“Ẹ Máa Dúpẹ́ Ohun Gbogbo”
Ó YẸ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé, ṣé mo máa ń dúpẹ́ oore? Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa jẹ́ “aláìmoore” ní àkókò òpin yìí. (2 Tím. 3:2) Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn kan tó máa ń ronú pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti ní gbogbo ohun táwọn bá fẹ́, àwọn èèyàn sì gbọ́dọ̀ máa fún àwọn ní nǹkan. Wọ́n máa ń ronú pé àwọn ò jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ọpẹ́ fún ohunkóhun táwọn rí gbà. Ó dájú pé ìwọ náà máa gbà pé kì í rọrùn láti da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó nírú èrò bẹ́ẹ̀.
Lọ́wọ́ kejì, Jèhófà gba àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ níyànjú pé ká “máa dúpẹ́.” Àní sẹ́, ó yẹ ká “máa dúpẹ́ ohun gbogbo.” (Kól. 3:15; 1 Tẹs. 5:18) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé tá a bá ń dúpẹ́ oore, ó máa ṣe àwa fúnra wa láǹfààní. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀.
INÚ WA MÁA DÙN TÁ A BÁ Ń DÚPẸ́
Ìdí tó lágbára jù tá a fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé tá a bá ń dúpẹ́, kò ní jẹ́ ká ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ, a sì máa láyọ̀. Téèyàn bá dúpẹ́ oore, inú ẹ̀ máa dùn, inú ẹni tó dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ náà sì máa dùn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Tó o bá rí i pé àwọn èèyàn ṣe tán láti ṣe ohunkóhun fún ẹ láìka ohun tó máa ná wọn sí, ṣé inú ẹ ò ní dùn pé wọ́n mọyì ẹ? Tíwọ náà bá rí bí wọ́n ṣe ń fìfẹ́ hàn sí ẹ, inú ẹ máa dùn. Bó ṣe rí lára Rúùtù náà nìyẹn nígbà tí Bóásì hùwà ọ̀làwọ́ sí i. Ó sì dájú pé inú Rúùtù dùn gan-an nígbà tó rí i pé Bóásì nífẹ̀ẹ́ òun, ọ̀rọ̀ òun sì jẹ ẹ́ lógún.—Rúùtù 2:10-13.
Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Kò sí àní-àní pé o máa ń ronú nípa àwọn ìbùkún tẹ̀mí tí Jèhófà ti pèsè àtèyí tó ń pèsè báyìí títí kan àwọn nǹkan tara. (Diu. 8:17, 18; Ìṣe 14:17) Dípò kó o kàn ronú lóréfèé nípa oore tí Ọlọ́run ń ṣe fún ẹ, o ò ṣe fara balẹ̀ ronú nípa ọ̀pọ̀ ìbùkún tíwọ àtàwọn tó o fẹ́ràn ti rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. Tó o bá ń fẹ̀sọ̀ ronú nípa gbogbo ohun rere tí Ẹlẹ́dàá ń ṣe fún ẹ, ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì mọyì ẹ.—1 Jòh. 4:9.
Kì í ṣe kó o kàn máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ ọ̀làwọ́ àti bó ṣe ń bù kún ẹ nìkan, ó tún yẹ kó o máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ torí gbogbo oore tó ń ṣe fún ẹ. (Sm. 100:4, 5) Àwọn kan máa ń sọ pé “téèyàn bá ń dúpẹ́ oore, ṣe ni inú ẹ̀ á máa dùn sí i.”
Ẹ̀MÍ ÌMOORE MÁA Ń JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN TÚBỌ̀ SÚN MỌ́RA
Ìdí míì tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ ni pé ó máa ń jẹ́ kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú àwọn míì túbọ̀ lágbára. Gbogbo wa la fẹ́ káwọn èèyàn mọyì wa. Tó o bá dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹnì kan látọkàn wá torí oore tó ṣe fún ẹ, ẹ̀yin méjèèjì máa túbọ̀ sún mọ́ra. (Róòmù 16:3, 4) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó moore sábà máa ń ran àwọn míì lọ́wọ́. Wọ́n máa ń mọyì ẹ̀ táwọn èèyàn bá fi inú rere hàn sí wọn, àwọn náà sì máa ń fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn míì. Ó ṣe kedere nígbà náà pé èèyàn á túbọ̀ láyọ̀ tó bá ń dúpẹ́ oore. Bí Jésù ṣe sọ ọ́ gan-an ló rí, ó ní: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
Wọ́n ṣèwádìí kan nípa ẹ̀mí ìmoore ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of California. Ọ̀kan lára àwọn olùdarí ilé ẹ̀kọ́ náà tó ń jẹ́ Robert Emmons sọ pé: “Tá a bá máa moore lóòótọ́, àfi ká gbà pé igi kan ò lè dágbó ṣe, a nílò àwọn míì. Ìgbà míì wà tá a máa fún àwọn èèyàn ní nǹkan, ìgbà míì sì wà táwọn náà máa fún wa lẹ́bùn.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé a nílò àwọn míì ká lè wà láàyè ká sì máa láyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè fún wa lóúnjẹ, àwọn míì sì lè tọ́jú wa tá a bá ṣàìsàn. (1 Kọ́r. 12:21) Ẹni tó moore kì í fi bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ bò, ṣe lá máa dúpẹ́. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé ó mọ́ ẹ lára láti máa dúpẹ́ oore táwọn míì ṣe fún ẹ?
Ẹ̀MÍ ÌMOORE MÁA Ń JẸ́ KÍ NǸKAN RỌRÙN FÚN WA
Ìdí míì tó fi yẹ kó o máa dúpẹ́ ni pé á jẹ́ kó o pọkàn pọ̀ sórí nǹkan tó dáa dípò àwọn nǹkan tó kù díẹ̀ káàtó. Ẹ̀mí ìmoore máa jẹ́ kó o fojú tó tọ́ wo nǹkan dípò kó o máa ronú ṣáá nípa àwọn ìṣòro tó o ní. Tó o bá ṣe túbọ̀ ń moore, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa kíyè sí àwọn nǹkan dáadáa tó ń ṣẹlẹ̀. Tó o bá ń moore, á rọrùn fún ẹ láti fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa.”—Fílí. 4:4.
Tó o bá moore, o ò ní máa ronú nípa ohun tí kò yẹ kó o rò. Ẹ gbọ́ ná, ṣé èèyàn lè mọyì nǹkan tí Ọlọ́run ṣe fún un, kó sì tún máa ranjú mọ́ nǹkan táwọn míì ní, kó máa bínú sí wọn tàbí kó tiẹ̀ máa dinú? Àwọn tó moore kì í wa nǹkan máyà. Ohun tí wọ́n ní tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn kì í ronú bí wọ́n ṣe máa ní tibí ní tọ̀hún.—Fílí. 4:12.
MÁA RONÚ LÓRÍ ÀWỌN ÌBÙKÚN TÓ Ò Ń RÍ GBÀ!
Àwa Kristẹni mọ̀ pé Sátánì máa fẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì ká sì banú jẹ́ torí àwọn ìṣòro tá à ń kojú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Inú rẹ̀ máa dùn tó o bá ń ronú lódìlódì tó o sì ń ráhùn. Tó bá jẹ́ pé irú èèyàn bẹ́ẹ̀ ni ẹ́, ó máa ṣòro fáwọn èèyàn láti tẹ́tí sí ẹ lóde ẹ̀rí. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé tí o kò bá moore, o ò lè sọ pé ò ń fi èso tẹ̀mí hàn. Ìdí ni pé tó o bá ń dúpẹ́ àwọn oore tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ, wàá máa láyọ̀, ayọ̀ sì wà lára èso tẹ̀mí. Yàtọ̀ síyẹn, wàá tún nígbàgbọ́ nínú gbogbo ìlérí tí Jèhófà ṣe.—Gál. 5:22, 23.
Torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, ó dájú pé o gbà pé òótọ́ làwọn nǹkan tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí. Síbẹ̀, o mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti fi ìmoore hàn, kéèyàn sì gbà pé nǹkan ṣì máa dáa. Àmọ́, má ṣe jẹ́ kíyẹn mú kó o rẹ̀wẹ̀sì. O lè kọ́ béèyàn ṣe ń dúpẹ́ oore àti bó o ṣe lè fi ẹ̀mí ìmoore hàn. Lọ́nà wo? Lójoojúmọ́, máa ronú nípa àwọn nǹkan rere tó ò ń rí tó yẹ kó o dúpẹ́ fún. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ máa fi ìmoore hàn. Ìyẹn sì máa mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn fún ẹ ju àwọn tó jẹ́ pé ìṣòro wọn nìkan ni wọ́n ń gbájú mọ́ ṣáá. Máa ronú lórí àwọn nǹkan dáadáa tí Jèhófà àtàwọn míì ń ṣe fún ẹ tó ń múnú ẹ dùn. Kódà, o lè máa kọ wọ́n sínú ìwé kan. Máa kọ nǹkan méjì sí mẹ́ta tó múnú ẹ dùn lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́.
Àwọn kan tó ṣèwádìí sọ pé “tó bá ti mọ́ wa lára láti máa dúpẹ́ oore, á mú kó rọrùn fún ọpọlọ wa láti máa ro nǹkan tó dáa, àá sì máa láyọ̀.” Àwọn tó moore ló máa ń láyọ̀ jù. Torí náà, ronú lórí àwọn ìbùkún tó ò ń rí gbà. Ó ṣe tán wọ́n máa ń sọ pé ẹni tó bá mọnú rò á mọpẹ́ dá. Máa gbádùn àwọn nǹkan rere tó o ní báyìí, kó o sì máa fi ẹ̀mí ìmoore hàn nígbà gbogbo. Ìbùkún yòówù kó o rí gbà, dípò kó o kàn gbà pé ohun tó o lẹ́tọ̀ọ́ sí náà lo rí gbà, ṣe ni kó o “fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere.” Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ ká “máa dúpẹ́ ohun gbogbo.”—1 Kíró. 16:34; 1 Tẹs. 5:18.