Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Wá Ohun Tó Sàn Ju Góòlù Lọ

Máa Wá Ohun Tó Sàn Ju Góòlù Lọ

Ṣé o ti rí ògidì góòlù he rí? Ìwọ̀nba èèyàn ló tíì rírú ẹ̀ rí. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí nǹkan míì tó sàn ju góòlù lọ, ìyẹn ọgbọ́n Ọlọ́run tí a “kò lè fi ògidì wúrà ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ̀.”—Jóòbù 28:12, 15.

ÀWỌN tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dà bí àwọn tó ń wa góòlù. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbọ́dọ̀ máa walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa yẹ Ìwé Mímọ́ wò dáadáa kí wọ́n lè rí ọgbọ́n Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́ta táwọn èèyàn ń gbà rí góòlù, ká sì wo ohun tá a lè rí kọ́ lára wọn.

ÌGBÀ TÓ O BẸ̀RẸ̀ SÍ Í KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ

Ká sọ pé ò ń rìn létí odò lọ́jọ́ kan, lo bá tajú kán rí òkúta kékeré kan tó ń dán bí oòrùn ṣe ń tàn sí i. Nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ wò ó, o rí i pé góòlù kékeré kan ni. Ó kéré ju orí ìṣáná lọ, àmọ́ ó ṣeyebíye ju dáyámọ́ǹdì tó níye lórí pàápàá. Ó dájú pé wàá túbọ̀ wolẹ̀ dáadáa bóyá wàá tún rí àwọn góòlù kéékèèké míì níbẹ̀.

Lọ́nà kan náà, ó ṣeé ṣe kó o rántí ọjọ́ náà lọ́hùn-ún táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ wá sọ́dọ̀ rẹ, tí wọ́n sì sọ àwọn nǹkan tó wà nínú Bíbélì fún ẹ. O lè rántí ìgbà tó o kọ́kọ́ rí òtítọ́ tó dà bí góòlù kékeré tó ṣeyebíye. Ó lè jẹ́ ìgbà tó o kọ́kọ́ rí orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà nínú Bíbélì. (Sm. 83:18) Ó sì lè jẹ́ ìgbà tó o mọ̀ pé o lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Ják. 2:23) Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tó o kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ yẹn lo mọ̀ pé o ti rí ohun tó dáa ju góòlù lọ. Ó sì dájú pé á máa wù ẹ́ gan-an láti kọ́ àwọn òtítọ́ míì tó wà nínú Bíbélì.

Ò Ń KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I

Àwọn góòlù tín-tìn-tín máa ń kóra jọ sínú odò. Ìdí nìyẹn táwọn tó ń wa góòlù fi máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè rí góòlù tó pọ̀ gan-an kó. Kódà, góòlù tí wọn máa ń rí láàárín àkókò díẹ̀ lè mú owó rẹpẹtẹ wọlé fún wọn.

Nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ńṣe lo dà bí ẹni tó ń wá góòlù láàárín àwọn òkúta tó wà lábẹ́ odò. Bó o ṣe ń ronú lorí onírúurú ẹsẹ Bíbélì túbọ̀ ń mú kí òye rẹ pọ̀ sí i, ó sì ń mú kó o sún mọ́ Ọlọ́run. Bó o ṣe ń walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó o sì ń rí àwọn òtítọ́ tó ṣeyebíye yìí, o bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ bó o ṣe lè sún mọ́ Jèhófà àti bó o ṣe lè máa ṣe ohun tó fẹ́ kó o lè rí ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú.—Ják. 4:8; Júúdà 20, 21.

Bí ẹni tó ń wá góòlù ṣe máa ṣiṣẹ́ kára kó tó rí i, ṣé ìwọ náà ń sapá kó o lè mọ àwọn òtítọ́ tó ṣeyebíye tó wà nínú Bíbélì?

Bí ẹni tó ń wá góòlù ṣe máa ń ṣiṣẹ́ kára kó tó rí i, ìwọ náà ti ní láti walẹ̀ jìn dáadáa kó o lè rí àwọn òtítọ́ tó ṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ohun tó o kọ́ yìí ló sún ẹ láti ya ara rẹ sí mímọ́ tó o sì ṣèrìbọmi.—Mát. 28:19, 20.

TÚBỌ̀ MÁA WALẸ̀ JÌN

Nígbà míì, wọ́n máa ń rí àwọn góòlù tín-tìn-tín nínú àpáta. Tí wọ́n bá mọ̀ pé góòlù wà nínú àpáta kan, wọ́n á fọ́ àpáta náà kí wọ́n lè wa góòlù inú rẹ̀ jáde. Àmọ́ tó o bá kọ́kọ́ wo àpáta náà, o lè má rí góòlù tó wà nínú rẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé góòlù tí wọ́n máa ń rí nínú àpáta náà lè má ju bíńtín lọ. Síbẹ̀, àwọn tó ń wa góòlù gbà pé iṣẹ́ táwọn ṣe láti rí bíńtín yẹn tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Ó gba ìsapá kéèyàn tó lè tẹ̀ síwájú kọjá àwọn “àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ nípa Kristi.” (Héb. 6:1, 2) O ní láti walẹ̀ jìn dáadáa tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tuntun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Torí náà, kí lo lè ṣe kó o lè jàǹfààní kíkún tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́, kódà tó bá jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́?

Jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́, kó o máa fiyè sí àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ohun tó ń kọ́, kó o sì túbọ̀ sapá láti máa walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá rí ọgbọ́n Ọlọ́run àti ìtọ́sọ́nà tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní. (Róòmù 11:33) Kí òye Bíbélì tó o ní lè pọ̀ sí i, o lè máa lo àwọn ohun tá a fi ń ṣèwádìí tó wà lédè rẹ. Máa fara balẹ̀ wá àwọn ohun táá ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì máa wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó o ní. Béèrè àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tàbí àwọn àpilẹ̀kọ tó ti ran àwọn míì lọ́wọ́, tó sì fún wọn níṣìírí. Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o máa sọ àwọn ohun tuntun tó ò ń kọ́ nínú Bíbélì fáwọn ẹlòmíì.

Kì í ṣe torí kó o kàn lè ní ìmọ̀ orí lásán lo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé “ìmọ̀ a máa wú fùkẹ̀.” (1 Kọ́r. 8:1) Torí náà, sapá láti máa rẹ ara rẹ sílẹ̀, kó o sì mú kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára. Máa ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé, kó o sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Àwọn nǹkan yìí á mú kó o máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kó o sì máa ran àwọn míì lọ́wọ́. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wàá láyọ̀ torí pé ọgbọ́n Ọlọ́run tó o ní máa ṣe ẹ́ láǹfààní ju góòlù lọ.—Òwe 3:13, 14.