Ǹjẹ́ O Rántí?
Ṣé o lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó dá lórí àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lọ́dún 2019?
Kí ni ìlérí tí Jèhófà ṣe yìí túmọ̀ sí: “Ohun ìjà èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe sí ọ kò ní ṣàṣeyọrí”? (Àìsá. 54:17)
Ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ “ẹ̀fúùfù òjijì àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀.” (Àìsá. 25:4, 5) Ó sì dájú pé àwọn ọ̀tá wa kò ní lè pa wá run.—w19.01, ojú ìwé 6 àti 7.
Kí ló fi hàn pé Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo nínú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Kénáánì àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ aláìgbọràn?
Jèhófà dẹ́bi fáwọn tó ń lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe àtàwọn tó ń fojú pọ́n àwọn obìnrin àtàwọn ọmọ tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jèhófà máa ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n bá pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọ́n sì ń ṣèdájọ́ òdodo.—w19.02, ojú ìwé 22 àti 23.
Kí ló yẹ ká ṣe tí ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ń gbàdúrà?
A lè dákẹ́ ká sì fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún wọn. Àmọ́, a ò ní bá wọn ṣàmín tàbí ká di àwọn tó kù lọ́wọ́ mú bí àdúrà náà ṣe ń lọ. A lè pinnu láti gbàdúrà tiwa sínú.—w19.03, ojú ìwé 31.
Báwo ni bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe ṣe burú tó?
Ìwà ìkà lẹni tó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe hù sí ọmọ náà, ó sì tún ṣẹ̀ sí ìjọ. Yàtọ̀ síyẹn, ìwà ọ̀daràn lẹni tó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe hù, ó tàpá sí òfin ìjọba, ó sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. Láwọn ilẹ̀ tí wọ́n bá ti ṣòfin pé kí wọ́n fi ẹ̀sùn bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe tó ìjọba létí, àwọn alàgbà máa ń pa òfin náà mọ́, wọ́n á sì rí i pé ọ̀rọ̀ náà dé etí ìjọba.—w19.05, ojú ìwé 9 àti 10.
Báwo lo ṣe lè yí pa dà tàbí yí agbára tó ń darí ìrònú rẹ pa dà?
Àwọn ohun pàtàkì tó o lè ṣe ni pé: Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Máa ṣàṣàrò kó o lè mọ àwọn ìyípadà tó yẹ kó o ṣe nínú èrò àti ìṣe rẹ, kó o sì rí i pé àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lo yàn lọ́rẹ̀ẹ́.—w19.06, ojú ìwé 11.
Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ de inúnibíni?
Máa ṣe ohun táá mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀, kò sì ní fi wá sílẹ̀ láé. Máa ka Bíbélì déédéé kó o sì máa gbàdúrà. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ìjọba Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣẹ. Há àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o fẹ́ràn sórí àtàwọn orin Ìjọba Ọlọ́run.—w19.07, ojú ìwé 2 sí 4.
Báwo la ṣe lè ran àwọn mọ̀lẹ́bí wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìgbàlà?
Ó yẹ ká máa gba tiwọn rò, ká sì máa hùwà tó dáa ká lè yí wọn lérò pa dà. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká máa mú sùúrù ká sì fọgbọ́n ṣe é tá a bá ń wàásù fún wọn.—w19.08, ojú ìwé 15 sí 17.
Báwo ni Jésù ṣe ń tù wá lára bó ṣe wà nínú Mátíù 11:28?
Àwọn alábòójútó tó nífẹ̀ẹ́ wa dénú ló ń bójú tó wa, àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa jù la ní, iṣẹ́ tó dáa jù la sì ń ṣe.—w19.09, ojú ìwé 23.
Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń mú kó máa wù wá láti gbé ìgbésẹ̀, tó sì ń fún wa ní agbára láti ṣe é? (Fílí. 2:13)
Bá a ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, Jèhófà máa ń mú kó wù wá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó sì ń fún wa lágbára tá a máa fi ṣe é. Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ máa ń ràn wá lọ́wọ́ kí ẹ̀bùn àbínibí wa lè túbọ̀ wúlò.—w19.10, ojú ìwé 21.
Àwọn ìgbésẹ̀ wo ló yẹ kó o gbé kó o tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì?
Àwọn ìgbésẹ̀ márùn-ún tó yẹ kó o gbé rèé: Ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀. Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n. Mọ ìdí tó o fi ṣèpinnu. Mọ ohun tó o fẹ́ ṣe gan-an. Má tanra ẹ jẹ.—w19.11, ojú ìwé 27 sí 29.
Ṣé ọ̀rọ̀ tí Sátánì sọ fún Éfà nínú ọgbà Édẹ́nì ló bí ẹ̀kọ́ èké nípa àìleèkú ọkàn?
Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Èṣù ò sọ fún Éfà pé tó bá jẹ èso tí Ọlọ́run ní kí wọ́n má jẹ, ó kàn máa dà bíi pé ó kú ni àmọ́ kò kú. Ó ṣe kedere nígbà náà pé ẹ̀yìn Ìkún Omi ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn táwọn èèyàn fi ń kọ́ni lónìí bẹ̀rẹ̀. Kò sí àní-àní pé ìgbà tí Ọlọ́run da èdè àwọn èèyàn rú ní Bábélì tí wọ́n sì tú ká “sí gbogbo ayé” ni wọ́n tan ẹ̀kọ́ èké nípa àìleèkú ọkàn kálẹ̀.—w19.12, ojú ìwé 15.