Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́

Máa Kọ́ Ohun Tuntun Tó O Bá Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Máa Kọ́ Ohun Tuntun Tó O Bá Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a lè bi ara wa pé: ‘Kí làwọn nǹkan tí màá kọ́?’ Síbẹ̀, ó yẹ ká rántí pé tá a bá tiẹ̀ ní ohun kan lọ́kàn tá a fẹ́ kọ́, àwọn nǹkan tuntun míì ṣì wà níbẹ̀ tí Jèhófà fẹ́ kọ́ wa. Torí náà, báwo la ṣe lè mọ àwọn nǹkan tuntun yẹn?

Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ohun tó o fẹ́ kọ́ lásìkò yẹn yé ẹ. (Jém. 1:5) Dípò tí wàá fi gbájú mọ́ àwọn nǹkan tó o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, sapá láti kọ́ àwọn nǹkan tuntun.—Òwe 3:5, 6.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára, jẹ́ kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè.” (Héb. 4:12) Torí pé “ọ̀rọ̀” Ọlọ́run wà láàyè, gbogbo ìgbà tá a bá ń ka Bíbélì la máa kọ́ ohun tuntun tó máa ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́ ká tó lè jàǹfààní, a gbọ́dọ̀ gbà pé nǹkan kan wà tí Jèhófà fẹ́ kọ́ wa.

Mọyì gbogbo nǹkan tí Jèhófà fi ń kọ́ wa. Àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tí Jèhófà fi ń bọ́ wa dà bí “[oúnjẹ] tó dọ́ṣọ̀.” (Àìsá. 25:6) Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, má ṣe sá fún àwọn ẹ̀kọ́ tó dà bí “oúnjẹ” tó o rò pé kò lè dùn. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bó ṣe yẹ, wàá túbọ̀ jàǹfààní, wàá sì túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run!