Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 37

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Bíi Ti Sámúsìn

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Bíi Ti Sámúsìn

“Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, jọ̀ọ́ rántí mi, jọ̀ọ́ fún mi lókun.”—ONÍD. 16:28.

ORIN 30 Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1-2. Kí nìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa Sámúsìn?

 KÍ LÓ máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá gbọ́ orúkọ náà Sámúsìn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun tó máa ń wá sí ẹ lọ́kàn ni ọkùnrin kan tó lágbára gan-an. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Àmọ́ Sámúsìn ṣe ìpinnu tí kò tọ́, àbájáde ẹ̀ ò sì dáa. Síbẹ̀, Jèhófà kíyè sí bí Sámúsìn ṣe sin òun tọkàntọkàn, ó sì jẹ́ kí wọ́n kọ ìtàn ẹ̀ sínú Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹ̀.

2 Jèhófà lo Sámúsìn láti ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ribiribi ló sì gbé ṣe. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Sámúsìn kú, ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dárúkọ ẹ̀ mọ́ àwọn ọkùnrin tó nígbàgbọ́ àrà ọ̀tọ̀ nígbà tó ń kọ ìwé Hébérù. (Héb. 11:​32-34) Kò sí àní-àní pé ìtàn Sámúsìn máa fún wa níṣìírí. Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kódà láwọn ìgbà tó níṣòro. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan rere tá a rí kọ́ lára Sámúsìn àti bá a ṣe máa yẹra fáwọn àṣìṣe tó ṣe.

SÁMÚSÌN GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ

3. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà gbé fún Sámúsìn?

3 Nígbà tí wọ́n bí Sámúsìn, àwọn Filísínì ló ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń jẹ gàba lé wọn lórí. (Oníd. 13:1) Àwọn Filísínì rorò gan-an, wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Torí náà, Jèhófà yan Sámúsìn pé kó “ṣáájú láti gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Filísínì.” (Oníd. 13:5) Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ yẹn ò rọrùn rárá! Kí Sámúsìn tó lè ṣe iṣẹ́ tó le yìí, ó gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

Sámúsìn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì ṣe tán láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Ó lo ohun tó rí láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ (Wo ìpínrọ̀ 4-5)

4. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Sámúsìn lọ́wọ́ kó lè gba ara ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Filísínì? (Àwọn Onídàájọ́ 15:​14-16)

4 Ẹ jẹ́ ká wo bí Sámúsìn ṣe fọkàn tán Jèhófà, tó sì gbẹ́kẹ̀ lé e pé ó máa ran òun lọ́wọ́. Ìgbà kan wà táwọn ọmọ ogun Filísínì wá mú Sámúsìn ní Léhì, tó ṣeé ṣe kó wà ní Júdà. Torí pé ẹ̀rù ń ba àwọn ọkùnrin Júdà, wọ́n pinnu pé àwọn á jẹ́ káwọn ọ̀tá mú Sámúsìn lọ. Torí náà, àwọn èèyàn Júdà fi okùn tuntun méjì de Sámúsìn, wọ́n sì mú un wá fún àwọn Filísínì. (Oníd. 15:​9-13) Àmọ́, “ẹ̀mí Jèhófà fún un lágbára,” ó sì já àwọn okùn náà dà nù. Lẹ́yìn náà, ó rí “egungun tútù kan tó jẹ́ egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,” ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ọkùnrin!—Ka Àwọn Onídàájọ́ 15:​14-16.

5. Báwo ni Sámúsìn ṣe fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tó fi páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́tẹ́tẹ́ jà?

5 Kí nìdí tí Sámúsìn ṣe fi egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jà? Ó ṣọ̀wọ́n gan-an kẹ́nì kan tó lè fi egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ jà! Ó dá Sámúsìn lójú pé ohun ìjà yòówù kóun lò, Jèhófà ló máa ran òun lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun. Síbẹ̀, ọkùnrin olóòótọ́ yìí lo ohun tó rí láti ṣiṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un. Torí náà, ó hàn kedere pé ohun tó mú kí Sámúsìn ṣẹ́gun ni pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

6. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ lára Sámúsìn tó lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń ṣiṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wa?

6 Jèhófà máa ran àwa náà lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ èyíkéyìí tí ètò rẹ̀ bá gbé fún wa, kódà tó bá dà bíi pé a ò lè ṣiṣẹ́ náà. Ọlọ́run máa jẹ́ ká ṣiṣẹ́ náà lọ́nà tó máa yà wá lẹ́nu. Torí náà, tó o bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó ṣe ran Sámúsìn lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tó gbé fún ẹ.—Òwe 16:3.

7. Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà?

7 Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó máa ń ṣèrànwọ́ níbi tá a ti ń kọ́lé ètò Ọlọ́run ti fi hàn pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Tẹ́lẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló sábà máa ń yàwòrán ilé ètò Ọlọ́run tá a sì máa ń kọ́ àwọn Ilé Ìpàdé tuntun àtàwọn ilé ètò Ọlọ́run míì. Àmọ́ torí pé àwọn tó ń ṣèrìbọmi ń pọ̀ sí i, ó wá pọn dandan pé kí ètò Ọlọ́run ṣe àwọn àyípadà kan. Àwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ àwọn sọ́nà. Ohun tí wọ́n ń ṣe báyìí ni pé wọ́n máa ń ra àwọn ilé tí wọ́n ti kọ́ tẹ́lẹ̀, wọ́n á sì tún un ṣe. Arákùnrin Robert tó ti ṣiṣẹ́ láwọn ibi tá a ti ń kọ́lé ètò Ọlọ́run kárí ayé lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé: “Kò kọ́kọ́ rọrùn fún àwọn kan lára wa láti fara mọ́ ọ̀nà tuntun tí ètò Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbà ṣe nǹkan.” Ó tún sọ pé: “Bá a ṣe ń ṣe nǹkan báyìí ti yàtọ̀ pátápátá sí bá a ṣe ń ṣe nǹkan ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Àmọ́, àwọn arákùnrin wa ń ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ, wọ́n sì rí i pé Jèhófà ń bù kún àyípadà náà.” Àpẹẹrẹ tá a sọ yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà, kí ohun tó fẹ́ lè ṣẹ. Torí náà, látìgbàdégbà, ó yẹ kí gbogbo wa máa bi ara wa pé, ‘Ṣé mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ mi sọ́nà, tí mo sì ṣe tán láti ṣe àwọn àyípadà kan kí n lè máa sìn ín tọkàntọkàn?’

SÁMÚSÌN LO GBOGBO OHUN TÍ JÈHÓFÀ FÚN UN

8. Nígbà kan tí òùngbẹ ń gbẹ Sámúsìn gan-an, kí ló ṣe?

8 Ó ṣeé ṣe kó o ti kà nípa àwọn nǹkan míì tí Sámúsìn ṣe tó yani lẹ́nu. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tóun nìkan bá kìnnìún jà, tó sì pa á. Lẹ́yìn ìyẹn, ó pa ọgbọ̀n (30) ọkùnrin Filísínì nílùú Áṣíkẹ́lónì. (Oníd. 14:​5, 6, 19) Sámúsìn mọ̀ pé Jèhófà ló ran òun lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àṣeyọrí yẹn. Àpẹẹrẹ kan nìgbà tí òùngbẹ ń gbẹ ẹ́ gan-an lẹ́yìn tó pa ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lára àwọn Filísínì. Kí ni Sámúsìn wá ṣe? Dípò kó wá omi tó máa mu fúnra ẹ̀, ńṣe ló ké pe Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́.—Oníd. 15:18.

9. Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tí Sámúsìn bẹ̀ ẹ́ pé kó ran òun lọ́wọ́? (Àwọn Onídàájọ́ 15:19)

9 Jèhófà dáhùn àdúrà Sámúsìn, ó sì jẹ́ kí omi ṣàn jáde látinú kòtò kan lọ́nà ìyanu. Nígbà tó mu omi náà, “okun rẹ̀ pa dà, ó sì sọ jí.” (Ka Àwọn Onídàájọ́ 15:19.) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣeé ṣe kí omi ṣì wà nínú kòtò náà nígbà tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí wòlíì Sámúẹ́lì láti kọ ìwé Àwọn Onídàájọ́. Torí náà, nígbàkigbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá rí kòtò omi tó ń ṣàn náà, wọ́n á máa rántí pé tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.

Sámúsìn lókun lẹ́yìn tó mu omi tí Jèhófà pèsè fún un. Ó ṣe pàtàkì káwa náà máa lo gbogbo ohun tí Jèhófà ń pèsè fún wa, kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, kí la gbọ́dọ̀ ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

10 Ó yẹ káwa náà máa bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láìka ẹ̀bùn tá a ní sí àtàwọn nǹkan míì tá a ti gbé ṣe nínú ètò rẹ̀. Ó yẹ ká mọ̀wọ̀n ara wa, ká sì gbà pé ohun tó máa jẹ́ ká ṣàṣeyọrí ni tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí Sámúsìn ṣe pa dà lókun lẹ́yìn tó mu omi tí Jèhófà pèsè fún un, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wa máa lágbára tá a bá ń lo gbogbo nǹkan tí Jèhófà ń pèsè fún wa.—Mát. 11:28.

11. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.

11 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Aleksey tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ó ń fara da inúnibíni tó le gan-an. Kí ló mú kó lè fara da inúnibíni yẹn? Ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni pé òun àti ìyàwó ẹ̀ máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì fi ìjọsìn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. Ó sọ pé: “Mo máa ń rí i pé mò ń dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, mo sì ń ka Bíbélì lójoojúmọ́. Láràárọ̀, èmi àti ìyàwó mi máa ń jíròrò ẹsẹ ojúmọ́, a sì máa ń gbàdúrà pa pọ̀.” Kí la rí kọ́? Dípò ká gbẹ́kẹ̀ lé ara wa, Jèhófà ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé. Báwo la ṣe lè ṣe é? Bá a ṣe lè ṣe é ni pé ká máa ṣe àwọn nǹkan tó máa mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, ká máa gbàdúrà, ká máa lọ sípàdé, ká sì máa wàásù. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa sìn ín nìṣó. Jèhófà ló fún Sámúsìn lókun, ó sì dájú pé ó máa fún àwa náà lókun.

SÁMÚSÌN Ò JẸ́ KÓ SÚ ÒUN LÁTI MÁA SIN JÈHÓFÀ

12. Ìpinnu tí ò dáa wo ni Sámúsìn ṣe, báwo nìyẹn sì ṣe yàtọ̀ sáwọn ìpinnu tó kọ́kọ́ ṣe?

12 Aláìpé bíi tiwa ni Sámúsìn, torí náà láwọn ìgbà kan, ó ṣe àwọn ìpinnu tí ò dáa. Kódà, ó ṣe ìpinnu kan tí ìgbẹ̀yìn ẹ̀ ò dáa rárá. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ tí Sámúsìn di onídàájọ́, “ó nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dẹ̀lílà ní Àfonífojì Sórékì.” (Oníd. 16:4) Ṣáájú ìgbà yẹn, Sámúsìn ti fẹ́ obìnrin ará Filísínì kan, àmọ́ “Jèhófà ló fẹ́ kó” fẹ́ ẹ kó lè lo àǹfààní yẹn láti “gbógun ja àwọn Filísínì.” Nígbà tó yá, Sámúsìn lọ sílùú Gásà ní Filísínì, ó sì dé sílé obìnrin aṣẹ́wó kan. Ìgbà yẹn ni Jèhófà fún un lágbára láti yọ àwọn ilẹ̀kùn ẹnubodè ìlú náà kúrò, ìyẹn á sì mú kó rọrùn fáwọn ọ̀tá láti wọlé. (Oníd. 14:​1-4; 16:​1-3) Àmọ́, ọ̀rọ̀ Dẹ̀lílà yàtọ̀ ní tiẹ̀ torí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì. Torí náà, bí Sámúsìn ṣe fẹ́ Dẹ̀lílà ò ní lè ṣí àǹfààní sílẹ̀ láti gbéjà ko àwọn Filísínì.

13. Báwo ni Dẹ̀lílà ṣe mú kí Sámúsìn ṣe ohun tí ò dáa?

13 Dẹ̀lílà gba owó gọbọi táwọn Filísínì fún un kó lè dalẹ̀ Sámúsìn. Ṣé ó ṣeé ṣe kí ìfẹ́ Dẹ̀lílà ti kó sí Sámúsìn lórí débi pé kò fura pé ó fẹ́ dalẹ̀ òun? Èyí ó wù ó jẹ́, ńṣe ni Dẹ̀lílà fúngun mọ́ Sámúsìn kó lè sọ ibi tí agbára ẹ̀ wà, nígbẹ̀yìngbẹ́yín ó sọ fún un. Ó mà ṣe o! Àṣìṣe tí Sámúsìn ṣe yìí ló jẹ́ kó pàdánù agbára ẹ̀, ó sì tún pàdánù ojúure Jèhófà fáwọn àkókò kan.—Oníd. 16:​16-20.

14. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Sámúsìn torí pé ó fọkàn tán Dẹ̀lílà?

14 Torí pé Sámúsìn fọkàn tán Dẹ̀lílà dípò Jèhófà, ó jìyà ẹ̀. Àwọn Filísínì mú Sámúsìn, wọ́n sì fọ́ ojú ẹ̀. Wọ́n fi sẹ́wọ̀n nílùú Gásà, níbi tó ti kọ́kọ́ pa àwọn èèyàn lọ rẹ́kẹrẹ̀kẹ. Àwọn ará ìlú yẹn kan náà ló wá sọ ọ́ dẹrú báyìí, ó sì ń bá wọn lọ ọkà nínú ẹ̀wọ̀n. Lẹ́yìn ìyẹn, nígbà táwọn Filísínì ń ṣe àjọyọ̀ kan, wọ́n mú Sámúsìn wá síbẹ̀. Wọ́n rú ẹbọ ńlá kan sí ọlọ́run èké wọn tó ń jẹ́ Dágónì torí wọ́n gbà pé òun ló jẹ́ káwọn rí Sámúsìn mú. Torí náà, wọ́n mú Sámúsìn jáde látinú ẹ̀wọ̀n wá síbi àjọyọ̀ náà kó lè “dá wọn lára yá,” kí wọ́n sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́.—Oníd. 16:​21-25.

Jèhófà fún Sámúsìn lágbára láti gbéjà ko àwọn Filísínì (Wo ìpínrọ̀ 15)

15. Báwo ni Sámúsìn ṣe tún fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (Àwọn Onídàájọ́ 16:​28-30) (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

15 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sámúsìn ṣe àṣìṣe ńlá, síbẹ̀ kò jẹ́ kó sú òun láti máa sin Jèhófà. Ó lo àǹfààní tó ní láti ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un, ìyẹn ni pé kó gbéjà ko àwọn Filísínì. (Ka Àwọn Onídàájọ́ 16:​28-30.) Sámúsìn bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun ‘gbẹ̀san lára àwọn Filísínì.’ Ọlọ́run tòótọ́ dáhùn àdúrà Sámúsìn, ó sì fún un lágbára lọ́nà ìyanu. Àwọn Filísínì tí Sámúsìn pa lọ́tẹ̀ yìí pọ̀ gan-an ju àwọn tó pa tẹ́lẹ̀ lọ.

16. Kí la rí kọ́ nínú àṣìṣe tí Sámúsìn ṣe?

16 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sámúsìn jìyà àbájáde àṣìṣe tó ṣe, kò ṣíwọ́ láti máa sin Jèhófà. Torí náà tá a bá ṣàṣìṣe, tí wọ́n sì bá wa wí tàbí tá a pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti máa sin Jèhófà nìṣó. Máa rántí pé Jèhófà kì í jẹ́ kọ́rọ̀ wa sú òun. (Sm. 103:​8-10) Torí náà, tá a bá tiẹ̀ ṣe àwọn àṣìṣe kan, Jèhófà ṣì lè lò wá bó ṣe lo Sámúsìn.

Ó ṣeé ṣe kí Sámúsìn kábàámọ̀ àṣìṣe tó ṣe, síbẹ̀ kò jẹ́ kó sú òun láti máa sin Jèhófà. Àwa náà ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa (Wo ìpínrọ̀ 17-18)

17-18. Kí lo rí kọ́ lára Michael tó fún ẹ níṣìírí? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Michael. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni, kò sì fi ìjọsìn Jèhófà ṣeré rárá. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ó ṣe àwọn àṣìṣe kan, ìyẹn sì jẹ́ kó pàdánù àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ẹ̀ nínú ìjọ. Ó sọ pé: “Kó tó di pé mo pàdánù àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yẹn, ọ̀pọ̀ nǹkan ni mò ń gbé ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́ bí mo ṣe pàdánù àwọn àǹfààní yẹn lójijì dà bíi pé kò sóhun tí mo lè ṣe fún Jèhófà mọ́. Mo mọ̀ pé Jèhófà ò ní pa mí tì láé, àmọ́ mo máa ń rò ó pé bóyá ni mo tún lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀ àti pé bóyá ni màá tún lè sin Jèhófà tọkàntọkàn nínú ìjọ bí mo ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀.”

18 Inú wa dùn pé Michael ò jẹ́ kó sú òun. Ó tún sọ pé: “Mo ṣiṣẹ́ kára gan-an kí àárín èmi àti Jèhófà lè pa dà gún régé. Torí náà, mo máa ń gbàdúrà déédéé, mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì máa ń ṣàṣàrò.” Nígbà tó yá, Michael pa dà ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó pàdánù. Ní báyìí, alàgbà àti aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni. Ó sọ pé: “Àwọn ará, pàápàá àwọn alàgbà ràn mí lọ́wọ́, wọ́n sì fún mi níṣìírí, ìyẹn jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ mi. Inú mi dùn pé mo láǹfààní láti pa dà máa sìn nínú ìjọ, mo sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi yìí ti jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà máa ń dárí ji ẹnikẹ́ni tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.” Torí náà, ó dá wa lójú pé táwa náà bá ṣàṣìṣe, àmọ́ tá a ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ṣàtúnṣe tó yẹ, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa lò wá, ó sì máa bù kún wa.—Sm. 86:5; Òwe 28:13.

19. Báwo ni àpẹẹrẹ Sámúsìn ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára?

19 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé Sámúsìn tó wú wa lórí. Òótọ́ ni pé aláìpé ni, síbẹ̀ kò jẹ́ kó sú òun láti máa sin Jèhófà nìṣó, kódà lẹ́yìn tó fẹ́ Dẹ̀lílà tó dalẹ̀ ẹ̀. Jèhófà náà ò sì jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ sú òun. Ọlọ́run tún lo Sámúsìn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Jèhófà rí i pé ọkùnrin tó nígbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni Sámúsìn, ó sì jẹ́ kí orúkọ ẹ̀ wà lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ tá a kọ orúkọ wọn sínú Hébérù orí kọkànlá (11). Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó bá a ṣe mọ̀ pé Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa là ń sìn, ó sì máa ń wù ú láti fún wa lókun nígbà ìṣòro! Torí náà, bíi ti Sámúsìn, ẹ jẹ́ káwa náà máa bẹ Jèhófà pé: “Jọ̀ọ́ rántí mi, jọ̀ọ́ fún mi lókun.”—Oníd. 16:28.

ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa

a Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sámúsìn, ọ̀pọ̀ èèyàn sì mọ̀ ọ́n bí ẹni mowó. Kódà, àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Bíbélì náà mọ̀ ọ́n. Àwọn èèyàn ti fi ìtàn ẹ̀ ṣe eré, wọ́n ti fi kọrin, wọ́n sì ti fi ṣe fíìmù. Àmọ́, ìtàn Sámúsìn kì í ṣe ìtàn àkàgbádùn lásán. Ọkùnrin yìí nígbàgbọ́ tó lágbára gan-an, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la sì lè rí kọ́ lára ẹ̀.