Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 52

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà

“Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.”​—SM. 127:3.

ORIN 134 Ọmọ Jẹ́ Ohun Ìní Tí Ọlọ́run Fi Síkàáwọ́ Òbí

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Iṣẹ́ pàtàkì wo ni Jèhófà gbé fáwọn òbí?

JÈHÓFÀ dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó sì mú kó máa wù wọ́n láti bímọ. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Sm. 127:3) Kí lọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí? Ká sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ kan tọ́jú owó ńlá kan sí ẹ lọ́wọ́, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Ó dájú pé inú ẹ máa dùn pé ọ̀rẹ́ ẹ yìí fọkàn tán ẹ. Àmọ́ ó ṣeé ṣe káyà rẹ máa já kó o sì máa ronú nípa bó o ṣe máa tọ́jú owó náà tí nǹkan ò ní ṣe é. Lọ́nà kan náà, ohun kan wà tí Jèhófà tó jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ jù lọ fi sí ìkáwọ́ àwọn òbí, ohun tó fún wọn yìí sì ju owó lọ fíìfíì. Ó ní kí wọ́n tọ́jú àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì rí i dájú pé àwọn ọmọ náà láyọ̀.

2. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?

2 Ta ló yẹ kó pinnu bóyá kí tọkọtaya kan bímọ tàbí kí wọ́n má bímọ àtìgbà tó yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Kí làwọn òbí lè ṣe táá jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn láyọ̀? Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì mélòó kan tó máa ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání.

JẸ́ KÁWỌN TỌKỌTAYA ṢÈPINNU FÚNRA WỌN

3. (a) Ta ló máa pinnu bóyá kí tọkọtaya kan bímọ tàbí kí wọ́n má bímọ? (b) Ìlànà Bíbélì wo ló yẹ kí tẹbí-tọ̀rẹ́ fi sọ́kàn?

3 Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn èèyàn máa ń retí pé gbàrà tí tọkọtaya bá ti ṣègbéyàwó ló yẹ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. Kódà àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn míì lè máa fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n tètè bímọ. Arákùnrin Jethro tó ń gbé nílẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Nínú ìjọ, àwọn tọkọtaya tó ti lọ́mọ máa ń sọ fún àwọn tí kò tíì bímọ pé kí ni wọ́n ń dúró dè tí wọn ò fi tíì bímọ.” Arákùnrin Jeffrey, tóun náà ń gbé nílẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Àwọn míì máa ń sọ pé á dáa káwọn tọkọtaya tí kò tíì bímọ ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ọmọ ló máa tọ́jú wọn lọ́jọ́ ogbó, òun náà ló sì máa sin wọ́n tí wọ́n bá kú.” Bó ti wù kó rí, tọkọtaya kọ̀ọ̀kan ló máa dá pinnu bóyá wọ́n á bímọ tàbí wọn ò ní bímọ. Ọwọ́ wọn ni ìpinnu yẹn wà, ojúṣe wọn sì ni. (Gál. 6:​5, àlàyé ìsàlẹ̀) Lóòótọ́, ire tọkọtaya làwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ náà ń wá, àmọ́ ó yẹ kí wọ́n fi sọ́kàn pé ọwọ́ tọkọtaya náà ló wà láti pinnu bóyá àwọn máa bímọ tàbí àwọn ò ní bí.​—1 Tẹs. 4:11.

4-5. Kókó méjì wo ló yẹ kí tọkọtaya jíròrò pa pọ̀, ìgbà wo ló sì bọ́gbọ́n mu pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣàlàyé.

4 Ìbéèrè pàtàkì méjì kan wà tó yẹ káwọn tọkọtaya wá ìdáhùn sí tí wọ́n bá pinnu pé àwọn máa bímọ: Àkọ́kọ́, ìgbà wo ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ? Ìkejì, ọmọ mélòó ni wọ́n máa bí? Àmọ́, ìgbà wo ló bọ́gbọ́n mu pé kí tọkọtaya jọ sọ̀rọ̀ yìí? Kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n jọ fẹnu kò lórí ọ̀rọ̀ yìí?

5 Lọ́pọ̀ ìgbà, àsìkò tí wọ́n ń fẹ́ra sọ́nà ló bọ́gbọ́n mu jù pé kí wọ́n jọ pinnu bóyá àwọn máa bímọ tàbí àwọn ò ní bímọ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí kan ni pé á jẹ́ kí wọ́n lè gbọ́ ara wọn yé kí wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan. Yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá agbára àwọn á lè gbé ẹrù ọmọ títọ́ tàbí kò ní lè gbé e. Àwọn tọkọtaya kan pinnu pé àwọn á mú sùúrù fún ọdún kan tàbí méjì káwọn tó bímọ torí pé ọmọ títọ́ máa ń tánni lókun, ó sì ń gba ọ̀pọ̀ àkókò. Wọ́n gbà pé táwọn bá mú sùúrù díẹ̀, á jẹ́ káwọn túbọ̀ sún mọ́ra, káwọn sì túbọ̀ mọwọ́ ara àwọn.​—Éfé. 5:33.

6. Ìpinnu wo làwọn tọkọtaya kan ṣe torí àkókò tó nira tá à ń gbé yìí?

6 Àwọn Kristẹni kan ti pinnu pé àwọn á ṣe bíi tàwọn ọmọ Nóà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àtàwọn ìyàwó wọn. Kí làwọn ọmọ Nóà ṣe? Kì í ṣe gbàrà tí wọ́n ṣègbéyàwó ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. (Jẹ́n. 6:18; 9:​18, 19; 10:1; 2 Pét. 2:5) Jésù fi àkókò wa yìí wé bí “àwọn ọjọ́ Nóà” ṣe rí. Bẹ́yin náà ṣe mọ̀, ‘àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira’ là ń gbé yìí. (Mát. 24:37; 2 Tím. 3:1) Kókó yìí làwọn tọkọtaya kan fi sọ́kàn tí wọ́n fi pinnu pé àwọn ò ní tíì bímọ torí wọ́n gbà pé ìyẹn á mú káwọn lè túbọ̀ lo ara wọn fún iṣẹ́ Jèhófà.

Àwọn tọkọtaya tó gbọ́n máa ń “ṣírò ohun tó máa ná” wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ pinnu bóyá káwọn bímọ tàbí káwọn má bímọ àti iye ọmọ tí wọ́n máa bí (Wo ìpínrọ̀ 7) *

7. Báwo làwọn ìlànà tó wà nínú Lúùkù 14:​28, 29 àti Òwe 21:5 ṣe lè ran tọkọtaya lọ́wọ́?

7 Àwọn tọkọtaya tó gbọ́n máa ń “ṣírò ohun tó máa ná” wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ pinnu bóyá káwọn bímọ tàbí káwọn má bímọ àti iye ọmọ tí wọ́n máa bí. (Ka Lúùkù 14:​28, 29.) Àwọn tó ti tọ́mọ darí gbà pé ọmọ títọ́ máa ń náni lówó gan-an. Ìyẹn nìkan kọ́, ó máa ń tánni lókun, ó sì máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kí tọkọtaya bi ara wọn pé: ‘Ṣé àwa méjèèjì la máa ṣiṣẹ́ ká bàa lè gbọ́ bùkátà ìdílé wa? Kí làwọn “bùkátà” tá a gbọ́dọ̀ bójú tó? Tó bá jẹ́ pé àwa méjèèjì ló máa ṣiṣẹ́, ta ló máa bójú tó àwọn ọmọ wa tá ò bá sí nílé? Ta lá máa kọ́ wọn lóhun tí wọ́n á máa ṣe táá sì máa darí èrò wọn?’ Àwọn tọkọtaya tó gbọ́n máa ń fi ìlànà inú Òwe 21:5 sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ń jíròrò àwọn ìbéèrè yìí.​—Kà á.

Ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀ máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 8)

8. Àwọn ìṣòro tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ wo ló yẹ káwọn tọkọtaya fi sọ́kàn, kí ló sì yẹ kí ọkọ kan tó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ ṣe?

8 Ó ṣe pàtàkì kí ìyá àti bàbá máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì máa tọ́ wọn sọ́nà. Torí náà, tí tọkọtaya bá wẹ́ ọmọ jọ láàárín ọdún mélòó kan péré, ó lè ṣòro fún wọn láti wáyè fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ náà. Àwọn tọkọtaya tó wẹ́ ọmọ jọ gbà pé kò rọrùn rárá. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló lè rẹ ìyá bẹ́ẹ̀, kó sì máa kanra. Ṣérú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú kó nira fún un láti ráyè kẹ́kọ̀ọ́, láti gbàdúrà tàbí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé? Ìṣòro míì lèyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ nípàdé, kì í sábà rọrùn fáwọn ìyá ọlọ́mọ láti gbádùn ìpàdé. Àmọ́ ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ kò ní dá iṣẹ́ náà dá a yálà nílé tàbí nípàdé. Bí àpẹẹrẹ, irú ọkọ bẹ́ẹ̀ máa ń ran ìyàwó ẹ̀ lọ́wọ́ nínú ilé. Ó máa ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé, ó sì máa ń rí i pé ìyàwó ẹ̀ àtàwọn ọmọ gbádùn ìṣètò náà. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń bá ìdílé rẹ̀ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí déédéé.

KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ RẸ KÍ WỌ́N LÈ NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ

9-10. Kí ló ṣe pàtàkì pé káwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn ṣe?

9 Kí làwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe káwọn ọmọ wọn lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Báwo ni wọ́n ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn kí ayé èṣù yìí má bàa kó èèràn ràn wọ́n? Ẹ jẹ́ ká jíròrò díẹ̀ lára ohun táwọn òbí lè ṣe.

10 Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká wo ohun táwọn òbí Sámúsìnì ṣe, ìyẹn Mánóà àtìyàwó ẹ̀. Nígbà tí Mánóà gbọ́ pé ìyàwó òun máa lóyún, á sì bí ọmọkùnrin kan, ó bẹ Jèhófà pé kó tọ́ àwọn sọ́nà káwọn lè tọ́ ọmọ náà yanjú.

11. Báwo làwọn òbí ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Mánóà, bó ṣe wà nínú Àwọn Onídàájọ́ 13:8?

11 Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Nihad àti Alma, tí wọ́n ń gbé lórílẹ̀-èdè Bosnia àti Herzegovina tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Mánóà. Wọ́n sọ pé: “Bíi ti Mánóà, a bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká mọ ohun tá a máa ṣe ká lè jẹ́ òbí rere. Onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà sì gbà dáhùn àdúrà wa, ó tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ìtẹ̀jáde wa, ìpàdé ìjọ àtàwọn àpéjọ.”​—Ka Àwọn Onídàájọ́ 13:8.

12. Àpẹẹrẹ wo ni Jósẹ́fù àti Màríà fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn?

12 Fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀, àmọ́ ìwà wa gan-an ló máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ jù. Ó dájú pé àpẹẹrẹ rere ni Jósẹ́fù àti Màríà fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn títí kan Jésù. Jósẹ́fù ṣiṣẹ́ kára kó lè bójú tó ìdílé rẹ̀. Bákan náà, ó mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Diu. 4:​9, 10) Lóòótọ́ Òfin Mósè ò sọ pé dandan ni kí wọ́n kó tọmọ-tìyá dání tí wọ́n bá ń lọ sí Jerúsálẹ́mù “lọ́dọọdún” láti ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá, àmọ́ Jósẹ́fù ṣe bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 2:​41, 42) Àwọn olórí ìdílé kan lè ronú pé kò sídìí káwọn ṣe bẹ́ẹ̀ torí á tán àwọn lókun, á ná àwọn lówó, kò sì ní rọrùn. Àmọ́, ó ṣe kedere pé Jósẹ́fù mọyì nǹkan tẹ̀mí, ó sì kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, ẹ̀rí fi hàn pé Màríà mọ Ìwé Mímọ́ gan-an, ó sì dájú pé ó kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́rọ̀ àti níṣe láti nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

13. Báwo ni tọkọtaya kan ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù àti Màríà?

13 Nihad àti Alma tá a sọ̀rọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan sapá kí wọ́n lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù àti Màríà. Kí ni wọ́n ṣe kí ọmọ wọn lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Wọ́n ní: “A jẹ́ kí ọmọ wa rí i nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa pé àǹfààní wà nínú kéèyàn máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà.” Nihad fi kún un pé: “Ìwà tó o bá fẹ́ káwọn ọmọ rẹ̀ máa hù ni kíwọ náà máa hù.”

14. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí mọ àwọn táwọn ọmọ wọn ń bá ṣọ̀rẹ́?

14 Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè láwọn ọ̀rẹ́ tó dáa. Ó yẹ kí bàbá àti ìyá mọ àwọn táwọn ọmọ wọn ń bá ṣọ̀rẹ́ àtohun tí wọ́n ń ṣe. Ó yẹ kí wọ́n tún mọ àwọn tí wọ́n jọ ń kàn síra lórí ìkànnì àjọlò àtàwọn tí wọ́n ń bá sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Ìdí ni pé àwọn tí wọ́n ń bá rìn lè nípa lórí bí wọ́n ṣe ń ronú àti bí wọ́n ṣe ń hùwà, ó ṣe tán wọ́n máa ń sọ pé fi ọ̀rẹ́ rẹ hàn mí kí n lè sọ irú èèyàn tó o jẹ́.​—1 Kọ́r. 15:33.

15. Kí làwọn òbí lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jessie?

15 Kí làwọn òbí tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ẹ̀rọ ìgbàlódé lè ṣe láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́? Bàbá kan tó ń jẹ́ Jessie tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Philippines sọ pé: “A ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ẹ̀rọ ìgbàlódé. Àmọ́ ìyẹn ò ní ká má kìlọ̀ fáwọn ọmọ wa nípa ewu tó wà nínú lílo ẹ̀rọ ìgbàlódé.” Arákùnrin Jessie ò sọ pé káwọn ọmọ rẹ̀ má ṣe lo fóònù tàbí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé míì torí pé òun ò mọ̀ nípa ẹ̀. Ó ní: “Mo gba àwọn ọmọ mi níyànjú pé wọ́n lè lo àwọn ẹ̀rọ náà láti kọ́ èdè tuntun, láti múra ìpàdé sílẹ̀, wọ́n sì lè máa ka Bíbélì lórí wọn lójoojúmọ́.” Ẹ̀yin òbí, ṣé ẹ̀yin àtàwọn ọmọ yín ti jíròrò ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà ní abala “Ọ̀dọ́” lórí ìkànnì jw.org®? Àwọn àpilẹ̀kọ tó wà ní abala yẹn ṣàlàyé bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè máa lo fóònù àtohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀ tó bá di pé kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ àti fọ́tò ránṣẹ́ sẹ́lòmíì. Ṣé ẹ ti jọ wo fídíò Ṣé Fóònù Tàbí Tablet Ò Tíì Di Bárakú fún Ẹ? àti Máa Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò? * Àwọn ìsọfúnni yìí máa ràn yín lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ yín nípa bí wọ́n ṣe lè máa fọgbọ́n lo fóònù àtàwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé míì.​—Òwe 13:20.

16. Kí ni ọ̀pọ̀ ṣe fáwọn ọmọ wọn, àǹfààní wo ni wọ́n sì rí?

16 Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ti sapá kí àwọn ọmọ wọn lè dọ̀rẹ́ àwọn tó ń ṣe dáadáa nínú ètò Jèhófà. Àpẹẹrẹ kan ni ti tọkọtaya kan tó ń jẹ́ N’Déni àti Bomine lórílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire, wọ́n sábà máa ń gba alábòójútó àyíká lálejò nílé wọn. Arákùnrin N’Déni sọ pé: “Bá a ṣe ń gbà wọ́n lálejò mú kí ọmọ wa nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìsìn. Bó ṣe di pé ó gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé nìyẹn, ní báyìí ó ti di adelé alábòójútó àyíká.” Ṣé ìwọ náà lè ṣètò bí àwọn ọmọ rẹ á ṣe mú àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lọ́rẹ̀ẹ́?

17-18. Ìgbà wo ló yẹ káwọn òbí bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ wọn?

17 Àtikékeré ni kó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ rẹ. Ó ṣe pàtàkì káwọn òbí tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ wọn kó tó pẹ́ jù. (Òwe 22:6) Ronú nípa àpẹẹrẹ Tímótì tó láǹfààní láti bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò nígbà tó dàgbà. Ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni pé láti “kékeré jòjòló” ni ìyá rẹ̀ Yùníìsì àti Lọ́ìsì ìyá rẹ̀ àgbà ti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.​—2 Tím. 1:5; 3:15.

18 Orílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire ni tọkọtaya míì tó ń jẹ́ Jean-Claude àti Peace ń gbé, wọ́n sapá gan-an débi pé àwọn ọmọ wọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ló ń sin Jèhófà. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é? Àpẹẹrẹ Yùníìsì àti Lọ́ìsì ni wọ́n tẹ̀ lé. Wọ́n sọ pé: “Àtikékeré la ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ wa ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kódà a ò jẹ́ kó pẹ́ sígbà tá a bí wọn.”​—Diu. 6:​6, 7.

19. Kí lẹ̀yin òbí lè ṣe táá jẹ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ wọ àwọn ọmọ yín lọ́kàn?

19 Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè “kọ́ àwọn ọmọ” yín ní Ọ̀rọ̀ Jèhófà “léraléra”? Ìyẹn gba pé kẹ́ ẹ máa rán wọn létí ìlànà Ọlọ́run lásọtúnsọ láìjẹ́ kó sú yín. Kó lè ṣeé ṣe, ó ṣe pàtàkì kẹ́ ẹ máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Ó máa ń sú èèyàn tó bá di pé kéèyàn máa sọ ọ̀rọ̀ kan náà ṣáá. Àmọ́, á dáa kẹ́yin òbí wò ó bí ọ̀nà kan tẹ́ ẹ lè gbà gbin ẹ̀kọ́ òtítọ́ sọ́kàn àwọn ọmọ yín, táá sì jẹ́ kí wọ́n fi ẹ̀kọ́ náà sílò.

Ó yẹ káwọn òbí pinnu bí wọ́n ṣe máa tọ́ ọmọ kọ̀ọ̀kan dàgbà (Wo ìpínrọ̀ 20) *

20. Sọ bí Sáàmù 127:4 ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn òbí tó ń tọ́mọ lọ́wọ́.

20 Ẹ mọ àwọn ọmọ yín dáadáa. Sáàmù kẹtàdínláàádóje (127) fi àwọn ọmọ wé ọfà. (Ka Sáàmù 127:4.) Bó ṣe jẹ́ pé oríṣiríṣi nǹkan ni wọ́n lè fi ṣe ọfà, tí wọ́n sì máa ń gùn jura wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọ yàtọ̀ síra. Fún ìdí yìí, ó yẹ káwọn òbí pinnu bí wọ́n ṣe máa tọ́ ọmọ kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n má sì fi ọ̀kan wé èkejì. Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan lórílẹ̀-èdè Israel ní ọmọ méjì, àwọn méjèèjì ni wọ́n sì tọ́ yanjú nínú òtítọ́. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? Wọ́n ní: “A máa ń bá wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá wọ́n máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tàbí wọ́n máa ṣe é pa pọ̀.

JÈHÓFÀ MÁA RÀN YÍN LỌ́WỌ́

21. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ran ẹ̀yin òbí lọ́wọ́?

21 Nígbà míì, àwọn ìṣòro tẹ́yin òbí ń kojú lè mú kí nǹkan sú yín, àmọ́ ẹ rántí pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ọmọ jẹ́. Ó ṣe tán láti ràn yín lọ́wọ́, inú ẹ̀ sì máa ń dùn láti dáhùn àdúrà yín. Ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ Bíbélì, àwọn ìtẹ̀jáde àti nípasẹ̀ àpẹẹrẹ àti ìmọ̀ràn àwọn ará tó ti tọ́ ọmọ yanjú.

22. Kí làwọn ohun tó dáa jù tí òbí lè fún ọmọ?

22 Àwọn kan sọ pé ó máa ń gba ogún (20) ọdún kéèyàn tó lè tọ́ ọmọ kan yanjú, àmọ́ kókó ibẹ̀ ni pé òbí ni òbí á máa jẹ́ lọ́jọ́kọ́jọ́. Lára ohun tó dáa jù tẹ́yin òbí lè fún àwọn ọmọ yín ni ìfẹ́, àkókò yín àti ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ọmọ kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bó ṣe máa fàwọn ẹ̀kọ́ náà sílò. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn tí òbí Kristẹni tọ́ dàgbà ló sọ òtítọ́ di tiwọn bíi ti arábìnrin kan tó ń jẹ́ Joanna Mae nílẹ̀ Éṣíà. Ó sọ pé: “Tí mo bá rántí báwọn òbí mi ṣe tọ́ mi dàgbà, ṣe ni mo máa ń dúpẹ́ pé wọ́n kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ òtítọ́, wọ́n sì mú kí n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Òótọ́ ni pé wọ́n bí mi, àmọ́ ohun tí wọ́n ṣe fún mi jùyẹn lọ, wọ́n mú kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀.” (Òwe 23:​24, 25) Ó dájú pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára ọ̀pọ̀ wa náà nìyẹn.

ORIN 59 Jẹ́ Ká Yin Jáà

^ ìpínrọ̀ 5 Ṣé dandan ni pé káwọn tọkọtaya bímọ? Tí wọ́n bá sì pinnu pé àwọn máa bímọ, ọmọ mélòó ló yẹ kí wọ́n bí? Báwo ni wọ́n ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì pinnu pé Jèhófà làwọn máa sìn? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì táá jẹ́ ká rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, a sì tún máa rí àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní tí wọ́n ti tọ́mọ yanjú.

^ ìpínrọ̀ 15 Tún wo ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní, orí 36 àti Apá Kejì, orí 11.

^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN: Tọkọtaya kan ń jíròrò bóyá káwọn bímọ tàbí káwọn má bímọ. Wọ́n ń ronú nípa ayọ̀ àtàwọn ìṣòro téèyàn máa ń ní tó bá lọ́mọ.

^ ìpínrọ̀ 64 ÀWÒRÁN: Tọkọtaya kan ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ torí pé ọjọ́ orí wọn àti òye wọn yàtọ̀ síra.