Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 32

Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Yín Máa Pọ̀ Sí I

Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Yín Máa Pọ̀ Sí I

“Ohun tí mò ń gbà ládùúrà ni pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ pọ̀ gidigidi.”​—FÍLÍ. 1:9.

ORIN 106 Bá A Ṣe Lè Ní Ìfẹ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Àwọn wo ló mú kí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ nílùú Fílípì?

NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, Sílà, Lúùkù àti Tímótì dé sílùú Fílípì, wọ́n wàásù fún àwọn èèyàn, ọ̀pọ̀ sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn arákùnrin mẹ́rin tó nítara yìí ló mú kí wọ́n dá ìjọ kan sílẹ̀ nílùú yẹn. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilé arábìnrin ọ̀làwọ́ kan tó ń jẹ́ Lìdíà làwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni yẹn ti ń pàdé pọ̀.—Ìṣe 16:40.

2. Ìṣòro wo ló yọjú kété lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọ náà sílẹ̀?

2 Kò pẹ́ tí wọ́n dá ìjọ náà sílẹ̀ ni Èṣù gbé ìṣe rẹ̀ dé. Ó mú káwọn ọ̀tá òtítọ́ gbé àtakò dìde, wọn ò sì fẹ́ kí Pọ́ọ̀lù àtàwọn yòókù rẹ̀ wàásù nílùú yẹn mọ́. Èyí tá à ń wí yìí pẹ́, wọ́n ti fàṣẹ ọba mú Pọ́ọ̀lù àti Sílà, wọ́n fi ọ̀pá lù wọ́n, wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni, wọ́n sì fún wọn níṣìírí. Ẹ̀yìn náà ni Pọ́ọ̀lù, Sílà àti Tímótì fi ìlú náà sílẹ̀, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí Lúùkù ní tiẹ̀ dúró síbẹ̀. Báwo ni nǹkan ṣe rí fáwọn ará tó wà níjọ tuntun yẹn? Ẹ̀mí Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run láìfi àtakò pè. (Fílí. 2:12) Ẹ wá rídìí tí inú Pọ́ọ̀lù fi dùn sí wọn gan-an!

3. Bó ṣe wà nínú Fílípì 1:9-11, kí ni Pọ́ọ̀lù gbà ládùúrà?

3 Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Fílípì. Tẹ́ ẹ bá ka lẹ́tà yẹn, ẹ̀ẹ́ kíyè sí i pé Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn ará náà gan-an. Ó sọ pé, “Àárò gbogbo yín ń sọ mí nítorí ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, irú èyí tí Kristi Jésù ní.” (Fílí. 1:8) Ó sọ fún wọn pé òun máa ń fi wọ́n sádùúrà. Ó gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ìfẹ́ wọn lè máa pọ̀ sí i, kí wọ́n máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù, kí wọ́n jẹ́ aláìní àbààwọ́n, kí wọ́n má ṣe mú àwọn míì kọsẹ̀, kí wọ́n sì máa so èso òdodo. Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yẹn máa ṣe wá láǹfààní gan-an. Torí náà, a máa ka ohun tó kọ sáwọn ará Fílípì. (Ka Fílípì 1:9-11.) Lẹ́yìn náà, àá jíròrò àwọn kókó tó mẹ́nu kàn nínú ẹsẹ yẹn àti bá a ṣe lè fi wọ́n sílò.

KÍ ÌFẸ́ YÍN MÁA PỌ̀ SÍ I

4. (a) Bó ṣe wà nínú 1 Jòhánù 4:9, 10, báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà jinlẹ̀ tó?

4 Jèhófà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an nígbà tó rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Ka 1 Jòhánù 4:9, 10.) Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa yìí ló mú káwa náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Róòmù 5:8) Àmọ́ báwo ló ṣe yẹ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà jinlẹ̀ tó? Jésù dáhùn ìbéèrè yìí nígbà tó sọ fún Farisí kan pé: “Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Mát. 22:36, 37) Èyí fi hàn pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ìfẹ́ orí ahọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kó dà bí igi tó ń gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lójoojúmọ́. Ó ṣe tán, Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Fílípì níyànjú pé kí ìfẹ́ wọn “túbọ̀ pọ̀ gidigidi.” Àwọn nǹkan wo lá mú ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

5. Kí lá mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà pọ̀ sí i?

5 Ká tó lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó ṣe pàtàkì ká mọ̀ ọ́n dáadáa. Bíbélì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, torí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á túbọ̀ jinlẹ̀ tá a bá ní “ìmọ̀ tó péye àti òye tó kún rẹ́rẹ́” nípa Jèhófà. (Fílí. 1:9) Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tá a mọ̀ nípa rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan. Àmọ́, bá a ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní fún un túbọ̀ ń jinlẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ẹ̀ lójoojúmọ́.—Fílí. 2:16.

6. Bó ṣe wà nínú 1 Jòhánù 4:11, 20, 21, kí lá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́?

6 Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló ń mú ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa. (Ka 1 Jòhánù 4:11, 20, 21.) A lè ronú pé ó rọrùn gan-an láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, àbí ta lèèyàn ì bá tún nífẹ̀ẹ́ bí kò ṣe àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà? Ó ṣe tán, gbogbo wa là ń sapá ká lè fìwà jọ Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá, a sì mọyì bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Àmọ́ ká sòótọ́, àwọn ìgbà kan lè wà tó máa ń ṣòro láti fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pa láṣẹ. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ tó wà ní Fílípì.

7. Kí la rí kọ́ nínú ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba Yúódíà àti Síńtíkè?

7 Yúódíà àti Síńtíkè nítara gan-an, wọ́n sì ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Síbẹ̀, èdèkòyédè wáyé láàárín àwọn obìnrin méjèèjì yìí. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ yẹn, ó dìídì dárúkọ Yúódíà àti Síńtíkè, ó sì gbà wọ́n níyànjú láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé “kí wọ́n ní èrò kan náà.” (Fílí. 4:2, 3) Pọ́ọ̀lù tún sọ fáwọn ará ìjọ yẹn lápapọ̀ pé: “Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti ìjiyàn.” (Fílí. 2:14) Kò sí àní-àní pé ìmọ̀ràn tó sojú abẹ níkòó tí Pọ́ọ̀lù fún wọn yìí mú kí àwọn arábìnrin yẹn àtàwọn ará inú ìjọ lápapọ̀ túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn.

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fojú tó tọ́ wo àwọn ará wa? (Wo ìpínrọ̀ 8) *

8. Kí lohun kan tó lè mú kó ṣòro fún wa láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, kí la sì lè ṣe nípa ẹ̀?

8 Bíi ti Yúódíà àti Síńtíkè, ohun kan wà tó lè mú kó ṣòro fáwa náà láti fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa, ìyẹn tó bá jẹ́ pé ibi tí wọ́n kù sí nìkan la gbájú mọ́. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe lójoojúmọ́. Tó bá jẹ́ pé àṣìṣe àwọn míì là ń wò ṣáá, a ò ní lè nífẹ̀ẹ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, tí arákùnrin kan ò bá dara pọ̀ mọ́ wa nígbà tá à ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe, inú lè bí wa. Tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn àṣìṣe tí arákùnrin náà ti ṣe sẹ́yìn, ṣe ni inú ẹ̀ á túbọ̀ máa bí wa, a ò sì ní fẹ́ bá a da nǹkan pọ̀ mọ́. Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, á dáa kó o ronú lórí kókó yìí: Jèhófà mọ ibi tí àwa àti arákùnrin náà kù sí. Síbẹ̀, bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa náà ló ṣe nífẹ̀ẹ́ arákùnrin yẹn. Nítorí náà, ó yẹ ká fara wé Jèhófà, ká sì rí i pé ibi táwọn ará wa dáa sí là ń gbájú mọ́. Tá a bá ń sapá láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, okùn ìfẹ́ wa á túbọ̀ lágbára, àárín wa á sì túbọ̀ gún.—Fílí. 2:1, 2.

“ÀWỌN OHUN TÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ”

9. Kí ni díẹ̀ lára “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn nínú lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ará Fílípì?

9 Ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará ìjọ Fílípì àti gbogbo wa lápapọ̀ pé ká “máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.” (Fílí. 1:10) Lára ohun tó ṣe pàtàkì jù náà ni bí Jèhófà ṣe máa ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́, bí ohun tó ní lọ́kàn ṣe máa ṣẹ àti bí ìjọ ṣe máa wà níṣọ̀kan tí àlàáfíà sì máa jọba. (Mát. 6:9, 10; Jòh. 13:35) Tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù yìí ló gbà wá lọ́kàn, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

10. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Jèhófà lè kà wá sí aláìní àbààwọ́n?

10 Pọ́ọ̀lù tún sọ pé ká “jẹ́ aláìní àbààwọ́n.” Èyí ò túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni pípé. Kò sí bí àwa èèyàn ṣe lè jẹ́ aláìní àbààwọ́n bíi ti Jèhófà. Àmọ́ Jèhófà máa kà wá sí aláìní àbààwọ́n tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú kí ìfẹ́ tá a ní túbọ̀ jinlẹ̀, tá a sì ń ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn ni pé ká rí i dájú pé a ò mú àwọn míì kọsẹ̀.

11. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká mú àwọn míì kọsẹ̀?

11 Ìkìlọ̀ tó lágbára lohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé ká má ṣe mú àwọn míì kọsẹ̀. Báwo la ṣe lè mú àwọn míì kọsẹ̀? A lè fa ìkọ̀sẹ̀ fáwọn míì nípasẹ̀ eré ìnàjú tá a yàn láàyò, ìmúra wa àti iṣẹ́ tá à ń ṣe. Àwọn nǹkan tá à ń ṣe lè má burú láyè ara wọn. Àmọ́, tó bá ń da ẹ̀rí ọkàn àwọn míì láàmú débi tí wọ́n fi kọsẹ̀, a jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà kọjá bẹ́ẹ̀. Jésù sọ pé á sàn kí wọ́n so òkúta ńlá mọ́ ẹnì kan lọ́rùn kí wọ́n sì jù ú sínú agbami òkun dípò táá fi mú ọ̀kan lára àwọn àgùntàn òun kọsẹ̀!—Mát. 18:6.

12. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà kan ṣe?

12 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà kan ṣe tó fi hàn pé wọn ò fẹ́ mú ẹnikẹ́ni kọsẹ̀. Inú ìjọ kan náà ni wọ́n wà pẹ̀lú tọkọtaya kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi tí wọ́n sì tọ́ dàgbà nínú ìdílé tí wọn ò ti gba gbẹ̀rẹ́. Tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi yìí gbà pé kò yẹ kí Kristẹni máa lọ wo eré nílé sinimá, kódà bí eré ọ̀hún kò bá tiẹ̀ burú. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà yẹn lọ wo fíìmù nílé sinimá, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an. Torí náà, tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà yẹn pinnu pé àwọn ò ní lọ sílé sinimá mọ́ títí táwọn tọkọtaya kejì á fi túbọ̀ kọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn tí wọ́n á sì máa fojú tó tọ́ wo nǹkan. (Héb. 5:14) Bí tọkọtaya yẹn ṣe gba tàwọn míì rò fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn lọ́rọ̀ àti níṣe.—Róòmù 14:19-21; 1 Jòh. 3:18.

13. Báwo la ṣe lè mú kẹ́nì kan dẹ́ṣẹ̀?

13 Ọ̀nà míì tá a lè gbà mú káwọn míì kọsẹ̀ ni pé ká sún wọn dẹ́ṣẹ̀. Báwo nìyẹn ṣe lè wáyé? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí. Ó pẹ́ tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ti ń sapá kó lè jáwọ́ nínú ọtí àmujù, nígbà tó yá ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ó pinnu pé òun ò ní fẹnu kan ọtí mọ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ló ṣèrìbọmi. Lọ́jọ́ kan, arákùnrin kan kó àwọn ará lẹ́nu jọ, ó sì pe ẹni tuntun náà síbẹ̀. Arákùnrin yẹn wá ń rọ ẹni tuntun náà pé kó mutí, ó ní: “Kí ló dé, ṣebí Kristẹni ni ẹ́, ẹ̀mí Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ẹ, torí náà kò ní ṣòro fún ẹ láti kó ara ẹ níjàánu. Kó o kàn mu díẹ̀ ni, ló bá tán, wàá gbádùn ara ẹ, kò jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Ẹ wo ohun tíyẹn lè fà fún arákùnrin tuntun náà tó bá fetí sí ìmọ̀ràn burúkú yẹn!

14. Báwo làwọn ìpàdé wa ṣe ń jẹ́ ká fi ìtọ́ni inú Fílípì 1:10 sílò?

14 Àwọn ìpàdé wa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fi ìtọ́ni inú Fílípì 1:10 sílò lónírúurú ọ̀nà. Àkọ́kọ́, àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ tá à ń rí gbà ń rán wa létí àwọn nǹkan tí Jèhófà kà sí pàtàkì jù. Ìkejì, à ń rí bá a ṣe lè máa fi ohun tá à ń kọ́ sílò ká bàa lè jẹ́ aláìní àbààwọ́n. Ìkẹta, ìpàdé wa ń jẹ́ ká lè “fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere.” (Héb. 10:24, 25) Báwọn ará ṣe túbọ̀ ń fún wa níṣìírí, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àtàwọn ará wa á máa pọ̀ sí i. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará wa látọkàn wá, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa mú ẹnikẹ́ni kọsẹ̀.

Ẹ MÁA KÚN FÚN “ÈSO ÒDODO”

15. Kí ló túmọ̀ sí pé ká kún fún “èso òdodo”?

15 Pọ́ọ̀lù rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé káwọn ará tó wà ní Fílípì kún fún “èso òdodo.” (Fílí. 1:11) Ó dájú pé ọ̀kan lára “èso òdodo” ni báwọn ará yẹn ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. Ohun míì tún ni pé kí wọ́n máa wàásù fáwọn míì nípa Jésù àti ìrètí ológo tí wọ́n ní. Pọ́ọ̀lù tún lo àkàwé míì nínú Fílípì 2:15, ó ní wọ́n ń “tàn bí ìmọ́lẹ̀ nínú ayé.” Ìyẹn sì bọ́gbọ́n mu torí Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní “ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Mát. 5:14-16) Ó tún pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn “di ọmọ ẹ̀yìn,” ó sì sọ pé wọ́n á ‘jẹ́ ẹlẹ́rìí òun títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.’ (Mát. 28:18-20; Ìṣe 1:8) Torí náà, à ń so “èso òdodo” tá a bá ń lo ara wa tokuntokun lẹ́nu iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù yìí.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní àtìmọ́lé ní Róòmù, ó kọ lẹ́tà sí ìjọ tó wà nílùú Fílípì. Pọ́ọ̀lù tún máa ń lo àǹfààní tó bá yọjú láti wàásù fáwọn ẹ̀ṣọ́ àtàwọn tó bá wá kí i (Wo ìpínrọ̀ 16)

16. Báwo lohun tó wà nínú Fílípì 1:12-14 ṣe mú kó dá wa lójú pé a lè tàn bí ìmọ́lẹ̀ lábẹ́ ipò yòówù ká wà? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

16 Ipò yòówù ká wà, a ṣì lè tàn bí ìmọ́lẹ̀. Láwọn ipò kan, ohun tó dà bí ìdíwọ́ tẹ́lẹ̀ lè wá ṣí àǹfààní sílẹ̀ láti wàásù. Àpẹẹrẹ kan ni ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Àtìmọ́lé ló wà nílùú Róòmù nígbà tó kọ̀wé sáwọn ará Fílípì. Síbẹ̀, ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè é kò ní kó má wàásù fáwọn ẹ̀ṣọ́ tó ń ṣọ́ ọ àtàwọn tó wá kí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù wà ní àtìmọ́lé, ó fìtara wàásù, ìyẹn sì mú káwọn ará túbọ̀ nígboyà láti máa sọ “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù.”—Ka Fílípì 1:12-14; 4:22.

Máa wá gbogbo ọ̀nà láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run (Wo ìpínrọ̀ 17) *

17. Sọ àpẹẹrẹ òde òní kan tó fi hàn pé a lè so èso òdodo kódà bí nǹkan bá nira.

17 Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń lo ìgboyà bíi ti Pọ́ọ̀lù. Wọ́n ń gbé lórílẹ̀-èdè tí wọn ò ti gbà wá láyè láti wàásù ní fàlàlà tàbí láti ilé dé ilé. Torí náà, ṣe ni wọ́n máa ń wọ́nà míì láti wàásù. (Mát. 10:16-20) Lórílẹ̀-èdè kan, alábòójútó àyíká sọ fáwọn akéde pé kí wọ́n máa wàásù láwọn ibi tá a lè pè ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn, ìyẹn fáwọn ẹbí wọn, àwọn aládùúgbò, ọmọ ilé ìwé, ará ibiṣẹ́ àtàwọn ojúlùmọ̀ míì. Ní nǹkan bí ọdún méjì péré, ìjọ tó wà ní àyíká yẹn pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kí làwa tá à ń gbé nílẹ̀ tí wọn ò ti fòfin de iṣẹ́ wa lè ṣe? A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n ń wàásù lábẹ́ ipò tó nira. Ẹ̀kọ́ náà ni pé ká máa wá gbogbo ọ̀nà tá a lè fi bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó sì dá wa lójú pé Jèhófà á fún wa lágbára láti borí ìdènà èyíkéyìí.—Fílí. 2:13.

18. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

18 Láwọn àkókò òpin yìí, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Fílípì sílò. Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù là ń ṣe, ká wà láìní àbààwọ́n, ká má ṣe máa mú àwọn míì kọsẹ̀, ká sì máa so èso òdodo. Nípa bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àtàwọn ará wa á túbọ̀ pọ̀ sí i, àá sì mú ìyìn àti ògo bá Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́.

ORIN 17 “Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”

^ ìpínrọ̀ 5 Àsìkò tá a wà yìí gan-an ló yẹ ká túbọ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa. Lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Fílípì máa jẹ́ ká rí bá a ṣe lè túbọ̀ fìfẹ́ hàn sáwọn ará, kódà nígbà tó bá ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 54 ÀWÒRÁN: Lásìkò tí ìjọ ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Joe dáwọ́ iṣẹ́ tó ń ṣe dúró, ó sì ń bá arákùnrin kan àti ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ohun tó ṣe yẹn bí Arákùnrin Mike tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ nínú. Mike ronú pé, ‘Kì í ṣe ẹjọ́ ló yẹ kí Joe máa tò báyìí, iṣẹ́ ló yẹ kó máa ṣe.’ Ẹ̀yìn ìyẹn ni Mike rí Joe tó ń ran arábìnrin àgbàlagbà kan lọ́wọ́. Ohun tí Mike rí yìí mú kó rí i pé àwọn ànímọ́ rere tí Joe ní ló yẹ kóun gbájú mọ́.

^ ìpínrọ̀ 58 ÀWÒRÁN: Lórílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, arákùnrin kan dọ́gbọ́n wàásù fún ẹnì kan tó mọ̀. Nígbà tó tún dé ibiṣẹ́, ó wàásù fún ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ lásìkò ìsinmi.