Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Lè Fi Kún Ohun Tó Ò Ń Ṣe Nínú Ìjọsìn Ọlọ́run?

Ǹjẹ́ O Lè Fi Kún Ohun Tó Ò Ń Ṣe Nínú Ìjọsìn Ọlọ́run?

Máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba, fún ìgbani-níyànjú, fún kíkọ́ni.1 TÍM. 4:13.

ORIN: 45, 70

1, 2. (a) Báwo lohun tó wà nínú ìwé Aísáyà 60:22 ṣe ń nímùúṣẹ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí? (b) Àwọn apá wo ló ti yẹ ká fi kún ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run lónìí?

BÍBÉLÌ sọ pé: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè.” (Aísá. 60:22) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ń ṣẹ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2015, àwọn akéde tí ó tó 8,220,105 ló kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Síbẹ̀, ó yẹ kí gbogbo wa ronú lórí ohun tí Jèhófà sọ lápá ìgbẹ̀yìn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn pé: “Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” Gbogbo wa là ń fojú ara wa rí bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú lónìí. Kí lẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti rí i pé òun ń bá ètò Ọlọ́run rìn bó ṣe ń tẹ̀ síwájú? Ṣé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù? Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé àti aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Inú wa sì ń dùn bá a ṣe ń rí i tí ọ̀pọ̀ ń ṣí lọ síbi tí àìní gbé pọ̀ táwọn míì sì ń kópa nínú àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn míì.

2 Bákan náà, a túbọ̀ nílò àwọn táá máa bójú tó iṣẹ́ nínú ìjọ. Ìdí ni pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ìjọ tuntun là ń dá sílẹ̀ lọ́dọọdún. Ká sọ pé alàgbà márùn-ún máa wà nínú ìjọ tuntun kọ̀ọ̀kan, á jẹ́ pé lọ́dọọdún, a máa nílò kí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà. Ìyẹn sì máa gba pé kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ohun kan ni pé yálà a jẹ́ arákùnrin tàbí arábìnrin, gbogbo wa pátá la ní ‘púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.’—1 Kọ́r. 15:58.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI FI KÚN OHUN TÁ À Ń ṢE NÍNÚ ÌJỌSÌN ỌLỌ́RUN

3, 4. Báwo lo ṣe lè fi kún ohun tó ò ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run?

3 Ka 1 Tímótì 3:1. Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tá a tú sí “nàgà fún” túmọ̀ sí kéèyàn nawọ́ kọ́wọ́ rẹ̀ lè tó ohun tó ń fẹ́. Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lò yìí jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn gbọ́dọ̀ sapá kọ́wọ́ rẹ̀ tó lè tẹ àwọn ohun tó ń lé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé arákùnrin kan tí kò tíì di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ronú nípa bó ṣe lè fi kún ohun tó ń ṣe nínú ìjọ. Ó mọ̀ pé kóun tó lè kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, òun gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó ní láti dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè kó tó lè di alàgbà. Èyí fi hàn pé ó gba ìsapá kéèyàn tó lè tóótun láti ní àfikún iṣẹ́ èyíkéyìí nínú ìjọ.

4 Lọ́nà kan náà, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó bá fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà, tó fẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí tó fẹ́ yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba gbọ́dọ̀ sapá kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe gbà wá níyànjú láti fi kún ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run.

SAPÁ LÁTI FI KÚN OHUN TÓ Ò Ń ṢE NÍNÚ ÌJỌSÌN ỌLỌ́RUN

5. Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè lo okun wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?

5 Àwọn ọ̀dọ́ máa ń lo okun wọn láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Ka Òwe 20:29.) Àwọn ọ̀dọ́ kan tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì máa ń ṣiṣẹ́ níbi tá a ti ń tẹ Bíbélì àtàwọn ìwé míì. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n sì ń tún un ṣe. Àwọn ọ̀dọ́ míì sì máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń ṣètò ìrànwọ́ níbi tí àjálù bá ti ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ló sì ń tan ìhìn rere náà dé àwọn abúlé àtàwọn ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè.

6-8. (a) Kí ló mú kí arákùnrin kan yí èrò tó ní nípa iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run pa dà, kí ló sì yọrí sí? (b) Báwo la ṣe lè tọ́ Jèhófà wò, ká sì rí i pé ẹni rere ni?

6 Ó ṣeé ṣe kó máa wù ẹ́ láti lo ara rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Àmọ́ tó bá ń ṣe ẹ́ bíi ti arákùnrin kan tó ń jẹ́ Aaron ńkọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn tó tọ́ Aaron dàgbà, síbẹ̀ ó sọ pé, “Ìpàdé àti òde ẹ̀rí máa ń sú mi.” Ó wù ú pé kó máa fayọ̀ sin Jèhófà, àmọ́ kò láyọ̀. Kí ló wa ṣe nípa rẹ̀?

7 Aaron bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì déédéé, ó ń múra ìpàdé sílẹ̀ ó sì ń dáhùn nípàdé. Ó tún máa ń gbàdúrà déédéé. Ìfẹ́ Jèhófà túbọ̀ wá jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ̀, èyí mú kó túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn náà ló gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó sì ń ṣèrànwọ́ níbi tí àjálù bá ti ṣẹlẹ̀, kódà ó tún lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì. Ní báyìí, Aaron ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, ó sì tún jẹ́ alàgbà nínú ìjọ. Nígbà tí Aaron wo ìrìn àjò ìgbésí ayé rẹ̀, ó sọ pé: “Mo ti tọ́ Jèhófà wò, mo ‘sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.’ Jèhófà ti bù kún mi gan-an, torí náà mo mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi, bí mo sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ni ìbùkún yẹn túbọ̀ ń pọ̀ sí i.”

8 Onísáàmù náà kọrin pé: ‘Àwọn tí ń wá Jèhófà kì yóò ṣaláìní ohun rere èyíkéyìí.’ (Ka Sáàmù 34:8-10.) Jèhófà kì í gbàgbé àwọn tó ń fìtara sìn ín. Táwa náà bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, àwa náà ń tọ́ Jèhófà wò nìyẹn, àá sì rí i pé lóòótọ́ ló jẹ́ ẹni rere. Tá a bá ń fi gbogbo okun, agbára àti ọkàn wa sin Jèhófà, ayọ̀ wa á kọjá àfẹnusọ.

NÍ ÌFORÍTÌ, MÁ ṢE JẸ́ KÓ SÚ Ẹ

9, 10. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ní sùúrù?

9 Bó o ṣe ń sapá kí ọwọ́ rẹ lè tẹ ohun tó ò ń lé, ó ṣe pàtàkì pé kó o ní “ẹ̀mí ìdúródeni” tàbí sùúrù. (Míkà 7:7) Jèhófà máa ń dúró ti àwọn tó ń fòótọ́ inú sìn ín, kì í fi wọ́n sílẹ̀ rárá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè fẹ́ kí wọ́n ní sùúrù kọ́wọ́ wọn tó tẹ àǹfààní tí wọ́n ń fẹ́, ó sì lè má tètè yí ipò tí kò rọgbọ fún wọn pa dà. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé ó máa bímọ, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ọdún ni ọkùnrin olóòótọ́ yìí fi ní sùúrù, tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ò sì yingin. (Héb. 6:12-15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún kọjá kí Ábúráhámù tó bí Ísákì, síbẹ̀ kò sọ̀rètí nù, Jèhófà náà ò sì já a kulẹ̀.—Jẹ́n. 15:3, 4; 21:5.

10 Kì í rọrùn fáwa èèyàn láti mú sùúrù. (Òwe 13:12) Tá a bá ń dààmú ṣáá lórí ohun tá à ń lé àmọ́ tọ́wọ́ wa ò tíì tẹ̀, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Torí náà, á dáa ká máa fàkókò wa ronú lórí bá a ṣe lè sunwọ̀n sí i nínú ìjọsìn wa. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

11. Àwọn ànímọ́ àtàtà wo ló yẹ ká sapá láti ní, kí sì nìdí tí wọ́n fi ṣe pàtàkì?

11 Máa ṣe ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ jẹ́ni tẹ̀mí. Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, àá ní ọgbọ́n, òye, ìmọ̀, àá tún láròjinlẹ̀. Ó ṣe pàtàkì pé káwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ Ọlọ́run láwọn ànímọ́ yìí. (Òwe 1:1-4; Títù 1:7-9) Bá a bá ń ka àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, àá mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan. Èyí ṣe pàtàkì torí pé ojoojúmọ́ là ń ṣe àwọn ìpinnu tó kan eré ìnàjú tá a yàn láàyò, ìmúra wa, bá a ṣe ń náwó àti bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì. Tá a bá ń fi ohun tá à ń kọ́ nínú Bíbélì sílò, àá ṣe àwọn ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn.

12. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ ẹni tó ṣe é fọkàn tán?

12 Jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Yálà a jẹ́ arákùnrin tàbí arábìnrin, a gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún wa nínú ètò Ọlọ́run. Láyé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Nehemáyà tó jẹ́ gómìnà yan àwọn táá máa bójú tó àwọn iṣẹ́ pàtàkì láàárín àwọn èèyàn náà. Irú àwọn wo ló yàn? Bíbélì sọ pé ó yan àwọn tó ṣeé fọkàn tán, tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tó sì jẹ́ olùṣòtítọ́. (Neh. 7:2; 13:12, 13) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, torí pé ohun tá à ń retí lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ni pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. (1 Kọ́r. 4:2) Ohun kan ni pé àwọn èèyàn máa ń ṣàkíyèsí àwọn iṣẹ́ àtàtà tẹ́nì kan bá ń ṣe.—Ka 1 Tímótì 5:25.

13. Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù táwọn míì bá hùwà àìdáa sí ẹ?

13 Jẹ́ kí Jèhófà mú kó o túbọ̀ tóótun. Kí ló yẹ kó o ṣe táwọn míì bá hùwà àìdáa sí ẹ? Á dáa kó o tètè yanjú ọ̀rọ̀ náà. Tó o bá ń wá bó o ṣe máa dá ara rẹ láre nínú ọ̀rọ̀ kan, lọ́pọ̀ ìgbà ńṣe nìyẹn tún máa dá kún ohun tó wà nílẹ̀. A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jósẹ́fù. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ hùwà àìdáa sí i, síbẹ̀ kò dì wọ́n sínú. Nígbà tó ya, àwọn kan fẹ̀sùn èké kàn án, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n láìtọ́. Síbẹ̀, ó jẹ́ kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà ní gbogbo àsìkò tí nǹkan nira yẹn. Kí ló wá gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà? Bíbélì sọ pé: “Àsọjáde Jèhófà tìkára rẹ̀ yọ́ ọ mọ́.” (Sm. 105:19) Àwọn àdánwò yẹn mú kí Jósẹ́fù tóótun fún iṣẹ́ pàtàkì kan. (Jẹ́n. 41:37-44; 45:4-8) Bí ìwọ náà ṣe ń bá onírúurú ìṣòro yí, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó sì fún ẹ ní ọgbọ́n tó o nílò. Máa hùwà tútù kó o sì máa sọ̀rọ̀ tó ń tuni lára. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Ka 1 Pétérù 5:10.

FI KÚN ÌTARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

14, 15. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa “fiyè sí” ọ̀nà tá à ń gbà wàásù? (b) Kí lo lè ṣe tí kò bá rọrùn láti wàásù ládùúgbò rẹ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí àti àpótí náà “ Ǹjẹ́ O Lè Wàásù Láwọn Ọ̀nà Míì?”)

14 Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì pé: “Máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba, fún ìgbani-níyànjú, fún kíkọ́ni. Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ.” (1 Tím. 4:13, 16) Tímótì mọ béèyàn ṣe ń wàásù dáadáa, síbẹ̀ kí ìwàásù rẹ̀ tó lè méso jáde, ó gbọ́dọ̀ “máa fiyè sí” ọ̀nà tó ń gbà wàásù. Ìwàásù rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ dà bí adágún omi tí kì í kúrò lójú kan. Bí Tímótì bá fẹ́ kọ́rọ̀ rẹ̀ túbọ̀ máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, ó gbọ́dọ̀ máa lo onírúurú ọ̀nà láti wàásù. Ohun tó yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn.

15 Lónìí, a kì í sábà bá àwọn èèyàn nílé tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé. Láwọn ibòmíì, a kì í lè wọ àwọn ilé tàbí àdúgbò tó ní géètì. Bó bá jẹ́ pé bí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín ṣe rí nìyẹn, á dáa kó o ronú lórí àwọn ọ̀nà míì tó o lè máa gbà polongo ìhìn rere náà.

16. Báwo ni ìwàásù níbi térò pọ̀ sí ṣe gbéṣẹ́ tó?

16 Ọ̀nà kan tó dáa tá a lè gbà tan ìhìn rere náà kalẹ̀ ni pé ká máa wàásù níbi térò pọ̀ sí. Ọ̀pọ̀ àwọn akéde ló ti rí i pé ọ̀nà ìwàásù yìí gbéṣẹ́ gan-an. Wọ́n máa ń ṣètò láti lọ sí àwọn ibùdókọ̀, ọjà, ibi ìgbọ́kọ̀sí àtàwọn ibòmíì térò máa ń pọ̀ sí. Àwọn akéde yìí máa ń fọgbọ́n bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹni tí wọ́n bá rí. Wọ́n lè mẹ́nu ba ohun kan nínú ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ tàbí kí wọ́n gbóríyìn fáwọn ọmọ ẹni náà, wọ́n sì lè bí i nípa iṣẹ́ rẹ̀. Bí ìjíròrò náà ṣe ń lọ, akéde náà lè fọgbọ́n lo ọ̀rọ̀ Bíbélì kan táá gba pé kẹ́ni náà fèsì. Èyí lè mú kí ìjíròrò náà máa tẹ̀ síwájú.

17, 18. (a) Kí lo lè ṣe tẹ́rù bá ń bà ẹ́ láti wàásù níbi térò pọ̀ sí? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ní irú ẹ̀mí tí Dáfídì ní bá a ṣe ń wàásù?

17 Tó bá ṣòro fún ẹ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ níbi térò pọ̀ sí, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Aṣáájú-ọ̀nà ni Eddie tó ń gbé nílùú New York City. Nígbà kan, ẹ̀rù máa ń bà á láti wàásù níbi térò pọ̀ sí. Àmọ́ nígbà tó yá, ó borí ìbẹ̀rù yẹn. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Tá a bá ń ṣe ìjọsìn ìdílé, èmi àtìyàwó mi máa ń jíròrò onírúurú nǹkan táwọn èèyàn máa ń sọ, a sì máa ń ṣèwádìí nípa èsì tá a máa fáwọn tó bá ta ko ọ̀rọ̀ wa. A tún máa ń bi àwọn ará wa míì nípa ohun táwọn náà rò.” Ní báyìí, Arákùnrin Eddie ń gbádùn kó máa wàásù níbi térò pọ̀ sí.

18 Bó o ṣe ń jáfáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, tó o sì ń fìgboyà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ọ̀pọ̀ máa rí i pé o ti tẹ̀ síwájú dáadáa. (Ka 1 Tímótì 4:15.) Ìwọ náà á lè máa fìyìn fún Jèhófà bíi ti Dáfídì tó kọrin pé: “Ṣe ni èmi yóò máa fi ìbùkún fún Jèhófà ní gbogbo ìgbà; ìgbà gbogbo ni ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi. Ọkàn mi yóò máa ṣògo nínú Jèhófà; àwọn ọlọ́kàn tútù yóò gbọ́, wọn yóò sì máa yọ̀.” (Sm. 34:1, 2) Ó lè jẹ́ ìsapá rẹ ló máa mú káwọn ọlọ́kàn tútù wá dara pọ̀ mọ́ wa, kí wọ́n sì máa fayọ̀ sin Jèhófà.

BÓ O ṢE Ń FI KÚN OHUN TÓ Ò Ń ṢE NÍNÚ ÌJỌSÌN ỌLỌ́RUN Ń FÒGO FÚN JÈHÓFÀ

19. Kí nìdí tó fi yẹ kínú àwọn tó ń fọkàn sin Jèhófà máa dùn kódà tí nǹkan ò bá rọrùn fún wọn?

19 Dáfídì tún kọrin pé: “Gbogbo iṣẹ́ rẹ ni yóò máa gbé ọ lárugẹ, Jèhófà, àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yóò sì máa fi ìbùkún fún ọ. Wọn yóò máa sọ̀rọ̀ nípa ògo ipò ọba rẹ, wọn yóò sì máa sọ̀rọ̀ nípa agbára ńlá rẹ, láti sọ àwọn ìṣe agbára ńlá rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn àti ògo ọlá ńlá ipò ọba rẹ̀.” (Sm. 145:10-12) Ó dájú pé irú èrò yìí ni gbogbo àwọn tó ń fọkàn sin Jèhófà náà ní. Àmọ́ tí àìlera tàbí ara tó ń dara àgbà kò bá jẹ́ kó o lè wàásù tó bó o ṣe fẹ́ ńkọ́? Máa rántí pé bó o ṣe ń wàásù fáwọn dókítà àtàwọn míì tó ń tọ́jú ẹ, ṣe nìwọ náà ń fògo fún Ọlọ́run. Tó bá jẹ́ torí ohun tó o gbà gbọ́ ni wọ́n ṣe fi ẹ́ sẹ́wọ̀n, ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà máa wàásù fáwọn tẹ́ ẹ jọ wà lẹ́wọ̀n nígbà tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ ń múnú Jèhófà dùn. (Òwe 27:11) Inú Jèhófà sì máa ń dùn tẹ́nì kan bá ń sìn ín láìka pé àwọn tó kù nínú ìdílé rẹ̀ kò ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Pét. 3:1-4) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, o lè fi kún ohun tó ò ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run kódà tí nǹkan ò bá rọrùn fún ẹ pàápàá.

20, 21. Àǹfààní wo làwọn míì máa rí tó o bá ń lo ara rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?

20 Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ẹ tó o bá ń sapá láti fi kún ohun tó ò ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀. Tó o bá ṣètò ara rẹ̀ dáadáa, wàá túbọ̀ ráyè láti máa sọ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn. Bákan náà, bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, tó o sì túbọ̀ ń lo ara rẹ fún iṣẹ́ Ọlọ́run máa ṣe àwọn ará láǹfààní. Èyí á mú káwọn ará ìjọ nífẹ̀ẹ́ rẹ, wọ́n á sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń rí i tó ò ń lo ara rẹ fún iṣẹ́ Ọlọ́run.

21 Yálà ọ̀pọ̀ ọdún la ti ń sin Jèhófà bọ̀ tàbí kó jẹ́ oṣù mélòó kan péré, gbogbo wa pátá la lè fi kún ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Àmọ́ báwo làwọn tó nírìírí ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti fi kún iṣẹ́ ìsìn wọn? A máa jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.