ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ December 2019

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti February 3–March 1, 2020 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Ó Yẹ Ká Ní Àkókò fún Iṣẹ́ àti Ìsinmi

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa lo àpẹẹrẹ Sábáàtì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń pa mọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti ṣàlàyé bá a ṣe lè máa fojú tó tọ́ wo iṣẹ́ àti ìsinmi.

Jèhófà Ló Ń Fúnni Ní Òmìnira

Júbílì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe láyé àtijọ́ jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun kan tí Jèhófà ṣe fún wa ká lè ní òmìnira.

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Lábẹ́ Òfin Mósè, tí ọkùnrin kan bá fipá bá ọ̀dọ́bìnrin tó ti ní àfẹ́sọ́nà lòpọ̀ ní “inú oko” tí obìnrin náà sì pariwo tàbí lọgun, òfin sọ pé ọkùnrin náà jẹ̀bi ẹ̀sùn àgbèrè, obìnrin náà ò jẹ̀bi rárá. Kí nìdí?

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Nígbà tí Sátánì sọ fún Éfà pé kò ní kú tó bá jẹ nínú igi ìmọ̀ rere àti búburú, ṣé ohun tó ń sọ fún un ni pé ọkàn rẹ̀ ò ní kú gẹ́gẹ́ bí èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní lónìí?

Ṣé Ó Dá Ẹ Lójú Pé O Mọ Jèhófà?

Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan mọ Jèhófà? Kí la lè rí kọ́ nínú bí Mósè àti Ọba Dáfídì ṣe mọ Jèhófà dunjú tí wọ́n sì tún jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀?

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà

Báwo làwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì pinnu pé Jèhófà làwọn máa sìn?

“Ẹ Máa Dúpẹ́ Ohun Gbogbo”

Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tá a fi sọ pé tá a bá ń dúpẹ́ oore, ó máa ṣe àwa fúnra wa láǹfààní.

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè rántí.

Atọ́ka Àwọn Àkòrí Ilé Ìṣọ́ àti Jí! 2019

Atọ́ka gbogbo àpilẹ̀kọ́ tá a gbé jáde lọ́dún 2019 nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tá a tò ní àkòrí àkòrí.