Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 37

ORIN 118 “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”

Lẹ́tà Tó Máa Mú Ká Jẹ́ Olóòótọ́, Ká sì Fara Dà Á Dópin

Lẹ́tà Tó Máa Mú Ká Jẹ́ Olóòótọ́, Ká sì Fara Dà Á Dópin

‘A ní irú ìdánilójú tí a ní níbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.’HÉB. 3:14.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù, àwọn ẹ̀kọ́ náà sì máa mú ká jẹ́ olóòótọ́, ká sì fara dà á dópin.

1-2. (a) Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní Jùdíà nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà ẹ̀ sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé lẹ́tà náà dé lásìkò tí wọ́n nílò ẹ̀?

 LẸ́YÌN tí Jésù kú lọ́dún 33 S. K., àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti agbègbè Jùdíà láwọn ìṣòro tó le gan-an. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni tó le gan-an sí wọn. (Ìṣe 8:1) Ìyẹn nìkan kọ́ o, ní nǹkan bí ogún (20) ọdún lẹ́yìn náà, àtijẹ àtimu nira fáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù torí pé ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ náà. (Ìṣe 11:27-30) Àmọ́, ní nǹkan bí ọdún 61 S.K., wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni yẹn mọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé inúnibíni tí wọ́n máa ṣe sí wọn lọ́jọ́ iwájú máa le gan-an. Àsìkò yẹn ni wọ́n gba lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí wọn, ohun tó wà nínú lẹ́tà yẹn wúlò gan-an torí ó múra wọn sílẹ̀ fáwọn nǹkan tó máa tó ṣẹlẹ̀.

2 Lẹ́tà náà dé lásìkò tí wọ́n nílò ẹ̀ torí pé inúnibíni tó le gan-an ò ní pẹ́ dé. Torí náà, Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n nímọ̀ràn tó máa jẹ́ kí wọ́n fara da ìpọ́njú tó máa tó bẹ̀rẹ̀. Ìparun Jerúsálẹ́mù tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ máa dé láìpẹ́. (Lúùkù 21:20) Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó mọ ìgbà tí ìparun Jerúsálẹ́mù máa dé, kódà Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni tó ń gbé Jùdíà ò mọ̀ ọ́n. Àmọ́, kí ìparun yẹn tó dé, àwọn Kristẹni yẹn gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ nígbàgbọ́ àti ìfaradà.—Héb. 10:25; 12:1, 2.

3. Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Hébérù?

3 Láìpẹ́, àwa náà ń retí ìpọ́njú tó burú ju èyí tó dé bá àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù. (Mát. 24:21; Ìfi. 16:14, 16) Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí ìmọ̀ràn tí Jèhófà fún àwọn Kristẹni yẹn ṣe ṣe wọ́n láǹfààní àti bó ṣe máa ṣe àwa náà láǹfààní.

“Ẹ JẸ́ KÁ TẸ̀ SÍWÁJÚ, KÁ DÀGBÀ NÍPA TẸ̀MÍ”

4. Ìṣòro wo làwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù ní? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 Àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù ní ìṣòro ńlá kan. Ìgbà kan wà tí Jèhófà sọ pé àwọn Júù nìkan ni èèyàn òun. Yàtọ̀ síyẹn, ìlú Jerúsálẹ́mù ṣe pàtàkì gan-an nígbà yẹn torí pé ibẹ̀ làwọn ọba tó ń ṣojú fún Jèhófà ti ń ṣàkóso, àwọn èèyàn sì máa ń jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀. Gbogbo àwọn Júù máa ń tẹ̀ lé Òfin Mósè táwọn olórí ẹ̀sìn wọn ń kọ́ wọn. Ohun tí wọ́n ń kọ́ yẹn jẹ́ kí wọ́n mọ irú oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ, bí ìdádọ̀dọ́ ti ṣe pàtàkì tó àti bó ṣe yẹ kí wọ́n máa hùwà sáwọn tí kì í ṣe Júù. Àmọ́ lẹ́yìn tí Jésù kú, Jèhófà ò gba ẹbọ tí wọ́n máa ń rú ní tẹ́ńpìlì mọ́. Àyípadà yìí ò rọrùn fáwọn Júù tó di Kristẹni torí ó ti mọ́ wọn lára láti máa tẹ̀ lé Òfin Mósè. (Héb. 10:1, 4, 10) Ó ṣòro fáwọn Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn láti fara mọ́ àyípadà yìí, kódà àpọ́sítélì Pétérù wà lára wọn. (Ìṣe 10:9-14; Gál. 2:11-14) Torí náà, àwọn olórí ẹ̀sìn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni yẹn nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ di ẹ̀kọ́ òtítọ́ mú ṣinṣin, kí wọ́n má sì gba ẹ̀kọ́ èké táwọn olórí ẹ̀sìn Júù tó ń ta kò wọ́n ń gbé lárugẹ (Wo ìpínrọ̀ 4-5)


5. Ìṣòro wo làwọn Kristẹni ní?

5 Àwùjọ méjì ló ta ko àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù. Àwùjọ àkọ́kọ́ ni àwọn olórí ẹ̀sìn Júù tó ń fojú apẹ̀yìndà wo àwọn Kristẹni. Àwùjọ kejì ni àwọn Kristẹni tó sọ pé dandan ni káwọn ọmọlẹ́yìn Kristi máa tẹ̀ lé Òfin Mósè, bóyá torí wọn ò fẹ́ kí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn ni wọ́n fi ń sọ bẹ́ẹ̀. (Gál. 6:12) Torí náà, kí ló máa mú káwọn Kristẹni yẹn jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà?

6. Kí ni Pọ́ọ̀lù gba àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà níyànjú pé kí wọ́n ṣe? (Hébérù 5:14–6:1)

6 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù, ó gba àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà níyànjú pé kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ka Hébérù 5:14–6:1.) Ó lo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù láti fi ṣàlàyé fáwọn Kristẹni yẹn pé bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn báyìí dáa ju báwọn Júù ṣe ń jọ́sìn lọ. a Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé tí wọ́n bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó sì yé wọn dáadáa, wọ́n máa dá ẹ̀kọ́ èké mọ̀, wọn ò ní gbà á gbọ́, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀.

7. Àwọn ìṣòro wo làwa Kristẹni ní lónìí?

7 Bíi tàwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù, àwa náà ń gbé láàárín àwọn tó ń ta ko òtítọ́ Bíbélì. Àwọn alátakò wa sọ pé bá a ṣe ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì ò dáa torí pé a ò fara mọ́ ìṣekúṣe, wọ́n sì ní ìkà ni wá. Ojoojúmọ́ ni èrò àwọn èèyàn ń ta ko èrò Ọlọ́run. (Òwe 17:15) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká dá ẹ̀kọ́ èké mọ̀, ká má sì gbà á gbọ́. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn alátakò ṣì wá lọ́nà, ká má bàa fi Jèhófà sílẹ̀.—Héb. 13:9.

8. Báwo la ṣe lè máa tẹ̀ síwájú, ká sì dàgbà nípa tẹ̀mí?

8 Ó yẹ ká máa rántí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù pé kí wọ́n máa tẹ̀ síwájú, kí wọ́n sì dàgbà nípa tẹ̀mí. Ìyẹn máa gba pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ká lè mọ Jèhófà, ká sì máa ronú bó ṣe ń ronú. Ohun tó yẹ ká máa ṣe nìyẹn, kódà lẹ́yìn tá a bá ti ya ara wa sí mímọ́, tá a sì ti ṣèrìbọmi. Kódà, tó bá ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà, ó yẹ kí gbogbo wa máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀. (Sm. 1:2) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa nígbàgbọ́ tó lágbára bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Hébérù.—Héb. 11:1, 6.

Ẹ JẸ́ KÁ “NÍ ÌGBÀGBỌ́ KÍ A LÈ DÁ Ẹ̀MÍ WA SÍ”

9. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù nígbàgbọ́ tó lágbára?

9 Àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ tó lágbára, tí wọ́n bá máa la ìpọ́njú tó máa ṣẹlẹ̀ ní Jùdíà já. (Héb. 10:37-39) Jésù ti kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ tẹ́lẹ̀ pé tí wọ́n bá rí àwọn ọmọ ogun tó yí Jerúsálẹ́mù ká, kí wọ́n sá lọ sórí òkè. Gbogbo àwọn Kristẹni yẹn ni ìmọ̀ràn Jésù máa ṣe láǹfààní, bóyá inú ìlú Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ń gbé tàbí àwọn ìgbèríko Jùdíà. (Lúùkù 21:20-24) Nígbà àtijọ́, táwọn ọ̀tá bá gbógun dé, àwọn èèyàn máa ń sá lọ sínú àwọn ìlú tó lódi, irú bíi Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí Jésù ní kí wọ́n sá lọ sórí àwọn òkè, ó lè dà bíi pé kò bọ́gbọ́n mu, torí náà ó gba pé kí wọ́n nígbàgbọ́ tó lágbára.

10. Táwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù bá nígbàgbọ́ tó lágbára, kí ni wọ́n máa ṣe? (Hébérù 13:17)

10 Àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù tún gbọ́dọ̀ fọkàn tán àwọn tí Jésù ń lò pé kí wọ́n máa ṣàbójútó ìjọ Kristẹni. Ó ṣeé ṣe káwọn tó ń ṣàbójútó nígbà yẹn fún àwọn Kristẹni yẹn nímọ̀ràn tààràtà nípa ìgbà tí wọ́n máa sá àti bí wọ́n ṣe máa ṣe é. (Ka Hébérù 13:17.) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ẹ máa ṣègbọràn” nínú Hébérù 13:17 ń sọ nípa ẹni tó ṣègbọràn torí pé ó fọkàn tán ẹni tó ń tọ́ ọ sọ́nà. Ìdí tó fi ń ṣègbọràn sẹ́ni náà kì í ṣe torí pé onítọ̀hún láṣẹ jù ú lọ, àmọ́ torí pé ó fọkàn tán an. Torí náà, àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù yẹn gbọ́dọ̀ fọkàn tán àwọn tó ń ṣàbójútó kí ìpọ́njú náà tó bẹ̀rẹ̀. Táwọn Kristẹni yẹn bá ń ṣe ohun táwọn tó ń ṣàbójútó sọ kí ìpọ́njú tó bẹ̀rẹ̀, á rọrùn fún wọn láti ṣègbọràn nígbà ìpọ́njú.

11. Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni òde òní nígbàgbọ́ tó lágbára?

11 Lónìí, ó yẹ káwa náà nígbàgbọ́ tó lágbára bíi tàwọn Kristẹni tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sí. Ayé burúkú yìí máa tó dópin, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ò gbà bẹ́ẹ̀, kódà wọ́n máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí a gbà pé ayé burúkú yìí ò ní pẹ́ pa run. (2 Pét. 3:3, 4) Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan la ò mọ̀. Torí náà, ó yẹ ká nígbàgbọ́ tó lágbára pé ayé burúkú yìí máa pa run lásìkò tó yẹ, ó sì dájú pé Jèhófà máa bójú tó wa nígbà yẹn.—Háb. 2:3.

12. Kí ló máa jẹ́ ká là á já nígbà ìpọ́njú ńlá?

12 Ó yẹ kó túbọ̀ dá wa lójú pé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ni Jèhófà ń lò láti máa tọ́ wa sọ́nà. (Mát. 24:45) Nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n sọ pé ká ṣe àwọn nǹkan kan tó máa gba ẹ̀mí wa là, bí wọ́n ṣe sọ fáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù wá sí Jerúsálẹ́mù. Torí náà, àsìkò yìí gan-an ló yẹ ká túbọ̀ fọkàn tán àwọn tó ń ṣàbójútó wa nínú ètò Ọlọ́run, ká sì máa ṣe ohun tí wọ́n bá sọ. Tó bá ṣòro fún wa láti ṣe ohun tí wọ́n ń sọ báyìí, ó máa túbọ̀ ṣòro fún wa láti ṣègbọràn nígbà ìpọ́njú ńlá.

13. Kí nìdí tí ìmọ̀ràn tó wà ní Hébérù 13:5 fi wúlò?

13 Báwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù ṣe ń dúró dìgbà tí wọ́n máa sọ pé kí wọ́n sá, wọ́n jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n sì yẹra fún “ìfẹ́ owó.” (Ka Hébérù 13:5.) Àwọn kan lára wọn ti fara dà á nígbà tí ìyàn mú, tí wọn ò sì ní nǹkan kan lọ́wọ́. (Héb. 10:32-34) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fara da ìyà nítorí ìhìn rere, àwọn kan lára wọn lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé àwọn gbọ́dọ̀ lówó káwọn má bàa jìyà kú. Àmọ́ kò sí bí owó tí wọ́n ní ṣe lè pọ̀ tó, táá lè gbà wọ́n lọ́wọ́ ìparun tó ń bọ̀. (Jém. 5:3) Ká sòótọ́, ó máa ṣòro fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ nǹkan tara láti sá, kó sì fi ilé àtàwọn nǹkan ìní ẹ̀ sílẹ̀.

14. Tá a bá nígbàgbọ́ tó lágbára, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká ṣèpinnu tó tọ́ nípa nǹkan tara?

14 Tá a bá nígbàgbọ́ tó lágbára, tó sì dá wa lójú pé ayé burúkú yìí ò ní pẹ́ pa run, a ò ní máa kó ohun ìní jọ. Nígbà ìpọ́njú ńlá, àwọn èèyàn máa “ju fàdákà wọn sí ojú ọ̀nà” torí wọ́n á rí i pé “fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.” (Ìsík. 7:19) Torí náà, dípò ká máa kó ọrọ̀ jọ, ó yẹ ká máa ṣe àwọn ìpinnu tó fi hàn pé ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, táá sì jẹ́ ká máa sin Jèhófà nìṣó. Ara ẹ̀ ni pé ká má tọrùn bọ gbèsè, ká má sì kó ohun ìní jọ débi pé gbogbo àkókò wa làá máa fi bójú tó wọn. Ó tún yẹ ká kíyè sára, ká má jẹ́ kí ohun ìní wa ṣe pàtàkì ju ẹ̀mí wa lọ. (Mát. 6:19, 24) Bí òpin ayé burúkú yìí ṣe ń sún mọ́lé, àwọn nǹkan kan lè dán ìgbàgbọ́ wa wò tó máa fi hàn bóyá Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé tàbí ohun ìní wa.

“Ẹ NÍLÒ ÌFARADÀ”

15. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù ní ìfaradà?

15 Bí nǹkan ṣe ń burú sí i, tí ìpọ́njú sì ń sún mọ́lé ní Jùdíà, ó máa gba pé káwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù fara da àwọn nǹkan tó máa dán ìgbàgbọ́ wọn wò. (Héb. 10:36) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣenúnibíni sáwọn kan lára wọn, ìgbà tí nǹkan ṣì rọrùn ni ọ̀pọ̀ lára wọn di Kristẹni. Pọ́ọ̀lù sọ pé òótọ́ ni pé wọ́n fara da àdánwò ìgbàgbọ́ tó le gan-an, àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe tán láti jìyà títí dójú ikú bíi ti Jésù. (Héb. 12:4) Bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń di Kristẹni, àwọn alátakò tó jẹ́ Júù ń bínú burúkú burúkú sáwọn Kristẹni. Ní ọdún mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn, rògbòdìyàn kan ṣẹlẹ̀ nítorí Pọ́ọ̀lù nígbà tó ń wàásù ní Jerúsálẹ́mù. Àwọn Júù tó ju ogójì (40) lọ “fi ègún de ara wọn, pé àwọn ò ní jẹ, àwọn ò sì ní mu títí àwọn á fi pa Pọ́ọ̀lù.” (Ìṣe 22:22; 23:12-14) Láìka gbogbo rògbòdìyàn àti ìkórìíra yìí sí, àwọn Kristẹni yẹn ń pàdé láti jọ́sìn Jèhófà, wọ́n ń wàásù, wọ́n sì ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára.

16. Báwo ni lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù ṣe lè jẹ́ ká máa fojú tó tọ́ wo inúnibíni? (Hébérù 12:7)

16 Kí ló jẹ́ káwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù fara da àtakò tó dé bá wọn? Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí wọ́n fara da àtakò yẹn torí ó mọ̀ pé ó máa ṣe wọ́n láǹfààní. Ó wá ṣàlàyé pé Ọlọ́run lè fàyè gbà á kí àdánwò dé bá Kristẹni kan kó lè kẹ́kọ̀ọ́. (Ka Hébérù 12:7.) Irú ẹ̀kọ́ yẹn máa jẹ́ kí Kristẹni náà láwọn ànímọ́ tó ṣe pàtàkì tàbí kó mú káwọn ànímọ́ tó ní tẹ́lẹ̀ túbọ̀ dáa. Torí náà, táwọn Kristẹni yẹn bá ń ronú nípa àǹfààní tí wọ́n máa rí, wọ́n á lè fara da àdánwò náà.—Héb. 12:11.

17. Kí ni Pọ́ọ̀lù kọ́ nípa béèyàn ṣe ń fara da inúnibíni?

17 Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù níyànjú pé kí wọ́n máa fara da ìṣòro, kí wọ́n má sì jẹ́ kó sú wọn. Ohun tó jẹ́ kó lè gbà wọ́n níyànjú ni pé òun náà ti fara da ìṣòro rí. Kí Pọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, ó ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni, ó sì mọ ohun tójú wọn ń rí. Ó tún mọ béèyàn ṣe ń fara da inúnibíni. Ó ṣe tán, lẹ́yìn tó di Kristẹni, onírúurú àdánwò ló dé bá a. (2 Kọ́r. 11:23-25) Torí náà, Pọ́ọ̀lù mọ ohun téèyàn lè ṣe kó lè fara da àdánwò. Ó wá rán àwọn Kristẹni yẹn létí pé tí wọ́n bá ń fara da ìṣòro, Jèhófà ló yẹ kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé kì í ṣe ara wọn. Ìyẹn ló mú kí Pọ́ọ̀lù fìgboyà sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù.”—Héb. 13:6.

18. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, báwo la sì ṣe lè múra sílẹ̀?

18 Ní báyìí, àwọn ará wa kan ń fara da inúnibíni. Bá a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn ni pé ká máa rántí wọn tá a bá ń gbàdúrà. Nígbà míì sì rèé, a lè fún wọn láwọn nǹkan tí wọ́n nílò. (Héb. 10:33) Àmọ́, Bíbélì sọ pé “gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tím. 3:12) Torí náà, gbogbo wa ló yẹ ká múra sílẹ̀ de wàhálà tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ká sì mọ̀ dájú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò èyíkéyìí tó lè dé bá wa. Tó bá tó àsìkò lójú Jèhófà, ó máa yanjú gbogbo ìṣòro àwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀ tọkàntọkàn.—2 Tẹs. 1:7, 8.

19. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe ká lè múra sílẹ̀ de ìpọ́njú ńlá? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

19 Ó dájú pé lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de ìpọ́njú tó máa dé bá wọn. Ó gba àwọn Kristẹni yẹn níyànjú pé kí wọ́n máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì lóye Ìwé Mímọ́ dáadáa. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á dá àwọn ẹ̀kọ́ tó lè ba ìgbàgbọ́ wọn jẹ́ mọ̀, wọ́n á sì sá fáwọn ẹ̀kọ́ náà. Ó ní kí wọ́n jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára, kí wọ́n lè tètè máa ṣe ohun tí Jésù àtàwọn tó ń ṣàbójútó nínú ìjọ sọ. Ó gba àwọn Kristẹni náà níyànjú pé kí wọ́n máa fojú tó tọ́ wo àdánwò àti pé Jèhófà ń lò ó láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ó yẹ káwa náà fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sílò. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa jẹ́ olóòótọ́, àá sì fara dà á dópin.—Héb. 3:14.

Jèhófà dáàbò bo àwọn Kristẹni tó ń sìn ín tọkàntọkàn torí pé wọ́n nífaradà. Lẹ́yìn tí wọ́n sá kúrò ní Jùdíà, wọ́n ṣì ń pàdé láti jọ́sìn. Kí la rí kọ́? (Wo ìpínrọ̀ 19)

ORIN 126 Wà Lójúfò, Dúró Gbọn-in, Jẹ́ Alágbára

a Nínú orí àkọ́kọ́ ìwé Hébérù, ìgbà méje ni Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù láti fi hàn pé ọ̀nà táwọn Kristẹni gbà ń jọ́sìn dáa ju ti àwọn Júù lọ.—Héb. 1:5-13.