Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó O Lè Fi Ṣèwádìí

Ohun Tó O Lè Fi Ṣèwádìí

Àwọn Nǹkan Tá A Lè Fi Kọ́ Àwọn Ọmọdé

Iṣẹ́ ẹ̀yin òbí ni láti kọ́ àwọn ọmọ yín nípa Jèhófà, iṣẹ́ náà ò sì rọrùn rárá. (Éfé. 6:4) Torí náà, ètò Ọlọ́run tẹ àwọn ìwé, wọ́n ṣe àwọn fídíò àtàwọn orin tẹ́ ẹ lè fi ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́. Báwo lẹ̀yin òbí ṣe máa lo àwọn nǹkan yìí?

  • Lọ wo jw.org. Àwọn fídíò àtàwọn àpilẹ̀kọ tá a ṣe fáwọn ọmọdé wà níbẹ̀. a Kó o lè rí àwọn nǹkan náà, tẹ “Ọmọdé” tàbí “Ọ̀dọ́” sínú àpótí tá a fi ń wá nǹkan.

  • Yan àwọn ohun tó máa ran ọmọ ẹ lọ́wọ́. Àwọn nǹkan tó wà ní abala “Ọmọdé” máa jẹ́ kó o yan ohun tó máa ran ọmọ ẹ lọ́wọ́. Kó o lè rí àwọn nǹkan náà, tẹ “Iṣẹ́ Ìjọsìn Ìdílé” sínú àpótí tá a fi ń wá nǹkan.

  • Ṣàlàyé ẹ̀kọ́ náà fún wọn. Má kàn ní kí ọmọ ẹ máa wo àwọn fídíò náà, kó sì máa kọ̀rọ̀ sínú àwọn eré aláwòrán náà torí pé ó ń dí ẹ lọ́wọ́ tàbí torí pé o ò fẹ́ kó máa fàkókò ṣòfò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ náà fún ọmọ ẹ, kó lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.

a Ní báyìí, gbogbo fídíò tá a ṣe fáwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́ ló wà lórí JW Library®, àmọ́ àwọn nǹkan tí wọ́n lè yàwòrán sí tàbí tí wọ́n lè kọ nǹkan sí tó wà níbẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀.