Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 50

Jèhófà Ló Ń Fúnni Ní Òmìnira

Jèhófà Ló Ń Fúnni Ní Òmìnira

“Kí ẹ . . . kéde òmìnira fún gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà.”​—LÉF. 25:10.

ORIN 22 Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso​—Jẹ́ Kó Dé!

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. (a) Kí là ń pè ní Júbílì? (Wo àpótí náà,  “Kí Ni Ọdún Júbílì Táwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Máa Ń Ṣe?”) (b) Kí ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú Lúùkù 4:​16-18?

LÁWỌN ilẹ̀ kan, wọ́n máa ń ṣe àwọn àkànṣe ayẹyẹ nígbà tí olórí tàbí ọba wọn bá pé àádọ́ta (50) ọdún lórí oyè. Irú ọdún bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń pè ní ọdún Júbílì. Wọ́n lè fi odindi ọjọ́ kan tàbí ọ̀sẹ̀ kan ṣe ayẹyẹ náà, kódà ó lè ju bẹ́ẹ̀ lọ, àmọ́ bópẹ́ bóyá ayẹyẹ náà á kásẹ̀ ńlẹ̀, gbogbo pọ̀pọ̀ṣìnṣìn náà á sì dópin.

2 Àmọ́ Júbílì kan wà tó ju èyí táwọn orílẹ̀-èdè máa ń ṣe lọ, kódà ó ṣàǹfààní ju Júbílì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe fún odindi ọdún kan ní gbogbo àádọ́ta (50) ọdún. Àsìkò Júbílì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe yẹn ni wọ́n ti máa ń dá àwọn kan àtohun ìní wọn sílẹ̀ lómìnira. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ̀ nípa Júbílì yẹn? Ìdí ni pé ọdún Júbílì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe nígbà yẹn jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun kan tí Jèhófà ṣe fún wa. Ohun yìí ló máa jẹ́ ká ní òmìnira títí láé, ìyẹn sì ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.​—Ka Lúùkù 4:​16-18.

Inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń dùn lọ́dún Júbílì torí pé àwọn tó wà lóko ẹrú máa ń gba òmìnira, wọ́n á pa dà sọ́dọ̀ ìdílé wọn, wọ́n á sì gba ilẹ̀ wọn pa dà (Wo ìpínrọ̀ 3) *

3. Bó ṣe wà nínú Léfítíkù 25:​8-12, àǹfààní wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rí ní ọdún Júbílì?

3 Ká lè túbọ̀ lóye ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa òmìnira, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ọdún Júbílì tí Jèhófà ṣètò fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Jèhófà sọ fún wọn pé: “Kí ẹ ya ọdún àádọ́ta (50) sí mímọ́, kí ẹ sì kéde òmìnira fún gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà. Yóò di Júbílì fún yín, kálukú yín á pa dà sídìí ohun ìní rẹ̀, kálukú yín á sì pa dà sọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀.” (Ka Léfítíkù 25:​8-12.) Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a jíròrò báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jàǹfààní bí wọ́n ṣe ń pa Sábáàtì mọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àmọ́ àǹfààní wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí nínú ètò Júbílì tí Jèhófà ṣe? Ẹ jẹ́ ká sọ pé ọmọ Ísírẹ́lì kan jẹ gbèsè, ó wá di dandan pé kó ta ilẹ̀ rẹ̀ kó lè san gbèsè tó jẹ. Tó bá di ọdún Júbílì, wọ́n gbọ́dọ̀ dá ilẹ̀ náà pa dà fún un. Nípa bẹ́ẹ̀, á ṣeé ṣe fún ẹni tó ni ilẹ̀ náà láti “pa dà sídìí ohun ìní rẹ̀,” á sì rí ogún fi sílẹ̀ fáwọn ọmọ rẹ̀. Nígbà míì sì rèé, nǹkan lè nira fún ẹnì kan débi tó fi máa ta ọmọ rẹ̀ tàbí ara rẹ̀, á sì di ẹrú ẹni tó jẹ ní gbèsè. Tó bá di ọdún Júbílì, ẹrú náà máa “pa dà sọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀.” Torí náà, kò sí pé ẹnì kan ń fi gbogbo ayé rẹ̀ sìnrú fún ẹlòmíì láìnírètí! Ẹ ò rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ gan-an!

4-5. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ̀ nípa Júbílì?

4 Àǹfààní míì wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí nínú Júbílì? Jèhófà sọ pé: “Ẹnikẹ́ni nínú yín ò gbọ́dọ̀ tòṣì, torí ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ọ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún.” (Diu. 15:4) Ẹ wo bíyẹn ṣe yàtọ̀ pátápátá sóhun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí, táwọn olówó ń lówó sí i, táwọn òtòṣì sì túbọ̀ ń tòṣì!

5 Àwa Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè. Torí náà, a kì í ṣe ọdún Júbílì tí wọ́n ti máa ń dá ẹrú sílẹ̀ lómìnira, tí wọ́n máa ń fagi lé gbèsè tí wọ́n sì máa ń dá ilẹ̀ àwọn èèyàn pa dà. (Róòmù 7:4; 10:4; Éfé. 2:15) Síbẹ̀, ó yẹ ká mọ̀ nípa Júbílì. Kí nìdí? Ìdí ni pé bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó gbádùn òmìnira, Jèhófà ti ṣètò òmìnira fáwa náà lónìí.

JÉSÙ KÉDE ÒMÌNIRA

6. Ọ̀nà wo ni aráyé gbà jẹ́ ẹrú?

6 Gbogbo wa pátá la nílò kí wọ́n dá wa sílẹ̀ lómìnira torí pé a jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ìyẹn sì ni ìsìnrú tó burú jù. Torí pé a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ la ṣe ń darúgbó, tá à ń ṣàìsàn, tá a sì ń kú. Ìgbà táwọn kan bá lọ sọ́dọ̀ dókítà láti gba ìtọ́jú tàbí tí wọ́n bá wo dígí ni wọ́n máa ń rí i pé àwọn ti ń dàgbà. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń dùn wá tá a bá dẹ́ṣẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ara rẹ̀ pé òun di “ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tó wà nínú ara [òun].” Ó wá fi kún un pé: “Èmi abòṣì èèyàn! Ta ló máa gbà mí lọ́wọ́ ara tó ń kú lọ yìí?”​—Róòmù 7:​23, 24.

7. Òmìnira wo ni Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀?

7 A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ti ṣètò láti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀! Jésù sì ni Jèhófà lò láti dá wa sílẹ̀ lómìnira. Ní ohun tó lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún méje (700) kí Jésù tó wá sáyé, wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé òmìnira kan máa wáyé lọ́jọ́ iwájú, èyí tó ju òmìnira èyíkéyìí lọ. Ohun tí òmìnira yìí máa ṣàṣeparí ẹ̀ máa ju ti òmìnira táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbà lọ́dún Júbílì lọ. Wòlíì náà sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wà lára mi, torí Jèhófà ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn oníwà pẹ̀lẹ́. Ó rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn, láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú.” (Àìsá. 61:1) Ta ló mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ?

8. Ta ló mú àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà yẹn ṣẹ?

8 Ìgbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Àìsáyà sọ nípa òmìnira bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ. Nígbà tó lọ sínú sínágọ́gù tó wà ní Násárẹ́tì tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, ó ka àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà yẹn sétígbọ̀ọ́ àwọn Júù tó wà níbẹ̀. Jésù pe àwọn ọ̀rọ̀ inú àsọtẹ́lẹ̀ náà mọ́ ara rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà wà lára mi, torí ó ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn aláìní. Ó rán mi láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú, pé àwọn afọ́jú máa pa dà ríran, láti mú kí àwọn tí wọ́n tẹ̀ rẹ́ máa lọ lómìnira, láti wàásù ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.” (Lúùkù 4:​16-19) Báwo ni Jésù ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ?

ÀWỌN TÓ KỌ́KỌ́ GBA ÒMÌNIRA

Nínú sínágọ́gù tó wà ní Násárẹ́tì, Jésù kéde pé àwọn èèyàn máa gba òmìnira (Wo ìpínrọ̀ 8 àti 9)

9. Òmìnira wo làwọn èèyàn ń retí nígbà tí Jésù wà láyé?

9 Àsìkò tí Jésù ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn òmìnira tí Jésù kà jáde nínú àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà. Jésù jẹ́ kí èyí ṣe kedere nígbà tó sọ pé: “Òní ni ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ yìí ṣẹ.” (Lúùkù 4:21) Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù lọ́jọ́ yẹn lè máa ronú pé Jésù máa dá àwọn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìjọba Róòmù tó ń ṣàkóso wọn. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ronú bíi tàwọn méjì kan tó sọ pé: “Àwa ń retí pé ọkùnrin yìí ni ẹni tó máa gba Ísírẹ́lì sílẹ̀.” (Lúùkù 24:​13, 21) Bó ti wù kó rí, a mọ̀ pé kò sígbà tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n dìtẹ̀ sí ìjọba Róòmù tó ń fayé ni àwọn èèyàn lára. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n san “àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì.” (Mát. 22:21) Torí náà, báwo ni Jésù ṣe dá àwọn èèyàn sílẹ̀ lómìnira lásìkò yẹn?

10. Báwo ni Jésù ṣe dá àwọn èèyàn sílẹ̀ lómìnira?

10 Ọ̀nà méjì ni Jèhófà gbà lo Ọmọ rẹ̀ láti dá àwọn èèyàn sílẹ̀ lómìnira. Àkọ́kọ́, Jésù mú kí wọ́n mọ̀ pé ẹ̀kọ́ èké làwọn aṣáájú ìsìn wọn fi ń kọ́ wọn. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ọ̀pọ̀ Júù ni wọ́n fipá mú láti gba ẹ̀kọ́ èké gbọ́, tí wọ́n sì ń lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Òfin Ọlọ́run mu. (Mát. 5:​31-37; 15:​1-11) Afọ́jú lásán-làsàn ni àwọn tó pera wọn ní afinimọ̀nà yẹn. Kí nìdí? Torí pé wọ́n kọ Jésù ní Mèsáyà, tí wọn ò sì gbà pé kó tọ́ àwọn sọ́nà, inú òkùnkùn biribiri ni wọ́n wà, wọn ò sì ní rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Jòh. 9:​1, 14-16, 35-41) Torí pé Jésù kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́, tó sì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀, ó ṣeé ṣe fáwọn oníwà pẹ̀lẹ́ láti ní òmìnira nípa tẹ̀mí.​—Máàkù 1:22; 2:23–3:5.

11. Sọ ọ̀nà kejì tí Jésù gbà dá aráyé sílẹ̀ lómìnira.

11 Ọ̀nà kejì tí Jésù gbà dá aráyé sílẹ̀ lómìnira ni bó ṣe mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún. Àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, tó sì ń hàn nínú ìgbésí ayé wọn ló máa rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Héb. 10:​12-18) Jésù sọ pé: “Tí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira, ẹ máa di òmìnira lóòótọ́.” (Jòh. 8:36) Òmìnira yìí kọjá òmìnira èyíkéyìí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń gbà lọ́dún Júbílì. Bí àpẹẹrẹ, béèyàn kan bá gba òmìnira lọ́dún Júbílì, ó sì lè tún pa dà di ẹrú. Yàtọ̀ síyẹn, bópẹ́ bóyá ó ṣì máa kú.

12. Àwọn wo ló kọ́kọ́ jàǹfààní òmìnira tí Jésù kéde?

12 Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn àpọ́sítélì Jésù àtàwọn olóòótọ́ míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ó tipa bẹ́ẹ̀ sọ wọ́n di ọmọ rẹ̀, tó bá sì tó àkókò, á jí wọn dìde sí ọ̀run kí wọ́n lè bá Jésù ṣàkóso. (Róòmù 8:​2, 15-17) Àwọn ló kọ́kọ́ jàǹfààní nínú òmìnira tí Jésù kéde nínú sínágọ́gù tó wà ní Násárẹ́tì. Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ àwọn amúnisìn, ìyẹn àwọn aṣáájú ìsìn Júù tí wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni tí wọ́n sì ń fipá mú àwọn èèyàn láti lọ́wọ́ nínú àṣà tí kò bá òfin Ọlọ́run mu. Bákan náà, wọ́n ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Júbílì ìṣàpẹẹrẹ yìí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, ó sì máa dópin nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá parí. Àwọn nǹkan rere wo ni Kristi ti máa ṣàṣeparí ẹ̀ lópin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀?

Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN ṢÌ MÁA LÓMÌNIRA

13-14. Yàtọ̀ sáwọn ẹni àmì òróró, àwọn wo ló tún máa jàǹfààní òmìnira tí Jésù kéde?

13 Lónìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tí wọ́n wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè ló wà lára àwọn tí Bíbélì pè ní “àgùntàn mìíràn.” (Jòh. 10:16) Wọn ò sí lára àwọn tí Jèhófà yàn láti bá Jésù jọba lọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni pé wọ́n á láǹfààní àtiwà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Ṣé ìrètí tó o ní nìyẹn?

14 Kódà, àwọn àǹfààní kan wà tó ò ń gbádùn báyìí bíi tàwọn tó máa bá Jésù jọba lọ́run. Torí pé o nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, o lè bẹ Jèhófà pé kó dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. Ìyẹn á mú kó o ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, wàá sì tún ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Éfé. 1:7; Ìfi. 7:​14, 15) Tún ronú nípa òmìnira tó o ní torí pé o ò gba ẹ̀kọ́ èké gbọ́, o ò sì lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu. Jésù sọ pé: “Ẹ ó mọ òtítọ́, òtítọ́ á sì sọ yín di òmìnira.” (Jòh. 8:32) Ẹ wo bí inú wa ṣe ń dùn pé a ní irú òmìnira bẹ́ẹ̀!

15. Òmìnira àti ìbùkún wo la máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú?

15 O ṣì máa gbádùn òmìnira tó ju èyí tó ò ń gbádùn báyìí lọ. Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, Jésù máa pa gbogbo ìsìn èké àtàwọn alákòóso burúkú run. Bákan náà, Ọlọ́run máa dáàbò bo “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín, á sì rọ̀jò ìbùkún lé wọn lórí nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Ìfi. 7:​9, 14) Ọlọ́run máa jí ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ èèyàn dìde, wọ́n á sì bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù.​—Ìṣe 24:15.

16. Òmìnira tó ju òmìnira lọ wo ni aráyé máa rí gbà lọ́jọ́ iwájú?

16 Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Jésù àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣàkóso máa mú kí aráyé ní ìlera pípé, kí wọ́n sì ní àjọṣe tó túbọ̀ dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. Àsìkò yẹn máa dà bí ọdún Júbílì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe. Gbogbo èèyàn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn á ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n á sì ti di pípé.

Nínú ayé tuntun, a máa gbádùn iṣẹ́ tá à ń ṣe (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ló wà nínú Àìsáyà 65:​21-23? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

17 Àsọtẹ́lẹ̀ bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú ayé tuntun wà nínú Àìsáyà 65:​21-23. (Kà á.) Lásìkò yẹn, kò sẹ́ni táá káwọ́ gbera láìṣiṣẹ́ tàbí tó máa jẹ́ ọ̀lẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì fi hàn pé àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà nígbà yẹn á máa ṣe iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀. Tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà bá parí, Ọlọ́run máa “dá ìṣẹ̀dá fúnra rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹrú ìdíbàjẹ́, kí ó sì lè ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”​—Róòmù 8:21.

18. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé àsìkò ìtura ṣì máa dé?

18 Bí Jèhófà ṣe ṣètò pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣiṣẹ́ kí wọ́n sì máa wáyè sinmi, ó dájú pé bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa rí nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. A máa ní àkókò láti jọ́sìn Jèhófà. Ó ṣe tán, ìjọsìn Ọlọ́run ṣe pàtàkì téèyàn bá máa láyọ̀ lónìí, bó sì ṣe máa rí nìyẹn nínú ayé tuntun. Ó ṣe kedere pé gbogbo àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin máa gbádùn lábẹ́ àkóso Kristi torí pé wọ́n á máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n sì ń jọ́sìn Jèhófà.

ORIN 142 Ká Jẹ́ Kí Ìrètí Wa Lágbára

^ ìpínrọ̀ 5 Jèhófà ṣe ètò àkànṣe kan fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ kí wọ́n lè gbádùn òmìnira. Ètò yẹn ni Bíbélì pè ní Júbílì. Òótọ́ ni pé àwa Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, síbẹ̀ a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ètò Júbílì náà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí Júbílì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe láyé àtijọ́ ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun kan tí Jèhófà ṣe fún wa àti bó ṣe ṣe wá láǹfààní.

^ ìpínrọ̀ 61 ÀWÒRÁN: Lọ́dún Júbílì, wọ́n máa ń dá àwọn tó wà lóko ẹrú sílẹ̀ lómìnira, wọ́n á pa dà sọ́dọ̀ ìdílé wọn, wọ́n á sì gba ilẹ̀ wọn pa dà.