọ́n ta dáadáa tó bá yá. Kódà tó bá ti wá mọ̀ ọ́n ta, á ṣì máa ṣàṣìṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, kò ní jẹ́ kó sú òun. Ṣe lá máa kọ́ bó ṣe máa túbọ̀ já fáfá bó ṣe ń lò ó. Lọ́nà kan náà, tá a bá tiẹ̀ rò pé a ti borí kùdìẹ̀-kudiẹ wa, a lè pa dà ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, ó yẹ ká máa kó ara wa níjàánu, ká má bàa pa dà ṣàṣìṣe. Gbogbo wa la máa ń sọ tàbí ṣe ohun tá a máa ń kábàámọ̀ ẹ̀ tó bá yá, àmọ́ tá ò bá jẹ́ kó sú wa, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe, ká sì máa ṣe dáadáa. (1 Pét. 5:10) Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Pétérù ò ṣe jẹ́ kó sú òun. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ṣe àwọn àṣìṣe kan, àánú tí Jésù fi hàn sí i jẹ́ ká rí i pé àwa náà lè máa sin Jèhófà nìṣó bá a tiẹ̀ ṣàṣìṣe.

ÀWỌN KÙDÌẸ̀-KUDIẸ TÍ PÉTÉRÙ NÍ ÀTÀWỌN OHUN RERE TÓ RÍ GBÀ

Kí lo máa ṣe tí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ? (Wo ìpínrọ̀ 4)

4. Nínú Lúùkù 5:​5-10, kí ni Pétérù pe ara ẹ̀, kí sì ni Jésù fi dá a lójú?

4 Ìwé Mímọ́ ò sọ ìdí tí Pétérù fi pe ara ẹ̀ ní “ẹlẹ́ṣẹ̀,” bẹ́ẹ̀ ni kò sọ ẹ̀ṣẹ̀ náà. (Ka Lúùkù 5:​5-10.) Àmọ́ ó lè jẹ́ àwọn àṣìṣe ńlá kan ló ṣe. Jésù rí i pé ẹ̀rù ń ba Pétérù, ó sì ṣeé ṣe kó máa rò pé òun ò kúnjú ìwọ̀n. Jésù mọ̀ pé Pétérù máa jẹ́ olóòótọ́. Torí náà, ó sọ fún Pétérù pé kó “má bẹ̀rù mọ́.” Torí pé Jésù fọkàn tán Pétérù, ìyẹn jẹ́ kó ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé ẹ̀. Pétérù àti Áńdérù tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò fi iṣẹ́ ẹja pípa tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀, àwọn àti Jésù jọ ń ṣiṣẹ́ ìwàásù, Jèhófà sì bù kún wọn gan-an.—Máàkù 1:​16-18.

5. Àwọn nǹkan rere wo ló ṣojú Pétérù torí pé ó borí ìbẹ̀rù, tó sì tún gbà láti máa wàásù pẹ̀lú Jésù?

5 Ọ̀pọ̀ nǹkan rere tí Jésù ṣe ló ṣojú Pétérù nígbà tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, ó wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù mú àwọn èèyàn tó ń ṣàìsàn lára dá, nígbà tó lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde àti nígbà tó jí òkú dìde. b (Mát. 8:​14-17; Máàkù 5:​37, 41, 42) Pétérù tún fojú ara ẹ̀ rí i nígbà tí Jèhófà yí Jésù pa dà di ológo, ìyẹn jẹ́ kó rí bí Jésù ṣe máa rí nígbà tó bá di Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ohun tó rí yẹn sì fún un lókun gan-an. (Máàkù 9:​1-8; 2 Pét. 1:​16-18) Ó dájú pé tí Pétérù ò bá tẹ̀ lé Jésù, àwọn nǹkan yìí ò ní ṣojú ẹ̀. Ẹ ò rí i pé inú Pétérù máa dùn gan-an pé ó borí èrò tí ò tọ́ tó ní, ó sì tún láǹfààní láti rí àwọn nǹkan rere tí Jésù ṣe!

6. Ṣé ojú ẹsẹ̀ ni Pétérù borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní? Ṣàlàyé.

6 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Pétérù rí tó sì gbọ́, ó ṣì láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ń bá yí. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan. Nígbà tí Jésù sọ pé òun máa jìyà òun sì máa kú bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́ lẹ̀, ńṣe ni Pétérù sọ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ní ṣẹlẹ̀ sí Jésù. (Máàkù 8:​31-33) Yàtọ̀ síyẹn, léraléra ni Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù jiyàn nípa ẹni tó máa jẹ́ olórí láàárín wọn. (Máàkù 9:​33, 34) Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, Pétérù gé etí ọkùnrin kan dà nù láìjáfara. (Jòh. 18:10) Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, ẹ̀rù ba Pétérù, ó sì sẹ́ Jésù ọ̀rẹ́ ẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta. (Máàkù 14:​66-72) Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí Pétérù sunkún gan-an.—Mát. 26:75.

7. Àǹfààní wo ni Jésù fún Pétérù lẹ́yìn tí Jésù jíǹde?

7 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ti rẹ̀wẹ̀sì, Jésù ò jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ sú òun. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fún Pétérù láǹfààní láti fi hàn pé ó ṣì nífẹ̀ẹ́ òun. Torí náà, Jésù ní kí Pétérù máa fìrẹ̀lẹ̀ bójú tó àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. (Jòh. 21:​15-17) Pétérù sì múra tán láti ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún un. Torí náà, ó wà lára àwọn tí Jèhófà kọ́kọ́ fi ẹ̀mí mímọ́ yàn ní Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì.

8. Àṣìṣe ńlá wo ni Pétérù ṣe nígbà tó wà ní Áńtíókù?

8 Kódà lẹ́yìn tí Pétérù di Kristẹni ẹni àmì òróró, ó ṣì ń bá àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan yí. Nígbà tó di ọdún 36 S.K., Pétérù wà níbẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run fẹ̀mí yan Kọ̀nílíù tí kì í ṣe Júù. Èyí jẹ́ ká rí i kedere pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú,” ó sì fẹ́ káwọn tí kì í ṣe Júù di ara ìjọ Kristẹni. (Ìṣe 10:​34, 44, 45) Àtìgbà yẹn ni Pétérù ti ń jẹun pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe Júù torí kì í ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. (Gál. 2:12) Àmọ́ àwọn Júù kan ṣì ń rò pé kò yẹ káwọn Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù máa jẹun pa pọ̀. Nígbà táwọn Júù tó nírú èrò yẹn wá sí Áńtíókù, Pétérù ò jẹun pẹ̀lú àwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù mọ́, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé kò fẹ́ múnú bí àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí ohun tí Pétérù ṣe yìí, ó bá a wí lójú àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀. (Gál. 2:​13, 14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ṣàṣìṣe, ó ń sin Jèhófà nìṣó. Kí ló ràn án lọ́wọ́?

KÍ LÓ JẸ́ KÍ PÉTÉRÙ MÁA SIN JÈHÓFÀ NÌṢÓ?

9. Kí ni Jòhánù 6:​68, 69 sọ tó fi hàn pé olóòótọ́ ni Pétérù?

9 Pétérù jẹ́ olóòótọ́, kò sì jẹ́ kó sú òun láti máa tẹ̀ lé Jésù. Nígbà kan tí Jésù sọ ohun tí kò yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, Pétérù ṣe ohun tó fi hàn pé ó jẹ́ olóòótọ́. (Ka Jòhánù 6:​68, 69.) Dípò kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn ní sùúrù, kí wọ́n sì gbọ́ àlàyé tí Jésù máa ṣe, ńṣe ni ọ̀pọ̀ lára wọn fi Jésù sílẹ̀. Àmọ́ Pétérù ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó mọ̀ pé Jésù ló ní “àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”

Jésù fọkàn tán Pétérù, báwo nìyẹn ṣe fún ẹ níṣìírí? (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó fọkàn tán Pétérù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

10 Jésù ò pa Pétérù tì. Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó mọ̀ pé Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù máa sá fi òun sílẹ̀. Síbẹ̀, Jésù sọ fún Pétérù pé ó máa pa dà, ó sì máa jẹ́ olóòótọ́. (Lúùkù 22:​31, 32) Jésù mọ̀ dáadáa pé “ẹ̀mí ń fẹ́, àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.” (Máàkù 14:38) Kódà, lẹ́yìn tí Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù rárá, Jésù ò jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ sú òun. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han Pétérù, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà tí Pétérù dá wà. (Máàkù 16:7; Lúùkù 24:34; 1 Kọ́r. 15:5) Ẹ ò rí i pé ìyẹn máa fún Pétérù lókun gan-an bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣàṣìṣe!

11. Báwo ni Jésù ṣe fi dá Pétérù lójú pé Jèhófà máa bójú tó o?

11 Jésù fi dá Pétérù lójú pé Jèhófà máa bójú tó o. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó jẹ́ kí Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù rí ẹja pa lọ́nà ìyanu. (Jòh. 21:​4-6) Iṣẹ́ ìyanu yìí jẹ́ kó túbọ̀ dá Pétérù lójú pé Jèhófà máa pèsè àwọn ohun tó nílò. Ó ṣeé ṣe kí Pétérù rántí ohun tí Jésù sọ pé Jèhófà máa pèsè fún àwọn tó bá ń ‘wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mát. 6:33) Torí náà, iṣẹ́ ìwàásù ni Pétérù gbájú mọ́, kì í ṣe iṣẹ́ ẹja pípa. Ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì 33 S.K., ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn. (Ìṣe 2:​14, 37-41) Lẹ́yìn náà, ó tún ran àwọn ará Samáríà àtàwọn tí kì í ṣe Júù lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. (Ìṣe 8:​14-17; 10:​44-48) Ó dájú pé Jèhófà lo Pétérù lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ láti ran onírúurú èèyàn lọ́wọ́, kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni.

KÍ LA RÍ KỌ́?

12. Báwo ni àpẹẹrẹ Pétérù ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ní kùdìẹ̀-kudiẹ tá à ń bá yí?

12 Jèhófà máa ran àwa náà lọ́wọ́ ká lè máa sìn ín nìṣó. Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn, pàápàá tó bá ti pẹ́ tá a ti ní kùdìẹ̀-kudiẹ kan tá à ń bá yí. Nígbà míì, kùdìẹ̀-kudiẹ wa lè burú ju ti Pétérù lọ. Àmọ́, Jèhófà máa fún wa lókun ká lè máa sìn ín nìṣó. (Sm. 94:​17-19) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún ni arákùnrin kan ti ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ kó tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ohun tó kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ kó fi ìwà náà sílẹ̀ pátápátá. Síbẹ̀, nígbà míì, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí máa ń wá sí i lọ́kàn. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: ‘Jèhófà ló ń fún mi lókun. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, ó sì ti jẹ́ kí n rí i pé mo lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni mí, Jèhófà ń lò mí, ó sì ń fún mi lókun.’

Horst Henschel bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáajú-ọ̀nà ní January 1, 1950. Ṣé o rò pé ó kábàámọ̀ bó ṣe fayé ẹ̀ sin Jèhófà? (Wo ìpínrọ̀ 13, 15) d

13.Ìṣe 4:​13, 29, 31 ṣe sọ, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pétérù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 A ti rí i pé ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí Pétérù jẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn mú òun. Àmọ́ ó bẹ Jèhófà pé kó fún òun nígboyà, ìyẹn sì jẹ́ kó máa wàásù nìṣó. (Ka Ìṣe 4:​13, 29, 31.) Bíi ti Pétérù, àwa náà lè borí ìbẹ̀rù. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Horst nígbà ìjọba Násì lórílẹ̀-èdè Jámánì. Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tẹ́rù bà á nílé ìwé, tó sì sọ pé “Ti Hitler Ni Ìgbàlà!” Dípò káwọn òbí ẹ̀ bá a wí, ṣe ni wọ́n jọ gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kó nígboyà. Nígbà táwọn òbí ẹ̀ ràn án lọ́wọ́ tó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, Horst wá nígboyà, kò sì bá wọn yin Hitler mọ́. Nígbà tó yá, ó sọ pé: “Jèhófà ò pa mí tì rárá.” c

14. Báwo làwọn alábòójútó tó nífẹ̀ẹ́ wa ṣe lè fún àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ò lágbára mọ́ níṣìírí?

14 Bákan náà, Jèhófà àti Jésù ò ní pa wá tì. Lẹ́yìn tí Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù rí, ó gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu pàtàkì kan nígbèésí ayé ẹ̀. Ṣé ó máa lóun ò wàásù mọ́ àbí á ṣì máa wàásù nípa Kristi nìṣó? Jésù ti gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí ìgbàgbọ́ Pétérù túbọ̀ lágbára. Jésù sọ fún Pétérù nípa àdúrà yẹn, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun fọkàn tán an pé tó bá yá, ó máa fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lókun. (Lúùkù 22:​31, 32) Ẹ ò rí i pé tí Pétérù bá rántí ohun tí Jésù sọ yìí, ó máa fún un níṣìírí gan-an! Táwa náà bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì nígbèésí ayé wa, Jèhófà lè lo àwọn alábòójútó tó nífẹ̀ẹ́ wa láti tọ́ wa sọ́nà, ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Éfé. 4:​8, 11) Ohun tí Arákùnrin Paul tó ti ń ṣiṣẹ́ alàgbà tipẹ́ ṣe nìyẹn. Ó ní kí àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ò lágbára mọ́ ronú nípa ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó sì fi dá wọn lójú pé Jèhófà ò ní jẹ́ kó rẹ̀ wọ́n torí ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí wọn. Ó wá parí ọ̀rọ̀ ẹ̀ pé, “Mo ti rí ọ̀pọ̀ àwọn ará tí ìgbàgbọ́ wọn ò lágbára mọ́, àmọ́ Jèhófà ti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lè pa dà lágbára.”

15. Báwo ni àpẹẹrẹ Pétérù àti Horst ṣe jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lohun tó wà nínú Mátíù 6:33?

15 Bí Jèhófà ṣe pèsè àwọn nǹkan tí Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù nílò, ó máa pèsè fáwa náà tá a bá gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù nígbèésí ayé wa. (Mát. 6:33) Lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, Horst tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́ torí pé kò lówó lọ́wọ́, ẹ̀rù ń bà á pé òun ò ní lè gbọ́ bùkátà òun, kóun sì máa ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Kí ló wá ṣe? Ó pinnu pé òun á wò ó bóyá Jèhófà máa pèsè fún òun, torí náà jálẹ̀ ọ̀sẹ̀ kan tí alábòójútó àyíká fi bẹ̀ wọ́n wò ló fi lọ sóde ìwàásù. Lẹ́yìn tí ìbẹ̀wò parí, ó yà á lẹ́nu gan-an nígbà tí alábòójútó àyíká fún un ní àpò ìwé kan tí owó wà nínú ẹ̀, kò sì sọ ẹni tó fún un. Owó tó wà nínú ẹ̀ pọ̀ débi pé ó máa tó o ná fún ọ̀pọ̀ oṣù. Horst gbà pé Jèhófà fẹ́ kó dá òun lójú pé òun máa pèsè gbogbo ohun tí òun nílò, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ kí wọ́n fún òun lówó yẹn. Torí náà, jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀ ló fi gbájú mọ́ iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.—Mál. 3:10.

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára Pétérù àtàwọn lẹ́tà tó kọ?

16 Ẹ ò rí i pé inú Pétérù máa dùn gan-an pé Jésù ò pa òun tì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà kan ó sọ pé kí Jésù kúrò lọ́dọ̀ òun! Kristi ń dá àpọ́sítélì Pétérù lẹ́kọ̀ọ́ nìṣó kó lè jẹ́ olóòótọ́, kó sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwa Kristẹni. Ọ̀pọ̀ nǹkan la sì rí kọ́ nínú ẹ̀kọ́ tí Pétérù gbà lọ́dọ̀ Jésù. Pétérù sọ lára àwọn ẹ̀kọ́ náà nínú lẹ́tà méjì tó kọ sáwọn ìjọ nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó wà nínú àwọn lẹ́tà náà àti bá a ṣe lè fi wọ́n sílò lónìí.

ORIN 126 Wà Lójúfò, Dúró Gbọn-in, Jẹ́ Alágbára

a Ọ̀pọ̀ wa la ní kùdìẹ̀-kudiẹ tá à ń bá yí. Torí náà, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí i pé a lè borí wọn, ká sì máa sin Jèhófà nìṣó tọkàntọkàn.

b A mú ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí látinú Ìwé Ìhìn Rere Máàkù. Ó jọ pé ohun tí Máàkù gbọ́ lọ́dọ̀ Pétérù ló kọ sílẹ̀, ìyẹn àwọn nǹkan tí Jésù ṣe tó ṣojú Pétérù.

c Wo ìtàn ìgbésí ayé Horst Henschel nínú Jí!, February 22, 1998. Àkòrí ẹ̀ ni “Bí Ìdílé Mi Ṣe Dúró Ṣinṣin Ti Ọlọ́run Sún Mi Ṣiṣẹ́.”

d ÀWÒRÁN: Bá a ṣe rí i nínú àwòrán yìí, àwọn òbí Horst Henschel ń gbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀ kó lè nígboyà.