Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 41

Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Lẹ́tà Méjì Tí Pétérù Kọ

Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Lẹ́tà Méjì Tí Pétérù Kọ

Ó “wù mí kí n máa rán yín létí àwọn nǹkan yìí nígbà gbogbo.”—2 PÉT. 1:12.

ORIN 127 Irú Èèyàn Tó Yẹ Kí N Jẹ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Kí ni Jèhófà sọ pé kí àpọ́sítélì Pétérù ṣe nígbà tó kù díẹ̀ kó kú?

 ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pétérù mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ kú. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi sin Jèhófà tọkàntọkàn. Láwọn àsìkò yẹn, ó wà pẹ̀lú Jésù nígbà tí Jésù ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, òun ló kọ́kọ́ wàásù fáwọn tí kì í ṣe Júù, nígbà tó sì yá, ó di ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ olùdarí. Àmọ́ kó tó kú, Jèhófà gbé àwọn iṣẹ́ míì fún un. Ní nǹkan bí ọdún 62-64 S.K., Jèhófà fẹ̀mí ẹ̀ darí Pétérù láti kọ ìwé Pétérù kìíní àti ìkejì. Pétérù gbà pé àwọn lẹ́tà tóun kọ máa ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ lẹ́yìn tóun bá kú.—2 Pét. 1:​12-15.

2. Kí ló mú káwọn lẹ́tà Pétérù bọ́ sákòókò táwọn Kristẹni nílò ẹ̀?

2 Àsìkò tí “oríṣiríṣi àdánwò kó ìdààmú” bá àwọn Kristẹni ni Pétérù kọ àwọn lẹ́tà rẹ̀. (1 Pét. 1:6) Àwọn èèyàn burúkú ń dọ́gbọ́n mú ẹ̀kọ́ èké àti ìwà àìmọ́ wọnú ìjọ. (2 Pét. 2:​1, 2, 14) Àwọn Kristẹni tó ń gbé Jerúsálẹ́mù máa tó rí “òpin ohun gbogbo,” ìyẹn ìgbà táwọn ọmọ ogun Róòmù máa pa ìlú yẹn àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run. (1 Pét. 4:7) Kò sí iyè méjì pé àwọn lẹ́tà tí Pétérù kọ máa ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò tó bá yọjú kí wọ́n sì múra sílẹ̀ de àwọn àdánwò tó lè yọjú lọ́jọ́ iwájú. b

3. Kí nìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn lẹ́tà tí Pétérù kọ?

3 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ni Pétérù dìídì kọ àwọn lẹ́tà rẹ̀ sí, Jèhófà jẹ́ káwọn àkọsílẹ̀ náà wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Torí náà, àwa náà lè jàǹfààní gan-an nínú àwọn lẹ́tà rẹ̀. (Róòmù 15:4) Ìwà àìmọ́ pọ̀ nínú ayé tá à ń gbé yìí, torí náà kì í rọrùn láti sin Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, ìpọ́njú ńlá tó ju èyí tó pa Jerúsálẹ́mù run máa tó ṣẹlẹ̀. Nínú lẹ́tà méjì tí Pétérù kọ, àwọn ìránnilétí kan wà níbẹ̀ tó ṣe pàtàkì. Àwọn ìránnilétí náà máa jẹ́ ká múra sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà, ká borí ìbẹ̀rù èèyàn, ká sì nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú. Ó tún máa ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti máa bójú tó àwọn ará ìjọ kí ìgbàgbọ́ wọn lè lágbára.

MÁA RETÍ ỌJỌ́ JÈHÓFÀ

4. Kí ni 2 Pétérù 3:​3, 4 sọ pé ó lè mú kí ìgbàgbọ́ wa má lágbára mọ́?

4 Àwọn tí ò gba àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì gbọ́ pọ̀ láyé yìí. Àwọn alátakò lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé ọ̀pọ̀ ọdún la ti ń sọ pé òpin máa dé. Àwọn kan tó ń ṣàríwísí sọ pé òpin ò lè dé láé. (Ka 2 Pétérù 3:​3, 4.) Tá a bá gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lẹ́nu ẹni tá à ń wàásù fún, ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí wa kan, ìgbàgbọ́ wa lè má lágbára mọ́. Àmọ́ Pétérù sọ ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́.

5. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti fi sùúrù dúró de ìgbà tí òpin máa dé? (2 Pétérù 3:​8, 9)

5 Lójú àwọn kan, ó jọ pé Jèhófà ń fi nǹkan falẹ̀ torí kò pa ayé burúkú yìí run. Ohun tí Pétérù sọ máa jẹ́ ká fojú tó tọ́ wo nǹkan, ó sì máa rán wa létí pé ojú tí Jèhófà fi ń wo àkókò yàtọ̀ pátápátá sí tàwa èèyàn. (Ka 2 Pétérù 3:​8, 9.) Torí lójú Jèhófà, ẹgbẹ̀rún ọdún (1,000) dà bí ọjọ́ kan. Jèhófà ní sùúrù gan-an, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run. Àmọ́ tí ọjọ́ Jèhófà bá dé, ayé burúkú yìí máa dópin. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi àkókò tó kù yìí wàásù fún gbogbo èèyàn.

6. Báwo la ṣe lè máa ‘fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn?’ (2 Pétérù 3:​11, 12)

6 Pétérù rọ̀ wá pé ká máa ‘fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn.’ (Ka 2 Pétérù 3:​11, 12.) Báwo la ṣe lè ṣe é? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ronú lójoojúmọ́ nípa àwọn ohun rere tá a máa gbádùn nínú ayé tuntun. Fojú inú wò ó pé ò ń mí afẹ́fẹ́ tó mọ́ símú, ò ń jẹ oúnjẹ aṣaralóore, ò ń kí àwọn èèyàn ẹ tó jíǹde káàbọ̀, o sì ń ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti ṣẹ fáwọn tó ti gbé ayé ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Tó o bá ń ronú nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, wàá máa fayọ̀ retí àkókò yẹn, á sì dá ẹ lójú pé òpin ò ní pẹ́ dé mọ́. Tá a bá “mọ àwọn nǹkan yìí tẹ́lẹ̀,” àwọn olùkọ́ èké ò ní ‘ṣì wá lọ́nà.’—2 Pét. 3:17.

BÓ O ṢE LÈ BORÍ ÌBẸ̀RÙ ÈÈYÀN

7. Báwo ni ìbẹ̀rù èèyàn ṣe lè mú wa?

7 A mọ̀ pé ọjọ́ Jèhófà ò ní pẹ́ dé, torí náà a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wàásù ìhìn rere náà fáwọn èèyàn. Síbẹ̀ nígbà míì, ẹ̀rù lè máa bà wá láti wàásù. Kí nìdí? Ìdí ni pé a lè máa bẹ̀rù ohun táwọn èèyàn máa sọ tàbí ohun tí wọ́n máa ṣe fún wa. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù náà nìyẹn. Lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ Jésù, ẹ̀rù ba Pétérù débi tó fi sọ pé òun kì í ṣe ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Kódà, léraléra ló sọ pé òun ò mọ Jésù rí. (Mát. 26:​69-75) Pétérù yìí kan náà wá fi ìdánilójú sọ nígbà tó yá pé: “Ẹ má bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà.” (1 Pét. 3:14) Ohun tó sọ yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé àwa náà lè borí ìbẹ̀rù èèyàn.

8. Kí ló máa jẹ́ ká borí ìbẹ̀rù èèyàn? (1 Pétérù 3:15)

8 Kí ló máa jẹ́ ká borí ìbẹ̀rù èèyàn? Pétérù sọ fún wa pé: “Ẹ gbà nínú ọkàn yín pé Kristi jẹ́ mímọ́.” (Ka 1 Pétérù 3:15.) Ọ̀rọ̀ yẹn jẹ́ ká rántí pé Jésù Kristi ni Olúwa àti Ọba wa, ó sì lágbára gan-an. Tẹ́rù bá ń bà ẹ́ nígbà tó o láǹfààní láti wàásù, máa rántí pé Jésù ni Ọba wa. Máa fojú inú wo bó ṣe ń ṣàkóso lọ́run, tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn áńgẹ́lì sì wà pẹ̀lú ẹ̀. Máa rántí pé Jèhófà ti fún un ní “gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé,” ó sì ṣèlérí pé òun máa “wà pẹ̀lú [wa] ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:​18-20) Pétérù rọ̀ wá pé ká “ṣe tán nígbà gbogbo” láti ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́. Ṣé wàá fẹ́ wàásù níbi iṣẹ́, nílé ìwé tàbí láwọn ibòmíì? Ronú nípa ìgbà tí àǹfààní ẹ̀ lè yọ, kó o sì múra ohun tó o máa sọ sílẹ̀. Gbàdúrà kó o lè nígboyà, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á jẹ́ kó o borí ìbẹ̀rù èèyàn.—Ìṣe 4:29.

“Ẹ NÍ ÌFẸ́ TÓ JINLẸ̀”

Pétérù gba ìbáwí tí Pọ́ọ̀lù fún un. Àwọn lẹ́tà méjèèjì tí Pétérù kọ jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa (Wo ìpínrọ̀ 9)

9. Kí ni Pétérù ṣe nígbà kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé kò fìfẹ́ hàn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

9 Pétérù kọ́ bó ṣe yẹ kéèyàn máa fìfẹ́ hàn. Ó wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù sọ pé: “Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín.” (Jòh. 13:34) Síbẹ̀ nígbà tó yá, ìbẹ̀rù èèyàn mú Pétérù, kò sì jẹun mọ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí kì í ṣe Júù. Ìyẹn ló mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ṣe ni Pétérù ń “díbọ́n.” (Gál. 2:​11-14) Pétérù gba ìbáwí tí Pọ́ọ̀lù fún un, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Nínú lẹ́tà méjèèjì tí Pétérù kọ, ó sọ pé kì í ṣe ká kàn sọ pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa nìkan, a tún gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn lóòótọ́.

10. Kí ló máa jẹ́ ká ní “ìfẹ́ ará láìsí ẹ̀tàn”? Ṣàlàyé. (1 Pétérù 1:22)

10 Pétérù sọ pé ó yẹ ká fi “ìfẹ́ ará láìsí ẹ̀tàn” hàn sí àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. (Ka 1 Pétérù 1:22.) Àmọ́, ‘ìgbọràn wa sí òtítọ́’ ló máa jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe. Ọ̀kan lára òtítọ́ náà ni pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” (Ìṣe 10:​34, 35) Kò sí bá a ṣe lè sọ pé à ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa tó bá jẹ́ pé àwọn kan là ń fìfẹ́ hàn sí nínú ìjọ, tá a sì ń pa àwọn yòókù tì. Lóòótọ́, a lè sún mọ́ àwọn kan ju àwọn míì lọ bíi ti Jésù. (Jòh. 13:23; 20:2) Àmọ́ ohun tí Pétérù gbà wá níyànjú ni pé ká ní “ìfẹ́ ará” sí gbogbo àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ìyẹn irú ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín àwọn ọmọ ìyá.—1 Pét. 2:17.

11. Kí ni “ìfẹ́ tó jinlẹ̀”?

11 Pétérù rọ̀ wá pé ká “ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí ara [wa] látọkàn wá.” Nínú ẹsẹ yìí, ‘ìfẹ́ tó tọkàn wá’ ni pé ká fìfẹ́ hàn sẹ́nì kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, kí la máa ṣe tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣẹ̀ wá tàbí tó ṣe ohun tó dùn wá gan-an? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó máa kọ́kọ́ wá sí wa lọ́kàn ni bá a ṣe máa gbẹ̀san dípò ká fìfẹ́ hàn sí i. Àmọ́ ohun tí Jésù kọ́ Pétérù ni pé inú Ọlọ́run kì í dùn sáwọn tó bá ń gbẹ̀san. (Jòh. 18:​10, 11) Pétérù sọ pé: “Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, ẹ má sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù san ọ̀rọ̀ àbùkù. Kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ máa súre.” (1 Pét. 3:9) Torí náà, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ tó tọkàn wá mú ká máa finúure hàn sáwọn ará, ká sì máa gba tiwọn rò kódà nígbà tí wọ́n bá ṣe ohun tó dùn wá.

12. (a) Kí ni ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tún máa mú ká ṣe? (b) Kí ni wàá máa ṣe bó o ṣe rí i nínú fídíò Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Da Àárín Yín Rú?

12 Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pétérù kọ, ó lo gbólóhùn náà “ìfẹ́ tó jinlẹ̀.” “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀” ni irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń bò mọ́lẹ̀, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ díẹ̀. (1 Pét. 4:8) Ó ṣeé ṣe kí Pétérù rántí ohun tí Jésù kọ́ ọ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa dárí jini. Nígbà tá à ń sọ yìí, Pétérù gbà pé èèyàn dáadáa lòun nígbà tó sọ pé òun máa dárí ji arákùnrin òun ní “ìgbà méje.” Àmọ́ ohun tí Jésù kọ́ Pétérù àti àwa náà ni pé ká máa dárí ji ara wa ní “ìgbà àádọ́rin lé méje (77),” ìyẹn ni pé ká máa dárí ji ara wa fàlàlà. (Mát. 18:​21, 22) Tí kò bá rọrùn fún ẹ láti ṣe ohun tí Jésù sọ yìí, má jẹ́ kó sú ẹ. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ló máa ń ṣòro fún láti dárí jini torí pé aláìpé ni wá. Torí náà, ohun tó ṣe pàtàkì jù báyìí ni pé kó o dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́, kó o sì wá àlàáfíà pẹ̀lú ẹ̀. c

Ẹ̀YIN ALÀGBÀ, Ẹ MÁA BÓJÚ TÓ ÀWỌN ARÁ

13. Kí ló lè mú kó ṣòro fáwọn alàgbà láti bójú tó àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nínú ìjọ?

13 Ó dájú pé Pétérù ò gbàgbé ohun tí Jésù sọ fún un nígbà tí Jésù jíǹde pé: “Máa bójú tó àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” (Jòh. 21:16) Tó o bá jẹ́ alàgbà, ó yẹ kó o mọ̀ pé àṣẹ Jésù yìí kan ìwọ náà. Àmọ́, ó lè má rọrùn fún ẹ láti máa ráyè ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí. Ìdí sì ni pé ẹ̀yin alàgbà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ pèsè ohun tí ìdílé yín nílò, kẹ́ ẹ máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run, kẹ́ ẹ sì máa wáyè láti wà pẹ̀lú wọn kí wọ́n lè mọ̀ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ máa ń fìtara wàásù, ẹ sì máa ń múra iṣẹ́ tẹ́ ẹ ní nípàdé àti láwọn àpéjọ wa. Kódà, àwọn kan lára yín tún máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC), àwọn kan sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ (LDC). Ẹ ò rí i pé ọwọ́ àwọn alàgbà máa ń dí gan-an!

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ àwọn alàgbà máa ń dí gan-an, àwọn alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ máa ń bójú tó àwa èèyàn Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 14-15)

14. Kí ló máa ran ẹ̀yin alàgbà lọ́wọ́ láti máa bójú tó àwọn ará? (1 Pétérù 5:​1-4)

14 Pétérù gba àwọn alàgbà nímọ̀ràn pé kí wọ́n “máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run.” (Ka 1 Pétérù 5:​1-4.) Tó bá jẹ́ pé alàgbà ni ẹ́, ó dájú pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ, ó sì wù ẹ́ kó o máa bójú tó wọn. Àmọ́ nígbà míì, ọwọ́ ẹ lè dí tàbí kó rẹ̀ ẹ́ débi pé o ò lè bójú tó àwọn ará. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe? Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà. Pétérù sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe ìránṣẹ́, kó ṣe é bí ẹni tó gbára lé okun tí Ọlọ́run ń fúnni.” (1 Pét. 4:11) Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan níṣòro tó jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ẹ̀. Àmọ́, máa rántí pé Jésù Kristi tó jẹ́ “olórí olùṣọ́ àgùntàn” máa ṣe ju ohun tó o lè ṣe fún wọn. Ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí, á sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ayé tuntun. Ohun tí Jèhófà fẹ́ kẹ́yin alàgbà máa ṣe ni pé kẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, kẹ́ ẹ máa bójú tó wọn, kẹ́ ẹ sì “jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo.”

15. Báwo ni alàgbà kan ṣe máa ń bójú tó àwọn ará? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Ó ti pẹ́ tí arákùnrin kan tó ń jẹ́ William ti di alàgbà, ó sì mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa bójú tó àwọn ará. Nígbà tí àrùn kòrónà bẹ̀rẹ̀, òun àtàwọn alàgbà tó kù pinnu pé àwọn gbọ́dọ̀ máa kàn sí gbogbo àwọn ará tó wà ní àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó sọ ìdí tí àwọn fi ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló jẹ́ pé àwọn nìkan ni wọ́n dá wà nílé, wọn ò rẹ́ni fọ̀rọ̀ lọ̀, tí wọn ò bá sì ṣọ́ra, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í ro èròkerò.” Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá níṣòro, Arákùnrin William máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí i kó lè mọ ohun tó nílò gan-an àtohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Lẹ́yìn ìyẹn, á wá ohun tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn fídíò tó wà lórí ìkànnì wa ló máa ń lò. Ó tún sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì láti máa bójú tó àwọn ará wa báyìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. A máa ń ṣiṣẹ́ kára gan-an ká lè kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, ṣé kò wá yẹ ká ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fáwọn ará wa kí wọ́n má bàa fi Jèhófà sílẹ̀.”

JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ PARÍ ÌDÁLẸ́KỌ̀Ọ́ Ẹ

16. Báwo la ṣe lè fi ohun tá a kọ́ nínú àwọn lẹ́tà tí Pétérù kọ sílò?

16 A ti gbé àwọn ẹ̀kọ́ díẹ̀ yẹ̀ wò nínú lẹ́tà méjèèjì tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí Pétérù láti kọ. Ó ṣeé ṣe kó o ti rí àwọn ibi tó yẹ kó o ti ṣàtúnṣe. Bí àpẹẹrẹ, ṣé wàá fẹ́ túbọ̀ máa ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ohun rere tá a máa rí nínú ayé tuntun? Ṣé o ti pinnu láti máa wàásù níbi iṣẹ́, nílé ìwé àti láwọn ibòmíì? Ṣé o ti kíyè sí àwọn ọ̀nà míì tó o lè túbọ̀ máa fìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ? Ẹ̀yin alàgbà, ṣé ẹ ti ṣe tán láti máa fìtara bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà tọkàntọkàn? Tó o bá ṣàyẹ̀wò ara ẹ dáadáa, o lè rí i pé ó láwọn ibi tó o kù sí, àmọ́ má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Bíbélì sọ pé: “Onínúure ni [Jésù] Olúwa,” ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. (1 Pét. 2:3) Pétérù fi dá wa lójú pé: “Ọlọ́run . . . máa fúnra rẹ̀ parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yín. Ó máa fún yín lókun, ó máa sọ yín di alágbára, ó sì máa fẹsẹ̀ yín múlẹ̀ gbọn-in.”—1 Pét. 5:10.

17. Tá ò bá jẹ́ kó sú wa bí Jèhófà ṣe ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́, àǹfààní wo la máa rí?

17 Ìgbà kan wà tí Pétérù ronú pé òun ò yẹ lẹ́ni tó ń di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Lúùkù 5:8) Àmọ́ torí pé Jèhófà àti Jésù ràn án lọ́wọ́, ó ṣiṣẹ́ kára kó lè máa jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi nìṣó. Torí náà, Jèhófà fún Pétérù láǹfààní láti “wọlé fàlàlà sínú Ìjọba ayérayé ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.” (2 Pét. 1:11) Ẹ ò rí i pé èrè ńlá nìyẹn! Tá a bá fara wé Pétérù, tá a jẹ́ kí Jèhófà dá wa lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, tá ò sì jẹ́ kó sú wa, àá gba èrè ìyè àìnípẹ̀kun. ‘Ọwọ́ wa sì máa tẹ èrè ìgbàgbọ́ wa, ìyẹn ìgbàlà wa.’—1 Pét. 1:9.

ORIN 109 Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá

a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí àwọn ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú àwọn lẹ́tà tí Pétérù kọ ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò. Bákan náà, àpilẹ̀kọ yìí máa ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn wọn láṣeyanjú.

b Ó ṣeé ṣe káwọn Kristẹni tó ń gbé ní Palẹ́sínì ti rí àwọn lẹ́tà tí Pétérù kọ sí wọn gbà kó tó di ọdún 66 S.K. nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù kọ́kọ́ gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.

c Wo fídíò Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Da Àárín Yín Rú lórí ìkànnì jw.org.