Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ní alẹ́ ọjọ́ tí Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, ibo làwọn àádọ́rin (70) ọmọlẹ́yìn tó rán jáde lọ wàásù wà? Ṣé wọ́n ti sá fi Jésù sílẹ̀ ni?

Ní alẹ́ ọjọ́ tí Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, àwọn àádọ́rin (70) ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ò sí lọ́dọ̀ ẹ̀, torí náà kò yẹ ká máa rò pé Jésù ti kọ̀ wọ́n tàbí pé wọ́n ti sá fi Jésù sílẹ̀. Ó kàn wu Jésù kó wà pẹ̀lú kìkì àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn ni.

Ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni àwọn méjìlá (12) àtàwọn àádọ́rin (70) yẹn. Lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tó pọ̀ ló ti yan àwọn ọkùnrin méjìlá (12) tó pè ní àpọ́sítélì. (Lúùkù 6:12-16) Nígbà tó wà ní Gálílì, ó “pe àwọn Méjìlá náà,” ó sì “rán wọn jáde láti wàásù Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa múni lára dá.” (Lúùkù 9:1-6) Àmọ́ nígbà tó dé Jùdíà, ó ‘yan àwọn àádọ́rin (70) míì, ó sì rán wọn jáde ní méjì-méjì.’ (Lúùkù 9:51; 10:1) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Jésù wá láwọn ọmọ ẹ̀yìn tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run káàkiri.

Àwọn Júù tó di ọmọlẹ́yìn Jésù ṣì máa ṣe Ìrékọjá tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn àti ìdílé wọn ló máa ṣe é. (Ẹ́kís. 12:6-11, 17-20) Bí ọjọ́ tí Jésù máa kú ṣe ń sún mọ́lé, òun àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ méjìlá (12) lọ sí Jerúsálẹ́mù. Àmọ́, kò pe gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tó wà lágbègbè Jùdíà, Gálílì àti Pèríà pé kí wọ́n wá bá òun ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá yẹn. Torí náà, ó hàn gbangba pé ó wu Jésù láti wà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ nìkan lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ó sọ fún wọn pé: “Ó wù mí gan-an pé kí n jẹ Ìrékọjá yìí pẹ̀lú yín kí n tó jìyà.”—Lúùkù 22:15.

Ìdí pàtàkì wà tí Jésù fi sọ̀rọ̀ yìí. Ìdí náà ni pé Jésù máa tó kú bí “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run tó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” (Jòh. 1:29) Ìlú Jerúsálẹ́mù nìyẹn ti máa ṣẹlẹ̀, níbi tí wọ́n ti máa ń rú ẹbọ sí Ọlọ́run tipẹ́tipẹ́. Òótọ́ ni pé àgùntàn Ìrékọjá táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì ṣe wọ́n láǹfààní torí pé Jèhófà dá wọn sílẹ̀, àmọ́ ikú Jésù ṣe wá láǹfààní tó jùyẹn lọ torí ó dá wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (1 Kọ́r. 5:7, 8) Ohun tí Jésù ṣe yìí jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn Méjìlá náà láti wà lára ìpìlẹ̀ ìjọ Kristẹni. (Éfé. 2:20-22) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, wọ́n kọ orúkọ “àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” sára “òkúta ìpìlẹ̀ méjìlá (12)” ti ìlú mímọ́ náà, Jerúsálẹ́mù. (Ìfi. 21:10-14) Ó dájú pé àwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ máa kó ipa pàtàkì kí ìfẹ́ Ọlọ́run lè ṣẹ. Torí náà, ó yé wa pé Jésù fẹ́ kí wọ́n wà pẹ̀lú òun nígbà tó máa ṣe Ìrékọjá tó kẹ́yìn àti Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tó ṣe lẹ́yìn náà.

Àwọn àádọ́rin náà àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù ò sí lọ́dọ̀ Jésù nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Síbẹ̀, gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó jẹ́ olóòótọ́ ló máa jàǹfààní Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tí Jésù dá sílẹ̀. Torí náà, gbogbo àwọn tó bá di Kristẹni ẹni àmì òróró máa wà lára àwọn tí Jésù bá dá májẹ̀mú Ìjọba tó sọ fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn.—Lúùkù 22:29, 30.