Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́?

Nítorí ìtọ́ni rere ni ohun tí èmi yóò fi fún yín dájúdájú.”ÒWE 4:2.

ORIN: 93, 96

1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ ká kọ́ àwọn míì kí wọ́n lè fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run?

IṢẸ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù sí Jésù nígbà tó wà láyé. Síbẹ̀, ó wá ààyè láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa bójú tó ìjọ Ọlọ́run kí wọ́n sì di olùkọ́ tó jáfáfá. (Mát. 10:5-7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ Fílípì dí gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, síbẹ̀ òun náà wá ààyè láti dá àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lẹ́kọ̀ọ́ kí àwọn náà lè di ajíhìnrere tó dáńtọ́. (Ìṣe 21:8, 9) Ǹjẹ́ irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì lónìí?

2 Ojoojúmọ́ ni iye àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ń pọ̀ sí i kárí ayé. Ó yẹ káwọn tí kò tíì ṣèrìbọmi mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ bí wọ́n á ṣe máa wàásù fún àwọn míì, kí wọ́n sì mọ béèyàn ṣe ń kọ́ni. Bákan náà, ó tún ṣe pàtàkì kí àwọn arákùnrin tó wà nínú ìjọ ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà. Àǹfààní lèyí jẹ́ fáwọn Kristẹni tó nírìírí láti kọ́ àwọn ẹni tuntun kí wọ́n lè fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run.—Òwe 4:2.

KỌ́ ÀWỌN ẸNI TUNTUN KÍ WỌ́N LÈ MÁA GBÁDÙN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ

3, 4. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé kéèyàn máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa? (b) Ká tó lè ran àwọn míì lọ́wọ́ láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí làwa náà gbọ́dọ̀ máa ṣe?

3 Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? A lè rí ìdáhùn nínú ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè. Ó ní: “Àwa kò ṣíwọ́ gbígbàdúrà fún yín àti bíbéèrè pé kí ẹ lè kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ [Ọlọ́run] nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí, kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún bí ẹ ti ń bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo, tí ẹ sì ń pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.” (Kól. 1:9, 10) Táwọn ará Kólósè bá ní ìmọ̀ pípéye, wọ́n á lè “máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún.” Èyí á mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa “bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo,” ní pàtàkì jù lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé tá a bá fẹ́ jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Ó sì ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà mọ̀ bẹ́ẹ̀.

4 Ká tó lè ran àwọn míì lọ́wọ́ láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwa náà gbọ́dọ̀ ti rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí fi hàn pé àwa náà gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Torí náà, bi ara rẹ pé: ‘Tí àwọn tí mo wàásù fún bá sọ ohun kan tó yàtọ̀ sí ohun tó wà nínú Bíbélì tàbí tí wọ́n béèrè ìbéèré tó le lọ́wọ́ mi, ṣé mo lè fi Bíbélì dá wọn lóhùn? Tí mo bá kà nípa bí Jésù, Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì ṣe ní ìforítì lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn, ṣé mo máa ń ronú nípa bí mo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn?’ Ó dájú pé gbogbo wa la ní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì máa fi ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sílò. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa sọ àwọn àǹfààní tá à ń rí látinú bá a ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn, èyí á mú kó yá wọn lára láti túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

5. Sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé.

5 Bi ara rẹ pé, ‘Kí ni mo lè ṣe tí ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ á fi máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé?’ Ohun tó o lè kọ́kọ́ ṣe ni pé, o lè kọ́ ọ báá ṣe máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ tẹ́ ẹ jọ ń ṣe sílẹ̀. O lè sọ fún un pé kó ka àwọn àfikún tó wà lẹ́yìn ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, kó sì ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí. Kọ́ ọ bó ṣe máa múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ kó lè dáhùn. Sọ fún un pé kó máa ka gbogbo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó bá jáde. Tí Watchtower Library tàbí ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ bá wà ní èdè rẹ̀, o lè fi bó ṣe lè lo àwọn ohun ìwádìí yìí láti wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ní. Tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, òun náà á máa gbádùn bó ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

6. (a) Báwo lo ṣe lè ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè máa wù ú láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (b) Kí ni akẹ́kọ̀ọ́ kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe tó bá ti ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

6 Kò yẹ ká fi dandan mú àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọ́n máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, á dáa ká lo àwọn ohun tí ètò Ọlọ́run ti pèsè láti ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, òun náà á ní irú èrò tí onísáàmù ní nígbà tó kọrin pé: “Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi. Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni mo fi ṣe ibi ìsádi mi.” (Sm. 73:28) Jèhófà máa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí ẹni tó bá ń sapá láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

KỌ́ WỌN BÍ WỌ́N Á ṢE MÁA WÀÁSÙ ÀTI BÍ WỌ́N Á ṢE MÁA KỌ́NI

7. Báwo ni Jésù ṣe kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

7 Nínú ìwé Mátíù orí 10, Jésù fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá láwọn ìtọ́ni nípa bí wọ́n á ṣe máa wàásù, ó sì sọ àwọn nǹkan pàtó tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe. [1] Àwọn àpọ́sítélì náà fetí sílẹ̀ bí Jésù ṣe ń kọ́ wọn. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu nìyẹn. Torí pé wọ́n ń fi àwọn ohun tí Jésù kọ́ wọn sílò, wọ́n di olùkọ́ tó mọ bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mát. 11:1) Àwa náà lè kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa kí wọ́n lè di oníwàásù tó dáńtọ́. Ẹ jẹ́ ká jíròrò ọ̀nà méjì tá a lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́.

8, 9. (a) Báwo ni Jésù ṣe máa ń ṣe sáwọn èèyàn tó ń wàásù fún? (b) Báwo la ṣe lè mú káwọn akéde tuntun máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ bíi ti Jésù?

8 Máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jésù máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ó bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ létí kànga Jékọ́bù tó wà nítòsí ìlú Síkárì. Ìjíròrò yìí gbádùn mọ́ obìnrin yìí débi pé òun àtàwọn ẹlòmíì di ọmọlẹ́yìn. (Jòh. 4:5-30) Ó tún bá agbowó orí kan tó ń jẹ́ Mátíù tàbí Léfì sọ̀rọ̀. Bíbélì ò fi bẹ́ẹ̀ sọ púpọ̀ nípa ìjíròrò tó wáyé láàárín Jésù àti Mátíù, àmọ́ ó sọ pé Mátíù gbà láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Nígbà kan tí Mátíù ṣe àsè nílé rẹ̀, òun àtàwọn míì gbọ́ àwọn ohun tí Jésù sọ fáwọn èèyàn.—Mát. 9:9; Lúùkù 5:27-39.

9 Ẹlòmíì tí Jésù bá sọ̀rọ̀ ni Nàtáníẹ́lì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú tí Nàtáníẹ́lì fi ń wo àwọn èèyàn Násárẹ́tì kù díẹ̀ káàtó, síbẹ̀ Jésù fìfẹ́ bá a sọ̀rọ̀, ìyẹn sì mú kó yí èrò rẹ̀ pa dà. Ó pinnu láti mọ ohun tí Jésù fi ń kọ́ni bó tiẹ̀ jẹ́ pé ará Násárẹ́tì ni Jésù. (Jòh. 1:46-51) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká máa kọ́ àwọn akéde tuntun bí wọ́n á ṣe máa fìfẹ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, tí wọ́n á sì jẹ́ kára tù wọ́n. [2] Ẹ wo bí inú àwọn akéde yìí á ṣe dùn tó pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ń fetí sọ́rọ̀ wọn! Ìdí táwọn èèyàn náà sì ṣe fetí sílẹ̀ ni pé àwọn akéde náà pọ́n wọn lé, wọ́n sì mọyì wọn.

10-12. (a) Báwo ni Jésù ṣe mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run? (b) Báwo la ṣe lè mú káwọn akéde tuntun túbọ̀ mọ bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

10 Mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ rẹ. Àkókò tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ kò tó nǹkan, síbẹ̀ ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ kan wà tí Jésù jókòó sínú ọkọ̀ ojú omi tó sì ń tibẹ̀ kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ̀yìn ìyẹn ló ṣe iṣẹ́ ìyanu tó jẹ́ kí Pétérù kó ẹja wọ̀ǹtìwọnti jáde lódò. Ó wá sọ fún Pétérù pé: “Láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò máa mú àwọn ènìyàn láàyè.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe yìí? Pétérù àtàwọn yòókù rẹ̀ “dá àwọn ọkọ̀ náà padà wá sí ilẹ̀, wọ́n sì pa ohun gbogbo tì, wọ́n sì tẹ̀ lé [Jésù].”—Lúùkù 5:1-11.

11 Nikodémù, tó jẹ́ ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn náà nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ tí Jésù fi ń kọ́ àwọn èèyàn. Ó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù, àmọ́ ẹ̀rù ń bà á torí ohun táwọn èèyàn máa sọ tí wọ́n bá rí i tó ń bá Jésù sọ̀rọ̀ ní gbangba. Torí náà, ó lọ bá Jésù lálẹ́, Jésù ò wá sọ pé ilẹ̀ ti ṣú, ó yẹ kóun lọ sùn, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fara balẹ̀ bá a sọ̀rọ̀. (Jòh. 3:1, 2) Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Jésù máa ń wá àyè fáwọn èèyàn torí ó fẹ́ kí wọ́n nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Torí náà, ó yẹ káwa náà máa sapá láti pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tá a ti bá sọ̀rọ̀ ká sì máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

12 Tá a bá ń bá àwọn akéde tuntun ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, àwọn náà á lè túbọ̀ mọ bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n máa pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa pàápàá. A lè mú àwọn akéde tuntun yìí dání tá a bá fẹ́ lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bá a ṣe ń dá àwọn ẹni tuntun yìí lẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń fún wọn níṣìírí, àwọn náà á mọ bí wọ́n ṣe lè mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bá ò bá tiẹ̀ sí pẹ̀lú wọn, wọ́n á mọ bí wọ́n ṣe lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á kọ́ pé ó yẹ káwọn máa mú sùúrù fáwọn èèyàn, káwọn má sì jẹ́ kí iṣẹ́ náà sú àwọn.—Gál. 5:22; wo àpótí náà “ Sùúrù Ṣe Pàtàkì.”

KỌ́ WỌN BÍ WỌ́N ṢE LÈ MÁA RAN ÀWỌN ARÁ LỌ́WỌ́

13, 14. (a) Kí lo rí kọ́ lára àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n lo ara wọn fún àwọn míì? (b) Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe káwọn ẹni tuntun àtàwọn ọ̀dọ́ lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará?

13 Àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ káwa Kristẹni nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ká sì máa ran ara wa lọ́wọ́. (Ka 1 Pétérù 1:22; Lúùkù 22:24-27.) Àpẹẹrẹ kan ni ti Jésù, gbogbo ohun tó ní ló fún àwọn èèyàn kí wọ́n lè mọ Ọlọ́run, títí kan ẹ̀mí rẹ̀. (Mát. 20:28) Àpẹẹrẹ míì ni ti Dọ́káàsì tó “pọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú.” (Ìṣe 9:36, 39) Ẹlòmíì tún ni Màríà tó ń gbé ní Róòmù. Bíbélì sọ pé ó máa ń ṣiṣẹ́ kára torí àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ. (Róòmù 16:6) Báwo la ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ káwọn náà lè rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n máa ran àwọn ará lọ́wọ́?

Kọ́ àwọn ẹni tuntun bí wọ́n á ṣe máa ṣoore fáwọn ẹlòmíì (Wo ìpínrọ̀ 13 àti 14)

14 Àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run lè mú àwọn ẹni tuntun dání tí wọ́n bá fẹ́ lọ kí àwọn tó ń ṣàìsàn àtàwọn àgbàlagbà. Nígbà míì, àwọn òbí lè mú àwọn ọmọ wọn dání tí wọ́n bá fẹ́ lọ kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Bákan náà, àwọn alàgbà lè ṣètò bí àwọn àtàwọn míì nínú ìjọ á ṣe rí sí i pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń jẹ oúnjẹ tó dáa, ilé wọn sì wà ní mímọ́. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn ẹni tuntun á mọ béèyàn ṣe ń ṣoore fáwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí alàgbà kan bá wà lóde ẹ̀rí, ó sábà máa ń yà kí àwọn ará tó wà lágbègbè ibi tí wọ́n ti ṣiṣẹ́, kó lè wo àlàáfíà wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀dọ́kùnrin tó sábà máa ń bá alàgbà yìí ṣiṣẹ́ wá mọ̀ pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ló yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sí.—Róòmù 12:10.

15. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn alàgbà rí i pé àwọn arákùnrin tó wà nínú ìjọ mọ̀ọ̀yàn kọ́?

15 Torí pé àwọn arákùnrin ni Jèhófà ń lò láti máa kọ́ni nínú ìjọ, ó ṣe pàtàkì pé káwọn arákùnrin mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa. Tó o bá jẹ́ alàgbà, ṣé o lè ní kí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan fi àsọyé rẹ̀ dánra wò lójú rẹ? Ó dájú pé tó o bá ràn án lọ́wọ́, á mọ bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Neh. 8:8. [3]

16, 17. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe dá Tímótì lẹ́kọ̀ọ́? (b) Báwo làwọn alàgbà ṣe lè dá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ káwọn náà lè di alàgbà lọ́jọ́ iwájú?

16 Ojoojúmọ́ ló túbọ̀ ń ṣe kedere sí i pé a nílò àwọn alàgbà nínú ìjọ. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa dá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè di alàgbà lọ́jọ́ iwájú. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí Tímótì, ó sọ àwọn nǹkan tó máa ṣe láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, ó ní: “Ìwọ, ọmọ mi, máa bá a nìṣó ní gbígba agbára nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí ó wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù, àwọn nǹkan tí ìwọ sì ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú ìtìlẹyìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹlẹ́rìí, nǹkan wọ̀nyí ni kí o fi lé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́wọ́, tí àwọn, ẹ̀wẹ̀, yóò tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.” (2 Tím. 2:1, 2) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dá Tímótì lẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀. Ọ̀nà kan náà yìí ni Tímótì wá ń lò láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àti láwọn ìgbà míì.—2 Tím. 3:10-12.

17 Pọ́ọ̀lù ò sọ pé Tímótì á kọ́ béèyàn ṣe ń ṣe nǹkan láyè ara rẹ̀. Rárá, ṣe lòun àti Tímótì jọ máa ń ṣe nǹkan. (Ìṣe 16:1-5) Àwọn alàgbà máa ń fara wé Pọ́ọ̀lù, wọ́n máa ń mú àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó kúnjú ìwọ̀n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn. Àwọn alàgbà ń tipa bẹ́ẹ̀ mú káwọn arákùnrin yìí rí i pé ẹni tó bá máa di alàgbà nínú ìjọ gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́, kó mọ̀ọ̀yàn kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, kó máa ní sùúrù, kó sì nífẹ̀ẹ́. Táwọn alàgbà bá ń bá àwọn ìránṣẹ́ ìṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣiṣẹ́ lọ́nà yìí, wọ́n á lè tóótun láti di “olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run” lọ́jọ́ iwájú.—1 Pét. 5:2.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ PÉ KÁ MÁA DÁ ÀWỌN MÍÌ LẸ́KỌ̀Ọ́

18. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà?

18 Ó ṣe pàtàkì pé ká máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ torí pé ojoojúmọ́ làwọn ẹni tuntun ń wá sínú ètò Jèhófà, bẹ́ẹ̀ náà la sì nílò àwọn arákùnrin tó máa bójú tó ìjọ. Tá a bá ń rántí àpẹẹrẹ Jésù àti ti Pọ́ọ̀lù, àá rí i pé ó yẹ ká máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè jáfáfá nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Àǹfààní ńlá ni Jèhófà fún wa pé ká dá àwọn ẹni tuntun lẹ́kọ̀ọ́ káwọn náà lè túbọ̀ wúlò nínú ìjọ. Bí ipò nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i nínú ayé làwọn èèyàn ṣe túbọ̀ nílò ìhìn rere. Torí náà, ó túbọ̀ ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́.

19. Kí ló mú kó dá wa lójú pé gbogbo ìsapá wa láti dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ máa yọrí sí rere?

19 Ó máa ń gba àkókò àti ọ̀pọ̀ ìsapá ká tó lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́, Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ máa tì wá lẹ́yìn, wọ́n sì máa fún wa lọ́gbọ́n tá a máa fi ṣe é. Inú wa máa dùn gan-an tá a bá ń rí àwọn tá a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ‘ń ṣiṣẹ́ kára, tí wọ́n sì ń tiraka.’ (1 Tím. 4:10) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ láti ṣe púpọ̀ sí i bá a ṣe ń jọ́sìn Jèhófà.

^ [1] (ìpínrọ̀ 7) Lára ohun tí Jésù sọ fún wọn ni pé: (1) Kí wọ́n máa wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. (2) Kí wọ́n jẹ́ kí ohun tí wọ́n ní tẹ́ wọn lọ́rùn. (3) Kí wọ́n má ṣe bá àwọn tí wọ́n ń wàásù fún jiyàn. (4) Kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run táwọn kan bá ta kò wọ́n. (5) Wọn ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù.

^ [2] (ìpínrọ̀ 9) Àwọn àbá tó wúlò nípa bá a ṣe lè máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí wà nínú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 62 sí 64.

^ [3] (ìpínrọ̀ 15) Wàá rí àwọn ànímọ́ táá jẹ́ kó o mọ béèyàn ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 52 sí 61.