Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Bíbélì sọ pé ẹni méjì gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ kan kí wọ́n tó lè fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀. (Nọ́ń. 35:30; Diu. 17:6; 19:15; Mát. 18:16; 1 Tím. 5:19) Àmọ́ lábẹ́ Òfin Mósè, tí ọkùnrin kan bá fipá bá ọ̀dọ́bìnrin tó ti ní àfẹ́sọ́nà lòpọ̀ ní “inú oko” tí obìnrin náà sì pariwo tàbí lọgun, òfin sọ pé ọkùnrin náà jẹ̀bi ẹ̀sùn àgbèrè, àmọ́ obìnrin náà ò jẹ̀bi rárá. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọkùnrin yẹn nìkan ló jẹ̀bi, nígbà tí ẹlẹ́rìí ò pé méjì?

Tá a bá wo ohun tó wà nínú Diutarónómì 22:​25-27 dáadáa, kì í ṣe pé bóyá ọkùnrin yẹn jẹ̀bi tàbí kò jẹ̀bi ló ń sọ nítorí pé àkọsílẹ̀ yẹn ti jẹ́ kó ṣe kedere pé ó jẹ̀bi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí òfin yẹn ń sọ ni bí wọ́n ṣe máa fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé obìnrin náà ò jẹ̀bi. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ yìí ká.

Àwọn ẹsẹ tó ṣáájú sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó bá obìnrin tó ti ní àfẹ́sọ́nà lòpọ̀ “nínú ìlú.” Ohun tó ṣe yìí fi hàn pé àgbèrè ló ṣe torí pé ojú ẹni tó ti lọ́kọ ni wọ́n fi máa ń wo obìnrin tó ti ní àfẹ́sọ́nà. Àmọ́ ṣé obìnrin náà jẹ̀bi? Bíbélì sọ pé: “Kò kígbe nínú ìlú.” Ká sọ pé ó kígbe ni, ó ṣeé ṣe káwọn míì tó wà nínú ìlú yẹn gbọ́, kí wọ́n sì gbà á sílẹ̀. Àmọ́ torí pé kò kígbe, òun náà ti ṣe àgbèrè. Fún ìdí yìí, àwọn méjèèjì ló jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.​—Diu. 22:​23, 24.

Òfin náà wá sọ̀rọ̀ nípa nǹkan míì tó lè ṣẹlẹ̀, ó ní: “Àmọ́ tó bá jẹ́ inú oko ni ọkùnrin náà ká obìnrin tó ní àfẹ́sọ́nà yẹn mọ́, tí ọkùnrin náà sì fi agbára mú un, tó sì bá a sùn, ọkùnrin tó bá a sùn yẹn nìkan ni kí ẹ pa, àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun fún obìnrin náà. Obìnrin náà kò dá ẹ̀ṣẹ̀ tó gba pé kí ẹ pa á. Ṣe ni ọ̀rọ̀ yìí dà bíi ti ọkùnrin kan tó lu ẹnì kejì rẹ̀, tó sì pa á. Torí pé inú oko ló ká obìnrin náà mọ́, obìnrin tó ti ní àfẹ́sọ́nà yẹn sì kígbe, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè gbà á sílẹ̀.”​—Diu. 22:​25-27.

Pẹ̀lú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí, àwọn adájọ́ gbà pé òótọ́ ni obìnrin náà sọ. Lọ́nà wo? Wọ́n gbà pé ó “kígbe, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè gbà á sílẹ̀.” Torí náà, obìnrin náà ò ṣàgbèrè. Àmọ́ ọkùnrin yẹn máa jẹ̀bi pé ó fipá bá obìnrin tó ní àfẹ́sọ́nà lò pọ̀, ó sì ṣàgbèrè, torí pé ṣe ló “fi agbára mú un, tó sì bá a sùn.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí òfin yìí tẹnu mọ́ ni pé obìnrin yẹn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn àgbèrè, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé ṣe ni ọkùnrin yẹn fipá bá obìnrin náà lò pọ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ̀bi àgbèrè. Kò sí àní-àní pé àwọn tó bójú tó ẹjọ́ náà máa “wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa” wọ́n á sì ṣèdájọ́ níbàámu pẹ̀lú ìlànà tí Ọlọ́run sọ fún wọn léraléra.​—Diu. 13:14; 17:4; Ẹ́kís. 20:14.