Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ṣètò Ìgbéyàwó?

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ṣètò Ìgbéyàwó?

Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: ‘Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un.’”JẸ́N. 2:18.

ORIN: 36, 11

1, 2. (a) Báwo ni ìgbéyàwó ṣe bẹ̀rẹ̀? (b) Kí ni tọkọtaya àkọ́kọ́ wá mọ̀ nípa ìgbéyàwó? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

LÁTIJỌ́ táláyé ti dáyé làwọn èèyàn ti máa ń ṣègbéyàwó. Tá a bá ronú lórí bí ìgbéyàwó ṣe bẹ̀rẹ̀ àtohun tó wà fún, àá lè fojú tó tọ́ wo ìgbéyàwó, àá sì lè jadùn àwọn ìbùkún tó ń tibẹ̀ wá. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá Ádámù, ó ní kó sọ àwọn ẹranko lórúkọ. Bíbélì wá sọ nípa Ádámù pé “kò sí olùrànlọ́wọ́ kankan gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” Torí náà, Ọlọ́run mú kí Ádámù sùn lọ fọnfọn, ó wá mú ọ̀kan lára àwọn eegun ìhà rẹ̀, ó fi dá obìnrin kan, ó sì mú un wá fún Ádámù. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:20-24.) Ó wá ṣe kedere pé Ọlọ́run ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀.

2 Jésù kín ọ̀rọ̀ Jèhófà lẹ́yìn nígbà tó sọ pé: “Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.” (Mát. 19:4, 5) Bí Ọlọ́run ṣe lo ọ̀kan lára àwọn eegun ìhà Ádámù láti dá obìnrin àkọ́kọ́ jẹ́ kí Ádámù àti ìyàwó rẹ̀ yìí mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe ara wọn lọ́kan. Ọlọ́run ò fẹ́ káwọn tọkọtaya máa kọ ara wọn sílẹ̀ tàbí kí wọ́n ní ju ọkọ tàbí aya kan lọ.

BÍ ÌGBÉYÀWÓ ṢE MÚ ÌFẸ́ ỌLỌ́RUN ṢẸ

3. Kí lohun pàtàkì kan tí Ọlọ́run tìtorí ẹ̀ dá ìgbéyàwó sílẹ̀?

3 Inú Ádámù dùn gan-an nígbà tó rí ìyàwó rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Éfà. Torí pé Éfà jẹ́ “àṣekún” ọkọ rẹ̀, á máa ràn án lọ́wọ́. Bí kálukú wọ́n ṣe ń ṣe ojúṣe rẹ̀ nínú ìdílé, àwọn méjèèjì á máa múnú ara wọn dùn lójoojúmọ́. (Jẹ́n. 2:18) Ohun pàtàkì kan tí Ọlọ́run tìtorí ẹ̀ dá ìgbéyàwó sílẹ̀ ni pé kí wọ́n lè mú káwọn èèyàn kúnnú ayé. (Jẹ́n. 1:28) Lóòótọ́, àwọn ọmọ nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn, àmọ́ bó pẹ́ bó yá wọ́n á fi àwọn òbí wọn sílẹ̀ káwọn náà lè ní ìdílé tiwọn. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn á kúnnú ayé débi tí Ọlọ́run fẹ́, wọ́n á sì mú kí gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè.

4. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìgbéyàwó àkọ́kọ́?

4 Ìgbéyàwó àkọ́kọ́ forí ṣánpọ́n torí pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà. “Ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà” Sátánì Èṣù tan Éfà jẹ nígbà tó sọ fún un pé tó bá jẹ èso “igi ìmọ̀ rere àti búburú,” á lè dá pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Éfà ò ronú pé ó yẹ kóun dúró de ọkọ òun kóun lè gbọ́ ohun tó máa sọ. Kàkà kí Ádámù náà ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ṣe ló kàn gba èso tí Éfà fún un, ó sì jẹ ẹ́.—Ìṣí. 12:9; Jẹ́n. 2:9, 16, 17; 3:1-6.

5. Kí la rí kọ́ látinú èsì tí Ádámù àti Éfà fún Jèhófà?

5 Nígbà tí Jèhófà béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ Ádámù, ṣe ló di ẹ̀bi náà ru ìyàwó rẹ̀, ó sọ pé: “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi láti wà pẹ̀lú mi, òun ni ó fún mi ní èso láti ara igi náà, nítorí náà, mo sì jẹ.” Éfà náà tún di ẹ̀bi ru ejò pé òun ló tan òun jẹ. (Jẹ́n. 3:12, 13) Àmọ́ gbogbo àwáwí yẹn ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Torí pé tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣàìgbọràn sí Jèhófà, Jèhófà kà wọ́n sí ọlọ̀tẹ̀. Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ ńlá lèyí kọ́ wa! Kí ìgbéyàwó tó lè yọrí sí rere, àtọkọ àtìyàwó gbọ́dọ̀ mẹ̀bi wọn lẹ́bi, kí wọ́n sì máa ṣègbọràn sí Jèhófà.

6. Ṣàlàyé ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15.

6 Láìka gbogbo ohun tí Sátánì ṣe ní ọgbà Édẹ́nì sí, Jèhófà tún fi aráyé lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la máa dáa nínú àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:15.) Jèhófà sọ pé ‘irú-ọmọ obìnrin náà’ máa pa Èṣù run. Jèhófà tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká mọ àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín òun àti àìmọye àwọn áńgẹ́lì onígbọràn tó ń jọ́sìn rẹ̀ lọ́run. Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa lo ẹnì kan látinú apá ti ọ̀run lára ètò rẹ̀ láti “pa” Èṣù run. Èyí á wá mú káwọn onígbọràn gbádùn ohun tí tọkọtaya àkọ́kọ́ pàdánù, ìyẹn gbígbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn á wá ṣẹ.—Jòh. 3:16.

7. (a) Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé látìgbà tí Ádámù àti Éfà ti ṣọ̀tẹ̀? (b) Kí ni Bíbélì sọ pé kí tọkọtaya máa ṣe?

7 Àtìgbà tí Ádámù àti Éfà ti ṣọ̀tẹ̀ ni nǹkan ò ti lọ dáadáa láàárín wọn mọ́, ọ̀tẹ̀ yìí kan náà ló sì kó bá gbogbo ìdílé látìgbà yẹn wá. Bí àpẹẹrẹ, Éfà àti gbogbo obìnrin á máa jẹ̀rora nínú oyún àti nígbà tí wọ́n bá fẹ́ bímọ, ọ̀dọ̀ ọkọ wọn lọkàn wọn á sì máa wà ní gbogbo ìgbà. Àwọn ọkọ náà á máa jọba lé wọn lórí, kódà wọ́n á máa pọ́n wọn lójú. Ohun tó sì ń ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìdílé lónìí nìyẹn. (Jẹ́n. 3:16) Bíbélì sọ pé kí àwọn ọkọ máa fìfẹ́ lo ipò orí wọn. Ó sì ní káwọn aya náà máa fọ̀wọ̀ wọ àwọn ọkọ wọn. (Éfé. 5:33) Torí pé àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, àwọn nǹkan tó lè fa wàhálà kì í pọ̀, wọ́n sì máa ń tètè yanjú rẹ̀.

BÍ ÌGBÉYÀWÓ ṢE RÍ LÁTÌGBÀ ÁDÁMÙ TÍTÍ DI ÌGBÀ ÌKÚN-OMI

8. Báwo ni ìgbéyàwó ṣe rí látìgbà ayé Ádámù sí ìgbà ayé Nóà?

8 Kí Ádámù àti Éfà tó kú, wọ́n bímọ. (Jẹ́n. 5:4) Àkọ́bí wọn tó ń jẹ́ Kéènì fẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin tó jẹ́ ìbátan rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Kéènì tó ń jẹ́ Lámékì ni ẹni àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ pé ó ní ìyàwó méjì. (Jẹ́n. 4:17, 19) Látìgbà ayé Ádámù títí di ìgbà Ìkún-omi ọjọ́ Nóà, ìwọ̀nba àwọn èèyàn ni Bíbélì sọ pé wọ́n sin Jèhófà. Lára wọn ni Ébẹ́lì, Énọ́kù, Nóà àti ìdílé rẹ̀. Nígbà ayé Nóà, “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, pé wọ́n dára ní ìrísí; wọ́n sì ń mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn.” Torí pé Ọlọ́run ò dá àwọn áńgẹ́lì pé kí wọ́n máa láya, àdàmọ̀dì ọmọ tí Bíbélì pè ní Néfílímù ni wọ́n bí jọ. Yàtọ̀ síyẹn, “Jèhófà rí i pé ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.”—Jẹ́n. 6:1-5.

9. Kí ni Jèhófà ṣe fáwọn èèyàn búburú nígbà ayé Nóà, kí la sì rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn?

9 Ọlọ́run fi àkúnya omi pa àwọn èèyàn búburú run nígbà ayé Nóà. Nígbà yẹn, ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu títí kan ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó ló gba àwọn èèyàn náà lọ́kàn. Ó burú débi pé wọn ò kọbi ara sí bí “Nóà oníwàásù òdodo” ṣe ń kìlọ̀ fún wọn pé ayé yẹn máa tó pa run. (2 Pét. 2:5) Jésù wá fi ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn wé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tiwa. (Ka Mátíù 24:37-39.) Lónìí, à ń wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé ká lè jẹ́rìí fún gbogbo èèyàn kí òpin tó dé, àmọ́ ọ̀pọ̀ ni kì í fẹ́ gbọ́. Kò yẹ ká jẹ́ kí ohunkóhun gbà wá lọ́kàn, ì báà jẹ́ ọ̀rọ̀ ìdílé, ìgbéyàwó tàbí ọmọ títọ́. Tá a bá wà lójúfò, àá máa fi sọ́kàn pé ọjọ́ Jèhófà ò ní pẹ́ dé.

BÍ ÌGBÉYÀWÓ ṢE RÍ LẸ́YÌN ÌKÚN-OMI SÍ ÌGBÀ AYÉ JÉSÙ

10. (a) Irú ìwà wo ló ti di bárakú láwọn ilẹ̀ kan? (b) Ọ̀nà wo ni Ábúráhámù àti Sárà gbà jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn tọkọtaya?

10 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aya kọ̀ọ̀kan làwọn ọmọ Nóà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fẹ́, àwọn kan wà láyé ìgbà yẹn tí wọ́n ní ju ìyàwó kan lọ. Láwọn ilẹ̀ kan, wọn ò rí ohun tó burú nínú ìṣekúṣe, kódà ìṣekúṣe wà lára ààtò ìsìn wọn. Nígbà tí Ábúráhámù àtìyàwó rẹ̀ Sárà lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n kíyè sí i pé ìwà àwọn èèyàn ibẹ̀ kò sunwọ̀n. Ìdí sì ni pé ìṣekúṣe ló kúnnú ìlú náà débi pé wọn ò ka ìgbéyàwó sí nǹkan iyì. Ìlú míì tí ìṣekúṣe àwọn èèyàn ibẹ̀ tún burú jáì ni Sódómù àti Gòmórà, abájọ tí Jèhófà fi pinnu pé òun máa pa wọ́n run. Ábúráhámù ò fọ̀rọ̀ ìdílé rẹ̀ ṣeré, Sárà náà sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó bá di pé kí obìnrin tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀. (Ka 1 Pétérù 3:3-6.) Ábúráhámù rí i dájú pé olùjọsìn Jèhófà ni Ísákì ọmọ rẹ̀ fẹ́. Ọ̀rọ̀ ìjọsìn tòótọ́ yìí náà ló wà lọ́kàn Jékọ́bù, ọmọ Ísákì. Àwọn ọmọ Jékọ́bù yìí ló wá di ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì.

11. Báwo ni Òfin Mósè ṣe tọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ́nà lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó?

11 Nígbà tó yá, Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú, wọ́n sì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn á ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn òfin kan wà lára Òfin Mósè tó ń darí àwọn lọ́kọláya títí kan àwọn tó ní ju ìyàwó kan lọ. Òfin yẹn sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn abọ̀rìṣà kí àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà má bàa bà jẹ́. (Ka Diutarónómì 7:3, 4.) Táwọn tọkọtaya bá ní èdèkòyédè tí wọn ò lè dá yanjú, wọ́n máa ń pe àwọn àgbààgbà pé kí wọ́n dá sí i. Àwọn àgbààgbà yìí máa ń lo òfin Ọlọ́run láti bójú tó ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìwà àìṣòótọ́, owú jíjẹ àti ìfura òdì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé tọkọtaya lè kọ ara wọn sílẹ̀, síbẹ̀ àwọn òfin kan wà tó rọ̀ mọ́ ọn. Bí àpẹẹrẹ, Òfin Mósè gbà pé ẹnì kan lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ torí “ohun àìbójúmu kan.” (Diu. 24:1) Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tí kò bójú mu náà, àmọ́ ó dájú pé kì í ṣe àwọn ẹ̀sùn tí ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀.—Léf. 19:18.

MÁ ṢE HÙWÀ ÀÌṢÒÓTỌ́ SÍ ẸNÌ KEJÌ RẸ

12, 13. (a) Kí làwọn ọkùnrin kan ń ṣe sí ìyàwó wọn nígbà ayé wòlíì Málákì? (b) Tí ẹnì kan tó ti ṣèrìbọmi bá sá lọ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya ẹlòmíì, kí ni ìjọ máa ṣe?

12 Nígbà ayé wòlíì Málákì, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló ń hùwà àìṣòótọ́ sí ìyàwó wọn. Ṣe ni wọ́n ń fọgbọ́n kọ àwọn ìyàwó tí wọ́n fẹ́ nígbà èwe sílẹ̀ torí àwọn ẹ̀sùn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí àtifẹ́ àwọn ọmọge tàbí àwọn obìnrin tí kì í ṣe Júù ni wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà nígbà tí Jésù wà láyé, ṣe làwọn Júù ń kọ àwọn aya wọn sílẹ̀ ‘lórí onírúurú ẹ̀sùn gbogbo.’ (Mát. 19:3) Àmọ́ Bíbélì fi yé wa pé Jèhófà kórìíra irú ìkọ̀sílẹ̀ bẹ́ẹ̀.—Ka Málákì 2:13-16.

13 Àwa èèyàn Jèhófà lónìí kì í gba irú ìwà àìṣòótọ́ bẹ́ẹ̀ láyè. Àmọ́ ká sọ pé ẹnì kan tó ti ṣèrìbọmi tó sì ti ṣègbéyàwó bá sá lọ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya ẹlòmíì, tí wọ́n sì jọ ṣègbéyàwó lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ ẹni tí wọ́n fẹ́ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ni ìjọ máa ṣe? Tírú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ronú pìwà dà, wọ́n máa yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ kí wọ́n lè dáàbò bo ìjọ. (1 Kọ́r. 5:11-13) Kí wọ́n tó lè gba irú ẹni bẹ́ẹ̀ pa dà, ó gbọ́dọ̀ “mú àwọn èso tí ó yẹ ìrònúpìwàdà jáde.” (Lúùkù 3:8; 2 Kọ́r. 2:5-10) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé irú ìwà yìí ṣọ̀wọ́n láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run, síbẹ̀ irú ìwà àìṣòótọ́ bẹ́ẹ̀ ò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Kò sí ìlànà kan tó sọ bó ṣe yẹ kó pẹ́ tó kí wọ́n tó gba irú ẹni bẹ́ẹ̀ pa dà, ó lè tó ọdún kan tàbí kó jù bẹ́ẹ̀ lọ kí oníwà àìtọ́ náà tó lè fi hàn pé lóòótọ́ lòun ti ronú pìwà dà. Àmọ́ ó yẹ ká fi sọ́kàn pé tí wọ́n bá tiẹ̀ gbà á pa dà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣì máa jíhìn “níwájú ìjókòó ìdájọ́ Ọlọ́run.”—Róòmù 14:10-12; wo Ilé Ìṣọ́ May 15, 1980, ojú ìwé 31 sí 32.

OJÚ TÁWỌN KRISTẸNI FI Ń WO ÌGBÉYÀWÓ

14. Àǹfààní wo ni Òfin Mósè ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

14 Òfin Mósè ló darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] ọdún. Ìlànà tó wà nínú Òfin yẹn làwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń lò láti yanjú ọ̀rọ̀ ìdílé àtàwọn ọ̀rọ̀ míì, ó sì tún ṣamọ̀nà wọn títí dìgbà tí Mèsáyà dé. (Gál. 3:23, 24) Àmọ́ nígbà tí Jésù kú, Òfin yẹn dópin, Ọlọ́run sì ṣètò míì láti darí àwọn èèyàn rẹ̀. (Héb. 8:6) Àwọn nǹkan kan wà tí Ọlọ́run fàyè gbà tẹ́lẹ̀, àmọ́ lábẹ́ ìṣètò tuntun yìí, kò fàyè gbà wọ́n mọ́.

15. (a) Òfin wo làwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ ìgbéyàwó? (b) Àwọn nǹkan wo ló yẹ kí Kristẹni kan ronú lé lórí kó tó pinnu pé òun máa kọ ẹni kejì òun sílẹ̀?

15 Nígbà tí Jésù ń dáhùn ìbéèrè kan táwọn Farisí bi í, ó sọ pé lóòótọ́ Òfin Mósè fàyè gbà wọ́n nígbà yẹn láti kọ ìyàwó wọn sílẹ̀, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ ṣe rí “láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” nìyẹn. (Mát. 19:6-8) Jésù wá jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nígbà tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀ ni ìjọ Kristẹni á máa tẹ̀ lé. (1 Tím. 3:2, 12) Ó yẹ káwọn tọkọtaya ṣe ara wọn lọ́kan torí pé wọ́n ti di “ara kan,” àárín wọn sì máa túbọ̀ wọ̀ dáadáa tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Tí tọkọtaya bá kọ ara wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, àmọ́ tí kì í ṣe torí panṣágà, wọn ò ní lè fẹ́ ẹlòmíì. (Mát. 19:9) Ọkọ tàbí aya lè dárí ji ẹnì kejì rẹ̀ tó ṣe panṣágà àmọ́ tó ronú pìwà dà, bí wòlíì Hóséà náà ṣe dárí ji Gómérì ìyàwó rẹ̀ tó ṣe panṣágà. Jèhófà náà dárí ji àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n jọ́sìn àwọn òrìṣà míì. (Hós. 3:1-5) Àmọ́ ohun kan rèé o, tí ẹnì kan bá mọ̀ pé ọkọ tàbí aya òun ti ṣe panṣágà, tó sì wá ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ti dárí jì í nìyẹn kò sì lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ mọ́.

16. Kí ni Jésù sọ nípa àwọn tí kò ṣègbéyàwó?

16 Lẹ́yìn tí Jésù sọ pé ìṣekúṣe nìkan ló lè mú kí ẹnì kan kọ ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, ó sọ̀rọ̀ nípa “àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn” láti wà láìlọ́kọ tàbí láìláya. Ó tún wá sọ pé: “Kí ẹni tí ó bá lè wá àyè fún un wá àyè fún un.” (Mát. 19:10-12) Ọ̀pọ̀ ló ti pinnu pé àwọn ò ní ṣègbéyàwó káwọn lè sin Jèhófà láìsí ìpínyà ọkàn. Ó yẹ ká gbóríyìn fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.

17. Kí ló yẹ kéèyàn rò kó tó pinnu pé òun máa ṣègbéyàwó tàbí òun ò ní ṣe?

17 Ó ṣe pàtàkì kéèyàn ronú jinlẹ̀ dáadáa kó tó dórí ìpinnu pé òun máa wà láìlọ́kọ tàbí láìláya. Ìdì sì ni pé, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló lè ṣe é. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ó dáa téèyàn bá wà láìlọ́kọ tàbí láìláya, àmọ́ ó tún sọ pé: “Nítorí ìgbòdekan àgbèrè, kí olúkúlùkù ọkùnrin ní aya tirẹ̀, kí olúkúlùkù obìnrin sì ní ọkọ tirẹ̀.” Ó tún sọ pé: “Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá ní ìkóra-ẹni-níjàánu, kí wọ́n gbéyàwó, nítorí ó sàn láti gbéyàwó ju kí ìfẹ́ onígbòónára máa mú ara ẹni gbiná.” Lóòótọ́, téèyàn bá ṣègbéyàwó, á lè yẹra fáwọn ìwà tí kò bójú mu, bíi kó máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ tàbí kó lọ ṣèṣekúṣe. Àmọ́, ó tún ṣe pàtàkì kéèyàn wò ó bóyá òun dàgbà tó ẹni tó ń ṣègbéyàwó torí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń hùwà lọ́nà àìbẹ́tọ̀ọ́mu sí ipò wúńdíá òun, bí onítọ̀hún bá ti ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe, tí èyí sì jẹ́ ọ̀nà tí ó yẹ kí ó gbà ṣẹlẹ̀, kí ó ṣe ohun tí ó fẹ́; kò dẹ́ṣẹ̀. Kí wọ́n gbéyàwó.” (1 Kọ́r. 7:2, 9, 36; 1 Tím. 4:1-3) Síbẹ̀, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni lọ ṣègbéyàwó torí àwọn ìmọ̀lára téèyàn máa ń ní nígbà ọ̀dọ́. Ẹni náà lè má tíì dàgbà tó láti bójú tó àwọn ojúṣe táwọn tó ti ṣègbeyàwó máa ń ní.

18, 19. (a) Ta ló yẹ kí Kristẹni kan fẹ́? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 Ọkùnrin àti obìnrin tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ti ṣèrìbọmi ló yẹ kó fẹ́ ara wọn. Nígbà tí wọ́n ṣì ń fẹ́ra sọ́nà, ó yẹ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn débi pé wọ́n á fẹ́ láti ṣègbéyàwó kí wọ́n sì bára wọn kalẹ́. Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún wọn torí pé wọ́n tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì pé kí wọ́n ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́r. 7:39) Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fẹ́ra, wọ́n á máa fi ìlànà Bíbélì sílò kí ìgbéyàwó wọn lè ṣàṣeyọrí.

19 Lónìí, ọ̀pọ̀ ló ń hu àwọn ìwà tó lè tú ìdílé ká, torí náà nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì tó máa ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ kí wọ́n lè kojú àwọn ìṣòro tó ń yọjú láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” yìí. (2 Tím. 3:1-5) Jèhófà ti fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó lè máa tọ́ wa sọ́nà kí ìgbéyàwó wa lè ládùn kó lóyin, ká sì máa bá ètò rẹ̀ rìn ní ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Mát. 7:13, 14.