Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jòhánù Arinibọmi—Àpẹẹrẹ Ẹnì Kan Tó Láyọ̀ Láìka Ìyípadà Tó Dé Bá A

Jòhánù Arinibọmi—Àpẹẹrẹ Ẹnì Kan Tó Láyọ̀ Láìka Ìyípadà Tó Dé Bá A

ṢÉ Ó wù ẹ́ pé kó o ní ojúṣe pàtàkì nínú ìjọ àmọ́ tí ọwọ́ rẹ ò tíì tẹ̀ ẹ́? Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé àwọn míì ló ń ṣe iṣẹ́ yẹn. Ó sì lè jẹ́ pé iṣẹ́ kan tó o ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ ni o ò lè bójú tó mọ́. Bóyá ọjọ́ orí ẹ, àìsàn, ìṣòro ìṣúnná owó tàbí ìṣòro àtigbọ́ bùkátà ni kò jẹ́ kó o lè ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn Jèhófà. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn ìyípadà tó ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run ló mú kó o gbé iṣẹ́ tó ò ń ṣe sílẹ̀. Èyí ó wù kó jẹ́, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò ṣe tó bó ṣe yẹ kó o ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Irú àwọn nǹkan yìí lè mú kéèyàn rẹ̀wẹ̀sì, ó ṣe tán èèyàn ni wá. Síbẹ̀, kí lo lè ṣe tí ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ ò fi ní bò ẹ́ mọ́lẹ̀ débi tí wàá fi ní èrò òdì? Kí lá mú kó o máa láyọ̀ láìka ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí?

Tó bá di pé kéèyàn láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, àpẹẹrẹ àtàtà ni Jòhánù Arinibọmi. Jòhánù gbádùn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, síbẹ̀ kò retí pé bìrí ni nǹkan máa yí pa dà fún òun. Kò ronú pé iye àkókò tóun máa lò lẹ́wọ̀n á ju èyí tóun fi wàásù lọ. Síbẹ̀, Jòhánù ṣì ń láyọ̀, bó sì ṣe rí nìyẹn jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Kí ló mú kó máa láyọ̀? Báwo làwa náà ṣe lè máa láyọ̀ tí nǹkan bá tiẹ̀ yí pa dà bìrí fún wa?

IṢẸ́ ÌSÌN TÓ Ń FÚNNI LÁYỌ̀

Jòhánù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní nǹkan bí April 29 Sànmánì Kristẹni gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọ́run rán wá láti múra àwọn èèyàn de Mèsáyà. Ó ń wàásù pé: “Ẹ ronú pìwà dà, torí Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” (Mát. 3:2; Lúùkù 1:12-17) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kódà, àwọn kan wá láti ọ̀nà jíjìn, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn débi pé wọ́n yí pa dà, wọ́n sì ṣèrìbọmi. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún kìlọ̀ fáwọn Farisí àtàwọn Sadusí pé ìdájọ́ Ọlọ́run ń bọ̀ lórí wọn tí wọn ò bá yí pa dà. (Mát. 3:5-12) Iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù tí Jòhánù ṣe ni ìrìbọmi tó ṣe fún Jésù ní nǹkan bí October 29 Sànmánì Kristẹni. Àtìgbà yẹn ni Jòhánù ti ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n tẹ̀ lé Jésù tó jẹ́ Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí.—Jòh. 1:32-37.

Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tí Jòhánù ní yìí ló mú kí Jésù sọ nípa rẹ̀ pé: “Nínú àwọn tí obìnrin bí, kò tíì sí ẹni tó tóbi ju Jòhánù Arinibọmi lọ.” (Mát. 11:11) Ó dájú pé inú Jòhánù dùn gan-an fún àǹfààní ńlá tó ní. Bíi ti Jòhánù, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ti gbádùn onírúurú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Terry. Ohun tó lé ní àádọ́ta [50] ọdún lòun àti ìyàwó rẹ̀ Sandra ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Terry sọ pé: “Onírúurú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ni mo ti gbádùn. Mo ti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, mo sìn ní Bẹ́tẹ́lì, mo di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, alábòójútó àyíká, alábòójútó agbègbè, lẹ́yìn náà ni mo tún di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.” Ká sòótọ́, inú èèyàn máa ń dùn téèyàn bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, àmọ́ bíi ti Jòhánù, ó máa ń gba ìsapá kéèyàn tó lè máa láyọ̀ tí nǹkan bá yí pa dà.

MỌYÌ IṢẸ́ ÌSÌN RẸ BÍ NǸKAN TIẸ̀ YÍ PA DÀ

Ohun kan tó jẹ́ kí Jòhánù Arinibọmi máa láyọ̀ ni pé ó mọyì iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láìka pé nǹkan yí pa dà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, àwọn ọmọlẹ́yìn Jòhánù bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù, àmọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń pọ̀ sí i. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú káwọn ọmọlẹ́yìn Jòhánù máa jowú, wọ́n wá sọ pé: “Wò ó, ẹni yìí ń ṣèrìbọmi fún àwọn èèyàn, gbogbo èèyàn sì ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.” (Jòh. 3:26) Jòhánù dá wọn lóhùn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó. Àmọ́ tí ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó bá dúró, tó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, inú rẹ̀ máa dùn gan-an torí ohùn ọkọ ìyàwó. Torí náà, ayọ̀ mi ti kún rẹ́rẹ́.” (Jòh. 3:29) Jòhánù ò bá Jésù díje, kò sì ronú pé iṣẹ́ òun ò wúlò mọ́ ní báyìí tí Jésù ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Dípò bẹ́ẹ̀, Jòhánù ń láyọ̀ torí ó mọyì bó ṣe jẹ́ “ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó.”

Ojú tí Jòhánù fi ń wo nǹkan mú kí inú rẹ̀ máa dùn bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló fi du ara rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Násírì ni Jòhánù látìgbà tí wọ́n ti bí i, ara ẹ̀jẹ́ Násírì sì ni pé kò gbọ́dọ̀ fi ẹnu kan ọtí. (Lúùkù 1:15) Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa irú ìgbésí ayé tí Jòhánù gbé, ó sọ pé: “Jòhánù wá, kò jẹ, kò sì mu.” Lọ́wọ́ kejì, Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ò sí lábẹ́ irú ẹ̀jẹ́ bẹ́ẹ̀, torí náà wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu. (Mát. 11:18, 19) Yàtọ̀ síyẹn, Jòhánù ò ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan, àmọ́ Jèhófà fún Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ títí kan àwọn tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jòhánù tẹ́lẹ̀ lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu. (Mát. 10:1; Jòh. 10:41) Dípò kí Jòhánù máa jowú àǹfààní tí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní, ṣe ló gbájú mọ́ iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un.

Táwa náà bá mọyì iṣẹ́ tá à ń ṣe báyìí nínú ètò Ọlọ́run, a máa láyọ̀. Terry tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mo máa ń pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí tí mo bá ń ṣe.” Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọdún tó lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ó sọ pé: “Mo mọyì àwọn ìrírí tí mo ní láwọn àsìkò yẹn, mi ò kábàámọ̀ rárá.”

Iṣẹ́ èyíkéyìí ká máa ṣe, a lè láyọ̀ tá a bá ń ronú nípa ohun tó mú kí iṣẹ́ ìsìn náà ṣe pàtàkì. Ohun náà sì ni pé a jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 3:9) Bó ṣe jẹ́ pé tá a bá ń tọ́jú ohun ọ̀ṣọ́ kan tá a ti ní tipẹ́tipẹ́, tá a sì ń tún un ṣe bó ṣe yẹ, ó máa tọ́jọ́. Lọ́nà kan náà, a máa láyọ̀ tá a bá ń ronú nípa àǹfààní tá a ní láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ìyẹn ò ní jẹ́ ká máa fi ohun tá à ń ṣe wé tàwọn míì. Yàtọ̀ síyẹn, a ò ní máa ronú pé àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí Jèhófà fún wa ò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ tàwọn míì.—Gál. 6:4.

JẸ́ KÍ ÌJỌSÌN JÈHÓFÀ MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀

Ó ṣeé ṣe kí Jòhánù ti mọ̀ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun ò ní fi bẹ́ẹ̀ gbòòrò, àmọ́ kò mọ̀ pé ó máa tètè parí. (Jòh. 3:30) Ní oṣù mẹ́fà péré lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi fún Jésù, ìyẹn lọ́dún 30 Sànmánì Kristẹni, Ọba Hẹ́rọ́dù jù ú sẹ́wọ̀n. Síbẹ̀, Jòhánù ṣì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti wàásù. (Máàkù 6:17-20) Kí ló mú kí Jòhánù máa láyọ̀ bó tiẹ̀ wà lẹ́wọ̀n? Ó gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn tí Jèhófà gbé fún un.

Nígbà tí Jòhánù wà lẹ́wọ̀n, ó gbọ́ ìròyìn nípa bí iṣẹ́ ìsìn Jésù ṣe ń gbòòrò sí i. (Mát. 11:2; Lúùkù 7:18) Jòhánù mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà, àmọ́ ó lè máa ṣe kàyéfì pé ṣé Jésù máa mú gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Mèsáyà ṣẹ. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé Mèsáyà máa di ọba, ó lè máa ronú pé ìgbà wo ni Jésù máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso? Ṣé Jésù á dá òun sílẹ̀ lẹ́wọ̀n tó bá di ọba? Kí Jòhánù lè túbọ̀ lóye ohun tí Jésù máa ṣe, ó rán méjì lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sí Jésù pé kí wọ́n lọ bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tó Ń Bọ̀, àbí ká máa retí ẹlòmíì?” (Lúùkù 7:19) Nígbà tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Jòhánù, ó dájú pé ó máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn bí wọ́n ṣe ń ròyìn ohun tí Jésù ṣe àtohun tó sọ. Jésù sọ fún wọn pé: “Àwọn afọ́jú ti ń ríran báyìí, àwọn arọ ń rìn, à ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń sọ ìhìn rere fún àwọn aláìní.”—Lúùkù 7:20-22.

Ó dájú pé ìròyìn yẹn máa múnú Jòhánù dùn. Ó jẹ́ kó ṣe kedere sí i pé Jésù ni Mèsáyà náà, ó sì ń mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣẹ. Jòhánù mọ̀ pé iṣẹ́ ìsìn òun ò já sásán, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò ní dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Bí nǹkan ò tiẹ̀ lọ bó ṣe rò, Jòhánù ṣì láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.

Àá máa láyọ̀ tá a bá ń ronú nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń gbòòrò sí i kárí ayé

Bíi ti Jòhánù, tá a bá gbájú mọ́ ìjọsìn Jèhófà, àá lè fara da ìyípadà yòówù kó wáyé láìbọ́hùn, àá sì máa láyọ̀. (Kól. 1:9-11) Kíyẹn lè ṣeé ṣe, ó ṣe pàtàkì ká máa ka Bíbélì, ká sì máa ṣàṣàrò lé e lórí, ká tún fi sọ́kàn pé kò sóhun tá a ṣe fún Jèhófà tó máa já sásán. (1 Kọ́r. 15:58) Sandra tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lókè sọ pé: “Bí mo ṣe máa ń ka orí Bíbélì kan lójoojúmọ́ mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ó ń jẹ́ kí n máa ronú nípa Jèhófà dípò ara mi.” Ohun míì tó lè ṣèrànwọ́ ni pé ká máa ronú nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń gbòòrò sí i, torí pé á jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tí Jèhófà ń gbéṣe nínú ètò rẹ̀ dípò àwọn ìṣòro tiwa. Sandra tún sọ pé: “Ètò oṣooṣù tá a máa ń wò lórí Tẹlifíṣọ̀n JW máa ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ ètò Jèhófà, ó sì ń jẹ́ ká máa fayọ̀ bá iṣẹ́ ìsìn wa lọ.”

Ní ìwọ̀nba àkókò tí Jòhánù Arinibọmi fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, Bíbélì sọ pé ó ní “ẹ̀mí àti agbára Èlíjà.” Bó ti wù kó rí, bíi ti Èlíjà “ẹni tó máa ń mọ nǹkan lára bíi tiwa ni” òun náà. (Lúùkù 1:17; Jém. 5:17) Tá a bá mọyì iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí tá a ní, tá a sì gbájú mọ́ ìjọsìn Jèhófà bíi ti Jòhánù, àá máa láyọ̀, ayọ̀ náà ò sì ní pẹ̀dín tí ìyípadà èyíkéyìí bá tiẹ̀ dé.