Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Bù Kún Mi Gan-an Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Ẹ̀

Jèhófà Bù Kún Mi Gan-an Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Ẹ̀

NÍ 1951, mo lọ sí abúlé kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Rouyn, nílùú Quebec, lórílẹ̀-èdè Kánádà. Nígbà tí mo débẹ̀, mo lọ sílé tí wọ́n fún mi ní àdírẹ́sì ẹ̀, mo sì kan ilẹ̀kùn. Míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Marcel Filteau a tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ló wá ṣílẹ̀kùn. Ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún (23) ni, ó sì ga, àmọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) péré lèmi, mo sì kúrú jù ú lọ. Torí náà, mo fi lẹ́tà tí wọ́n fi sọ mí di aṣáájú-ọ̀nà hàn án. Ó kà á, ó wojú mi, ó wá bi mí pé, “Ṣé mọ́mì ẹ mọ̀ pé o wá síbí ṣá?”

ILÉ TÍ WỌ́N TI Ń ṢE Ẹ̀SÌN Ọ̀TỌ̀Ọ̀TỌ̀ NI WỌ́N TI TỌ́ MI DÀGBÀ

Ọdún 1934 ni wọ́n bí mi. Ìlú Switzerland làwọn òbí mi ti ṣí wá sórílẹ̀-èdè Kánádà, a sì ń gbé nílùú Timmins tí wọ́n ti ń wa kùsà ní Ontario. Ní nǹkan bí ọdún 1939, màámi bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, wọ́n sì ń lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n máa ń mú èmi, àwọn ẹ̀gbọ́n mi méjì àtàwọn àbúrò mi mẹ́ta dání tí wọ́n bá ń lọ. Kò sì pẹ́ rárá tí màámi fi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Inú dádì wa ò dùn pé mọ́mì wa di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ Mọ́mì nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ gan-an, wọ́n sì ti pinnu pé kò sí ohunkóhun tó máa mú káwọn fi í sílẹ̀. Kódà, wọ́n fìtara sin Jèhófà láwọn ọdún 1940 tí ìjọba fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kánádà. Wọ́n máa ń finúure hàn sí Dádì, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni Dádì máa ń bú wọn. Àpẹẹrẹ àtàtà tí Mọ́mì fi lélẹ̀ ló jẹ́ kí èmi, àwọn ẹ̀gbọ́n mi àtàwọn àbúrò mi kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Inú wa dùn gan-an pé bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ìwà Dádì bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà, wọ́n sì ń fìfẹ́ hàn sí wa.

MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ÌSÌN ALÁKÒÓKÒ KÍKÚN

Ní August 1950, mo lọ sí Àpéjọ Ìbísí Ìjọba tá a ṣe nílùú New York City. Nígbà tí mo gbọ́ bí wọ́n ṣe fọ̀rọ̀ wá àwọn tó lọ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì lẹ́nu wò, tí mo sì rí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láyé, ó túbọ̀ wá wù mí láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà! Torí náà, mo pinnu pé kò sóhun tó máa dí mi lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí mo délé ni mo gba fọ́ọ̀mù aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ẹ̀ka ọ́fíìsì Kánádà wá fèsì pé á dáa kí n kọ́kọ́ ṣèrìbọmi ná. Torí náà, mo ṣèrìbọmi ní October 1, 1950. Oṣù kan lẹ́yìn náà, mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, wọ́n sì ní kí n máa lọ sìn nílùú Kapuskasing. Ìlú yẹn jìn gan-an síbi tá à ń gbé nígbà yẹn.

Mò ń wàásù nílùú Quebec

Nígbà òtútù ọdún 1951, ẹ̀ka ọ́fíìsì gba àwọn ará níyànjú pé àwọn tó bá gbọ́ èdè Faransé lè lọ sí ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè náà nílùú Quebec. Ìdí sì ni pé a nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i níbẹ̀. Torí pé mo gbọ́ èdè Faransé àti Gẹ̀ẹ́sì dáadáa, mo gbà láti lọ, wọ́n sì rán mi lọ sílùú Rouyn. Mi ò mọ ẹnì kankan níbẹ̀. Àdírẹ̀sì ibi tí mò ń lọ nìkan ni mo mọ̀ bí mo ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan. Èmi àti Marcel di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, a sì jọ gbádùn iṣẹ́ ìsìn wa fún ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà. Nígbà tó yá, mo di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Torí náà, gbogbo nǹkan ń lọ dáadáa níbẹ̀.

MO LỌ SÍLÉ Ẹ̀KỌ́ GÍLÍÁDÌ, ÀMỌ́ MO TÚN NÍ LÁTI MÚ SÙÚRÙ

Nígbà tí mo wà ní Quebec, inú mi dùn nígbà tí wọ́n pè mí sí kíláàsì kẹrìndínlọ́gbọ̀n (26) ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì nílùú South Lansing, ní ìpínlẹ̀ New York. February 12, 1956 la kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n sì rán mi lọ sórílẹ̀-èdè Gánà, b ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà. Àmọ́ kí n tó lọ, mo gbọ́dọ̀ pa dà sí Kánádà fún “ọ̀sẹ̀ díẹ̀,” kí n lè lọ ṣe ìwé ìgbélùú mi.

Kò ní yà yín lẹ́nu pé oṣù méje gbáko ni mo fi dúró sílùú Toronto, lórílẹ̀-èdè Kánádà kí wọ́n tó ṣèwé náà. Ìdílé Cripps ló gbà mí sílé ní gbogbo àsìkò yẹn, ibẹ̀ ni mo sì ti mọ Sheila ọmọbìnrin wọn. Kò pẹ́ tá a fi bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ ara wa. Àmọ́ bí mo ṣe ń ronú láti bi í pé ṣé ó máa fẹ́ mi ni ìwé ìgbélùú mi dé. Torí náà, èmi àti Sheila gbàdúrà gan-an nípa ohun tó yẹ ká ṣe, a sì pinnu pé kí n máa lọ síbi tí ètò Ọlọ́run rán mi lọ. Àmọ́ a jọ gbà pé ká máa kọ lẹ́tà síra wa ká lè mọ̀ bóyá a máa lè fẹ́ra lọ́jọ́ iwájú. Ìpinnu yẹn ò rọrùn fáwa méjèèjì, àmọ́ nígbà tó yá, a rí i pé ohun tó yẹ ká ṣe nìyẹn.

Lẹ́yìn oṣù kan tí mo fi rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ ojú irin, nínú ọkọ̀ ojú omi àti ọkọ̀ òfúrufú, mo gúnlẹ̀ sílùú Accra, lórílẹ̀-èdè Gánà. Ètò Ọlọ́run wá ní kí n máa ṣiṣẹ́ alábòójútó agbègbè. Iṣẹ́ náà gba pé kí n máa rìnrìn àjò káàkiri orílẹ̀-èdè Gánà, kódà mo máa ń dé orílẹ̀-èdè Ivory Coast (tá à ń pè ní Côte d’Ivoire báyìí) àti Togoland (tá à ń pè ní Togo báyìí) tó wà nítòsí Gánà. Lọ́pọ̀ ìgbà, èmi nìkan ni mo máa ń rìnrìn àjò, mọ́tò tí ètò Ọlọ́run gbé fún mi ni mo sì máa ń lò. Mo mà gbádùn ìbẹ̀wò tí mo máa ń ṣe sọ́dọ̀ àwọn ará yẹn o!

Láwọn òpin ọ̀sẹ̀, mo máa ń níṣẹ́ ní àpéjọ àyíká. Àmọ́ torí pé a ò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ kankan, àwọn ará máa ń gé ọparun, wọ́n á rì í mọ́lẹ̀, wọ́n á sì fi imọ̀ bò ó kí oòrùn má bàa pa àwọn ará. Torí pé kò sí fìríìjì tí wọ́n lè kó ẹran tútù sí, wọ́n máa ń so ẹran mọ́lẹ̀, wọ́n á sì pa á tí wọ́n bá ti fẹ́ se oúnjẹ fáwọn tó wá sí àpéjọ náà.

Nígbà míì, àwọn nǹkan tó máa ń pa wá lẹ́rìn-ín máa ń ṣẹlẹ̀ láwọn àpéjọ yẹn. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí Arákùnrin Herb Jennings c tá a jọ ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ń sọ àsọyé lọ́wọ́, màlúù kan já látibi tí wọ́n so ó mọ́. Ó já wá sáàárín pèpéle àti ibi táwọn ará jókòó sí. Arákùnrin Herb wá dá ọ̀rọ̀ ẹ̀ dúró, ara màlúù náà ò sì balẹ̀. Àwọn arákùnrin mẹ́rin tó taagun dáadáa bá rá màlúù náà mú, wọ́n sì mú un pa dà lọ sílé ìdáná, làwọn ará bá hó yèè.

Ní àárín ọ̀sẹ̀, mo máa ń fi fíìmù The New World Society in Action han àwọn èèyàn láwọn abúlé tó wà nítòsí. Torí náà, mo máa ń ta aṣọ funfun sáàárín igi méjì, àwọn èèyàn á wá máa wo fíìmù náà lára aṣọ yẹn. Àwọn ará abúlé nífẹ̀ẹ́ fíìmù náà gan-an, ìdí sì ni pé ọ̀pọ̀ wọn ni ò wo fíìmù rí. Inú wọn máa ń dùn, wọ́n sì máa ń pàtẹ́wọ́ gan-an tí fíìmù náà bá ti dé ibi táwọn èèyàn ti ń ṣèrìbọmi. Fíìmù yẹn jẹ́ káwọn tó wò ó rí i pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà níṣọ̀kan kárí ayé.

A ṣègbéyàwó ní Gánà lọ́dún 1959

Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún méjì tí mo ti lò nílẹ̀ Áfíríkà, mo lọ sí àpéjọ àgbáyé tá a ṣe nílùú New York City, inú mi sì dùn gan-an pé mo lọ. Ayọ̀ mi kún nígbà tí mo rí Sheila níbẹ̀, ìlú Quebec tó ti ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ló sì ti wá sí àpéjọ yẹn. Lẹ́tà la fi ń bára wa sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí tá a ríra lójúkojú, mo bi í pé ṣé ó máa fẹ́ mi, ó sì gbà. Torí náà, mo kọ lẹ́tà sí Arákùnrin Knorr, d mo sì bi wọ́n pé ṣé wọ́n lè pe Sheila sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì kó lè wá bá mi ní Áfíríkà? Wọ́n sì gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀! Nígbà tó yá, Sheila náà dèrò Gánà. Ní October 3, 1959, a ṣègbéyàwó nílùú Accra. Àwa méjèèjì gbà pé Jèhófà ti bù kún wa gan-an torí pé a fi iṣẹ́ ìsìn ẹ̀ ṣáájú láyé wa.

A JỌ ṢIṢẸ́ ÌSÌN NÍ KAMẸRÚÙNÙ

Mò ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Kamẹrúùnù

Ní 1961, ètò Ọlọ́run rán wa lọ sórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù. Ọwọ́ mi máa ń dí gan-an torí iṣẹ́ tí wọ́n ní kí n lọ ṣe ni bá a ṣe máa dá ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun sílẹ̀ níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo ní láti kọ́ torí pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìránṣẹ́ ẹ̀ka ni. Àmọ́ ní 1965, àyẹ̀wò fi hàn pé Sheila ti lóyún. Ká sòótọ́, kò rọrùn fún wa láti gbà pé a máa di bàbá àti ìyá ìkókó. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, a gba kámú, inú wa sì ń dùn pé àwa náà máa di òbí. Àmọ́, bá a ṣe ń ṣètò láti pa dà sí Kánádà, àjálù burúkú kan ṣẹlẹ̀ sí wa.

Oyún bà jẹ́ lára Sheila, dókítà sì sọ fún wa pé ọkùnrin lọmọ náà. Ohun tá à ń sọ yìí ti lé láàádọ́ta (50) ọdún, síbẹ̀ a ò gbàgbé ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn bà wá nínú jẹ́ gan-an, a ò kúrò níbi tá a ti ń sìn torí pé a nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ náà gan-an.

Èmi àti Sheila ní Kamẹrúùnù lọ́dún 1965

Ní Kamẹrúùnù, wọ́n sábà máa ń ṣenúnibíni sáwọn ará torí pé wọn kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú. Ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ máa ń le gan-an tí wọ́n bá fẹ́ dìbò yan ààrẹ orílẹ̀-èdè. Ní May 13, 1970, ohun kan tá ò retí rárá ṣẹlẹ̀, ìjọba fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè yẹn. Wọ́n tún gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé, oṣù márùn-ún péré la ṣì lò níbẹ̀. Kò pé ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ìyẹn, ìjọba ní kí gbogbo míṣọ́nnárì títí kan èmi àti Sheila kúrò lórílẹ̀-èdè náà. Kò rọrùn fún wa rárá láti fi àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa sílẹ̀ torí a nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, a ò sì mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn lẹ́yìn tá a bá kúrò níbẹ̀.

Lẹ́yìn náà, a lo oṣù mẹ́fà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Faransé. Àtibẹ̀ ni mo ti ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti bójú tó àwọn ará tó wà ní Kamẹrúùnù. Ní December ọdún yẹn, ètò Ọlọ́run ní ká lọ máa sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Nàìjíríà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì yẹn ló wá bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó iṣẹ́ wa ní Kamẹrúùnù. Àwọn ará tó wà ní Nàìjíríà gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀, a sì gbádùn iṣẹ́ tá a ṣe níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún.

A ṢÈPINNU KAN TÍ KÒ RỌRÙN RÁRÁ

Lọ́dún 1973, a ṣèpinnu kan tí kò rọrùn fún wa rárá. Ó pẹ́ díẹ̀ tí Sheila ti ń fara da àìsàn kan tó le gan-an. Nígbà tá a lọ sí àpéjọ kan nílùú New York, Sheila bú sẹ́kún, ó sì sọ fún mi pé: “Ó ti sú mi! Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń rẹ̀ mí, ara mi ò sì yá rárá.” Ó ti lé lọ́dún mẹ́rìnlá (14) tó ti ń sìn pẹ̀lú mi ní Áfíríkà. Inú mi dùn pé gbogbo ọkàn ẹ̀ ló fi ń sin Jèhófà, àmọ́ ní báyìí, a gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà kan. Lẹ́yìn tá a jíròrò ọ̀rọ̀ náà dáadáa, tá a sì gbàdúrà gan-an nípa ẹ̀, a pinnu pé á dáa ká pa dà sí Kánádà, kó lè rọrùn fún Sheila láti gbàtọ́jú. Ìpinnu tá a ṣe láti kúrò lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì àti iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ló ṣòro jù fún wa. Inú wa ò dùn rárá, ọkàn wa sì gbọgbẹ́.

Lẹ́yìn tá a dé Kánádà, mo ríṣẹ́ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ mi kan tó ń ta mọ́tò nílùú Toronto. A gbalé kan, a sì ra àga àlòkù. Torí náà, bá a ṣe ṣọ́wó ná ò jẹ́ ká jẹ gbèsè rárá. A ò fẹ́ kó nǹkan tó pọ̀ jọ torí a ṣì ń rò ó pé ó ṣeé ṣe ká pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ó yà wá lẹ́nu pé kò pẹ́ rárá tọ́wọ́ wa fi tẹ àfojúsùn yẹn.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀ǹda ara mi láwọn ọjọ́ Sátidé láti ṣiṣẹ́ ìkọ́lé ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà ní Norval, ìpínlẹ̀ Ontario. Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run ní kí n máa ṣiṣẹ́ Alábòójútó Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Ara Sheila ti ń yá díẹ̀díẹ̀, a sì gbà pé Sheila lè ṣiṣẹ́ tuntun yìí. Torí náà, ní June 1974, a kó lọ sílé tó wà nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Inú wa dùn gan-an pé a láǹfààní láti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún!

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ara Sheila túbọ̀ ń yá sí i. Torí náà, ọdún méjì lẹ́yìn náà, ó ṣeé ṣe fún wa láti gba iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Ìpínlẹ̀ Manitoba, lórílẹ̀-èdè Kánádà ni àyíká tí wọ́n rán wa lọ, òtútù sì máa ń mú gan-an níbẹ̀. Àmọ́, àwọn ará tó wà níbẹ̀ kóni mọ́ra, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ wa. A kẹ́kọ̀ọ́ pé ibi tá a ti ń sìn kọ́ ló ṣe pàtàkì jù, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká ṣáà máa sin Jèhófà níbikíbi tá a bá wà.

MO KẸ́KỌ̀Ọ́ PÀTÀKÌ KAN

Lẹ́yìn tá a ti ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká fún ọ̀pọ̀ ọdún, ètò Ọlọ́run ní ká máa bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Kánádà lọ́dún 1978. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó dùn mí gan-an, tó sì kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì. Níbi ìpàdé àkànṣe kan tá a ṣe ní Montreal, wọ́n ní kí n sọ àsọyé oníwákàtí kan ààbọ̀ lédè Faransé. Àmọ́, ó ṣòro fáwọn ará láti fọkàn bá àsọyé náà lọ. Torí náà, arákùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn gbà mí nímọ̀ràn nípa ẹ̀. Ká sòótọ́, mi ò mọ̀ pé mi ò lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ nígbà yẹn, ìgbà tó yá ló ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yé mi. Mi ò rára gba ìmọ̀ràn yẹn sí rárá. Torí náà inú bí mi, a sì wojú ara wa torí mo rò pé ọ̀rọ̀ tó sọ fún mi ti le jù, kò sì gbóríyìn fún mi. Àṣìṣe kan tí mo ṣe ni pé ẹni tó gbà mí nímọ̀ràn àti bó ṣe sọ̀rọ̀ ni mo gbájú mọ́, dípò kí n ronú lórí ìmọ̀ràn tó gbà mí.

Mo kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan lẹ́yìn tí mo sọ àsọyé lédè Faransé

Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka bá mi sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Mo gbà pé kò yẹ kí n sọ̀rọ̀ bí mo ṣe sọ̀rọ̀ yẹn, mo sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé mo kábàámọ̀ ohun tí mo ṣe. Lẹ́yìn náà, mo pe arákùnrin tó fún mi nímọ̀ràn yẹn, mo bẹ̀ ẹ́ pé kó má bínú, ó sì gbà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ tí mi ò ní gbàgbé láé, ìyẹn ni pé kí n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (Òwe 16:18) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti gbàdúrà nípa ẹ̀, mo sì ti pinnu pé irú ẹ̀ kò tún ní ṣẹlẹ̀ sí mi mọ́.

Ó ti lé lógójì (40) ọdún tí mo ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Kánádà, àtọdún 1985 sì ni mo ti wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Ní February 2021, Sheila mi ọ̀wọ́n kú. Bí mo ṣe ń fara da àdánù ìyàwó mi, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ní àìlera tèmi tí mò ń bá yí. Torí pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni mo gbájú mọ́, tí mo sì ń láyọ̀ bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ náà, ‘bóyá ni mo máa ń mọ̀ pé ọjọ́ ayé mi ń lọ.’ (Oníw. 5:20) Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìṣòro ni mo ti ní láyé mi, síbẹ̀ ayọ̀ tí mò ń ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó sì ti jẹ́ kí n lè fara dà á. Ní báyìí, mo ti lo àádọ́rin (70) ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ọ̀pọ̀ ìbùkún ni mo ti rí torí pé mo fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́ láyé mi, mo sì ń láyọ̀. Àdúrà mi ni pé káwọn ọ̀dọ́ wa náà lè fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ láyé wọn. Ó dájú pé tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, dídùn lọsàn wọn máa so, torí àwọn tó bá sin Jèhófà nìkan ló máa ń rí irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ gbà.

a Ka ìtàn ìgbésí ayé Marcel Filteau nínú Ilé Ìṣọ́ February 1, 2000. Àkòrí ẹ̀ ni “Jèhófà ni Ààbò àti Okun Mi.”

b Ṣáájú ọdún 1957, Gold Coast ni wọ́n ń pe orílẹ̀-èdè Gánà.

c Ka ìtàn ìgbésí ayé Herbert Jennings nínú Ilé Ìṣọ́ December 1, 2000. Àkòrí ẹ̀ ni “Ẹ Kò Mọ Ohun Tí Ìwàláàyè Yín Yóò Jẹ́ Lọ́la.”

d Arákùnrin Nathan H. Knorr ló ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn.