Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 33

“Àwọn Tó Ń Fetí Sí Ọ” Máa Rí Ìgbàlà

“Àwọn Tó Ń Fetí Sí Ọ” Máa Rí Ìgbàlà

“Máa kíyè sí ara rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ nígbà gbogbo. Rí i pé o ò jáwọ́ nínú ṣíṣe àwọn nǹkan yìí, torí tí o bá ń ṣe é, wàá lè gba ara rẹ àti àwọn tó ń fetí sí ọ là.”​—1 TÍM. 4:16.

ORIN 67 “Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà”

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ni gbogbo wa fẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí wa ṣe?

ARÁBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Pauline * sọ pé: “Àtìgbà tí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ló ti ń wù mí pé kí gbogbo mọ̀lẹ́bí mi náà kẹ́kọ̀ọ́ ká lè jọ wà ní Párádísè. Èyí tó tiẹ̀ wù mí jù ni pé kí ọkọ mi Wayne àti ọmọ wa di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ṣé àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ kan wà tí kò tíì mọ Jèhófà? Bíi ti Pauline, ó ṣeé ṣe kó máa ṣe ìwọ náà pé káwọn mọ̀lẹ́bí ẹ wá sin Jèhófà.

2. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 A ò lè fipá mú àwọn mọ̀lẹ́bí wa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́, a lè gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n fetí sí ìwàásù, kí wọ́n sì ronú nípa ohun tí wọ́n gbọ́. (2 Tím. 3:14, 15) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa? Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gba tiwọn rò? Kí la lè ṣe táá mú kí wọ́n wá jọ́sìn Jèhófà bíi tiwa? Ìrànlọ́wọ́ wo sì làwọn ará inú ìjọ lè ṣe?

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA WÀÁSÙ FÁWỌN MỌ̀LẸ́BÍ WA?

3. Bó ṣe wà nínú 2 Pétérù 3:9, kí nìdí tó fi yẹ ká máa wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa?

3 Láìpẹ́, Jèhófà máa pa ètò búburú yìí run. Kìkì “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” nìkan ló sì máa là á já. (Ìṣe 13:48) Tá a bá ń lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun láti wàásù fáwọn tí kò bá wa tan tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, mélòómélòó àwọn mọ̀lẹ́bí wa. Torí náà, ó yẹ kó túbọ̀ máa wù wá pé káwọn mọ̀lẹ́bí wa di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ṣe tán, Jèhófà Baba wa ọ̀run “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.”—Ka 2 Pétérù 3:9.

4. Ohun tí kò tọ́ wo la sábà máa ń ṣe tá a bá ń wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa?

4 Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé a lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́, a sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́. Ó ṣe tán, wọ́n máa ń sọ pé pẹ̀lẹ́ lákọ ó sì lábo. Tá a bá ń wàásù fáwọn tá ò mọ̀ rí, a máa ń fi pẹ̀lẹ́tù bá wọn sọ̀rọ̀, àmọ́ a kì í sábà ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń bá àwọn mọ̀lẹ́bí wa sọ̀rọ̀.

5. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn ká tó wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa?

5 Nígbà míì, tá a bá ronú nípa ìgbà tá a kọ́kọ́ wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa, a lè rí i pé ọ̀nà tá a gbà bá wọn sọ̀rọ̀ ò dáa tó. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure, tí iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bó ṣe yẹ kí ẹ dá ẹnì kọ̀ọ̀kan lóhùn.” (Kól. 4:5, 6) Ó yẹ ká fi ìmọ̀ràn yìí sílò nígbàkigbà tá a bá fẹ́ wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa. Torí tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe la máa lé wọn sá dípò ká fà wọ́n wá sínú òtítọ́.

BÁ A ṢE LÈ RAN ÀWỌN MỌ̀LẸ́BÍ WA LỌ́WỌ́

Ọ̀nà tó dáa jù tó o lè gbà wàásù ni pé kó o máa gba tiwọn rò, kó o sì máa hùwà tó dáa (Wo ìpínrọ̀ 6 sí 8) *

6-7. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa gba ti ọkọ tàbí aya wa rò.

6 Máa gba tiwọn rò. Pauline tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan ló máa ń wù mí ṣáá pé kí n bá ọkọ mi sọ, a kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ àwọn ọ̀rọ̀ míì.” Àmọ́ Wayne ọkọ ẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ mọ púpọ̀ nípa Bíbélì, torí náà ọ̀rọ̀ ìyàwó ẹ̀ kì í yé e rárá. Lójú ẹ̀, ṣe ló dà bíi pé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ni ìyàwó ẹ̀ gbé karí. Ẹ̀rù sì ń bà á pé ó ti kó wọnú ẹgbẹ́ kan àti pé ó ti gba wèrè mẹ́sìn.

7 Pauline sọ pé ìgbà kan wà tóun kì í fi bẹ́ẹ̀ gbélé. Ìdí sì ni pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìrọ̀lẹ́ àti òpin ọ̀sẹ̀ ló fi máa ń wà pẹ̀lú àwọn ará, yálà nípàdé, lóde ẹ̀rí tàbí níbi àpèjẹ. Pauline sọ pé: “Tí Wayne bá délé, kì í bá ẹnì kankan, ó sì máa ń dá wà.” Kò sí àní-àní pé ó máa ń wu Wayne pé kó bá ìyàwó àti ọmọ ẹ̀ nílé. Kò mọ àwọn tí ìyàwó rẹ̀ ń bá kẹ́gbẹ́, ó sì jọ pé àwọn ọ̀rẹ́ tuntun tó ní yìí ṣe pàtàkì sí i ju òun lọ. Ni Wayne bá sọ fún un pé òun máa kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ǹjẹ́ ẹ rò pé àwọn nǹkan kan wà tó yẹ kí Pauline ṣe àmọ́ tí kò ṣe?

8. Bó ṣe wà nínú 1 Pétérù 3:1, 2, kí ló lè mú káwọn mọ̀lẹ́bí wa nífẹ̀ẹ́ òtítọ́?

8 Máa hùwà tó dáa kó o lè yí wọn lọ́kàn pa dà. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn èèyàn máa ń kíyè sí ìwà wa ju ohun tá à ń sọ lọ. (Ka 1 Pétérù 3:1, 2.) Nígbà tí Pauline lóye kókó yìí, ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé ọkọ mi nífẹ̀ẹ́ mi gan-an, kò sì wù ú pé ká kọra wa sílẹ̀. Àmọ́ bó ṣe sọ pé òun máa kọ̀ mí sílẹ̀ yẹn mú kí n yẹra mi wò, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. Mo rí i pé á dáa kí n tẹra mọ́ ìwà rere dípò kí n máa sọ̀rọ̀ Bíbélì ṣáá.” Kí ni Pauline wá ṣe? Kì í fìgbà gbogbo wàásù fún ọkọ ẹ̀ mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n jọ máa ń sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe ń lọ. Wayne kíyè sí i pé ìyàwó òun kì í yọ òun lẹ́nu mọ́, ìwà ọmọ wọn sì ń wú u lórí gan-an. (Òwe 31:18, 27, 28) Nígbà tí Wayne rí bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe ń ṣe ìdílé òun láǹfààní, ó gbà kí wọ́n máa bá òun sọ̀rọ̀ Bíbélì.—1 Kọ́r. 7:12-14, 16.

9. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó sú wa láti máa wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa?

9 Má jẹ́ kó sú ẹ. Jèhófà ti fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa. Bíbélì sọ pé “léraléra” ni Jèhófà ń fún àwọn èèyàn láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere kí wọ́n lè jèrè ìyè. (Jer. 44:4) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé kó má jáwọ́ nínú sísọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó máa gba ara rẹ̀ àtàwọn tó ń fetí sí i là. (1 Tím. 4:16) Torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wa, a fẹ́ kí wọ́n mọ òtítọ́. Nígbà tó yá, ìwà Pauline àti ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ipa rere lórí ìdílé rẹ̀. Ní báyìí, inú ẹ̀ dùn pé òun àti ọkọ òun ti jọ ń sin Jèhófà. Àwọn méjèèjì ti di aṣáájú-ọ̀nà, kódà Wayne ti di alàgbà.

10. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe sùúrù?

10 Máa ṣe sùúrù. Nígbà tá a di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó lè má rọrùn fáwọn mọ̀lẹ́bí wa láti fara mọ́ ohun tuntun tá a gbà gbọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí wọ́n máa ń kọ́kọ́ kíyè sí ni pé a ò bá wọn ṣọdún mọ́, a ò sì dá sọ́rọ̀ òṣèlú. Ìyẹn lè mú káwọn kan lára wọn máa bínú sí wa. (Mát. 10:35, 36) Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú wa. Tá a bá jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú wa, tá ò sì wàásù fún wọn mọ́, ṣe ló dà bíi pé a ti dá wọn lẹ́jọ́ pé wọn ò yẹ lẹ́ni tó ń jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Kì í ṣe àwa ni Jèhófà yàn láti dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, Jésù ló gbéṣẹ́ náà fún. (Jòh. 5:22) Tá a bá ṣe sùúrù, ó ṣeé ṣe káwọn mọ̀lẹ́bí wa pa dà fetí sí wa.—Wo àpótí náà “ Máa Fi Ìkànnì Wa Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́.”

11-13. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Alice?

11 Dúró lórí ìpinnu rẹ, àmọ́ fi ọgbọ́n ṣe é. (Òwe 15:2) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Alice. Kò sí lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé olóṣèlú làwọn òbí rẹ̀, wọn ò sì gba Ọlọ́run gbọ́. Ó rí i pé á dáa tóun bá tètè sọ àwọn nǹkan rere tóun ń kọ́ fún wọn. Ó sọ pé: “Tó o bá jẹ́ kó pẹ́ kó o tó sọ ohun tó o gbà gbọ́ fún wọn, ó lè bí wọn nínú gan-an.” Torí náà, ó máa ń kọ lẹ́tà sí wọn, ó máa ń sọ àwọn kókó tó mọ̀ pé wọ́n á nífẹ̀ẹ́ sí bí ìfẹ́. Lẹ́yìn náà, á ní kí wọ́n sọ èrò wọn nípa ẹ̀. (1 Kọ́r. 13:1-13) Ó máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún bí wọ́n ṣe tọ́ òun dàgbà àti bí wọ́n ṣe bójú tó òun, ó sì máa ń fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí wọn. Nígbà kan tó lọ kí àwọn òbí rẹ̀ nílé, ó pa àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe tì kó lè bá ìyá ẹ̀ ṣiṣẹ́ ilé. Níbẹ̀rẹ̀, àwọn òbí ẹ̀ ò fara mọ́ ẹ̀sìn tuntun tó ń ṣe láìka gbogbo àlàyé tó ṣe sí.

12 Nígbà tí Alice lọ kí àwọn òbí rẹ̀, ojoojúmọ́ ló máa ń ka Bíbélì bó ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ó sọ pé: “Ohun tí mò ń ṣe yìí jẹ́ kí màámi rí bí Bíbélì ti ṣe pàtàkì sí mi tó.” Lẹ́sẹ̀ kan náà, bàbá Alice fẹ́ ka Bíbélì kó lè mọ ohun tó fà á tí ọmọ ẹ̀ fi ṣàdédé yí pa dà, kó sì lè fi hàn án pé irọ́ ló kún inú Bíbélì. Alice sọ pé: “Mo fún wọn ní Bíbélì, mo sì fi lẹ́tà kékeré kan há inú Bíbélì náà.” Kí nìyẹn wá yọrí sí? Dípò kí bàbá rẹ̀ rí àbùkù nínú Bíbélì, ṣe lohun tó kà wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an.

13 Ó yẹ ká sòótọ́ fún àwọn mọ̀lẹ́bí wa, síbẹ̀ ká fi ọgbọ́n ṣe é bí wọ́n tiẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí wa. (1 Kọ́r. 4:12b) Bí àpẹẹrẹ, ìyá Alice ta kò ó gan-an nígbà tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, síbẹ̀ ó fara dà á. Alice sọ pé: “Nígbà tí mo ṣèrìbọmi, ìyá mi sọ pé ọmọ burúkú ni mí.” Kí ni Alice wá ṣe? Ó ní: “Dípò kí n panu mọ́, ṣe ni mo fi pẹ̀lẹ́tù ṣàlàyé fún wọn pé mo ti pinnu pé màá di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì sóhun tó lè yí ìpinnu yẹn pa dà. Mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti jẹ́ kí màámi mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Ṣe làwa méjèèjì bú sẹ́kún, lẹ́yìn ìyẹn mo lọ se oúnjẹ aládùn kan fún wọn. Àtìgbà yẹn ni màámi ti ń kíyè sí i pé ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mò ń kọ́ ti mú kí n túbọ̀ máa hùwà ọmọlúàbí.”

14. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí wa yí wa lérò pa dà?

14 Àwọn mọ̀lẹ́bí wa lè má tètè lóye pé ìjọsìn Jèhófà ṣe pàtàkì sí wa gan-an. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Alice pinnu pé òun máa di aṣáájú-ọ̀nà dípò kó lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga báwọn òbí ẹ̀ ṣe fẹ́, ṣe ni ìyá rẹ̀ tún bú sẹ́kún. Àmọ́, Alice ò yí èrò rẹ̀ pa dà. Ó sọ pé: “Tó o bá jẹ́ kí wọ́n yí èrò ẹ pa dà lórí ìpinnu kan tó o ṣe, ohun tí wọ́n á máa ṣe lọ nìyẹn. Àmọ́, tó o bá fi pẹ̀lẹ́tù bá wọn sọ̀rọ̀ síbẹ̀ tó o dúró lórí ìpinnu ẹ, àwọn kan lára wọn á gbọ́ tìẹ.” Ohun tí Alice ṣe gan-an nìyẹn. Ní báyìí, bàbá àti ìyá ẹ̀ ti di aṣáájú-ọ̀nà, kódà alàgbà ni bàbá ẹ̀.

ÌRÀNLỌ́WỌ́ WO LÀWỌN ARÁ INÚ ÌJỌ LÈ ṢE?

Báwo làwọn ará ìjọ ṣe lè ran mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́? (Wo ìpínrọ̀ 15 àti 16) *

15. Bó ṣe wà nínú Mátíù 5:14-16 àti 1 Pétérù 2:12, báwo ni “iṣẹ́ rere” àwọn míì ṣe lè ran àwọn mọ̀lẹ́bí wa lọ́wọ́?

15 Jèhófà máa ń lo “iṣẹ́ rere” àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti fa àwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Ka Mátíù 5:14-16; 1 Pétérù 2:12.) Tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ kì í bá ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣé ó mọ èyíkéyìí lára àwọn ará ìjọ rẹ? Pauline tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan pe àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan wá sílé ẹ̀ kí Wayne ọkọ ẹ̀ lè mọ̀ wọ́n. Wayne sọ ohun tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin náà ṣe tó mú kó túbọ̀ mọyì àwa Ẹlẹ́rìí, ó ní: “Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin náà gba ọjọ́ kan kúrò lẹ́nu iṣẹ́ kó lè wá wo bọ́ọ̀lù pẹ̀lú mi. Ìyẹn mú kí n ronú pé, ‘Èèyàn bíi tèmi làwọn náà!’ ”

16. Kí nìdí tó fi dáa ká rọ àwọn mọ̀lẹ́bí wa pé kí wọ́n wá sípàdé?

16 Ohun míì tó lè ran àwọn mọ̀lẹ́bí wa lọ́wọ́ ni pé ká pè wọ́n sípàdé wa. (1 Kọ́r. 14:24, 25) Ìrántí Ikú Kristi ni Wayne kọ́kọ́ wá torí pé ìrọ̀lẹ́ lẹ́yìn iṣẹ́ ló bọ́ sí, ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ò sì gùn. Ó sọ pé: “Mi ò fi bẹ́ẹ̀ lóye ohun tí wọ́n sọ nínú àsọyé náà, àmọ́ mi ò lè gbàgbé báwọn èèyàn náà ṣe kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Wọ́n wá bá mi, wọ́n bọ̀ mí lọ́wọ́, wọ́n sì kí mi dáadáa. Mo mọ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi dénú.” Tọkọtaya kan tiẹ̀ wà tó máa ń ṣèrànwọ́ fún Pauline àti ọmọ rẹ̀ nípàdé àti lóde ẹ̀rí. Nígbà tó yá, Wayne pinnu pé òun fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ẹ̀sìn tí ìyàwó òun ń ṣe, torí náà ó ní kí ọkọ arábìnrin yẹn wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́.

17. Ṣé ó yẹ ká dá ara wa lẹ́bi táwọn mọ̀lẹ́bí wa ò bá wá sínú òtítọ́, àmọ́ kí nìdí tí kò fi yẹ kí ọ̀rọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wa sú wa?

17 Ó wù wá pé káwọn mọ̀lẹ́bí wa mọ Jèhófà, kí wọ́n sì jọ́sìn rẹ̀. Síbẹ̀, láìka bá a ṣe sapá tó, àwọn kan lè má wá. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má dá ara ẹ lẹ́bi. Ó ṣe tán, a ò lè fipá mú ẹnikẹ́ni di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó ti wù kó rí, táwọn mọ̀lẹ́bí ẹ bá ń rí bó o ṣe ń láyọ̀, ó máa nípa rere lórí wọn. Torí náà, máa gbàdúrà fún wọn. Máa fi sùúrù bá wọn sọ̀rọ̀. Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ láé, má sì ronú pé wọn ò lè yí pa dà! (Ìṣe 20:20) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa bù kún gbogbo ìsapá ẹ. Táwọn mọ̀lẹ́bí ẹ bá sì fetí sí ẹ, wọ́n máa rí ìgbàlà!

ORIN 57 Máa Wàásù fún Onírúurú Èèyàn

^ ìpínrọ̀ 5 Inú wa máa dùn táwọn mọ̀lẹ́bí wa bá yàn láti sin Jèhófà, àmọ́ àwọn ló máa pinnu bóyá wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀ àbí wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àwọn ohun tá a lè ṣe táá mú kó wù wọ́n láti fetí sí wa.

^ ìpínrọ̀ 1 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, “mọ̀lẹ́bí” tọ́ka sí àwọn ẹbí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 53 ÀWÒRÁN: Ọ̀dọ́kùnrin kan ń bá bàbá rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tún mọ́tò ṣe. Nígbà tí ọwọ́ wọn dilẹ̀ díẹ̀, ó fi fídíò kan hàn án lórí jw.org®.

^ ìpínrọ̀ 55 ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan ń fetí sí ọkọ rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bó ṣe ń sọ bí nǹkan ṣe lọ fún un lọ́jọ́ náà. Nígbà tó yá, òun, ọkọ ẹ̀ àti ọmọ wọn jọ ń ṣeré.

^ ìpínrọ̀ 57 ÀWÒRÁN: Arábìnrin náà pe àwọn ará ìjọ rẹ̀ wá sílé wọn. Àwọn ará yẹn ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti túbọ̀ sún mọ́ ọkọ arábìnrin náà. Nígbà tó yá, ọkùnrin náà tẹ̀ lé ìyàwó ẹ̀ lọ sí Ìrántí Ikú Kristi.