Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 36

ORIN 89 Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún

“Ẹ Máa Ṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Náà Sọ”

“Ẹ Máa Ṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Náà Sọ”

“Ẹ máa ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ náà sọ, ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán.”JÉM. 1:22.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó túbọ̀ wù wá láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká máa ronú nípa ohun tá a kà, ká sì máa fi í sílò láyé wa.

1-2. Kí ló máa ń jẹ́ káwa ìránṣẹ́ Jèhófà láyọ̀? (Jémíìsì 1:22-25)

 JÈHÓFÀ àti Ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n fẹ́ ká láyọ̀. Ẹni tó kọ Sáàmù 119:2 sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń kíyè sí àwọn ìránnilétí rẹ̀, àwọn tó ń fi gbogbo ọkàn wọn wá a.” Jésù náà jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí nígbà tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”Lúùkù 11:28.

2 Kí nìdí táwa ìránṣẹ́ Jèhófà fi máa ń láyọ̀? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń jẹ́ ká láyọ̀, àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù lára ẹ̀ ni pé a máa ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, a sì máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi ohun tá a kọ́ sílò.Ka Jémíìsì 1:22-25.

3. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń fi ohun tá a kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò?

3 Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí tá a bá ń “ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ náà sọ.” Bí àpẹẹrẹ, a mọ̀ pé tá a bá ń ṣe ohun tá a kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, inú Jèhófà máa dùn sí wa, ìyẹn sì máa jẹ́ ká láyọ̀. (Oníw. 12:13) Bákan náà, ó máa jẹ́ kí àwa àtàwọn tá a jọ wà nínú ìdílé túbọ̀ sún mọ́ra, ó sì máa jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ. Ó ṣeé ṣe kíwọ náà gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń sá fáwọn nǹkan tó lè mú ká kó síṣòro táwọn tí ò tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà máa ń ní. Lẹ́yìn tí Ọba Dáfídì mẹ́nu ba àwọn òfin Jèhófà, àwọn ìlànà àtàwọn ìdájọ́ ẹ̀ nínú orin tó kọ, ohun tó fi parí ẹ̀ ni pé: “Èrè ńlá wà nínú pípa wọ́n mọ́,” àwa náà sì gbà pé òótọ́ ló sọ.—Sm. 19:7-11.

4. Kí nìdí tí kì í fi í rọrùn nígbà míì láti ṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ?

4 Ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti ṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ. Torí pé ọwọ́ wa máa ń dí, a gbọ́dọ̀ máa wáyè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ ká lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àbá kan yẹ̀ wò táá jẹ́ ká lè máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ohun táá jẹ́ ká máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà, ká sì máa fi í sílò nígbèésí ayé wa.

MÁA WÁYÈ KA Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

5. Àwọn nǹkan wo ló sábà máa ń jẹ́ kọ́wọ́ wa dí?

5 Ọ̀pọ̀ lára àwa èèyàn Jèhófà lọwọ́ wa sábà máa ń dí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àkókò la máa ń lò nídìí àwọn nǹkan tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ká lè bójú tó ara wa àti ìdílé wa. (1 Tím. 5:8) Àwọn míì lára wa tún máa ń bójú tó àwọn mọ̀lẹ́bí wa tó ti dàgbà tàbí tó ń ṣàìsàn. Bákan náà, gbogbo wa ló yẹ ká máa bójú tó ìlera wa, ìyẹn sì máa ń gba àkókò. Yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan tá à ń ṣe yìí, a tún láwọn iṣẹ́ tá à ń bójú tó nínú ìjọ. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni bá a ṣe ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́, pẹ̀lú bí ọwọ́ wa ṣe dí tó yìí, báwo lo ṣe lè máa wáyè ka Bíbélì déédéé, kó o máa ronú lórí ohun tó o kà, kó o sì máa fi í sílò?

6. Kí lo lè ṣe kó o lè máa ka Bíbélì déédéé? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

6 Bíbélì kíkà wà lára “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” fáwa Kristẹni, torí náà ọwọ́ pàtàkì ló yẹ ká fi mú un. (Fílí. 1:10) Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó lè mú kéèyàn láyọ̀, Sáàmù kìíní sọ pé: “Òfin Jèhófà máa ń mú inú rẹ̀ dùn, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru.” (Sm. 1:1, 2) Kò sí àní-àní pé kéèyàn tó lè láyọ̀, àfi kó máa wáyè ka Bíbélì déédéé. Àmọ́ ìgbà wo ló dáa jù téèyàn lè ka Bíbélì? Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu àkókò tó máa rọ̀ ọ́ lọ́rùn. Àmọ́, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ àkókò tó máa rọrùn fún ẹ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Victor sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò kì í tètè jí, àárọ̀ ni mo máa ń ka Bíbélì torí àwọn nǹkan tó máa ń pín ọkàn mi níyà lásìkò yẹn ò pọ̀, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó rọrùn fún mi láti pọkàn pọ̀ dáadáa.” Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Torí náà, á dáa kó o bi ara ẹ pé, ‘Àsìkò wo ló rọrùn fún mi jù láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́?’

Ìgbà wo ló rọ̀ ẹ́ lọ́rùn jù láti máa ka Bíbélì déédéé? (Wo ìpínrọ̀ 6)


MÁA RONÚ JINLẸ̀ NÍPA OHUN TÓ O KÀ

7-8. Kí ló lè mú ká má fi bẹ́ẹ̀ jàǹfààní látinú Bíbélì tá à ń kà? Sọ àpèjúwe kan.

7 Tá ò bá ṣọ́ra, a lè ka ọ̀pọ̀ nǹkan, síbẹ̀ kó má fi bẹ́ẹ̀ wọ̀ wá lọ́kàn. Ṣé ó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí pé o ka nǹkan kan, àmọ́ láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀, o ti gbàgbé ohun tó o kà? Ọ̀pọ̀ wa nirú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí rí. Ohun kan náà lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ń ka Bíbélì. Ó ṣeé ṣe ká ti pinnu iye orí Bíbélì tá a fẹ́ máa kà lójoojúmọ́. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn dáa gan-an. Ó ṣe tán, ó yẹ ká máa pinnu ohun tá a fẹ́ ṣe, ká sì sapá láti ṣe é. (1 Kọ́r. 9:26) Ohun tó dáa ni téèyàn bá ń ka Bíbélì, àmọ́ tá a bá fẹ́ jàǹfààní tó pọ̀ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó yẹ ká ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.

8 Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná: Àwọn ewéko máa ń nílò òjò kí wọ́n má bàa kú. Àmọ́ tí òjò bá pọ̀ jù, ó máa ba àwọn ewéko náà jẹ́. Torí náà, àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò ò ní ṣàǹfààní kankan fáwọn ewéko. Ìdí sì ni pé ó máa gba àkókò kí ilẹ̀ tó lè fa omi náà mu dáadáa, kó sì ṣàǹfààní fáwọn ewéko yẹn. Lọ́nà kan náà, kò yẹ ká máa kánjú ka Bíbélì torí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní lè ronú lórí ohun tá a kà, a ò ní rántí ẹ̀, a ò sì ní lè fi í sílò.—Jém. 1:24.

Bó ṣe máa ń gba àkókò kí ilẹ̀ tó fa omi mu dáadáa, ó yẹ káwa náà máa wáyè ronú lórí ohun tá a kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì fi í sílò (Wo ìpínrọ̀ 8)


9. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí i pé a ti ń kánjú ka Bíbélì?

9 Ṣé o ti kíyè sí i pé àwọn ìgbà míì wà tó o máa ń kánjú ka Bíbélì? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe? Tó o bá ń ka Bíbélì, o lè dánu dúró díẹ̀, kó o sì ronú lórí ohun tó ò ń kà tàbí kó o kà á tán kó o wá ronú lórí ohun tó o kà. Kò yẹ kíyẹn ṣòro fún ẹ láti ṣe. O lè fi kún àkókò tó o fi ń kẹ́kọ̀ọ́, kó o lè máa ráyè ronú lórí ohun tó o kà. Bákan náà, o lè dín iye ẹsẹ Bíbélì tó ò ń kà kù, kó o lè ráyè ronú jinlẹ̀ lórí ẹ̀. Arákùnrin Victor tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Orí kan péré ni mo máa ń kà nínú Bíbélì, mi ò kì í ka orí tó pọ̀ jù. Torí pé àárọ̀ ni mo sì máa ń kà á, ó máa ń jẹ́ kí n lè ronú lórí ẹ̀ jálẹ̀ ọjọ́ yẹn.” Ọ̀nà yòówù kó o máa gbà ka Bíbélì, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o máa kà á lọ́nà tó máa jẹ́ kó o jàǹfààní tó pọ̀.—Sm. 119:97; wo àpótí náà “ Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Kó O Ronú Lé.”

10. Ṣàpèjúwe bó o ṣe lè fi ohun tó ò ń kọ́ sílò. (1 Tẹsalóníkà 5:17, 18)

10 Ó ṣe pàtàkì kó o máa fi ohun tó ò ń kà nínú Bíbélì sílò láìka bí àkókò tó o fi ń kà á ṣe pọ̀ tó tàbí ìgbà tó ò ń kà á. Tó o bá ń ka Bíbélì, bi ara ẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fi ohun tí mò ń kà yìí sílò nísinsìnyí tàbí lọ́jọ́ iwájú?’ Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o ka 1 Tẹsalóníkà 5:17, 18. (Kà á.) Lẹ́yìn tó o bá ka àwọn ẹsẹ yìí, dúró díẹ̀ kó o wá bi ara ẹ pé, ìgbà mélòó ni mo máa ń gbàdúrà, ṣé ó sì máa ń jẹ́ látọkàn wá? Bákan náà, o tún lè ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ tó yẹ kó o dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. O lè wá rántí mẹ́ta lára wọn, kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ́jú díẹ̀ lo fi ronú lórí àwọn nǹkan yìí, ìyẹn máa jẹ́ kó o fi àwọn nǹkan tó ò ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Wá wo àǹfààní tó o máa rí tó bá jẹ́ pé bó o ṣe ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ nìyẹn, tó o sì ń ronú jinlẹ̀ lórí ẹ̀! Ó dájú pé ìyẹn máa jẹ́ kó o di olùṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ tó o bá wá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí ńkọ́?

MỌ ÀWỌN ÀTÚNṢE TÓ YẸ KÓ O ṢE

11. Kí ló lè mú kí nǹkan sú ẹ nígbà míì? Sọ àpẹẹrẹ kan.

11 Nígbà míì tó o bá ń ka Bíbélì, inú ẹ lè má dùn tó o bá rí i pé ohun tó yẹ kó o ṣàtúnṣe ẹ̀ pọ̀ gan-an. Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tó o ka Bíbélì, o rí ìmọ̀ràn kan níbẹ̀ tó sọ pé kò yẹ kó o máa ṣojúsàájú. (Jém. 2:1-8) O wá rí i pé ó yẹ kó o ṣàtúnṣe bó o ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn, o sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyẹn dáa gan-an. Lọ́jọ́ kejì, o tún ka ẹsẹ Bíbélì tó jẹ́ kó o mọ̀ pé ó yẹ kó o ṣàtúnṣe bó o ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. (Jém. 3:1-12) O rí i pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ọ̀rọ̀ tó máa ń jáde lẹ́nu ẹ ò dáa tó. Torí náà, o pinnu pé wàá túbọ̀ máa wo ibi táwọn èèyàn dáa sí, wàá sì máa sọ̀rọ̀ tó gbé wọn ró. Lọ́jọ́ kẹta, Bíbélì tó o kà jẹ́ kó o rí i pé kò yẹ kó o máa bá àwọn èèyàn ayé ṣọ̀rẹ́. (Jém. 4:4-12) O tún rí i pé ó yẹ kó o máa fọgbọ́n yan irú eré ìnàjú tó o máa ṣe. Nígbà tó fi máa di ọjọ́ kẹrin, nǹkan lè ti tojú sú ẹ nítorí gbogbo àtúnṣe tó o fẹ́ ṣe yìí.

12. Tó o bá ń ka Bíbélì tó o sì rí i pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan, kí nìdí tó ò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú ẹ? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

12 Tó o bá rí i pé àwọn àtúnṣe kan wà tó yẹ kó o ṣe, má jẹ́ kó sú ẹ. Ṣe nìyẹn fi hàn pé o nírẹ̀lẹ̀, ohun tó dáa lo sì fẹ́ ṣe. Tí ẹni tó nírẹ̀lẹ̀ tí kì í sì í tan ara ẹ̀ jẹ bá ń ka Ìwé Mímọ́, àwọn apá ibi tó yẹ kó ti ṣàtúnṣe ló máa gbájú mọ́. a Má gbàgbé pé díẹ̀díẹ̀ lèèyàn máa ń gbé “ìwà tuntun” wọ̀, kì í ṣe iṣẹ́ ọjọ́ kan ṣoṣo. (Kól. 3:10; fi wé àlàyé ọ̀rọ̀ is being made new nínú nwtsty-E.) Torí náà, kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ?

13. Ọ̀nà wo ló dáa jù láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ kó o ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Dípò kó o ṣe gbogbo àtúnṣe tó yẹ kó o ṣe lẹ́ẹ̀kan náà, o ò ṣe gbìyànjú láti kọ́kọ́ ṣe ẹyọ kan tàbí méjì nínú ẹ̀. (Òwe 11:2) Gbìyànjú èyí wò: Kọ gbogbo àtúnṣe tó yẹ kó o ṣe sílẹ̀, mú ẹyọ kan tàbí méjì tó o máa kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ lé, kó o sì ṣiṣẹ́ lórí àwọn tó kù lẹ́yìn náà. Àmọ́, ibo ló yẹ kó o ti bẹ̀rẹ̀?

Dípò kó o ṣe gbogbo àtúnṣe tó yẹ kó o ṣe lẹ́ẹ̀kan náà, o ò ṣe gbìyànjú láti kọ́kọ́ ṣe ẹyọ kan tàbí méjì nínú ẹ̀? (Wo ìpínrọ̀ 13-14)


14. Àwọn àtúnṣe wo ló yẹ kó o kọ́kọ́ ṣe?

14 O lè pinnu pé àwọn àtúnṣe tó máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn lo máa kọ́kọ́ ṣe. O sì lè pinnu pé èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú ẹ̀ lo máa kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ lé. Tó o bá ti mú èyí tó o máa kọ́kọ́ ṣe, ohun tó kàn ni pé kó o ṣèwádìí nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run, irú bí Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè ṣe àwọn àtúnṣe yẹn, kó jẹ́ ‘kó wù ẹ́ láti gbé ìgbésẹ̀, kó sì fún ẹ ní agbára láti ṣe é.’ (Fílí. 2:13) Lẹ́yìn náà, fi àwọn ohun tó o ti kọ́ sílò. Tó o bá rí i pé o ti ṣàṣeyọrí nínú àwọn àtúnṣe tó o kọ́kọ́ ṣe, ó máa wù ẹ́ láti ṣe àwọn àtúnṣe tó kù. Kódà, tó o bá rí i pé o ti túbọ̀ ní ànímọ́ Kristẹni kan, ó máa rọrùn fún ẹ láti láwọn ànímọ́ Kristẹni míì.

JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN “WÀ LẸ́NU IṢẸ́” LÁYÉ Ẹ

15. Báwo làwa èèyàn Jèhófà ṣe yàtọ̀ sáwọn míì tó ń ka Bíbélì? (1 Tẹsalóníkà 2:13)

15 Àwọn kan sọ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ti ka Bíbélì. Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ni wọ́n ń ṣe ohun tí Bíbélì sọ? Ṣé wọ́n máa ń fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò, ṣé wọ́n sì ń jẹ́ kó yí ìgbésí ayé wọn pa dà? Ó bani nínú jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà, kì í rí bẹ́ẹ̀. Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ àwa èèyàn Jèhófà yàtọ̀ pátápátá síyẹn! Bíi tàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, àwa náà gba Bíbélì “gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ lóòótọ́, bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Bákan náà, a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi ohun tá à ń kọ́ sílò nígbèésí ayé wa.—Ka 1 Tẹsalóníkà 2:13.

16. Kí ló máa jẹ́ ká di olùṣe Ọ̀rọ̀ náà?

16 Kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì fi í sílò. Ó lè ṣòro fún wa láti wáyè kà á nígbà míì. Ìgbà míì sì wà tá a máa ń sáré kà á tíyẹn ò sì ní jẹ́ kí ohun tá a kà wọ̀ wá lọ́kàn. Àwọn àtúnṣe tá a fẹ́ ṣe sì lè pọ̀ débi pé gbogbo nǹkan máa wá tojú sú wa. Ohun yòówù kó jẹ́ ìṣòro ẹ, o ṣì lè borí ẹ̀. Lọ́lá ìtìlẹ́yìn Jèhófà, wàá borí ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká pinnu pé a máa jẹ́ kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, a ò sì ní jẹ́ olùgbọ́ nìkan, àmọ́ a máa jẹ́ olùṣe Ọ̀rọ̀ náà. Torí náà, ó dájú pé bá a bá ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń fi sílò láyé wa, bẹ́ẹ̀ layọ̀ wa ṣe máa pọ̀ tó.—Jém. 1:25.

ORIN 94 A Mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

a Tún wo fídíò yìí lórí jw.org, Ohun Táwọn Ojúgbà Rẹ Sọ—Kíka Bíbélì.